Ṣó o ti fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

Àkókò wo gan-an ní Nísàn 14 ló yẹ kí wọ́n pa ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá?

Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan sọ pé “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì náà,” ìyẹn ní wíríwírí ọjọ́ tàbí ní ọwọ́ alẹ́ lẹ́yìn tí oòrùn ti wọ̀ àmọ́ tí ilẹ̀ kò tíì ṣú ló yẹ kí wọ́n pa ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá. (Ẹ́kís. 12:6)—12/15, ojú ìwé 18 sí 19.

Àwọn ìlànà Bíbélì wo làwọn ọ̀dọ́ lè lò táá mú kí wọ́n yan àwọn ohun tó bọ́gbọ́n mu?

Mẹ́ta nínú wọn rèé (1) Máa wá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́. (Mát. 6:19-34) (2) Máa ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíì kó o lè láyọ̀. (Ìṣe 20:35) (3) Gbádùn sísin Ọlọ́run nígbà tó o ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. (Oníw. 12:1)—1/15, ojú ìwé 19 sí 20.

Àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin wo ni wọ́n ti ń gẹṣin lọ láti ọdún 1914?

Jésù ni ẹni tó gun ẹṣin funfun, ó sì ti lé Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò ní ọ̀run. Ẹni tó gun ẹṣin aláwọ̀ iná ń ṣàpẹẹrẹ àwọn ogun tó ti pọ́n aráyé lójú. Ẹni tó gun ẹṣin dúdú ń ṣàpẹẹrẹ ìyàn. Ẹni tó gun ẹṣin ràndánràndán ń fi àjàkálẹ̀ àrùn pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún mílíọ̀nù èèyàn. (Ìṣí. 6:2-8)—2/1, ojú ìwé 6 sí 7.

Ìgbà wo ni “ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn” náà máa wáyé? (Ìṣí. 19:7)

“Ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn” náà máa wáyé lẹ́yìn tí Ọba náà Jésù Kristi bá parí ìṣẹ́gun rẹ̀, ìyẹn lẹ́yìn tí Bábílónì Ńlá bá ti pa run, tí ogun Amágẹ́dọ́nì sì ti jà.—2/15, ojú ìwé 10.

Kí nìdí tí àwọn Júù tó wà nígbà ayé Jésù fi ń “fojú sọ́nà” fún Mèsáyà? (Lúùkù 3:15)

A kò rí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní lóye àsọtẹ́lẹ̀ tí Dáníẹ́lì sọ nípa Mèsáyà bí àwa ṣe lóye rẹ̀. (Dán. 9:24-27) Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti gbọ́ ohun tí áńgẹ́lì náà sọ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn kan tàbí ohun tí Ánà wòlíì obìnrin sọ nígbà tí ó rí ọmọ jòjòló náà, Jésù, ní tẹ́ńpìlì. Bákan náà, àwọn awòràwọ̀ wá, wọ́n sì ń béèrè nípa “ẹni tí a bí ní ọba àwọn Júù.” (Mát. 2:1, 2) Nígbà tó yá, Jòhánù Arinibọmi náà wàásù pé Kristi máa tó fara hàn.—2/15, ojú ìwé 26 sí 27.

Kí la lè ṣe tí Bẹ́ẹ̀ ni wa kò fi ní di Bẹ́ẹ̀ kọ́? (2 Kọ́r. 1:18)

Òótọ́ ni pé láwọn ìgbà míì, ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan lè mú ká wọ́gi lé àdéhùn kan tá a ṣe. Àmọ́ tá a bá ṣe ìlérí tàbí àdéhùn kan, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká lè pa àdéhùn náà mọ́.—3/15, ojú ìwé 32.

Kí la lè ṣe tá ò fi ní kó sínú ìdẹwò láti wo àwòrán oníhòòhò?

Nǹkan mẹ́ta tó máa ràn wá lọ́wọ́ rèé (1) Ká tètè gbójú wa kúrò tá a bá ṣèèṣì rí àwòrán ìṣekúṣe fìrí. (2) Ká fi àwọn èrò tó dára kún ọkàn wa ká sì gbàdúrà sí Ọlọ́run ká bàa lè gbọ́kàn kúrò lórí èròkerò. (3) Ká má ṣe rin ìrìnkurìn, ìyẹn ni pé ká má ṣe wo àwọn fíìmù tàbí lọ sórí ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ń gbé àwòrán ìṣekúṣe jáde.—4/1, ojú ìwé 10 sí 12.

Àwọn àbájáde àìròtẹ́lẹ̀ wo ló lè wáyé bí Kristẹni kan bá fi ìdílé rẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ìlú míì torí àtirí towó ṣe?

Tí àwọn òbí ò bá gbé pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ó lè fa ẹ̀dùn ọkàn fún àwọn ọmọ wọn, ó sì lè mú kí wọ́n hùwà tí kò tọ́. Wọ́n tiẹ̀ lè pa òbí yẹn tì tó bá yá. Àwọn tọkọtaya tí wọ́n bá ń gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ lè dojú kọ ewu láti lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe.—4/15, ojú ìwé 19 sí 20.

Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń ṣẹ́ ẹsẹ̀ àwọn ọ̀daràn tí wọ́n gbé kọ́ sórí igi nígbà tí wọ́n bá fẹ́ pa wọ́n?

Àwọn ará Róòmù máa ń pa àwọn ọ̀daràn kan nípa gbígbé wọn kọ́ sórí òpó igi oró. Àwọn Júù sọ pé kí wọ́n jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́ ẹsẹ̀ àwọn ọ̀daràn méjì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù. Èyí máa mú kó ṣòro fún àwọn ọ̀daràn náà láti mí, á sì mú kí ikú wọn yá kíákíá. Nípa bẹ́ẹ̀, kò ní jẹ́ pé wọ́n á wà lórí igi ní gbogbo òru. (Diu. 21:22, 23)—5/1, ojú ìwé 11.

Ìbéèrè mẹ́rin wo ló yẹ ká fi sọ́kàn nígbà tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

Àwọn wo ni mo fẹ́ wàásù fún? Ibo ni máa ti wàásù fún wọn? Ìgbà wo ni mo lè lọ wàásù fún wọn? Báwo ni kí n ṣe wàásù fún wọn?—5/15, ojú ìwé 12 sí 15.

Báwo ni ọṣẹ́ tí sìgá ṣe ti pọ̀ tó?

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá, ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù [100,000,000] èèyàn ló pa. Ní báyìí, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà [6,000,000] èèyàn ló ń pa lọ́dọọdún.—6/1, ojú ìwé 3.