Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  April 2014

 ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Ibi Tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún Gbé Mi Dé

Ibi Tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún Gbé Mi Dé

Ó ti pé ọdún márùnlélọ́gọ́ta [65] tí mo ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún báyìí. Tí mo bá ronú lórí àwọn ọdún yẹn, mo lè fi gbogbo ẹnu sọ pé ayé mi ládùn, ó sì lóyin. Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé kò sí ìṣòro kankan rárá o! (Sm. 34:12; 94:19) Àmọ́ lápapọ̀, ìgbésí ayé mi nítumọ̀, mo sì rí ọ̀pọ̀ ìbùkún!

NÍ September 7, ọdún 1950 mo di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn. Gbogbo àwa tá à ń sìn níbẹ̀ nígbà yẹn lọ́kùnrin àti lóbìnrin jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti márùnléláàádọ́ta [355], a wá láti orílẹ̀-èdè tó yàtọ̀ síra. Ẹni tó kéré jù jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] nígbà tẹ́ni tó dàgbà jù jẹ́ ọgọ́rin [80] ọdún, ọ̀pọ̀ ló sì jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró.

BÍ MO ṢE BẸ̀RẸ̀ SÍ Í SIN JÈHÓFÀ

Ìgbà tí mo ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún mẹ́wàá

Ọ̀dọ̀ ìyá mi ni mo ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run wa tó jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tím. 1:11) Mo ṣì kéré gan-an nígbà tí ìyá mi bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà. Àmọ́, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́wàá, a ṣe àpéjọ àyíká kan ní July 1, ọdún 1939 ní ìlú Columbus ní ìpínlẹ̀ Nebraska, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ibẹ̀ ni mo sì ti ṣèrìbọmi. Àwa bí ọgọ́rùn-ún la pé jọ sí ibì kan tá a háyà, ká lè gbọ́ àsọyé Arákùnrin Joseph Rutherford tí wọ́n gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé náà ni, “Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ Tàbí Òmìnira.” Nígbà tá a fi máa gbọ́ àsọyé náà dé ìdajì, àwọn jàǹdùkú kan kóra jọ sí ìta gbọ̀ngàn kékeré tá a wà. Wọ́n já wọlé, wọ́n da ìpàdé wa rú, wọ́n sì lé wa jáde kúrò ní ìlú náà. Ńṣe la lọ pé jọ sínú oko arákùnrin kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìn sílùú, ibẹ̀ la sì ti gbọ́ èyí tó kù lára àsọyé náà. Ẹ lè wá rí ìdí ti mi ò fi jẹ́ gbàgbé ọjọ́ tí mo ṣèrìbọmi!

Ìyá mi sa gbogbo ipá wọn láti tọ́ mi dàgbà nínú òtítọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé baba rere tó mọyì ọmọ ni bàbá mi, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ìsìn, wọn ò sì bìkítà nípa ipò tẹ̀mí wa. Ṣùgbọ́n ìyá mi àtàwọn Ẹlẹ́rìí míì nínú Ìjọ Omaha fún mi ní ìṣírí tí mo nílò gan-an nígbà yẹn.

MO PINNU OHUN TÍ MO FẸ́ FI ÌGBÉSÍ AYÉ MI ṢE

Nígbà tó ku díẹ̀ kí n ṣe tán ní ilé ẹ̀kọ́ girama, mo ní láti pinnu ohun tí máa fi ìgbésí ayé mi ṣe. Ní gbogbo ìgbà tá a bá gba ìsinmi ìgbà ẹ̀rùn, èmi àti àwọn ojúgbà mi kan máa ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò ìsinmi (èyí tá à ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ báyìí).

Wọ́n rán àwọn arákùnrin méjì kan tí wọ́n jẹ́ àpọ́n, ìyẹn John Chimiklis àti Ted Jaracz, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì keje ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì láti wá máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò ní àgbègbè wa. Ó yà mí lẹ́nu láti mọ̀ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ogún ọdún ni. Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni mí nígbà yẹn, mo sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣe tán ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Mo ṣì rántí ìgbà tí Arákùnrin  Chimiklis bi mí pé kí ni mo fẹ́ fi ìgbésí ayé mi ṣe. Nígbà tí mo sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún un, ó rọ̀ mí pé: “Bó bá ti yá kì í tún pẹ́ mọ́, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. O ò lè sọ ibi tó máa gbé ẹ dé.” Ìmọ̀ràn tó fún mi yẹn, tó fi mọ́ àpẹẹrẹ àwọn arákùnrin méjì yẹn, wú mi lórí gan-an ni. Torí náà, lẹ́yìn tí mo ṣe tán ní ilé ẹ̀kọ́ girama, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ọdún 1948.

