Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa ‘Dá Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Lóhùn’?

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa ‘Dá Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Lóhùn’?

“Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, . . . kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.”—KÓL. 4:6.

NÍ ÀWỌN ọdún mélòó kan sẹ́yìn, arábìnrin kan ń jíròrò Bíbélì pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí àmọ́ tó ti máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Nínú ìjíròrò wọn, ọkọ arábìnrin yìí sọ fún un pé òun gba Mẹ́talọ́kan gbọ́. Arábìnrin náà fòye gbé e pé ó ṣeé ṣe kí ọkọ òun má fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, ó wá fọgbọ́n bi í pé, “Ṣé o gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ni Ọlọ́run, pé Jésù jẹ́ Ọlọ́run àti pé ẹ̀mí mímọ́ náà jẹ́ Ọlọ́run, síbẹ̀ tó jẹ́ pé wọn kì í ṣe Ọlọ́run mẹ́ta bí kò ṣe Ọlọ́run kan?” Ọ̀rọ̀ yìí ya ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, ló bá sọ pé, “Rárá o, mi ò gba ìyẹn gbọ́ o!” Bó ṣe di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an nìyẹn.

1, 2. (a) Sọ ìrírí kan tó fi hàn pé ó dára gan-an ká máa béèrè àwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ kí àwọn ọ̀rọ̀ tó ta kókó máa bà wá lẹ́rù?

2 Ìrírí yìí jẹ́ ká rí bó ṣe dára tó pé ká máa béèrè àwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀, tó sì mọ́gbọ́n dání. Ó tún tẹ kókó pàtàkì kan mọ́ wa lọ́kàn. Ìyẹn ni pé a kò gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù láti jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ tó ta kókó, bí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, iná ọ̀rún àpáàdì àti pé bóyá òótọ́ ni Ẹlẹ́dàá wà. Tá a bá gbára lé Jèhófà tá a sì ń fi ìtọ́ni tó fún wa sílò, á ṣeé ṣe fún wa láti máa dáhùn lọ́nà táá wọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wa lọ́kàn táá sì yí wọn lérò pa dà.  (Kól. 4:6) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tí àwọn òjíṣẹ́ tó dáńgájíá máa ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń jíròrò irú àwọn kókó ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. A máa jíròrò (1) bá a ṣe lè lo ìbéèrè táá jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀, (2) bá a ṣe lè báni fèrò wérò lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, àti (3) bá a ṣe lè lo àpèjúwe láti mú kí ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn.

LO ÌBÉÈRÈ TÁÁ JẸ́ KÓ O MỌ OHUN TÓ WÀ LỌ́KÀN ÀWỌN TÓ Ò Ń BÁ SỌ̀RỌ̀

3, 4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lo ìbéèrè tó lè mú ká mọ ohun tí ẹnì kan gbà gbọ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.

3 Ìbéèrè lè mú ká mọ ohun tí ẹnì kan gbà gbọ́. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká lo ìbéèrè? Òwe 18:13 sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.” Látàrí èyí, kó tó di pé a máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa kókó kan, ohun tó dára jù ni pé ká gbìyànjú láti kọ́kọ́ mọ ohun tí ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ gbà gbọ́ ní ti gidi. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè ti fi ọ̀pọ̀ àkókò ṣàlàyé rẹpẹtẹ lórí ohun tí onítọ̀hún ò tiẹ̀ gbà gbọ́ rárá!—1 Kọ́r. 9:26.

4 Ẹ jẹ́ ká sọ pé à ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run àpáàdì. Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gbà pé ibi tí wọ́n ti ń fi iná dáni lóró ni ọ̀run àpáàdì. Láwọn ibì kan, ọ̀pọ̀ ló gbà pé ipò téèyàn ti jìnnà pátápátá sí Ọlọ́run ni ọ̀run àpáàdì. Torí náà, a lè sọ báyìí pé: “Níwọ̀n bí àwọn èèyàn ti ní èrò tó yàtọ̀ síra nípa ọ̀run àpáàdì, ǹjẹ́ o lè sọ ohun tó o gbà gbọ́ nípa rẹ̀ fún mi?” Lẹ́yìn tí ẹni náà bá ti sọ èrò rẹ̀, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti mú kó lóye ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ náà.

