Kí ló máa ń mú inú rẹ dùn gan-an? Ṣé ohun kan tó ní í ṣe pẹ̀lú àjọṣe àwa èèyàn ni, irú bí ìgbéyàwó, ọmọ títọ́ tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń bára yín ṣọ̀rẹ́? Bóyá o sì fẹ́ràn láti máa jẹun pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ, aya rẹ tàbí àwọn ọmọ rẹ. Àmọ́ torí pé o jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, ǹjẹ́ kò ní ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an tó o bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, tó ò ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tó o sì ń wàásù ìhìn rere?

Nínú orin atunilára kan tí Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì kọ láti fi yin Ẹlẹ́dàá, ó sọ pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, Òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.” (Sm. 40:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì fojú winá ọ̀pọ̀ ìṣòro nígbà tó wà láyé, inú rẹ̀ máa ń dùn gan-an láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́, Dáfídì nìkan kọ́ ni olùjọ́sìn Jèhófà tí inú rẹ̀ máa ń dùn láti sin Ọlọ́run tòótọ́ náà.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 40:8 nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Mèsáyà tàbí Kristi, ó sọ pé: “Nígbà tí [Jésù] wá sí ayé, ó wí pé: ‘“Ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́, ṣùgbọ́n ìwọ ti pèsè ara kan fún mi. Ìwọ kò tẹ́wọ́ gba àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.” Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó! Mo dé (nínú àkájọ ìwé ni a ti kọ ọ́ nípa mi) láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.”’”—Héb. 10:5-7.

Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, inú rẹ̀ máa ń dùn tó bá wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, nígbà tó bá ń kíyè sí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá àti nígbà tó bá ń bá àwọn míì jẹun. (Mát. 6:26-29; Jòh. 2:1, 2; 12:1, 2) Àmọ́, ohun tó wù ú tó sì múnú rẹ̀ dùn jù lọ ni pé kó ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run. Kódà, Jésù sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòh. 4:34; 6:38) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ́ àṣírí béèyàn ṣe ń ní ojúlówó ìdùnnú láti ọ̀dọ̀ Jésù tó jẹ́ Ọ̀gá wọn. Wọ́n ń fi tọkàntọkàn sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀.—Lúùkù 10:1, 8, 9, 17.

‘Ẹ LỌ, KÍ Ẹ SÌ SỌ ÀWỌN ÈÈYÀN DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN’

Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:19, 20) Tá a bá fẹ́ ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ yìí, ó ń béèrè pé ká wàásù fún àwọn èèyàn níbikíbi  tá a bá ti lè rí wọn, ká máa pa dà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò, ká sì máa kọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A máa láyọ̀ gan-an tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Bí àwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń dágunlá sí wa, ìfẹ́ ń mú ká máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó

Yálà àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere náà tàbí wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí i, tá a bá fẹ́ máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ìwà tiwa fúnra wa ṣe pàtàkì. Bí àwọn kan bá tiẹ̀ ń dágunlá sí ìhìn rere tá à ń polongo rẹ̀ tàbí tí wọn ò kọbi ara sí i, kí nìdí tá a fi ń bá a nìṣó láti máa polongo ìhìn rere náà? Ìdí ni pé bá a ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa. Ká sòótọ́, ẹ̀mí àwọn èèyàn wà nínú ewu, ìyẹn ò sì yọ àwa náà sílẹ̀. (Ìsík. 3:17-21; 1 Tím. 4:16) Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn kókó kan tó ti ran ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lọ́wọ́ tí wọn ò fi káàárẹ̀ tí wọ́n sì ń sọ ìtara wọn fún iṣẹ́ ìwàásù dọ̀tun bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpínlẹ̀ tí iṣẹ́ ìwàásù ò ti rọrùn ni wọ́n wà.

LO GBOGBO ÀǸFÀÀNÍ TÓ BÁ ṢÍ SÍLẸ̀

Tá a bá ń lo ìbéèrè tó yẹ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ó sábà máa ń so èso rere. Láàárọ̀ ọjọ́ kan, Arábìnrin Amalia rí ọkùnrin kan tó ń ka ìwé ìròyìn níbi ìgbọ́kọ̀sí kan. Ó tọ ọkùnrin náà lọ, ó wá bi í bóyá ó ti rí ìròyìn rere kankan kà nínú ìwé ìròyìn náà. Nígbà tó sọ pé òun ò tíì ka ìròyìn rere kankan, Amalia wá sọ pé, “Ìròyìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run ni mo mú wá fún yín.” Èyí mú kí ọkùnrin náà fẹ́ láti gbọ́, ó sì gbà kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà, ó ṣeé ṣe fún Amalia láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́ta níbi ìgbọ́kọ̀sí náà.

Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Janice sọ ibi tó ti ń ṣiṣẹ́ di ìpínlẹ̀ ìwàásù. Nígbà tó rí i pé ẹ̀ṣọ́ kan àti ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ nífẹ̀ẹ́ sí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, Janice pinnu láti máa mú ìwé ìròyìn náà wá fún wọn déédéé. Òṣìṣẹ́ míì tún wà tó fẹ́ràn láti máa ka onírúurú àpilẹ̀kọ tó ń jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn wa, torí náà ó máa ń fún òun náà ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ni òṣìṣẹ́ míì bá tún ní kó máa bá òun mú àwọn ìwé ìròyìn náà wá. Arábìnrin Janice wá sọ pé: “Ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà mà lèyí o!” Lápapọ̀ àwọn mọ́kànlá ló ń fún ní àwọn ìwé ìròyìn wa ní ibiṣẹ́ rẹ̀.

NÍ ÈRÒ TÓ DÁA

Alábòójútó arìnrìn-àjò kan dábàá pé tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, lẹ́yìn tá a bá ti parí ọ̀rọ̀ wa kò yẹ ká kàn sọ fún ẹni tá a wàásù fún pé a máa pa dà wá lọ́jọ́ míì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní a lè béèrè lọ́wọ́ onítọ̀hún pé: “Ṣé wàá fẹ́ kí n pa dà wá kí n lè fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn ẹ́?” tàbí, “Ọjọ́ wo àti déédéé àsìkò wo lo fẹ́ kí n pa dà wá ká lè máa bá ìjíròrò wa lọ?” Alábòójútó arìnrìn-àjò náà sọ pé nígbà tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà nínú ìjọ kan tí òun bẹ̀ wò lo àbá yìí, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́rìnlélógójì [44] ni wọ́n bẹ̀rẹ̀.

Ó máa ń gbéṣẹ́ gan-an tá a bá tètè pa dà lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn, pàápàá lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan tá a wàásù fún wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa fi hàn pé ó wù wá gan-an pé ká ran àwọn tó lọ́kàn rere lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye Bíbélì. Nígbà tí wọ́n bi obìnrin kan pé kí ló mú kó gba àwọn  Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè pé kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sọ pé, “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ torí pé wọ́n fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn sí mi, wọ́n sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ mi jẹ àwọn lógún.”

O lè bi ẹni tó ò ń wàásù fún pé: “Ṣé wàá fẹ́ kí n pa dà wá kí n lè fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn ẹ́?”

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí arábìnrin míì tó ń jẹ́ Madaí ṣe tán ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], ó sì ti gbé èyí tó ju márùn-ún lọ fún àwọn akéde míì pé kí wọ́n máa darí rẹ̀. Mélòó kan lára àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí àwọn ìpàdé wa déédéé. Kí ló ran Madaí lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ilé ẹ̀kọ́ náà mú kó rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé kó má ṣe jẹ́ kó sú òun láti máa pa dà lọ títí tó fi máa rí àwọn tó fìfẹ́ hàn nígbà àkọ́kọ́. Ẹlẹ́rìí míì tóun náà ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ sọ pé, “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ká tó lè ran àwọn tí wọ́n fẹ́ mọ Jèhófà lọ́wọ́, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti máa pa dà lọ sọ́dọ̀ wọn.”

Tá a bá ń tètè pa dà lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn èèyàn, ó máa fi hàn pé ó wù wá gan-an ká ran àwọn tó fẹ́ lóye Bíbélì lọ́wọ́

Ká sòótọ́, ó gba ìsapá gan-an ká tó lè ṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, èrè tó ń tibẹ̀ wá tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, àá lè ran àwọn míì lọ́wọ́ láti “wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́,” ìyẹn sì lè mú kí wọ́n rí ìgbàlà. (1 Tím. 2:3, 4) Ní tiwa, àá ní ojúlówó ìdùnnú àá sì mọ̀ pe a ti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe.