Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  April 2014

Jẹ́ Onígboyà Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Rẹ!

Jẹ́ Onígboyà Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Rẹ!

‘Jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí o sì sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi.”’—HÉB. 13:6.

ỌKÙNRIN kan tó ń jẹ́ Eduardo * sọ pé: “Nígbà tí mo wà lókè òkun, mo níṣẹ́ gidi lọ́wọ́, owó tabua sì ń wọlé fún mi. Ṣùgbọ́n, nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mo wá rí i pé mo ní ojúṣe míì tó ṣe pàtàkì ju kí n máa fowó ránṣẹ́ sílé, ìyẹn ni pé kí n wà pẹ̀lú ìdílé mi kí n sì rí i pé wọ́n ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Torí bẹ́ẹ̀, mo pa dà sílé.”—Éfé. 6:4.

1, 2. Ìṣòro wo ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ṣí lọ sí ilẹ̀ òkèèrè máa ń ní nígbà tí wọ́n bá pa dà sílé? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

2 Eduardo mọ̀ pé òun mú inú Jèhófà dùn bí òun ṣe pa dà sọ́dọ̀ ìdílé òun. Àmọ́ bíi ti Marilyn tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ó gba Eduardo náà lákòókò kó tó di pé àárín òun àti ìdílé rẹ̀ pa dà gún régé. Òun náà rí i pé kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti pèsè fún taya-tọmọ ní orílẹ̀-èdè tí nǹkan ò ti fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ṣọ̀mù. Báwo ló ṣe máa wá gbọ́ bùkátà wọn? Ìrànlọ́wọ́ wo ló lè retí pé àwọn míì nínú ìjọ máa ṣe fún òun?

Ó TÚN ÀJỌṢE RẸ̀ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN ÀTI ÌDÍLÉ RẸ̀ ṢE

3. Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn ọmọ bí bàbá tàbí màmá wọn kò bá sí pẹ̀lú wọn?

3 Eduardo sọ pé: “Mo gbà pé mi ò sí pẹ̀lú àwọn ọmọ mi nígbà tí wọ́n nílò mi láti máa tọ́ wọn sọ́nà kí n sì máa fìfẹ́ hàn sí wọn. Àjò ni mo wà ní gbogbo ìgbà tó yẹ kí n máa ka ìtàn Bíbélì sí wọn  létí, ká jọ máa gbàdúrà, kí n máa gbá wọn mọ́ra, kí n sì máa bá wọn ṣeré.” (Diu. 6:7) Anna tó jẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà sọ pé: “Ńṣe ni mo dà bí ẹni tí kò ní alábàárò ní gbogbo ìgbà tí dádì wa ò fi sí nílé. Nígbà tí wọ́n pa dà dé, ńṣe ni wọ́n dà bí àjèjì sí wa. Ó sì máa ń ṣe wá bákan tí wọ́n bá gbá wa mọ́ra.”

4. Bí ọkọ ò bá sí nílé, báwo ló ṣe lè ṣòro fún un láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé?

4 Àìsínílé bàbá lè mú kó ṣòro fún un láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé. Ruby tó jẹ́ ìyàwó Eduardo sọ pé: “Ó wá di dandan pé kí n máa ṣe ojúṣe tèmi àti tọkọ mi, ó sì ti mọ́ mi lára pé kí n máa pinnu ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ìdílé. Nígbà tí ọkọ mi pa dà dé ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá kọ́ bó ṣe yẹ kí Kristẹni aya máa fi ara rẹ̀ sábẹ́ ọkọ rẹ̀ ní ti gidi. Kódà lẹ́yìn tó ti dé, ìgbà míì wà tí mo ní láti máa rán ara mi létí pé ọkọ ní olórí aya.” (Éfé. 5:22, 23) Eduardo fi kún un pé: “Ó ti mọ́ àwọn ọmọ wa lára pé kí wọ́n máa gba àyè lọ́wọ́ ìyá wọn tí wọ́n bá fẹ́ ṣe nǹkan. A wá rí i pé gẹ́gẹ́ bí òbí, a gbọ́dọ̀ pawọ́ pọ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ wa, èmi náà sì rí i pé ó yẹ kí n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi bí mo ṣe ń darí ìdílé mi.”

