Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  June 2014

“Mú Ipa Ọ̀nà Ẹsẹ̀ Rẹ Jọ̀lọ̀” Kó O Lè Tẹ̀ Síwájú

“Mú Ipa Ọ̀nà Ẹsẹ̀ Rẹ Jọ̀lọ̀” Kó O Lè Tẹ̀ Síwájú

NÍGBÀ tí àwọn èèyàn Ọlọ́run kúrò ní Bábílónì ní ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà ò fẹ́ kí wọ́n rin ọ̀nà gbágungbàgun lọ sí Jerúsálẹ́mù. Torí náà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ tún ọ̀nà àwọn ènìyàn ṣe. Ẹ kọ bèbè, ẹ kọ bèbè òpópó. Ẹ ṣa àwọn òkúta rẹ̀ kúrò.” (Aísá. 62:10) Fojú inú yàwòrán bí àwọn Júù kan ṣe máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe yìí. Àwọn tó kọ́kọ́ kúrò ní Bábílónì lára wọn lè ti tún ojú ọ̀nà náà ṣe, bóyá kí wọ́n kó òkúta àti erùpẹ̀ dí àwọn kòtò tó wà lọ́nà kí wọ́n sì mú kí àwọn ibi tó ṣe gbágungbàgun tẹ́jú pẹrẹsẹ. Ńṣe ni ohun tí wọ́n ṣe yìí á mú kó túbọ̀ rọrùn fún àwọn arákùnrin wọn láti gba ibẹ̀ kọjá lọ sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn.

A lè fi ohun tá a sọ yìí ṣàpèjúwe ohun tó máa gbà pé ká ṣe kí ọwọ́ wa tó lè tẹ àwọn àfojúsùn wa nípa tẹ̀mí. Jèhófà fẹ́ kí ọwọ́ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tẹ àwọn àfojúsùn wọn nípa tẹ̀mí láìsí pé ohunkóhun tí kò pọn dandan dí wọn lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbà wá níyànjú pé: “Mú ipa ọ̀nà ẹsẹ̀ rẹ jọ̀lọ̀, ǹjẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀nà tìrẹ fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (Òwe 4:26) Yálà o ṣì wà lọ́mọdé tàbí o ti ń gòkè àgbà, o lè gbà pé ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fún wa yìí lọ́gbọ́n nínú.

OHUN ÀKỌ́KỌ́ NI PÉ KÓ O ṢE ÌPINNU TÓ TỌ́

Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ táwọn èèyàn ń sọ nípa ọ̀dọ́langba kan pé: ‘Ọ̀pọ̀ àǹfààní lọmọ yẹn ní’ tàbí, ‘Orí ọmọ yẹn pé gan-an.’ Ẹ kúkú mọ̀ pé eegun àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń le, ọpọlọ wọn máa ń ṣiṣẹ́ bí aago, bí wọ́n sì ṣe máa mókè ló máa ń wà lọ́kàn wọn. Abájọ tí Bíbélì fi tọ̀nà nígbà tó sọ pé: “Ẹwà àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn.” (Òwe 20:29) Bí ọ̀dọ́ kan bá lo ẹ̀bùn àti agbára tó ní láti sin Jèhófà, ọwọ́ rẹ̀ máa tẹ àwọn àfojúsùn tẹ̀mí tó ní, ó sì máa ní ojúlówó ayọ̀.

Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ṣe mọ̀, àwọn èèyàn kì í kóyán àwọn ọ̀dọ́ wa kéré torí pé wọ́n mọyì ẹ̀bùn tí wọ́n ní gan-an. Bí Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ bá ń ṣe dáadáa níléèwé, olùkọ́ rẹ̀, agbaninímọ̀ràn fáwọn ọmọléèwé tàbí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lè máa rọ̀ ọ́ pé kó lọ sí yunifásítì kó bàa lè rọ́wọ́ mú nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ bá sì ní ẹ̀bùn eré  ìdárayá, àwọn tó ń gbani sí eré ìdárayá lè fi ọgbọ́n fà á mọ́ra kó lè máa fi eré ìdárayá ṣiṣẹ́ ṣe. Ṣé irú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà rí, àbí o mọ ẹnì kan tí wọ́n ń fúngun mọ́ pé kó wá ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Kí ló máa ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti fi ọgbọ́n yan ohun tó máa ṣe?

