Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Máa Fi Ìlànà Pàtàkì Náà Sílò Lóde Ẹ̀rí

Máa Fi Ìlànà Pàtàkì Náà Sílò Lóde Ẹ̀rí

“Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—MÁT. 7:12.

NÍ NǸKAN bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, tọkọtaya Kristẹni kan lórílẹ̀-èdè Fíjì wà lóde ẹ̀rí, wọ́n ń fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ nígbà tí wọ́n ń bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ nítòsí ilé rẹ̀. Ni arákùnrin wá bá fún obìnrin náà ní agbòjò kan, òun àti ìyàwó rẹ̀ wá bọ́ sábẹ́ agbòjò kejì. Inú tọkọtaya yìí dùn nígbà tí wọ́n rí obìnrin náà lálẹ́ ọjọ́ tá a ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Obìnrin náà sọ pé òun ò fi bẹ́ẹ̀ rántí ohun tí tọkọtaya Ẹlẹ́rìí náà bá òun sọ lọ́jọ́ tí wọ́n bá òun sọ̀rọ̀. Àmọ́, ìwà tí tọkọtaya náà hù sí i wú u lórí débi tó fi pinnu pé òun á wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Kí ló mú kí tọkọtaya náà ṣe ohun tí wọ́n ṣe yẹn? Ìlànà Pàtàkì, tí àwọn kan sábà máa ń pè ní Òfin Oníwúrà, ni wọ́n tẹ̀ lé.

2. Kí ni Ìlànà Pàtàkì náà, báwo la sì ṣe lè fi í sílò?

2 Kí ni Ìlànà Pàtàkì náà? Òun ni ìmọ̀ràn tí Jésù gbà wá nígbà tó sọ pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mát. 7:12) Báwo la ṣe lè fi ìlànà yẹn sílò? Ó kéré tán, ohun méjì wà tá a máa ṣe. Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ bi ara wa pé, ‘Tó bá jẹ́ pé èmi ni mo wà nípò ẹni yẹn, irú ìwà wo ni màá fẹ́ kí wọ́n hù sí mi?’ Lẹ́yìn náà, ká hùwà tó tọ́ sí  onítọ̀hún, ká sì gba tiẹ̀ rò bó bá ti lè ṣeé ṣe tó.—1 Kọ́r. 10:24.

3, 4. (a) Ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe ìgbà tí nǹkan bá da àwa àtàwọn ará wa pọ̀ nìkan ló yẹ ká máa tẹ̀ lé ohun tí Ìlànà Pàtàkì náà sọ. (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 A sábà máa ń tẹ̀ lé ohun tí Ìlànà Pàtàkì yìí sọ nígbà tí nǹkan bá da àwa àtàwọn ará wa pọ̀. Àmọ́, Jésù ò sọ pé nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nìkan ló ti yẹ ká máa fi Ìlànà Pàtàkì yìí sílò. Òótọ́ ibẹ̀ tiẹ̀ ni pé ìgbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn èèyàn ní gbogbo gbòò, títí kan àwọn ọ̀tá wa, ló mẹ́nu kan Ìlànà Pàtàkì náà. (Ka Lúùkù 6:27, 28, 31, 35.) Tí a bá ní láti tẹ̀ lé Ìlànà Pàtàkì yìí nígbà tí nǹkan bá da àwa àti àwọn ọ̀tá wa pọ̀, mélòómélòó wá ló yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn, tó ṣeé ṣe kí púpọ̀ lára wọn ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun”!—Ìṣe 13:48.

4 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ìbéèrè mẹ́rin tá a lè máa fi sọ́kàn nígbà tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù: Àwọn wo ni mo fẹ́ wàásù fún? Ibo ni màá ti wàásù fún wọn? Ìgbà wo ló dára jù lọ láti lọ wàásù fáwọn èèyàn? Báwo ni kí n ṣe wàásù fún wọn? Bá a ṣe máa rí i, àwọn ìbéèrè yìí á mú ká mọ bá a ṣe lè máa gba tàwọn èèyàn tá à ń wàásù fún rò, kí ọ̀rọ̀ tá a máa sọ sì fi hàn bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́r. 9:19-23.

ÀWỌN WO NI MO FẸ́ WÀÁSÙ FÚN?

5. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

5 Tá a bá wà lóde ẹ̀rí, àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan la sábà máa ń bá sọ̀rọ̀. Ibi tí wọ́n ti tọ́ kálukú dàgbà àti ìṣòro tí kálukú ní sì yàtọ̀ síra. (2 Kíró. 6:29) Torí náà, tó o bá fẹ́ wàásù fún ẹnì kan, bi ara rẹ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé èmi ni mo wà nípò ẹni yìí, ojú wo ni màá fẹ́ kó fi wò mí? Ṣé inú mi máa dùn tó bá wò mí bí èèyàn kan lásán tó kàn ń gbé ládùúgbò? Àbí màá fẹ́ kó mọ ẹni tí mo jẹ́?’ Tá a bá ń ronú lórí irú àwọn ìbéèrè yìí, á mú ká lè máa fi ọ̀wọ̀ wọ àwọn tá à ń bá pàdé lóde ẹ̀rí.

6, 7. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá pàdé ẹnì kan tó jẹ́ aríjàgbá lóde ẹ̀rí?

6 Kò sẹ́ni tó máa fẹ́ kí wọ́n pe òun ní “elérò òdì.” Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Torí pé Kristẹni ni wá, a máa ń sa gbogbo ipá wa ká lè ṣe ohun tí Bíbélì s, pé ká ‘jẹ́ kí àsọjáde wa máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́.’ (Kól. 4:6) Àmọ́ torí pé a jẹ́ aláìpé, àwọn ìgbà míì wà tá a máa ń pa dà kábàámọ̀ ohun tá a sọ. (Ják. 3:2) Inú wa kò ní dùn tí wọ́n bá sọ wá lórúkọ tá ò jẹ́, pé “aláfojúdi” tàbí “ẹni tí kò níwà ọmọlúwàbí” ni wá torí pé a sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí ẹnì kan, láìmọ̀ pé bí nǹkan ṣe rí fún wa ló mú ká sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó dájú pé a máa retí pé kí onítọ̀hún gba tiwa rò. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà gba ti àwọn míì rò?

7 Bí ẹnì kan tó o bá pàdé lóde ẹ̀rí bá ń ṣe bí aríjàgbá, ǹjẹ́ kò ní dáa tó o bá gbà pé nǹkan kan ló fà á, kì í ṣe irú èèyàn bẹ́ẹ̀? Ṣé kì í ṣe àwọn ìṣòro kan tó ń kojú níbiiṣẹ́ tàbí níléèwé ló mú kó hùwà bẹ́ẹ̀? Àbí àìlera kan ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn tó gbaná jẹ́ nígbà tá a kọ́kọ́ bá wọn pàdé ti wá pa dà kẹ́kọ̀ọ́ torí pé àwa èèyàn Jèhófà bọ̀wọ̀ fún wọn a sì mú sùúrù fún wọn.—Òwe 15:1; 1 Pét. 3:15.

8. Kí nìdí tó fi yẹ ká múra tán láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún “ènìyàn gbogbo”?

8 Onírúurú èèyàn tó wá láti apá ibi gbogbo lágbàáyé là ń wàásù fún. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́nu ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ó lé ní ọgọ́ta [60] ìrírí àwọn èèyàn tá a tẹ̀ jáde nínú Ilé Ìṣọ́ wa nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà.” Tẹ́lẹ̀ rí, olè, ọ̀mùtí, ọmọọ̀ta tàbí àwọn tó ti sọ oògùn líle di bárakú ni díẹ̀ lára àwọn tá a tẹ ìrírí wọn jáde. Àwọn míì sì jẹ́ olóṣèlú, aṣáájú ẹ̀sìn tàbí ẹni tí àtijẹ àtimu gbà lọ́kàn. A sì rí àwọn tó yan ìṣekúṣe láàyò. Síbẹ̀, gbogbo wọ́n gbọ́ ìhìn rere, wọ́n kẹ́kọ̀ọ́  Bíbélì, wọ́n ṣe ìyípadà tó yẹ, wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká ronú láé pé àwọn kan wà tí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kò lè yí pa dà. (Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9-11.) Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbà pé “ènìyàn gbogbo” tàbí onírúurú èèyàn ló lè wá sínú òtítọ́.—1 Kọ́r. 9:22.

IBO NI MÀÁ TI WÀÁSÙ FÚN WỌN?

9. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ọ̀wọ̀ hàn nígbà tá a ba lọ wàásù fáwọn èèyàn nílé wọn?

9 Ibo la ti máa wàásù fáwọn èèyàn tá a bá wà lóde ẹ̀rí? A sábà máa ń bá wọn nílé wọn. (Mát. 10:11-13) A máa ń mọyì rẹ̀ táwọn èèyàn bá fi ọ̀wọ̀ hàn nígbà tí wọ́n bá wá sí ilé wa, tí wọn ò sì ṣe ohun tó fi hàn pé wọn kò ka ohun ìní wa sí. Ó ṣe tán, a kì í kóyán ibi tá à ń gbé kéré. A máa ń fẹ́ kó jẹ́ ibi tá a ti lè wà lómìnira ara wa kí ọkàn wa sì balẹ̀. Torí náà, ó yẹ kí àwa náà fi irú ọ̀wọ̀ bẹ́ẹ̀ hàn fáwọn aládùúgbò wa. Nípa bẹ́ẹ̀, tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, ó máa dára ká mọ bó ṣe yẹ ká ṣe tá a bá dé ilé wọn.Ìṣe 5:42.