5. Báwo ni bàbá kan ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í yanjú ìṣòro tí àìsínílé rẹ̀ dá sílẹ̀? Kí ni àbájáde ohun tó ṣe?

5 Eduardo pinnu pé òun máa sa gbogbo ipá òun kí àjọṣe ìdílé òun lè pa dà gún régé, kí àwọn sì túbọ̀ ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ohun tó wà lọ́kàn mi ni pé kí n gbin òtítọ́ sọ́kàn àwọn ọmọ mi, lọ́rọ̀ àti níṣe. Kì í ṣe kí n wulẹ̀ sọ pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, mo fẹ́ fi hàn pé òótọ́ ni mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (1 Jòh. 3:18) Ǹjẹ́ Jèhófà bù kún ohun tó fi ìgbàgbọ́ hàn tí Eduardo ṣe yìí? Ọmọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Anna sọ pé: “Bá a ṣe rí i tí dádì ń sapá láti jẹ́ bàbá rere tí wọ́n sì tún ń sún mọ́ wa jẹ́ ká rí i pé ìyàtọ̀ ńláǹlà ti wà. Ìwúrí ló sì jẹ́ fún wa bí wọ́n ṣe ń ṣe ohun táá jẹ́ kí wọ́n lè máa sìn nínú ìjọ. Ayé yìí fẹ́ mú ká jìnnà sí Jèhófà. Àmọ́, a rí i pé àwọn òbí wa pọkàn pọ̀ sórí òtítọ́, àwa náà sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Dádì ṣèlérí fún wa pé àwọn ò ní já wa jù sílẹ̀ mọ́, wọ́n sì mú ìlérí wọn ṣẹ. Bóyá ni màá wà nínú ètò Jèhófà lónìí ká sọ pé wọ́n tún pa dà lọ ni.”

Ẹ MÁA ṢE OJÚṢE YÍN

6. Ẹ̀kọ́ wo làwọn òbí kan kọ́ lásìkò tí ogun jà nílẹ̀ wọn?

6 Àwọn ìrírí kan tá a gbọ́ fi hàn pé nígbà tí ogun jà láwọn àgbègbè Balkan, inú àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ máa ń dùn bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò àwọn nǹkan nira fún wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé, ogun náà kò jẹ́ kí àwọn òbí wọn lè lọ síbi iṣẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ráyè kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n ń bá wọn ṣeré, wọ́n sì ń bá wọn sọ̀rọ̀. Kí nìyẹn kọ́ wa? Ó kọ́ wa pé yàtọ̀ sí owó tàbí ẹ̀bùn, ohun táwọn ọmọ nílò jù lọ ni pé kí ẹ̀yin òbí máa wà pẹ̀lú wọn. Ká sòótọ́, bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ ọ́ náà ló rí, ó máa ṣe àwọn ọmọ yín láǹfààní gan-an tí ẹ̀yin òbí bá ń wáyè gbọ́ tiwọn, tẹ́ ẹ sì ń kọ́ wọn.—Òwe 22:6.

7, 8. (a) Àṣìṣe wo làwọn òbí kan tó pa dà sílé máa ń ṣe? (b) Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti borí èrò òdì?

7 Nígbà tí àwọn òbí kan pa dà délé, ohun tí wọ́n retí kọ́ ni wọ́n bá. Ńṣe làwọn ọmọ kójú kúrò nílẹ̀, wọn ò sì náání ohun tí òbí yẹn ń ṣe. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ á fa ìbínú yọ, wọ́n á sì sọ pé, “Ẹyin ọmọ yìí ṣe ya aláìmoore báyìí, tẹ́ ẹ sì mọ̀ pé torí yín ni mo ṣe forí jágbó lọ?” Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí bí àwọn òbí wọn ṣe fi wọ́n sílẹ̀ ló fà á tí àwọn ọmọ náà fi hùwà bẹ́ẹ̀. Torí náà, kí ni òbí kan lè ṣe láti fa ojú àwọn ọmọ rẹ̀ mọ́ra?

8 Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fi sùúrù bá ìdílé rẹ lò. Tó o bá sì ń bá ìdílé rẹ sọ̀rọ̀, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìwọ náà jẹ nínú ẹ̀bi ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí, kó o sì gba ẹ̀bi rẹ lẹ́bi. Ọkàn wọn lè rọ̀ tó o bá tọrọ àforíjì látọkànwá lọ́wọ́ wọn. Bí ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ bá ṣe ń kíyè sí i pé gbogbo ìgbà lò ń wá bí nǹkan ṣe máa pa dà gún régé, wọ́n máa gbà pé kì í ṣe ojú ayé lò ń ṣe. Tó o bá sa gbogbo ipá rẹ tó o sì mú sùúrù, aya rẹ àtàwọn ọmọ rẹ lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ọ.

 ‘MÁA PÈSÈ FÚN ÀWỌN TÌRẸ’

9. Kí nìdí tí pípèsè fún ìdílé ẹni ò fi dandan túmọ̀ sí pé kéèyàn máa forí ṣe fọrùn ṣe kó lè ní àníkún nǹkan tara?

9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé tó bá di pé àwọn Kristẹni tó ti dàgbà kò lè bójú tó ara wọn mọ́, kí àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ ọmọ “san àsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí wọn àti àwọn òbí wọn àgbà.” Àmọ́ Pọ́ọ̀lù tún rọ gbogbo Kristẹni pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn nǹkan kòṣeémánìí ojoojúmọ́, bí oúnjẹ, aṣọ àti ilé, tẹ́ wọn lọ́rùn. Kò sídìí láti máa forí ṣe fọrùn ṣe torí ká lè máa gbé ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì tàbí ká lè kó ọrọ̀ jọ torí ọjọ́ iwájú. (Ka 1 Tímótì 5:4, 8; 6:6-10.) Kò pọn dandan pé kí Kristẹni kan máa lépa ọrọ̀ nínú ayé tó máa tó kọjá lọ yìí torí kó lè “pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” (1 Jòh. 2:15-17) A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí “agbára ìtannijẹ ọrọ̀” tàbí “àníyàn ìgbésí ayé” mú kí ìdílé wa dẹwọ́ nínú dídi “ìyè tòótọ́” nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run “mú gírígírí”!—Máàkù 4:19; Lúùkù 21:34-36; 1 Tím. 6:19.

10. Báwo ni ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa tọrùn bọ gbèsè?

10 Jèhófà mọ̀ pé a nílò owó díẹ̀. Àmọ́, ọgbọ́n Ọlọ́run ló lè dáàbò bò wá kó sì dá ẹ̀mí wa sí, kì í ṣe owó. (Oníw. 7:12; Lúùkù 12:15) Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó ń lọ sókè òkun máa ń fojú kéré owó tó ń ná wọn, kò sì dájú pé wọ́n máa rí towó ṣe níbẹ̀. Kódà, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn rí oko ní oko ikún, tó wá lọ gbin ẹ̀pà sí i. Gbèsè tó wà nílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ lára wọn kí wọ́n tó lọ sókè òkun kò tó èyí tó bá wọn wálé. Kàkà kí wọ́n túbọ̀ ní òmìnira láti máa sin Ọlọ́run, ńṣe ni wọ́n di ẹrú fún àwọn tó yá wọn lówó. (Ka Òwe 22:7.) Ohun tó ti bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn má tiẹ̀ tọrùn bọ gbèsè rárá.

