Torí pé ìkọ̀sílẹ̀ wọ́pọ̀ gan-an, ó ṣeé ṣe kó o mọ ẹnì kan tàbí ọ̀pọ̀ èèyàn tí ọkọ tàbí aya wọn ti kọ̀ sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Poland fi hàn pé àwọn ọmọ ọgbọ̀n [30] ọdún tó ti ṣègbéyàwó fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta sí mẹ́fà ló ṣeé ṣe jù lọ pé kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀. Àmọ́ o, kì í ṣe àwọn ọmọ ọgbọ̀n ọdún nìkan ló ń kọra wọn sílẹ̀.

Kódà, Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìdílé lórílẹ̀-èdè Sípéènì sọ pé, “ìròyìn fi hàn pé ìdajì lára àwọn tó ṣègbéyàwó [nílẹ̀ Yúróòpù] ló máa kọra wọn sílẹ̀. Bí ọ̀ràn sì ṣe rí láwọn orílẹ̀-èdè míì tó ti gòkè àgbà nìyẹn.

ONÍRÚURÚ ÈRÒ MÁA Ń GBÀ WỌ́N LỌ́KÀN

Kí ló fà á tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi wọ́pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Obìnrin kan tó wá láti Ìlà Oòrùn Yúróòpù tó sì ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ gbígba àwọn tó ṣègbéyàwó nímọ̀ràn sọ pé: “Ńṣe ni ìkọ̀sílẹ̀ wulẹ̀ ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ilé, pé àárín tọkọtaya kò gún mọ́ àti pé wọ́n ti dẹ̀yìn kọra wọn, èyí tó máa ń dá ọgbẹ́ ọkàn ńláǹlà sílẹ̀.” Ó wá sọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ní: “Ńṣe ni ẹ̀dùn ọkàn máa ń gorí ẹ̀dùn ọkàn tó fi jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n á máa bínú, wọ́n á máa kábàámọ̀, wọ́n á ní ìjákulẹ̀, nǹkan á tojú sú wọn, ojú á sì máa tì wọ́n. Nígbà míì, ìyẹn máa ń mú kí wọ́n fẹ́ láti gbẹ̀mí ara wọn. Tó bá wá di pé ilé ẹjọ́ tú irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ ká, ìgbà yẹn gan-an ni ìgbé ayé míì á wá bẹ̀rẹ̀. Nǹkan lè tojú sú ẹni tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ náà kó sì gbà pé òun ò rẹ́ni fojú jọ. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè máa ronú pé: ‘Ní báyìí tí ọkọ tàbí aya mi ti kọ̀ mí sílẹ̀, kí lèmi fúnra mi já mọ́? Kí ni mò ń gbélé ayé ṣe?’”

Nígbà tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Ewa ń sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ó sọ pé: “Ojú tì mí wẹ̀lẹ̀mù lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó wa ká. Mo wá ń ronú pé ní báyìí, àwọn aládùúgbò mi àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ á máa tọ́ka sí mi pé ‘ará ilé rẹ ò mà sí lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ mọ́.’ Kódà, inú máa ń bí mi gan-an. Ọmọ méjì ló já jù sílẹ̀ fún mi, bó ṣe di pé ẹrù ẹni méjì di tèmi nìkan nìyẹn o.” * Arákùnrin Adam, tó jẹ́ alàgbà táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún dáadáa, tó sì ti fi ọdún méjìlá sìn nípò yẹn, sọ pé: “Mo wá dẹni àbùkù débi pé láwọn ìgbà míì ṣe ni inú mi máa ń ru fún ìbínú, mo sì máa ń fẹ́ ya ara mi láṣo.”

WỌ́N Ń SAPÁ KÍ NǸKAN LÈ BỌ́ SÍPÒ

Kódà, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí ìkọ̀sílẹ̀ ti wáyé, àwọn kan tí àníyàn ọjọ́ iwájú ti gbà lọ́kàn ṣì ń wá bí nǹkan á ṣe pa dà bọ́ sípò. Wọ́n lè rò pé àwọn èèyàn ò rí tàwọn rò mọ́. Síwájú sí i, ẹnì kan tó máa ń kọ ìròyìn lórí ìkọ̀sílẹ̀ sọ pé ní báyìí, ṣe ni wọ́n ní láti “yí àwọn ohun tó ti mọ́ wọn lára pa dà kí wọ́n sì kọ́ bí wọ́n á ṣe máa dá bójú tó ìṣòro wọn.”

Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Stanisław sọ pé: “Nígbà témi àtìyàwó mi kọ ara wa sílẹ̀, kì í jẹ́ kí n rí àwọn ọmọbìnrin  wa kékeré méjèèjì mọ́. Ìyẹn mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé kò sí ẹni tó rí tèmi rò mọ́ àti pé Jèhófà alára ti pa mí tì. Ayé sú mi. Nígbà tó ṣe, mo wá rí i pé èrò mi ò tọ̀nà rárá.” Bákan náà, wàhálà bá arábìnrin kan tó ń jẹ́ Wanda torí pé kò mọ ibi tó máa gbé ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ gbà lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ó sọ pé: “Lójú ara mi, mo gbà pé lẹ́yìn àkókò díẹ̀, àwọn èèyàn ò ní rí tèmi àti tàwọn ọmọ mi rò mọ́, kódà mo ronú pé àwọn tá a jọ jẹ́ ará máa pa wá tì ni. Àmọ́, mo ti wá rí i báyìí pé ńṣe làwọn ará dúró tì mí tí wọ́n sì ń ràn mí lọ́wọ́ bí mo ṣe ń sapá láti tọ́ àwọn ọmọ mi kí wọ́n lè máa sin Jèhófà.”

O lè fòye mọ̀ látinú ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ yìí pé lẹ́yìn ìkọ̀sílẹ̀, ńṣe ni èrò òdì máa ń gba àwọn tí ìgbéyàwó wọn ti tú ká lọ́kàn. Wọ́n lè máa fi ojú tí kò tọ́ wo ara wọn, kí wọ́n máa ronú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan àti pé àwọn ò yẹ lẹ́ni táwọn èèyàn ń kà sí. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àríwísí àwọn tó sún mọ́ wọn. Látàrí ìyẹn, wọ́n lè máa ronú pé àwọn tó wà nínú ìjọ ò nífẹ̀ẹ́ àti pé wọn ò ní ẹ̀mí ìgbatẹnirò. Síbẹ̀, àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Stanisław àti Wanda fi hàn pé àwọn tí ọkọ tàbí aya wọn kọ̀ sílẹ̀ lè pa dà wá rí i pé àwọn ará ò fọ̀rọ̀ àwọn ṣeré rárá. Kódà, ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ làwọn ará máa ń fi hàn sírú àwọn bẹ́ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tọ́rọ̀ kàn lè má tètè kíyè sí i.

OHUN TÓ O LÈ ṢE BÓ BÁ Ń ṢE Ẹ́ BÍI PÉ O KÒ LẸ́NÌ KAN

Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé bó ti wù ká sapá tó, látìgbàdégbà ó lè máa ṣe àwọn tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ bíi pé àwọn ò lẹ́nì kan. Àgàgà tó bá jẹ́ pé obìnrin ni onítọ̀hún, ó lè máa rò pé ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn tó rí tòun rò. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Alicja gbà pé: “Ọdún kẹjọ rèé tí ọkọ mi ti kọ̀ mí sílẹ̀. Síbẹ̀, ìgbà míì wà tó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan. Láwọn ìgbà bẹ́ẹ̀, ó máa ń ṣe mí bíi kí n ya ara mi láṣo, mo máa n sunkún, mo sì máa ń káàánú ara mi.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wọ́pọ̀ kí ẹni tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ ní ìmọ̀lára bí èyí, Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe ya ara wa láṣo. Béèyàn ò bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, ó lè mú kó kọ “gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́.” (Òwe 18:1) Àmọ́, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o kò lẹ́nì kan, ohun kan wà tó yẹ kó o kíyè sí. Tó o bá jẹ́ obìnrin, kò bọ́gbọ́n mu kó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ọkùnrin ni wàá ti máa gba ìmọ̀ràn ṣáá, tó o bá sì jẹ́ ọkùnrin, má ṣe sọ obìnrin di agbọ̀ràndùn rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, ọkàn yín ò ní bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí àtibára yín ṣèṣekúṣe.

Òótọ́ ni pé onírúurú èrò lè máa gba àwọn ará wa tí ọkọ tàbí aya wọn ti kọ̀ sílẹ̀ lọ́kàn, kí wọ́n máa ṣàníyàn nípa ọjọ́ iwájú kó sì máa ṣe wọ́n bíi pé wọn ò lẹ́nì kan. Bá a ṣe mọ̀ pé irú àwọn ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ tá a sì tún mọ̀ pé ó lè nira fún wọn láti borí àwọn ìṣòro tó máa ń yọjú, ńṣe ló yẹ ká fìwà jọ Jèhófà nípa jíjẹ́ kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa mọ̀ pé adúrótini ni wá lọ́jọ́ ìṣòro. (Sm. 55:22; 1 Pét. 5:6, 7) Ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé wọ́n á mọrírì ìrànlọ́wọ́ tá a bá ṣe fún wọn gidigidi. Ó dájú pé àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tó wà nínú ìjọ á ràn wọ́n lọ́wọ́.—Òwe 17:17; 18:24.

^ ìpínrọ̀ 6 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.