Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) May 2014

Ẹ̀dà yìí sọ ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà dáhùn ìbéèrè tó ta kókó lóde ẹ̀rí lọ́nà táá yí àwọn èèyàn lérò pa dà. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká dúró ti ètò Ọlọ́run láìyẹsẹ̀?

‘Oúnjẹ Mi Ni Láti Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run’

Inú Dáfídì, Pọ́ọ̀lù àti Jésù máa ń dùn gan-an láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kí la lè ṣe tá ò fi ní káàárẹ̀ tí ìtara wa á sì dọ̀tun níbi tí iṣẹ́ ìwàásù ò ti rọrùn?

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa ‘Dá Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Lóhùn’?

Bá a ṣe lè fèrò wérò lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ tí wọ́n bá bi wá ní ìbéèrè tó ta kókó. Wo ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà dáhùn lọ́nà táá yí àwọn èèyàn lérò pa dà.

Máa Fi Ìlànà Pàtàkì Náà Sílò Lóde Ẹ̀rí

Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sẹ́nì kọ̀ọ̀kan tá a bá rí lóde ẹ̀rí? Báwo ni ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 7:12 ṣe kan iṣẹ́ ìwàásù wa?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Ti Ràn Mí Lọ́wọ́ Ní Ti Tòótọ́

Kenneth Little sọ bí Jèhófà ṣe ran òun lọ́wọ́ láti lè nígboyà àti láti borí ìtìjú. Wo bí Ọlọ́run sì ṣe bu kún ìsapá tó ṣe ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

Ọlọ́run Ètò Ni Jèhófà

Báwo ni ìtàn nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ àti tàwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní wà létòlétò?

Ǹjẹ́ Ò Ń Bá Ètò Jèhófà Rìn Bó Ṣe Ń Tẹ̀ Síwájú?

Ètò àwọn nǹkan Sátánì máa tó wá sópin. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká dúró ti ètò tí Ọlọ́rùn ń lò láyé lónìí láìyẹsẹ̀?

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

‘Ìkórè Ṣì Pọ̀’

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní 760,000 ló ń wàásù ìhìn rere náà ní orílẹ̀-èdè Brazil. Báwo làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkórè ní Amẹ́ríkà Gúúsù?