11. Bí ìdílé bá ń tẹ̀ lé ètò tí wọ́n ṣe láti máa náwó, báwo ni kò ṣe ní jẹ́ kí wọ́n wọko gbèsè?

11 Eduardo mọ̀ pé tóun bá máa dúró lórí ìpinnu tóun ṣe pé òun ò ní fi ìdílé òun sílẹ̀ mọ́, òun gbọ́dọ̀ mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná. Òun àti ìyàwó rẹ̀ gbé ìṣirò lé àwọn nǹkan tí wọ́n nílò, ìyẹn ni wọ́n sì lò láti ṣètò bí wọ́n á ṣe máa náwó. Ohun kan ni pé ètò ìṣúnná owó tí wọ́n ṣe kò fún wọn láyè láti máa náwó bí wọ́n ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Àmọ́ gbogbo wọn fọwọ́ sowọ́ pọ̀, wọn ò sì ra àwọn ohun tí kò pọn dandan. * Eduardo sọ pé: “Bí àpẹẹrẹ, mo mú àwọn ọmọ wa kúrò nílé ẹ̀kọ́ àdáni, mo sì fi wọ́n sílé ẹ̀kọ́ ìjọba tí wọ́n ti ń kọ́mọ níwèé dáadáa.” Òun àti ìdílé rẹ̀ gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí òun rí iṣẹ́ tí kò ní dí òun lọ́wọ́ àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà. Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà wọn?

12 Eduardo rántí pé: “Láàárín ọdún méjì ti mo pa dà dé, nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ. Owó tí mo ní lọ́wọ́ ti ń tán lọ, owó oṣù mi kò tó gbọ́ bùkátà, ó sì máa ń rẹ̀ mí gan-an. Àmọ́, a máa ń lọ sí gbogbo ìpàdé, a sì máa ń jáde òde ẹ̀rí.” Eduardo tún pinnu pé òun ò ní ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá máa mú kóun fi ìdílé òun sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù tàbí ọdún. Ó wá sọ pé: “Kàkà bẹ́ẹ̀, mo kọ́ onírúurú iṣẹ́ tó fi jẹ́ pé bí ìkan kò bá ṣe, òmíì á ṣe.”

Ṣé o lè kọ́ onírúurú iṣẹ́ tí wàá lè máa fi gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ? (Wo ìpínrọ̀ 12)

12, 13. Àwọn ohun tó bọ́gbọ́n mu wo ni bàbá kan ṣe kó lè máa pèsè fún ìdílé rẹ̀? Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún ìpinnu tí bàbá náà ṣe pé òun á máa jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ òun lọ́rùn?

13 Torí pé díẹ̀díẹ̀ ni Eduardo ní láti máa san àwọn gbèsè tó jẹ, èlé tó ní láti san lórí owó tó yá náà pọ̀ ju ojú owó lọ. Àmọ́, ó gbà pé ìyẹn ò tó nǹkan bí òun bá ṣáà ti wà pẹ̀lú ìdílé òun tí àwọn sì jọ ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò wọn, ó ṣe tán, ohun tí Jèhófà fẹ́ káwọn òbí máa ṣe nìyẹn. Eduardo sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó tí mò ń rí báyìí kò ju ìdá kan nínú mẹ́wàá èyí tí mò ń rí ní òkè òkun, síbẹ̀ ebi ò pa wá. ‘Ọwọ́ Jèhófà kò kúrú.’ Kódà, a tún gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé nígbà tó yá, ọ̀rọ̀ ìṣúnná owó rọjú, ó sì wá túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa gbọ́ bùkátà wa.”—Aísá. 59:1.

 BÁ Ò ṢE NÍ JẸ́ KÍ ÌDÍLÉ MÚ WA ṢE OHUN TÍ KÒ TỌ́

14, 15. Báwo làwọn ìdílé ò ṣe ní jẹ́ káwọn míì mú kí wọ́n pa àwọn nǹkan tẹ̀mí tì torí àtimáa lépa àwọn nǹkan tara? Kí ló lè ṣẹlẹ̀ táwọn ìdílé bá fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀?

14 Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn gbà pé ojúṣe àwọn ni pé káwọn máa fún àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ ní owó àti ẹ̀bùn. Eduardo sọ pé: “Bó ṣe rí nínú àṣà wa nìyẹn, ó sì máa ń dùn mọ́ wa láti fáwọn èèyàn ní nǹkan.” Ó wá fi kún un pé: “Àmọ́, ó níbi tó mọ o. Mo fọgbọ́n sọ fún àwọn ẹbí mi pé màá máa fún wọn ní nǹkan tí agbára mi bá gbé láìjẹ́ kó dí ìjọsìn àtàwọn ìgbòkègbodò ìdílé mi lọ́wọ́.”