BÍ MO ṢE DÈRÒ BẸ́TẸ́LÌ

Ní July ọdún 1950, èmi àti àwọn òbí mi lọ sí àpéjọ àgbáyé tó wáyé ní Pápá Ìṣeré Yankee ní ìlú New York City. Níbẹ̀, mo lọ sí ìpàdé tí wọ́n máa ń ṣe pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì, mo sì fún wọn ní lẹ́tà kan tí mo fi sọ pé inú mi á dùn láti sìn níbẹ̀.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá mi ò rí ohun tó burú nínú kí n máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà ká sì jọ máa gbé nínú ilé, wọ́n ronú pé ó yẹ kí n máa san lára owó yàrá tí mò ń gbé àti oúnjẹ tí mò ń jẹ. Torí náà, lọ́jọ́ kan ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù August, mo jáde láti wáṣẹ́ lọ, àmọ́ mo kọ́kọ́ lọ yẹ àpótí lẹ́tà wa wò. Ni mo bá rí lẹ́tà kan tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi láti Brooklyn. Arákùnrin Nathan H. Knorr ló buwọ́ lù ú, ó wá kọ ọ́ sínú lẹ́tà náà pé: “Fọ́ọ̀mù tó o fi béèrè fún iṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì ti tẹ̀ mí lọ́wọ́. Èyí jẹ́ kí n rí i pé o fẹ́ fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Torí náà, màá fẹ́ kó o dé sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní 124 Columbia Heights, Brooklyn, New York, ní September 7, 1950.”

Nígbà tí bàbá mi ti ibiṣẹ́ dé lọ́jọ́ yẹn, mo sọ fún wọn pé mo ti ríṣẹ́. Wọ́n dá mi lóhùn pé: “Ó dáa bẹ́ẹ̀, ibo wá lo ríṣẹ́ sí?” Mo fèsì pé, “Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn ni, wọ́n á sì máa fún mi ní dọ́là mẹ́wàá lóṣù.” Ó ṣe wọ́n bákan, àmọ́ wọ́n sọ pé tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ tó wù mí ṣe nìyẹn, kí n sapá láti ṣàṣeyọrí nídìí rẹ̀. Kò pẹ́ sígbà yẹn táwọn náà fi ṣèrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè tó wáyé ní Pápá Ìṣeré Yankee ní ọdún 1953!

Èmi àti Alfred Nussrallah tá a jọ ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà

Inú mi dùn pé ìgbà tí wọ́n pè mí sí Bẹ́tẹ́lì náà ni wọ́n ní kí Alfred Nussrallah tá a jọ ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà máa bọ̀ níbẹ̀. Nígbà tó yá, ó ṣègbéyàwó, òun àti ìyàwó rẹ̀ Joan sì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Lẹ́yìn yẹn, wọ́n rán wọn láti lọ máa ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Lẹ́bánónì, látibẹ̀ ni wọ́n ti rán wọn pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti wá máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò.

IṢẸ́ NÍ BẸ́TẸ́LÌ

Ibi Tí Wọ́n Ti Ń Di Ìwé Pọ̀ ni mo ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ nígbà tí mo dé Bẹ́tẹ́lì. Ìwé What Has Religion Done for Mankind? ni mo kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ lé lórí. Lẹ́yìn tí mo ti lo nǹkan bí oṣù mẹ́jọ ní Ibi Tí Wọ́n Ti Ń Di Ìwé Pọ̀, wọ́n gbé mi lọ sí Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn, mo sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Arákùnrin Thomas J. Sullivan. Inú mi dùn láti bá a ṣiṣẹ́ àti láti jàǹfààní nínú ọgbọ́n àti ìjìnlẹ̀ òye tó ti ní láti ọ̀pọ̀ ọdún tó ti ń sìn nínú ètò Ọlọ́run.