10 Nínú ayé tí ìwà ọ̀daràn ti gbòde kan yìí, ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń lọ wàásù fún máa ń fura sí ẹni tí wọn ò bá mọ̀ rí. (2 Tím. 3:1-5) Kò yẹ ká tún máa dá kún irú ìfura bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé nígbà tá a dé ilé kan, a kan ìlẹ̀kùn àbáwọlé, a ò sì gbúròó ẹnikẹ́ni. Ó lè ṣe wá bíi pé ká yọjú wonú ilé tàbí ká rìn yíká ilé náà bóyá a máa rí ẹni tó ń gbébẹ̀. Ládùúgbò tó ò ń gbé, ṣé àwọn èèyàn ò ní ka irú ìwà bẹ́ẹ̀ sí ìyọlẹ́nu? Kí ló ṣeé ṣe kí àwọn tó jẹ́ aládùúgbò onítọ̀hún rò nípa wa? Òótọ́ ni pé gbogbo èèyàn ló yẹ ká wàásù fún. (Ìṣe 10:42) Ó máa ń wù wá pé ká sọ ìhìn rere fáwọn èèyàn, a ò sì ní èrò búburú lọ́kàn. (Róòmù 1:14, 15) Síbẹ̀, a fẹ́ fi ọgbọ́n ṣe é kó má bàa dà bíi pé à ń yọ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa lẹ́nu. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kò sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀, kí a má bàa rí àléébù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.” (2 Kọ́r. 6:3) Tá a bá ń fi ọ̀wọ̀ hàn nígbà tá a bá wà nílé àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tá ò sì ṣe ohun tó fi hàn pé a kò ka ohun ìní wọn sí, ìwà wa lè mú kí àwọn kan lára wọn wá sínú òtítọ́.—Ka 1 Pétérù 2:12.

Ẹ jẹ́ ká máa fi ọ̀wọ̀ hàn nígbà tá a bá lọ sílé àwọn èèyàn ká má sì ṣe ohun tó fi hàn pé a kò ka ohun ìní wọn sí (Wo ìpínrọ̀ 10)

ÌGBÀ WO NI MO LÈ LỌ WÀÁSÙ FÁWỌN ÈÈYÀN?

11. Kí nìdí tá a fi máa ń mọyì rẹ̀ táwọn èèyàn ò bá fi àkókò wa ṣòfò?

11 Torí pé a jẹ́ Kristẹni, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa ni ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí. Nípa bẹ́ẹ̀, a máa ń ṣètò àwọn ìgbòkègbodò wa dáadáa ká bàa lè bójú tó àwọn ojúṣe wa. (Éfé. 5:16; Fílí. 1:10) Inú wa kì í dùn táwọn èèyàn bá da ètò tá a ṣe sílẹ̀ rú. Torí náà, a máa ń mọyì rẹ̀ táwọn èèyàn ò bá fi àkókò wa ṣòfò, tí wọ́n ro tiwa mọ́ tiwọn nígbà tí wọ́n bá ń bá wa sọ̀rọ̀, tí wọn ò sì gbà wá lákòókò jù. Tá a bá ń fi Ìlànà Pàtàkì náà sọ́kàn, báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fáwọn tá à ń wàásù fún?

12. Báwo la ṣe lè mọ ìgbà tó dára jù lọ tá a lè kàn sí àwọn tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?

12 Ó yẹ ká sapá láti mọ ìgbà tó dára jù lọ tá a lè kàn sí àwọn èèyàn. Ìgbà wo làwọn èèyàn sábà máa ń wà nílé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa? Ìgbà wo ló ṣeé ṣe kí wọ́n tẹ́tí sílẹ̀? Á dára ká ṣètò àkókò wa ká lè tọ àwọn èèyàn lọ nígbà tá a máa bá wọn nílé. Ní àwọn ibì kan láyé, ọ̀sán tàbí ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ làwọn ará sábà máa ń lọ wàásù láti ilé dé ilé torí wọ́n rí i pé ìgbà yẹn ló dára jù lọ. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀ ládùúgbò tó ò ń gbé, ǹjẹ́ o lè ṣètò àkókò rẹ kó o lè máa wàásù láti ilé dé ilé nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:24.) Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún wa tá a bá yááfì ohunkóhun torí àtilọ wàásù fún àwọn tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ní àkókò tá a rí i pé ó rọ̀ wọ́n lọ́rùn jù lọ.