15 Ohun tí ojú àwọn tó pa dà sílé láti ilẹ̀ òkèèrè àtàwọn tí kò gbà láti lọ rárá ń rí kì í ṣe kékeré. Ìjákulẹ̀ ló máa ń jẹ́ fún àwọn ẹbí tó ń retí pé wọ́n á máa ti òkè òkun gbọ́ bùkátà ìdílé, torí bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń bínú sí wọn, wọ́n sì máa ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Àwọn kan tiẹ̀ kà wọ́n sí ọ̀dájú. (Òwe 19:6, 7) Àmọ́, Anna, ìyẹn ọmọ Arákùnrin Eduardo sọ pé: “Tá ò bá pa àwọn nǹkan tẹ̀mí tì torí àtimáa lépa àwọn nǹkan tara, bópẹ́ bóyá, a lè rí lára àwọn ẹbí wa tí wọ́n á rí i pé ọwọ́ pàtàkì la fi mú ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe máa mọ̀ tá a bá ṣe ohun tí wọ́n fẹ́?”—Fi wé 1 Pétérù 3:1, 2.

BÓ O ṢE LÈ LO ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ ỌLỌ́RUN

16. (a) Báwo ni ẹnì kan ṣe lè fi ‘èrò èké tan ara rẹ̀ jẹ’? (Ják. 1:22) (b) Irú ìpinnu wo ni Jèhófà máa ń bù kún?

16 Arábìnrin kan fi ọkọ àtàwọn ọmọ rẹ̀ sílé ó sì dá lọ sí orílẹ̀-èdè kan tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù. Nígbà tó débẹ̀, ó sọ fún àwọn alàgbà pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan la yááfì kí n lè wá síbí. Kódà ọkọ mi fi ipò alàgbà sílẹ̀. Torí náà, ó dá mi lójú pé Jèhófà máa bù kún wíwá tí mo wá síbí.” Òótọ́ ni pé Jèhófà máa ń bù kún àwọn ìpinnu tó bá fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú rẹ̀, àmọ́ báwo ló ṣe lè bù kún ìpinnu tó ta ko ìfẹ́ rẹ̀, pàápàá tírú ìpinnu bẹ́ẹ̀ bá mú kéèyàn pa àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tì láìnídìí kan tó ṣe gúnmọ́?—Ka Hébérù 11:6; 1 Jòhánù 5:13-15.

17. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà ká tó ṣe ìpinnu? Báwo la ṣe lè wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀?

17 Máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà kó o tó ṣe ìpinnu tàbí àdéhùn èyíkéyìí, kì í ṣe lẹ́yìn tó o bá ti ṣe é tán. Gbàdúrà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà, pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ọgbọ́n.  (2 Tím. 1:7) Bi ara rẹ pé: ‘Lábẹ́ àwọn ipò wo ló ti máa ń wù mí pé kí n ṣègbọràn sí Jèhófà? Tí mo bá kojú inúnibíni ńkọ́?’ Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé wàá ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ tó bá tiẹ̀ gba pé kó o jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ ọ lọ́rùn? (Lúùkù 14:33) Ní kí àwọn alàgbà gbà ọ́ nímọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́, kó o sì fi hàn pé o nígbàgbọ́ nínú ìlérí Jèhófà àti pé o fọkàn tán an nípa fífi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò. Àwọn alàgbà ò ní bá ẹ ṣèpinnu, àmọ́ wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe yíyàn táá mú kó o láyọ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—2 Kọ́r. 1:24.