Ẹ̀kọ́ Bíbélì lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti gbára dì kó bàa lè máa tọ ọ̀nà tó dára jù lọ nígbèésí ayé rẹ̀. Ìwé Oníwàásù 12:1 sọ pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.” Ọ̀nà wo ló dára jù lọ tí ìwọ tàbí ọ̀dọ́ míì tó o mọ̀ lè gbà “rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá”?

Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Eric * tó ń gbé ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Ó fẹ́ràn láti máa gbá bọ́ọ̀lù. Nígbà tí Eric pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], wọ́n yàn án pé kó wà nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ìyẹn túmọ̀ sí pé láìpẹ́ láìjìnnà, ó lè retí pé òun á lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù kí òun lè lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó wà fún àwọn tó dáńgájíà jù lọ nínú eré ìdárayá. Ó sì ṣeé ṣe kí ìyẹn sọ òun di ẹni táá máa fi bọ́ọ̀lù gbígbá ṣiṣẹ́ ṣe. Báwo wá ni Eric ṣe máa fi ìmọ̀ràn tó sọ pé, “rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá” sílò? Ẹ̀kọ́ wo ni ìwọ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tó jẹ́ ọ̀dọ́ lè rí kọ́ nínú èyí?

Nígbà tí Eric wà nílé ẹ̀kọ́, ó gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó wá yé e pé Ẹlẹ́dàá òun máa tó yanjú gbogbo ìṣòro aráyé pátápátá. Èyí mú kí Eric rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí òun máa lo àkókò àti okun òun láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ní báyìí tí Eric ti wá lóye ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe yìí, ó pinnu pé òun ò ní fi bọ́ọ̀lù gbígbá ṣiṣẹ́ ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣèrìbọmi, ó sì ń fi àkókò rẹ̀ ṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Nígbà tó ṣe, ó di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ẹ̀yìn ìgbà náà ni wọ́n ní kó wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n.

Ká ní eré ìdarayá ní Eric yàn láti máa ṣe ni, ó ṣeé ṣe kó ti di olókìkí àti ọlọ́rọ̀. Ṣùgbọ́n ó wá rí i pé òótọ́ ni ìlànà Bíbélì tó sọ pé: “Àwọn nǹkan tí ó níye lórí tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ ni ìlú lílágbára rẹ̀, wọ́n sì dà bí ògiri adáàbòboni nínú èrò-ọkàn rẹ̀.” (Òwe 18:11) Ká sòótọ́, téèyàn bá kó ọrọ̀ jọ tó sì rò pé òun ti rí ààbò, onítọ̀hún kàn ń tan ara rẹ̀ jẹ ni. Ó ṣe tán, ńṣe làwọn tó ń fi torí tọrùn lépa ọrọ̀ máa ń “fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tím. 6:9, 10.

Àmọ́, inú wa dùn pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ń rí ayọ̀ àti ààbò tó tọ́jọ́ torí pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Dípò kí Eric dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù, ó sọ pé: “Mo ti dara pọ̀ mọ́ ‘ẹgbẹ́’ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, tí wọ́n sì pọ̀ níye. Ìyẹn ni ẹgbẹ́ tó dára jù lọ tí mo lè dara pọ̀ mọ́, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí n mọ ọ̀nà kan ṣoṣo tí mo lè gbà láyọ̀ kí n sì ṣàṣeyọrí láyé mi.”

Ìwọ ńkọ́? Dípò tí wàá fi máa lépa àwọn nǹkan ti ayé, o ò ṣe fìdí ‘àwọn ọ̀nà rẹ’ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in níwájú Jèhófà nípa lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà?—Wo àpótí náà, “ Bí Ọwọ́ Rẹ Ṣe Lè Tẹ Àwọn Àǹfààní Téèyàn Ò Lè Rí ní Yunifásítì.”

MÚ ÀWỌN OHUN TÓ LÈ DÍ Ẹ LỌ́WỌ́ KÚRÒ LỌ́NÀ

Nígbà tí tọkọtaya kan ṣe ìbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n rí i pé ṣe ni inú àwọn ará tó ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà ní Bẹ́tẹ́lì ń dùn. Lẹ́yìn náà ni arábìnrin náà kọ̀wé pé: “Ìgbà yìí la ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ̀ pé púpọ̀ ṣì wà fún wa láti ṣe.” Bó ṣe di pé tọkọtaya náà pinnu pé àwọn máa túbọ̀ lo okun àti àkókò wọn láti ṣe púpọ̀ sí i nìyẹn.