13. Báwo la ṣe lè bọ̀wọ̀ fún àwọn tá à ń wàásù fún?

 13 Ọ̀nà mìíràn wo la tún lè gbà bọ̀wọ̀ fún ẹnì kan? Tá a bá rí ẹni tó ṣe tán láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ó dáa ká jẹ́rìí kúnnákúnná fún un, àmọ́ kò yẹ ká wá kan ìdí mọ́ àga. Ó ṣeé ṣe kí ẹni tá à ń wàásù fún náà ti ya àkókò yẹn sọ́tọ̀ láti ṣe nǹkan míì tó kà sí pàtàkì. Tó bá sọ pé ọwọ́ òun dí, a lè sọ fún un pé ọ̀rọ̀ wa ò ní gùn, ká sì mú ìlérí wa ṣẹ. (Mát. 5:37) Tá a bá fẹ́ parí ọ̀rọ̀ wa, á dára ká béèrè ìgbà tí onítọ̀hún máa fẹ́ ká pa dà wá bẹ òun wò. Ohun kan wà táwọn akéde kan ti rí pé ó gbéṣẹ́ gan-an. Wọ́n á ní: “Á wù mí pé kí n tún pa dà wá. Ṣé ẹ máa fẹ́ kí n pè yín lórí fóònù tàbí kí n tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ sí yín kí n tó wá?” Tá a bá mú àkókò tiwa bá àkókò àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa mu, ńṣe là ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, tí kì í ‘wá àǹfààní ti ara rẹ̀ bí kò ṣe ti ọ̀pọ̀ ènìyàn, kí a bàa lè gbà wọ́n là.’—1 Kọ́r. 10:33.

BÁWO NI KÍ N ṢE WÀÁSÙ FÚN WỌN?

14-16. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kí ẹni tá a fẹ́ wàásù fún mọ ohun tó gbé wa wá sílé rẹ̀? Ṣàkàwé. (b) Ọ̀nà wo ni alábòójútó arìnrìn-àjò kan rí i pé ó gbéṣẹ́ láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?

14 Rò ó wò ná, ká sọ pé lọ́jọ́ kan ni ẹnì kan tá ò mọ̀ rí ṣàdédé pè wá lórí fóònù. Lẹni tá ò mọ̀ rí yìí bá ń bi wá léèrè irú oúnjẹ tá a fẹ́ràn. Ńṣe ni a ó máa ronú ẹni tí onítọ̀hún lè jẹ́ àti ohun tó fẹ́ gan-an. Torí pé a bọ̀wọ̀ fún onítọ̀hún, a lè bá a sọ̀rọ̀ díẹ̀, àmọ́ ó ṣeé ṣe ká wá ọ̀nà tá a fi máa jẹ́ kó mọ̀ pé a ò ní fẹ́ máa bá ìjíròrò náà lọ. Ṣùgbọ́n, jẹ́ ká sọ pé onítọ̀hún dárúkọ ara rẹ̀,  ó sọ fún wa pé ilé iṣẹ́ tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ oúnjẹ lòun ti ń ṣiṣẹ́, tó sì rọ̀ wá pé ká tẹ́tí sí ìsọfúnni kan tó máa ṣe wá láǹfààní tí òun fẹ́ sọ fún wa. Ó ṣeé ṣe ká fara balẹ̀ tẹ́tí sí i. Ó ṣe tán, a máa ń mọyì rẹ̀ nígbà táwọn èèyàn bá sọ ẹni tí wọ́n jẹ́ àtohun tí wọ́n fẹ́, tí wọ́n sì fi ọ̀wọ̀ wọ̀ wá. Báwo làwa náà ṣe lè hu irú ìwà ọmọlúwàbí yìí nígbà tá a bá bá àwọn èèyàn pàdé lóde ẹ̀rí?