18. Ta ló yẹ kó máa bójú tó ìdílé? Àwọn nǹkan wo ló lè mú kí àwọn míì ṣèrànwọ́?

18 Ìkáwọ́ olórí ìdílé ni Jèhófà fi gbígbé “ẹrù” ìdílé rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́ sí. Ó yẹ ká máa yin àwọn tó dúró ti ìdílé wọn tí wọ́n sì bójú tó wọn ká sì tún máa fi wọ́n sádùúrà. Ìdí ni pé wọ́n kọ̀ láti fi aya tàbí àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò nǹkan le àti pé àwọn èèyàn ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ìṣòro téèyàn ò rò tẹ́lẹ̀ bí ìjábá tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, lè mú ká rí ìdí tó fi yẹ ká fi ojúlówó ìfẹ́ ará àti ìgbatẹnirò hàn fún àwọn ará wa. (Gál. 6:2, 5; 1 Pét. 3:8) Ǹjẹ́ o lè fún wọn lówó nírú àsìkò pàjáwìrì bẹ́ẹ̀, tàbí kẹ̀ bóyá o lè wá iṣẹ́ fún arákùnrin rẹ ní àgbègbè ibi tẹ́ ẹ̀ ń gbé? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní sídìí fún arákùnrin náà láti fi ìdílé rẹ̀ sílẹ̀ torí pé ó ń wáṣẹ́ lọ sílẹ̀ míì.—Òwe 3:27, 28; 1 Jòh. 3:17.

RÁNTÍ PÉ JÈHÓFÀ NI OLÙRÀNLỌ́WỌ́ RẸ!

19, 20. Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkàn àwọn Kristẹni balẹ̀ pé Jèhófà máa ran àwọn lọ́wọ́?

19 Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí [Ọlọ́run] ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’ Kí a lè jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí a sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?’” (Héb. 13:5, 6) Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe jóòótọ́ sí?

20 Alàgbà kan tó ti ń sìn tipẹ́ ní orílẹ̀-èdè kan tí nǹkan kò ti fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ṣọ̀mù sọ pé: “Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé ńṣe ni inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn ṣáá. Wọ́n tún máa ń kíyè sí i pé ìgbà gbogbo ni àwọn ará wa tí kò rí já jẹ pàápàá máa ń múra dáadáa, ó sì dà bíi pé nǹkan ṣẹnuure fún wọn ju àwọn míì lọ.” Èyí bá ìlérí tí Jésù ṣe fún àwọn tó bá fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ mu. (Mát. 6:28-30, 33) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, Jèhófà Baba rẹ ọ̀run nífẹ̀ẹ́ rẹ kò sì fẹ́ kí láburú kankan ṣẹlẹ̀ sí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ. Bíbélì sọ pé: “Ojú [Jèhófà] ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíró. 16:9) Ó ti fún wa ní àwọn òfin rẹ̀, títí kan àwọn tó dá lórí ọ̀rọ̀ ìdílé àtàwọn ohun tá a nílò nípa tara. Àwọn òfin rẹ̀ sì ń ṣe wá láǹfààní. Tá a bá pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ a sì fọkàn tán an. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.”—1 Jòh. 5:3.

21, 22. Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá máa fọkàn tán Jèhófà?

21 Eduardo sọ pé: “Mo mọ̀ pé mi ò lè san àkókò tí mi ò fi wà pẹ̀lú ìyàwó àtàwọn ọmọ mi pa dà, àmọ́ mi ò kábàámọ̀ pé mo pa dà wálé. Ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ lọ ti dolówó rẹpẹtẹ, àmọ́ wọn ò láyọ̀. Ńṣe ni ìṣòro ń ṣubú lu ìṣòro nínú ìdílé wọn. Àmọ́ ní tiwa, ìdílé wa ń láyọ̀ ṣáá ni! Orí mi sì máa ń wú tí mo bá ń rí bí àwọn ará wa tó wà lórílẹ̀-èdè yìí ṣe ń fi nǹkan tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́, bí wọn ò tiẹ̀ rí já jẹ. Gbogbo wa pátá là ń jadùn ohun tí Jésù ṣèlérí.”—Ka Mátíù 6:33.

22 Jẹ́ onígboyà! Pinnu pé wàá ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, kó o sì fọkàn tán an. Jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run, ìyàwó tàbí ọkọ rẹ àtàwọn ọmọ rẹ mú kó o ṣe ojúṣe rẹ, ìyẹn láti mú kí ìdílé rẹ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ rẹ’ ní tòótọ́.

^ ìpínrọ̀ 1 A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

^ ìpínrọ̀ 11 Wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó jíròrò béèyàn ṣe lè ṣọ́wó ná, tá a pè ní “How to Manage Money,” nínú Jí! September 2011 lédè Gẹ̀ẹ́sì.