5. Báwo ni ìbéèrè ṣe lè mú ká mọ ìdí tí ẹnì kan fi gba ẹ̀kọ́ kan gbọ́?

5 Àwọn ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání tún lè mú ká mọ ìdí tí ẹnì kan fi gba ẹ̀kọ́ kan gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé a bá ẹnì kan pàdé lóde ẹ̀rí tó sọ pé òun kò gba Ọlọ́run gbọ́ ńkọ́? Ó rọrùn fún wa láti rò pé àwọn ẹ̀kọ́ ayé, bí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ló nípa lórí onítọ̀hún. (Sm. 10:4) Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyà tó ń jẹ àwọn kan tàbí èyí tó ń jẹ aráyé ló fà á táwọn kan ò fi gba Ọlọ́run gbọ́. Wọ́n lè máa ronú pé kò yẹ ká máa jìyà bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni Ẹlẹ́dàá tó nífẹ̀ẹ́ wa wà. Torí náà, bí ẹni tá à ń wàásù fún bá sọ pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà, a lè bi í pé, “Ṣé ohun tó o gbà gbọ́ nìyẹn látilẹ̀ wá?” Tó bá sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè béèrè ohun tó fà á gan-an tó fi gbà pé kò sí Ọlọ́run. Ohun tó bá sọ lè mú ká mọ ọ̀nà tó dára jù lọ tá a fi lè mú kó gbà pé Ọlọ́run wà.—Ka Òwe 20:5.

6. Kí ló yẹ ká ṣe lẹ́yìn tá a bá ti bi ẹnì kan ní ìbéèrè?

6 Lẹ́yìn tá a ti bi ẹnì kan léèrè ọ̀rọ̀, ó ṣe pàtàkì ká tẹ́tí dáadáa sí èsì tó fún wa, ká sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ torí pé ó sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè sọ pé àjálù kan tó ṣẹlẹ̀ ló fà á tí òun ò fi gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó nífẹ̀ẹ́ wa. Ká tó máa sọ àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà, ó máa dára ká kọ́kọ́ bá onítọ̀hún kẹ́dùn ká sì jẹ́ kó mọ̀ pé kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn máa béèrè ìdí tá a fi ń jìyà. (Háb. 1:2, 3) Bá a ṣe mú sùúrù tá a sì fìfẹ́ hàn sí i lè mú kó fẹ́ mọ púpọ̀ sí i. *

BÁ WỌN FÈRÒ WÉRÒ LÓRÍ OHUN TÍ ÌWÉ MÍMỌ́ SỌ

Kí ló sábà máa ń mú ká jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? (Wo ìpínrọ̀ 7)

7 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè bá àwọn èèyàn fèrò wérò lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ. Ó ṣe tán, Bíbélì ni olórí irinṣẹ́ tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ó ń mú ká di ẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tím. 3:16, 17) Àmọ́, kì í ṣe bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a  lò ṣe pọ̀ tó ló ń mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbéṣẹ́, bí kò ṣe bá a ṣe fèrò wérò lórí àwọn ẹsẹ tá a kà àti bá a ṣe ṣàlàyé wọn. (Ka Ìṣe 17:2, 3.) Kó lè túbọ̀ ṣe kedere, ẹ jẹ́ ká jíròrò àpẹẹrẹ mẹ́ta kan.

8, 9. (a) Kí ni ọ̀nà kan tá a lè gbà fèrò wérò pẹ̀lú ẹnì kan tó gbà pé Jésù bá Ọlọ́run dọ́gba? (b) Ọ̀nà míì wo lo tún máa ń gbà fèrò wérò lórí kókó yìí tó o bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?

8 Àpẹẹrẹ 1: Lóde ẹ̀rí, a pàdé ẹnì kan tó gbà pé Jésù bá Ọlọ́run dọ́gba. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo la lè lò láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú onítọ̀hún? A lè ní kó ka Jòhánù 6:38, níbi tí Jésù ti sọ pé: “Èmi sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.” Tá a bá ti ka ẹsẹ yẹn tán, a lè wá bi ẹni náà pé: “Tó bá jẹ́ pé Jésù ni Ọlọ́run, ta ló rán an wá láti ọ̀run? Ǹjẹ́ Ẹni náà kò ní ju Jésù lọ? Ó ṣe tán, àgbàlagbà ló sábà máa ń rán ọmọdé níṣẹ́.”