Nígbà tó fi máa pé nǹkan bí ọdún mẹ́ta tí mo ti ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn, Arákùnrin Max Larson tó jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka ìtẹ̀wé sọ fún mi pé Arákùnrin Knorr fẹ́ rí mi. Ṣe ni mò ń ronú pé àbí mo ti ṣẹ̀ ni? Àmọ́ ọkàn mi balẹ̀ nígbà tí Arákùnrin Knorr sọ fún mi pé ńṣe lòun kàn fẹ́ mọ̀ bóyá máa fẹ́ kúrò ní Bẹ́tẹ́lì láìpẹ́. Ó fẹ́ kí ẹnì kan wá bá òun ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ ní ọ́fíìsì rẹ̀, ó sì fẹ́ mọ̀ bóyá màá lè ṣiṣẹ́ yẹn. Mo wá sọ fún un pé mi ò ní in lọ́kàn láti kúrò ní Bẹ́tẹ́lì. Bó ṣe di pé mo ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì rẹ̀ fún ogún ọdún nìyẹn o.

Mo ṣì máa ń sọ ọ́ pé ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ nígbà tí mò ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Arákùnrin Sullivan àti Arákùnrin Knorr ò ṣeé fowó rà. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn míì ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn bí Arákùnrin Milton Henschel, Klaus Jensen, Max Larson, Hugo Riemer àti Grant Suiter. *

 Àwọn arákùnrin tí mo bá ṣiṣẹ́ mọ iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fún ètò Ọlọ́run dunjú, wọ́n sì wà létòlétò. Akíkanjú èèyàn ni Arákùnrin Knorr, ohun tó jẹ ẹ́ lógún ni bí àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọba Ọlọ́run ṣe máa tẹ̀ síwájú dé ibi tó bá lè ṣeé ṣe dé. Ó jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, torí ó rọrùn fún àwọn tó ń bá a ṣiṣẹ́ láti bá a sọ̀rọ̀. Kódà nígbà tí èrò tiwa bá yàtọ̀ sí tiẹ̀, ó máa ń fún wa láyè láti sọ tinú wa, ó sì máa ń gba tiwa rò.

Ìgbà kan wa tí Arákùnrin Knorr bá mi sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká máa fún ohun tá a lè kà sí èyí tí kò tó nǹkan láfiyèsí. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún mi pé nígbà tí òun ṣì jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka ìtẹ̀wé, Arákùnrin Rutherford máa ké sí òun lórí fóònù, á sì sọ pé: “Arákùnrin Knorr, tó o bá ti ń bọ̀ wá sí ilé ìjẹun, kó o bá mi mú ohun tí wọ́n fi ń pa pẹ́ńsù rẹ́ dání. Mo fẹ́ lò ó níbi iṣẹ́.” Arákùnrin Knorr sọ pé ńṣe lòun á kọ́kọ́ lọ gbà á níbi tí wọ́n ń kó àwọn nǹkan ọ́fíìsì sí, òun á sì fi í sínú àpò òun. Tó bá di ọ̀sán òun á wá mú un lọ sí ọ́fíìsì Arákùnrin Rutherford. Ohun kékeré ni lóòótọ́ àmọ́ ó wúlò fún Arákùnrin Rutherford. Lẹ́yìn ìyẹn Arákùnrin Knorr wá sọ fún mi pé: “Mo máa ń fẹ́ kí pẹ́ńsù tí ẹnu rẹ̀ mú wà lórí tábìlì mi. Torí náà, jọ̀ọ́ máa rí i pé ó wà níbẹ̀ lójoojúmọ́.” Fún ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi máa ń rí sí i pé pẹ́ńsù tẹ́nu rẹ̀ mú wà lórí tábìlì rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Arákùnrin Knorr máa ń sọ fún wa pé ká máa fetí sílẹ̀ dáadáa tí wọ́n bá ní ká ṣe iṣẹ́ kan. Lọ́jọ́ kan, ó fún mi ní ìtọ́ni tó ṣe kedere nípa bó ṣe yẹ kí n bójú tó ọ̀rọ̀ kan, àmọ́ mi ò fetí sílẹ̀ dáadáa. Èyí mú kí n kó ìtìjú bá a. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn bà mí lọ́kàn jẹ́ gan-an, mo wá kọ lẹ́tà kan sí i láti jẹ́ kó mọ̀ pé mo kábàámọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn àti pé mo ronú pé ó máa dáa tí wọ́n bá gbé mi kúrò ní ọ́fíìsì rẹ̀. Nígbà tó ṣe láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, Arákùnrin Knorr wá bá mi ó sì sọ pé: “Robert, mo rí lẹ́tà tó o kọ. Òótọ́ lo ṣàṣìṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣàlàyé fún ẹ tẹ́lẹ̀. Àmọ́, ó dá mi lójú pé wàá túbọ̀ kíyè sára lọ́jọ́ míì. Ní báyìí, jẹ́ káwa méjèèjì pa dà sẹ́nu iṣẹ́ wa.” Mo mọrírì bó ṣe gba tèmi rò gan-an ni.