15 Ní ọ̀pọ̀ ibi láyé, ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ kí onílé tètè mọ ìdí tá a fi wá sọ́dọ̀ rẹ̀. A gbà pé ẹni tá a fẹ́ wàásù fún lè má mọ̀ pé ohun tó máa ṣe òun láǹfààní la tìtorí rẹ̀ wá, àmọ́ ṣe kò ní kù díẹ̀ káàtó, tó bá jẹ́ pé a ò dárúkọ ara wa àti ìdí tá a fi wá, tá a sì wá ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Tó o bá lágbára láti yanjú àwọn ìṣòro tó wà láyé yìí, èwo lo máa kọ́kọ́ yanjú níbẹ̀?” A mọ̀ pé torí ká lè mọ èrò rẹ̀ la ṣe béèrè irú ìbéèrè yẹn, a sì fẹ́ kó mọ ohun tí Bíbélì sọ. Ṣùgbọ́n, ó lè máa ronú pé: ‘Ta ni àjèjì tí mi ò mọ̀ rí tó wá ń da ìbéèrè bò mí yìí? Kí ló pa èmi àtiẹ̀ pọ̀?’ Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa sọ̀rọ̀ lọ́nà táá mú kí ara tu àwọn tá à ń wàásù fún. (Fílí. 2:3, 4) Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

16 Ohun kan wà tí alábòójútó arìnrìn-àjò kan máa ń ṣe tó ń mú kí ara tu àwọn èèyàn. Ohun tó máa ń ṣe ni pé lẹ́yìn tí òun àti ẹni tó fẹ́ wàásù fún bá ti kíra, á fún un ní ẹ̀dà ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? Lẹ́yìn náà, á wá sọ pé: “Gbogbo èèyàn tó wà lágbègbè yìí là ń fún ní ìwé yìí lónìí. Ó jíròrò ìbéèrè mẹ́fà tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè. Ẹ̀dà tìrẹ rèé.” Arákùnrin yìí sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ara máa ń tù gbàrà tí òun bá ti jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí òun bá wá. Tí ara bá ti tù wọ́n, ó sábà máa ń rọrùn láti bá wọn jíròrò. Ìbéèrè míì tí alábòójútó arìnrìn-àjò náà á bi onítọ̀hún ni pé: “Ǹjẹ́ o ti ronú nípa èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè yìí rí?” Tó bá yan ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè náà, arákùnrin yìí á ṣí ìwé àṣàrò kúkúrú náà, á wá bá a jíròrò ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbéèrè náà. Bí kò bá sì tọ́ka sí èyíkéyìí lára ìbéèrè náà, arákùnrin náà á yan ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè náà, á sì máa bá ìjíròrò lọ láìdójú ti ẹni tó ń wàásù fún. Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló wà téèyàn lè gbà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀. Láwọn ibì kan, ẹni tá à ń wàásù fún lè retí pé ká béèrè ọkọ, aya, ọmọ àtàwọn aráalé ká tó sọ ohun tá a bá wá. Kókó ibẹ̀ ni pé kéèyàn mọ ohun tí àwọn tó wà lágbègbè ibi tó ti ń wàásù fẹ́, kéèyàn sì hùwà bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.

MÁA FI ÌLÀNÀ PÀTÀKÌ NÁÀ SÍLÒ LÓDE Ẹ̀RÍ

17. Bá a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà lo Ìlànà Pàtàkì náà?

17 Kí wá ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi Ìlànà Pàtàkì náà sílò tá a bá ń wàásù? A máa ń fi ọ̀wọ̀ wọ àwọn tá à ń wàásù fún, a kì í sì í ṣe ohun tó fi hàn pé a kò ka ohun ìní wọn sí. A máa ń sapá láti lọ sóde ẹ̀rí nígbà tá a mọ̀ pé àwọn èèyàn á wà nílé àti lásìkò tá a mọ̀ pé wọ́n á fẹ́ láti gbọ́rọ̀ wa. A máa ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wa lọ́nà táá mú kí ara tu àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa.

18. Tó bá jẹ́ pé bá a ṣe fẹ́ kí àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ṣe sí wa làwa náà ń ṣe sí wọn, àǹfààní wo la máa rí?

18 Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí tó bá jẹ́ pé bá a ṣe fẹ́ kí àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ṣe sí wa làwa náà ń ṣe sí wọn. Bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wọn, tá a sì ń gba tiwọn rò, ńṣe là ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn, à ń jẹ́ kí wọ́n rí i pé ìlànà inú Ìwé Mímọ́ ń ṣeni láǹfààní, a sì ń fi ògo fún Baba wa ọ̀run. (Mát. 5:16) Ọ̀nà tá à ń gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lè mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ wá sínú òtítọ́. (1 Tím. 4:16) Yálà àwọn tá à ń wàásù fún wá sínú òtítọ́ tàbí wọn kò wá, inú wa máa ń dùn pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (2 Tím. 4:5) Ǹjẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó sọ pé: “Mo ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.” (1 Kọ́r. 9:23) Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká rí i pé ìgbà gbogbo là ń fi Ìlànà Pàtàkì náà sílò tá a bá ń wàásù.