9 Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì tó tún tan mọ́ ọn ni Fílípì 2:9, níbi tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ ohun tí Ọlọ́run ṣe lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì jíǹde. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà kà pé: ‘Ọlọ́run gbé [Jésù] sí ipò gíga, ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn.’ Ká lè mú kí ẹni náà ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ yẹn sọ, a lè bi í pé: “Tó bá ṣe pé Jésù àti Ọlọ́run dọ́gba kó tó di pé Jésù kú, tí Ọlọ́run sì tún wá gbé Jésù sí ipò gíga lẹ́yìn tó jíǹde, ṣé ìyẹn ò ní gbé Jésù ga ju Ọlọ́run lọ? Síbẹ̀, ǹjẹ́ o rò pé ẹnikẹ́ni wà tó ga ju Ọlọ́run lọ?” Bí ẹni tá a wàásù fún bá bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sì lọ́kàn tó dára, bá a ṣe bá a fèrò wérò yẹn lè mú kó fẹ́ láti mọ̀ síwájú sí i nípa kókó ọ̀rọ̀ náà.—Ìṣe 17:11.

10. (a) Báwo la ṣe lè fèrò wérò pẹ̀lú ẹni tó gbà pé ọ̀run àpáàdì wà? (b) Ọ̀nà tó gbéṣẹ́ míì wo lo máa ń lò tó o bá ń bá ẹnì kan fèrò wérò lórí ọ̀run àpáàdì?

10 Àpẹẹrẹ 2: Ó ṣòro fún ẹnì kan tí kò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré láti gbà pé àwọn ẹni burúkú kò ní máa joró títí láé nínú iná ọ̀run àpáàdì. Ó lè jẹ́ pé ohun tó mú kó gbà pé ọ̀run àpáàdì wà ni pé ó wù ú kí àwọn èèyàn burúkú jìyà iṣẹ́ ibi wọn. Báwo la ṣe lè fèrò wérò pẹ̀lú ẹni tó bá ní irú èrò bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, a lè mú kó dá onítọ̀hún lójú pé àwọn ẹni ibi máa jìyà iṣẹ́ ibi wọn. (2 Tẹs. 1:9) Lẹ́yìn náà, a lè ní kó ka Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17, tó jẹ́ ká mọ̀ pé ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀. A lè wá ṣàlàyé pé ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù dá ló sọ aráyé di ẹlẹ́ṣẹ̀, torí pé inú ẹ̀ṣẹ̀ la bí wa sí. (Róòmù 5:12) Àmọ́ ká jẹ́ kó ṣe kedere sí i pé Ọlọ́run kò sọ pé yóò lọ jìyà nínú iná ọ̀run àpáàdì. A lè wá bi í pé, “Tó bá jẹ́ pé ṣe ni Ádámù àti Éfà yóò máa joró títí láé, ǹjẹ́ kò ní bá ìdájọ́ òdodo mu pé kí Ọlọ́run ti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bẹ́ẹ̀?” A lè wá ka Jẹ́nẹ́sísì 3:19, níbi tí  Ọlọ́run ti dá wọn lẹ́jọ́ lẹ́yìn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ tí kò sọ ohunkóhun nípa iná ọ̀run àpáàdì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ fún Ádámù pé inú erùpẹ̀ ló máa pa dà sí. A lè wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó dáa kó jẹ́ pé inú ọ̀run àpáàdì ni Ádámù ń lọ, kí Ọlọ́run sì wá sọ fún un pé ó máa pa dà sínú ilẹ̀?” Bí ẹni náà kò bá ní ẹ̀tanú, irú ìbéèrè yìí lè mú kó túbọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí kókó náà.

11. (a) Kí ni ọ̀nà kan tá a lè gbà fèrò wérò pẹ̀lú ẹnì kan tó gbà pé ọ̀run ni gbogbo èèyàn rere ń lọ? (b) Ọ̀nà wo lo ti rí i pé ó gbéṣẹ́ láti fèrò wérò pẹ̀lú àwọn tó gbà pé ọ̀run ni gbogbo ẹni rere ń lọ?