Ó WÙ MÍ KÍ N ṢE ÌGBÉYÀWÓ

Lẹ́yìn tí mo ti sìn fún ọdún mẹ́jọ ní Bẹ́tẹ́lì, mi ò ní èrò míì lọ́kàn ju pé kí n máa bá iṣẹ́ ìsìn mi lọ ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́ nǹkan yí pa dà. Nígbà tí a fẹ́ ṣe àpéjọ àgbáyé ní Pápá Ìṣeré Yankee àti ti Polo Grounds ní ọdún 1958, mo rí arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Lorraine Brookes. Mo ti kọ́kọ́ pàdé rẹ̀ ní ọdún 1955 nígbà tó ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Montreal, lórílẹ̀-èdè Kánádà. Ọwọ́ tó fi mú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún àti bó ṣe múra tán láti sìn ní ibikíbi tí ètò Jèhófà bá rán an lọ wú mi lórí gan-an ni. Lorraine tiẹ̀ ti fi ṣe àfojúsùn rẹ̀ láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Nígbà tó pé ọmọ ọdún méjìlélógún [22], wọ́n ní kó wá sí kíláàsì kẹtàdínlọ́gbọ̀n [27] lọ́dún 1956. Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n ní kó lọ máa ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Brazil. Nígbà táwa méjèèjì pa dà ríra lọ́dún 1958, mo dẹnu ìfẹ́ kọ ọ́, ó sì gbà láti fẹ́ mi. A fi ètò ìgbéyàwó wa sí ọdún tó tẹ̀ lé e, a sì lérò pé a ó jọ máa ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì nìṣó.

Nígbà tí mo sọ ohun tí mò ń gbèrò àtiṣe fún  Arákùnrin Knorr, ó dábàá pé ká ṣì ní sùúrù fún ọdún mẹ́ta ká tó ṣe ìgbéyàwó, ká lè ní àǹfààní láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn. Nígbà yẹn, kí tọkọtaya tó lè máa sìn nìṣó ní Bẹ́tẹ́lì lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn, ẹnì kan nínú wọn ti ní láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì fún ọdún mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí ẹnì kejì sì ti sìn fún ọdún mẹ́ta, ó kéré tán. Torí náà, Lorraine gbà láti sìn fún ọdún méjì ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní orílẹ̀-èdè Brazil lẹ́yìn náà ó lo ọdún kan ní Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn ká tó ṣègbéyàwó.

Ní ọdún méjì àkọ́kọ́ tá a bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra, lẹ́tà nìkan la máa ń kọ síra. Owó gegere ni fóònù máa ń náni nígbà yẹn, kò sì sí ohun tó ń jẹ́ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà. Àǹfààní tí kò lẹ́gbẹ́ ló jẹ́ pé Arákùnrin Knorr ló sọ àsọyé ìgbéyàwó wa ní September 16, ọdún 1961. Ká sòótọ́, ó dà bíi pé àwọn àkókò tá a fi dúró yẹn pẹ́ lójú wa. Àmọ́ ní báyìí, tayọ̀tayọ̀ la fi máa ń rántí ohun tó ti lé ní àádọ́ta ọdún tá a ti ṣègbéyàwó, a sì gbà pé sùúrù tá a ní tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ!

