Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣó yẹ kí àwọn Kristẹni máa fi iná sun òkú?

Kò sí ibì kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó sọ pé kò dára kéèyàn máa fi iná sun òkú.

Àwọn àkọsílẹ̀ kan wà nínú Bíbélì tó sọ pé wọ́n fi iná sun egungun àwọn èèyàn tó ti kú tàbí òkú náà lódindi. (Jóṣ. 7:25; 2 Kíró. 34:4, 5) Èyí lè mú kó jọ pé àwọn èèyàn tí kò yẹ kí wọ́n sin lọ́nà iyì àti ẹ̀yẹ ni wọ́n máa ń fi iná sun. Ṣùgbọ́n kì í fi ìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀.

Èyí ṣe kedere látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sọ́ọ̀lù Ọba àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ta kú. Ojú ogun ni àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin kú sí nígbà tí wọ́n ń bá àwọn Filísínì jagun. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ tó kú náà ni Jónátánì tó jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà fún Dáfídì tó sì tún dúró tì í lọ́jọ́ ìṣòro. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ akíkanjú tí wọ́n ń gbé ní Jabẹṣi-gílíádì gbọ́ pé wọ́n ti pa Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀, wọ́n lọ gbé òkú àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, wọ́n sun wọ́n, lẹ́yìn náà ni wọ́n wá sin àwọn egungun wọn. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Dáfídì yin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà torí ohun tí wọ́n ṣe.—1 Sám. 31:2, 8-13; 2 Sám. 2:4-6.

Ìwé Mímọ́ sọ pé àjíǹde àwọn òkú máa wà, èyí tó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run máa mú kí àwọn èèyàn tó ti kú pa dà wà láàyè. Yálà wọ́n fi iná sun ẹni tó ti kú náà tàbí wọn kò fi iná sun ún, ìyẹn ò lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti jí i pa dà sí ìyè kó sì fún un ní ara tuntun. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Nebukadinésárì Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n gbé àwọn Hébérù mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin jù sínú iná ìléru, wọn ò mikàn pé táwọn bá jóná lúúlúú bóyá ni Ọlọ́run máa jí àwọn dìde tó bá yá. (Dán. 3:16-18) Bíi ti àwọn Hébérù mẹ́ta yìí ni ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ lábẹ́ ìjọba Násì náà rí. Wọn ò bẹ̀rù, kódà nígbà tó dájú pé wọ́n máa pa wọ́n tí wọ́n á sì fi iná sun òkú wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin ni bọ́ǹbù tàbí nǹkan míì ti pa tó sì jẹ́ pé kò sí ohun téèyàn lè fi dá òkú wọn mọ̀. Síbẹ̀, ó dájú gbangba pé Ọlọ́run máa jí wọn dìde.—Ìṣí. 20:13.

Kò dìgbà tí Jèhófà bá ṣa ara òkú kan jọ kó tó lè jí i dìde. A lè lóye pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí látinú bí Ọlọ́run ṣe máa jí àwọn Kristẹni tó jẹ́ ẹni àmì òróró dìde sókè ọ̀run. Bíi ti Jésù, “tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí,” Ọlọ́run máa jí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró dìde, á wá fún wọn ní ara ti ẹ̀mí. Wọn ò ní gbé ara ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ lọ sí ọ̀run.—1 Pét. 3:18; 1 Kọ́r. 15:42-53; 1 Jòh 3:2.

Yálà wọ́n fi iná sun òkú tàbí wọn kò fi iná sun ún, ìyẹn ò ní kó máà jíǹde. Ìdí sì ni pé a gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde torí pé ó lágbára láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó sì wù ú pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 24:15) Òótọ́ ni pé a lè má mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe jí àwọn òkú dìde nígbà àtijọ́ tàbí bó ṣe máa jí àwọn òkú dìde lọ́jọ́ iwájú. Síbẹ̀, a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà. Ó ti pèsè “ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà” ní ti pé ó jí Jésù dìde.—Ìṣe 17:31; Lúùkù 24:2, 3.

Torí náà, ọ̀nà yòówù kí àwọn Kristẹni yàn láti gbà palẹ̀ òkú èèyàn wọn mọ́, ó yẹ kí wọ́n ronú nípa bí wọ́n ṣe máa ń sin òkú lágbègbè wọn, bó ṣe máa rí lára àwọn aládùúgbò àti ohun tó bá òfin mu. (2 Kọ́r. 6:3, 4) Nípa báyìí, ọwọ́ ẹni ti òkú kú fún tàbí ẹbí òkú náà ló wá kù sí bóyá wọ́n máa fi iná sun òkú náà tàbí wọn kò ní sun ún.