11 Àpẹẹrẹ 3: Lóde ẹ̀rí, a pàdé ẹnì kan tó gbà pé ọ̀run ni gbogbo ẹni rere ń lọ. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ lè mú kí onítọ̀hún tú Bíbélì síbi tó fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé a fẹ́ jọ jíròrò ohun tó wà nínú ìwé Ìṣípayá 21:4. (Kà á.) Ẹni náà lè rò pé ọ̀run la ti máa gbádùn àwọn ìbùkún tí ẹsẹ yẹn sọ. Báwo la ṣe lè bá a fèrò wérò? Dípò tá ó fi máa lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì, a lè lo àwọn kókó tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn gan-an. Ó sọ pé “ikú kì yóò sì sí mọ́.” A lè béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó gbà pé kó tó di pé ohun kan kò ní sí mọ́, ó ní láti jẹ́ pé nǹkan ọ̀hún ti wà rí nìyẹn. Ó ṣeé ṣe kó gbà bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà a lè wá jẹ́ kó yé e pé a ò tíì gbọ́ ọ rí pé wọ́n ń kú ní ọ̀run, orí ilẹ̀ ayé níbí nìkan làwọn èèyàn ti ń kú. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé àwọn ìbùkún tá a máa gbádùn lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú ni Ìṣípayá 21:4, ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.—Sm. 37:29.

MÁA LO ÀPÈJÚWE KÍ Ọ̀RỌ̀ RẸ LÈ WỌNI LỌ́KÀN

12. Kí nìdí tí Jésù fi máa ń lo àpèjúwe?

12 Yàtọ̀ sí pé Jésù máa ń lo ìbéèrè, ó tún máa ń lo àpèjúwe nínú iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀. (Ka Mátíù 13:34, 35.) Àwọn àpèjúwe tí Jésù lò mú kó mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn tó bá sọ̀rọ̀. (Mát. 13:10-15) Àwọn àpèjúwe tí Jésù lò máa ń mú kí ẹ̀kọ́ rẹ̀ wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, ó sì ń mú kí wọ́n rántí ohun tó kọ́ wọn. Báwo làwa náà ṣe lè máa lo àpèjúwe nígbà tá a bá ń kọ́ni?

13. Àpèjúwe wo la lè lò láti mú káwọn èèyàn mọ̀ pé Ọlọ́run ju Jésù lọ?

13 Àpèjúwe tó rọrùn ló dára jù kéèyàn máa lò. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ ṣàlàyé pé Ọlọ́run ju Jésù lọ, a lè lo àbá yìí. A lè sọ pé nígbà tí Ọlọ́run àti Jésù bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe jẹ́ síra, irú ọ̀rọ̀ táwọn tó wà nínú ìdílé máa ń lò láàárín ara wọn ni wọ́n máa ń lò. Ọlọ́run máa ń pe Jésù ní Ọmọ rẹ̀, Jésù sì máa ń pe Ọlọ́run ní Bàbá rẹ̀. (Lúùkù 3:21, 22; Jòh. 14:28) Lẹ́yìn náà, a lè wá bi ẹni náà pé: “Ká sọ pé o fẹ́ kọ́ mi pé àwọn méjì kan jẹ́ ẹgbẹ́, àpẹẹrẹ àwọn wo nínú ìdílé ni wàá lò?” Ẹni náà lè tọ́ka sí àpẹẹrẹ àwọn ìbejì. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè jẹ́ kó rí i pé irú ìfiwéra yẹn bá a mu gẹ́lẹ́. A lè wá béèrè pé: “Wò ó bó ṣe rọrùn fún èmi àti ìwọ láti wá àpèjúwe tó bá a mu wẹ́kú, ṣé Jésù tó jẹ́ Olùkọ́ Ńlá kò wá lè ronú kan irú àpẹẹrẹ yẹn ni? Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló pe Ọlọ́run ní Bàbá òun. Jésù tipa bẹ́ẹ̀ mú kó ṣe kedere pé Ọlọ́run ju òun lọ àti pé ó láṣẹ lórí òun.”

14. Àpèjúwe wo la lè lò táá jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu pé kí Ọlọ́run lo Èṣù láti máa dá àwọn èèyàn lóró ní ọ̀run àpáàdì?