Ọjọ́ ìgbéyàwó wa. Láti apá òsì: Nathan H. Knorr, Patricia Brookes (àbúrò ìyàwó mi), ìyàwó mi àti èmi, Curtis Johnson, Faye àti Roy Wallen (àwọn òbí mi)

ÀWỌN ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌSÌN TÁ A NÍ

Ní ọdún 1964, mo láǹfààní láti máa lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì gẹ́gẹ́ bí alábòójútó láti ilẹ̀ òkèèrè. Nígbà yẹn, wọn kì í jẹ́ kí àwọn ìyàwó bá àwọn ọkọ wọn lọ. Àmọ́ ní ọdún 1977, ìyẹn yí pa dà, àwọn ìyàwó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọkọ wọn lọ. Ní ọdún yẹn èmi àti ìyàwó mi tẹ̀ lé Arákùnrin Grant Suiter àti ìyàwó rẹ̀ Edith Suiter lọ sí àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa tó wà ní orílẹ̀-èdè Jámánì, Austria, Gíríìsì, Kípírọ́sì, Tọ́kì àti Ísírẹ́lì. Gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti dé lágbàáyé jẹ́ àádọ́rin [70].

Nígbà kan tá a lọ sí orílẹ̀-èdè Brazil ní ọdún 1980, a dé ìlú Belém tó wà ní agbedeméjì ayé. Lorraine ti ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì rí níbẹ̀ ká tó fẹ́ra. A tún fẹsẹ̀ kan yà lọ́dọ̀ àwọn ará tó wà ní ìlú Manaus. Níbi àsọyé kan tá a sọ ní pápá ìṣeré kan, a rí i pé àwùjọ àwọn èèyàn kan jókòó pa pọ̀ àmọ́ wọn ò ṣe bíi tàwọn ará Brazil yòókù táwọn obìnrin wọn máa ń fi ẹnu ko ara wọn lẹ́ẹ̀kẹ̀ẹ́ tí wọ́n bá ń kíra. Àwọn tó jẹ́ ọkùnrin lára wọn ò sì bọ ara wọn lọ́wọ́ bíi tàwọn arákùnrin yòókù. Kí nìdí?

Àṣé àwọn ará wa ọ̀wọ́n tó wá láti ibi tí àwọn adẹ́tẹ̀ ń gbé ní àárín gbùngbùn igbó kìjikìji Amazon ni wọ́n. Kí wọ́n má bàa kó àrùn náà ran àwọn ará ni wọ́n ṣe ta kété sí àwọn tó kù. Àmọ́ ohun tí wọ́n ṣe wú wa lórí gan-an ni, a ò sì jẹ́ gbàgbé bí ojú wọn ṣe kún fún ayọ̀! Òótọ́ gbáà ni ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ pé: “Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà.”—Aísá. 65:14.

ÌGBÉSÍ AYÉ TÓ NÍTUMỌ̀ ÀTI ÌBÙKÚN TÍ KÒ LÓǸKÀ

Lóòrèkóòrè, èmi àti ìyàwó mi máa ń ronú lórí ohun tó lé ní ọgọ́ta ọdún tá a ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Inú wá dùn bí Jèhófà ṣe bù kún wa lọ́pọ̀ yanturu torí pé a gbà kó máa darí wa nípasẹ̀ ètò rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lè máa rin ìrìn àjò lọ sí onírúurú orílẹ̀-èdè kárí ayé mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, mo ṣì ń ṣe iṣẹ́ mi lójoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí, mo sì tún máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí àti Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn. Mo sì mọrírì ìtìlẹ́yìn ráńpẹ́ tí mo láǹfààní láti máa ṣe lọ́nà yìí fún ẹgbẹ́ ará tó wà kárí ayé. Kàyéfì ló ṣì máa ń jẹ́ fún wa láti rí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n ti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún pẹ̀lú irú ẹ̀mí tí Aísáyà ní pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísá. 6:8) Ńṣe ni ògìdìgbó àwọn èèyàn yìí ń jẹ́rìí sí òtítọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí alábòójútó àyíká yẹn sọ fún mi lọ́jọ́sí pé: “Bó bá ti yá kì í tún pẹ́ mọ́, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. O ò lè sọ ibi tó máa gbé ẹ dé.”

^ ìpínrọ̀ 20 Tó o bá fẹ́ ka ìtàn ìgbésí ayé díẹ̀ lára àwọn arákùnrin yìí, wo àwọn Ilé Ìṣọ́ tí a tọ́ka sí yìí: Thomas J. Sullivan (January 1, 1967, ojú ìwé 27); Klaus Jensen (October 1, 1970, ojú ìwé 603); Max Larson (September 1, 1989, ojú ìwé 23); Hugo Riemer (September 15, 1964 [Gẹ̀ẹ́sì]); àti Grant Suiter (March 1, 1984, ojú ìwé 23).