Àkókò kan wà tó dà bíi pé ìyípadà tí tọkọtaya náà fẹ́ ṣe máa mu wọ́n lómi. Àmọ́, lọ́jọ́ kan, wọ́n ronú lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọjọ́ náà. Ìwé Jòhánù 8:31 ni, níbi tí Jésù ti sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́.” Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn wọn, wọ́n ronú pé: “Ohun yòówù kó ná wa ká bàa lè máa lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Wọ́n ta ilé ńlá tí wọ́n ń gbé, wọ́n wá nǹkan ṣe sí àwọn ohun mìíràn tó ń dí wọn lọ́wọ́, wọ́n sì lọ sìn ní ìjọ kan tó nílò ìrànlọ́wọ́. Wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà báyìí, wọ́n máa ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n sì tún máa ń yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ní àwọn àpéjọ àgbègbè. Báwo lèyí ṣe rí lára wọn? Wọ́n sọ pé: “Ó yà wá lẹ́nu pé a lè máa láyọ̀ tó pọ̀ tó yìí nígbà tá a jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wa lọ́rùn, tá a sì ń ṣe ohun tí ètò Jèhófà rọ̀ wá pé ká ṣe.”

MÁ ṢE KÚRÒ LÓJÚ Ọ̀NÀ TÓ O TI LÈ MÁA TẸ̀ SÍWÁJÚ NÍPA TẸ̀MÍ

Sólómọ́nì kọ̀wé pé: ‘Ọ̀kánkán tààrà ni kí o máa wò, bẹ́ẹ̀ ni, kí ojú rẹ títàn yanran tẹjú mọ́ ọ̀kánkán gan-an ní iwájú rẹ.’ (Òwe 4:25) Bí awakọ̀ ṣe máa ń wo iwájú tó bá ń wakọ̀, àwa náà gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn ohun tó lè pín ọkàn wa níyà tí kò ní jẹ́ ká ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí tàbí tí kò ní jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àwọn àfojúsùn wa.

 Àwọn nǹkan tí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ wo lo lè fi ṣe àfojúsùn rẹ? Àfojúsùn tó dáa ni pé kó o fẹ́ láti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Òmíràn ni pé kó o lọ sìn ní ìjọ kan tó wà nítòsí, tí wọ́n nílò àwọn oníwàásù tó ní ìrírí láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Ó sì lè jẹ́ ìjọ kan tí wọ́n ní ọ̀pọ̀ akéde tó ń ṣe déédéé, àmọ́ tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ǹjẹ́ o lè yọ̀ọ̀da ara rẹ láwọn ọ̀nà tá a mẹ́nu kàn yìí? O ò ṣe bá alábòójútó àyíká sọ ọ́? Tó o bá sì fẹ́ láti lọ sìn láwọn ibi tó jìnnà, yálà lórílẹ̀-èdè rẹ tàbí ibòmíì, o lè kọ̀wé láti wádìí nípa àwọn ìjọ tó nílò ìrànlọ́wọ́. *

Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká pa dà sórí ọ̀rọ̀ tá à ń bá bọ̀ nínú ìwé Aísáyà 62:10. Àwọn kan lára àwọn Júù yẹn lè ti ṣiṣẹ́ kára láti dí àwọn kòtò tó wà lójú ọ̀nà tó lọ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn kí wọ́n sì ti kó àwọn ohun tó lè ṣèdíwọ́ kúrò káwọn èèyàn Ọlọ́run lè gúnlẹ̀ sí ibi tí wọ́n ń lọ. Tó o bá ṣì ń tiraka kọ́wọ́ rẹ lè tẹ àwọn ohun tó o fi ṣe àfojúsùn rẹ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, má ṣe juwọ́ sílẹ̀. Ọlọ́run máa ran ìwọ náà lọ́wọ́ kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn yẹn. Máa bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n bó o ṣe ń gbìyànjú láti mú àwọn ohun tó lè dí ẹ lọ́wọ́ kúrò. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ó ṣeé ṣe kó o wá rí bí Jèhófà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ‘mú ipa ọ̀nà ẹsẹ̀ rẹ jọ̀lọ̀.’—Òwe 4:26.

^ ìpínrọ̀ 8 A ti yí orúkọ náà pa dà.

^ ìpínrọ̀ 18 Wo A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 111 sí 112.