14 Tún wo àpẹẹrẹ míì. Àwọn kan gbà pé Sátánì ló ń dá àwọn èèyàn lóró ní ọ̀run àpáàdì. Àpèjúwe kan wà tó lè mú kí òbí kan rí i pé kò bọ́gbọ́n mu pé kí Ọlọ́run lo Èṣù láti máa dá àwọn èèyàn lóró ní ọ̀run àpáàdì. A lè sọ báyìí pé: “Ọmọkùnrin kan wà tó ya ọmọ burúkú, tó sì ń hùwà tí kò dáa. Tó bá jẹ́ pé ẹ̀yin ni bàbá ọmọ náà, kí lẹ máa ṣe?” Ó ṣeé ṣe kí òbí náà sọ pé òun á bá ọmọ náà wí láti tọ́ ọ sọ́nà. Ó tiẹ̀ lè sọ pé òun á sapá léraléra kí ọmọ náà lè jáwọ́ nínú  ìwà àìdáa tó ń hù. (Òwe 22:15) A lè wá bi òbí náà pé kí ló máa ṣe tí ọmọ náà bá ṣe agídí tí kò sì yí pa dà. Ọ̀pọ̀ òbí ló máa sọ pé kò sí nǹkan míì ju pé káwọn jẹ ọmọ náà níyà. A lè wá béèrè pé, “Tẹ́ ẹ bá wá rí i pé ìkà ọkùnrin kan ló ń kọ́ ọmọ náà ní gbogbo ìwà burúkú tó ń hù yẹn ńkọ́?” Kò sí àní-àní pé òbí yẹn máa bínú sí ọkùnrin náà gan-an. Láti mú kí àpèjúwe náà túbọ̀ ṣe kedere, a lè wá bi òbí náà pé, “Lẹ́yìn tẹ́ ẹ ti wá mọ̀ pé ìkà ọkùnrin yẹn ló ń kọ́ ọmọ yín ní ìkọ́kúkọ̀ọ́, ṣé ọkùnrin yẹn náà lẹ tún máa ní kó bá yín jẹ ọmọ yín níyà?” Ó dájú pé bẹ́ẹ̀ kọ́ ni òbí náà máa dáhùn. Ó ṣe kedere nígbà náà pé kì í ṣe Sátánì tó ń kọ́ àwọn èèyàn ní ìwà búburú ni Ọlọ́run á tún wá sọ pé kó máa dá wọn lóró!

MÁA NÍ ÈRÒ TÓ TỌ́ NÍPA IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

15, 16. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká retí pé gbogbo ẹni tá a bá wàásù fún ló máa wá sínú òtítọ́? (b) Ṣé ó dìgbà tá a bá ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ ká tó lè di olùkọ́ tó dáńgájíá? Ṣàlàyé. (Tún wo àpótí tá a pè ní “ Àwọn Àpilẹ̀kọ Táá Mú Ká Mọ Bá A Ṣe Lè Dá Àwọn Èèyàn Lóhùn.”)

15 A mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ẹni tá a bá wàásù fún ló máa wá sínú òtítọ́. (Mát. 10:11-14) Kódà bá a tiẹ̀ béèrè àwọn ìbéèrè tó bọ́gbọ́n mu, tá a fèrò wérò lọ́nà tí òpè èèyàn fi lè yí pa dà, tá a sì lo àwọn àpèjúwe tó bọ́ sójú ẹ̀, kò ní kí gbogbo èèyàn wá sínú òtítọ́. Ó ṣe tán, kò sí olùkọ́ tó dà bíi Jésù láyé yìí. Síbẹ̀, ìwọ̀nba èèyàn ló fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn rẹ̀!—Joh. 6:66; 7:45-48.

16 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tá a bá tiẹ̀ rò pé a ò ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀, a ṣì lè kọ́ni lọ́nà tó dáńgájíá tá a bá wà lóde ẹ̀rí. (Ka Ìṣe 4:13.) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kó dá wa lójú gbangba pé “gbogbo àwọn tí wọ́n . . . ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” máa wá sínú òtítọ́. (Ìṣe 13:48) Torí náà, ẹ jẹ́ ká ní èrò tó tọ́ nípa ara wa àti nípa àwọn tá à ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún, ká má sì gba èrò tí kò tọ́ láyè. Ǹjẹ́ ká máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà ń fún wa, kó sì dá wa lójú pé ó máa ṣe àwa àtàwọn tó ń fetí sí wa láǹfààní. (1 Tím. 4:16) Jèhófà lè mú ká mọ bá ó ṣe máa dá ẹnì kọ̀ọ̀kan lóhùn. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí i pé ọ̀nà kan tá a lè gbà kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ni pé ká máa tẹ̀ lé Ìlànà Pàtàkì náà, èyí táwọn kan sábà máa ń pè ní Òfin Oníwúrà.

^ ìpínrọ̀ 6 Wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní, “Ṣó Ṣeé Ṣe Láti Nígbàgbọ́ Nínú Ẹlẹ́dàá?” nínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 2009.