Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  April 2014

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Mósè

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Mósè

“Nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè, nígbà tí ó dàgbà, fi kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò.”—HÉB. 11:24.

MÓSÈ mọ àwọn nǹkan tí òun lè gbádùn nílẹ̀ Íjíbítì. Ó rí àwọn ilé gbàràmù gbaramu táwọn ọlọ́rọ̀ ní. Ààfin ọba ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Wọ́n fún un “ní ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì,” èyí tó ṣeé ṣe kó ní nínú ìmọ̀ nípa iṣẹ́ ọnà, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà, ìṣirò àti nípa àwọn nǹkan míì. (Ìṣe 7:22) Àwọn nǹkan tó jẹ́ àléèbá fún ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Íjíbítì, irú bí ọrọ̀, agbára àti ọlá tún wà níkàáwọ́ rẹ̀!

1, 2. (a) Ìpinnu wo ni Mósè ṣe nígbà tó pé ẹni ogójì ọdún? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí nìdí tí Mósè fi yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run?

2 Síbẹ̀, nígbà tí Mósè pé ogójì ọdún, ó ṣe ìpinnu kan tó ti ní láti ya àwọn tó ń gbé láàfin ọba Íjíbítì lẹ́nu. Ká tiẹ̀ gbà pé kò yàn láti gbé ìgbésí ayé ẹni ńlá, ṣebí ì bá tiẹ̀ yàn láti máa gbé irú ìgbésí ayé tí ọ̀pọ̀ àwọn ará Íjíbítì ń gbé, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yàn láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹrú. Kí nìdí? Ìdí ni pé Mósè ní ìgbàgbọ́. (Ka Hébérù 11:24-26.) Ìgbàgbọ́ yìí mú kí Mósè wò ré kọjá ohun téèyàn lè fi ojú lásán rí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ ẹni tẹ̀mí, ó ní ìgbàgbọ́ nínú “Ẹni tí a kò lè rí,” ìyẹn Jèhófà. Ó sì tún ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ní ìmúṣẹ.—Héb. 11:27.

3. Àwọn ìbéèrè mẹ́ta wo la máa rí ìdáhùn sí nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Ó yẹ kí àwa náà máa rí kọjá àwọn ohun tá a lè fi ojú wa yìí rí. A gbọ́dọ̀ jẹ́ “irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́.” (Héb. 10:38, 39) Ká lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa Mósè  nínú Hébérù 11:24-26. Bí a sì ṣe ń ṣe àyẹ̀wò náà, wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni ìgbàgbọ́ tí Mósè ní ṣe mú kó kọ àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara sílẹ̀? Nígbà tí wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, báwo ni ìgbàgbọ́ tó ní ṣe ràn án lọ́wọ́ láti mọrírì àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn rẹ̀? Kí sì nìdí tí Mósè fi “tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà”?

Ó KỌ ÌFẸ́KÚFẸ̀Ẹ́ TI ARA SÍLẸ̀

4. Kí ni Mósè mọ̀ nípa “ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀”?

4 Torí pé Mósè ní ìgbàgbọ́, ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ni “ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀” wà fún. Àwọn kan lè ronú pé bó tílẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Íjíbítì ti jingiri sínú ìbọ̀rìṣà àti ìbẹ́mìílò, ó di agbára ayé, síbẹ̀, àwọn èèyàn Jèhófà ń jìyà gẹ́gẹ́ bí ẹrú! Láìka ìyẹn sí, Mósè mọ̀ pé Ọlọ́run lè yí ipò táwọn èèyàn rẹ̀ wà pa dà. Lóòótọ́, ó lè dà bíi pé àwọn tó ń ṣe ohun tó wù wọ́n ń rọ́wọ́ mú, síbẹ̀ Mósè ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ẹni burúkú máa tó pa run. Látàrí ìyẹn, kò wù ú láti ‘jẹ̀gbádùn ẹ̀ṣẹ̀ kódà fún ìgbà díẹ̀.’

5. Kí ni kò ní jẹ́ ká fẹ́ láti ‘jẹ̀gbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀’?

5 Kí ló máa mú kó o kọ̀ láti ‘jẹ̀gbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀’? Má ṣe gbàgbé pé ìgbádùn téèyàn ń rí nínú dídá ẹ̀ṣẹ̀ kì í tọ́jọ́. Máa fi ojú ìgbàgbọ́ wò ó pé “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (1 Jòh. 2:15-17) Máa ṣe àṣàrò lórí ohun tó máa gbẹ̀yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà. “Orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́ ni” wọ́n wà, “tí a mú wọn wá sí òpin wọn nípasẹ̀ ìpayà òjijì!” (Sm. 73:18, 19) Tó o bá dojú kọ ìdẹwò láti dẹ́ṣẹ̀, bí ara rẹ pé, ‘Ibo ni mo fẹ́ kí ayé mí já sí?’

6. (a) Kí nìdí tí Mósè fi kọ̀ pé kí wọ́n máa “pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò”? (b) Kí nìdí tó o fi rò pé ìpinnu tó tọ́ ni Mósè ṣe?

6 Ìgbàgbọ́ tí Mósè ní tún ràn án lọ́wọ́ láti pinnu ohun tó máa fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Bíbélì sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè, nígbà tí ó dàgbà, fi kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò.” (Héb. 11:24) Mósè kò ronú pé òun lè máa gbé ní ààfin Ọba kóun máa sin Ọlọ́run níbẹ̀ kóun sì máa fi ọrọ̀ àti ọlá tí òun ní ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ èèyàn òun lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló pinnu pé òun máa fi gbogbo ọkàn-àyà òun àti gbogbo ọkàn òun àti gbogbo okunra òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Diu. 6:5) Ìpinnu tí Mósè ṣe yìí ni kò jẹ́ kó ní ẹ̀dùn ọkàn. Kò sì pẹ́ tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣúra tí Mósè pa tì yìí fi bọ́ mọ́ àwọn ará Íjíbítì lọ́wọ́ tó sì wá di ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ẹ́kís. 12:35, 36) Fáráò kàbùkù, Ọlọ́run sì fìyà ikú jẹ ẹ́. (Sm. 136:15) Ṣùgbọ́n Ọlọ́run dá ẹ̀mí Mósè sí, ó sì lò ó láti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan. Dájúdájú, ìgbésí ayé Mósè nítumọ̀.

7. (a) Gẹ́gẹ́ bí Mátíù 6:19-21 ṣe sọ, kí nìdí tó fi yẹ ká máa wò ré kọjá òun tá à ń rí lọ́wọ́lọ́wọ́? (b) Sọ ìrírí kan tó jẹ́ ká mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìṣura tara àti ìṣúra tẹ̀mí.

7 Tó o bá jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó o sì jẹ́ ọ̀dọ́, báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yan ohun tó o máa fi ìgbésí ayé rẹ ṣe? Ó bọ́gbọ́n mu tó o bá wéwèé ohun tó o máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́, látàrí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run, ṣé àwọn ohun tó máa wà títí láé ni wàá máa lépa ni àbí àwọn ohun tó máa tó bá ayé yìí lọ? (Ka Mátíù 6:19-21.) Irú ìbéèrè yìí ló wà lọ́kàn obìnrin kan tó ń jẹ́ Sophie, tó mọ bí wọ́n ṣe ń jó ijó alálọ̀ọ́yípo gan-an. Jákèjádò orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà làwọn ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń kọ́ irú ijó yìí ti ń fi àǹfààní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ àti ipò ńláńlá lọ̀ ọ́. Òun fúnra rẹ̀ gbà pé: “Kò sẹ́ni tí wọ́n gbé gẹṣin tí ò ní ju ìpàkọ́. Kódà, ṣe ni mo dà bí ọba láàárín àwọn ojúgbà mi. Ṣùgbọ́n mi ò láyọ̀.” Sophie wá wo fídíò tó ṣàlàyé bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè lo ìgbésí ayé wọn, ìyẹn Young People Ask—What Will I Do With My Life? Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Mo wá rí i pé ayé yìí ti gba iṣẹ́ ìsìn tó yẹ kí n máa ṣe fún Jèhófà tọkàntọkàn mọ́ mi lọ́wọ́, ó sì ti fi àṣeyọrí àti àpọ́nlé látọ̀dọ̀ àwọn tó ń gba tèmi dípò rẹ̀. Mo gbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà mo fi ijó alálọ̀ọ́yípo tí mo fi ń ṣiṣẹ́ ṣe sílẹ̀.” Báwo ni ìpinnu tó ṣe yìí ṣe rí lára rẹ̀? Ó ní: “Kò ṣe mí bíi pé mo pàdánù ohunkóhun. Ní báyìí, ayọ̀ tí mo ní kò lẹ́gbẹ́. Èmi àti ọkọ mi ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà. A ò lókìkí, a ò sì fi bẹ́ẹ̀  rí já jẹ. Àmọ́, a ní Jèhófà, a ní àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a sì ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí. Mi ò kábàámọ̀ rárá.”

8. Ìmọ̀ràn Bíbélì wo ló lè ran ọ̀dọ́ kan lọ́wọ́ láti pinnu ohun tó máa fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe?

8 Jèhófà mọ ohun tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní jù lọ. Mósè sọ pé: “Kí sì ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, bí kò ṣe láti máa fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o lè máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti láti máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti láti máa sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ; láti máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, fún ire rẹ?” (Diu. 10:12, 13) Ní báyìí tó o ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, yan iṣẹ́ tó máa jẹ́ kó o fẹ́ràn Jèhófà kó o sì máa fi “gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ” sìn ín. Sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé “ire rẹ” ló máa jẹ́ tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀.

Ó MỌYÌ ÀWỌN ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌSÌN TÓ NÍ

9. Ṣàlàyé ìdí tó fi lè ṣòro fún Mósè láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́.

9 Mósè “ka ẹ̀gàn Kristi sí ọrọ̀ tí ó tóbi ju àwọn ìṣúra Íjíbítì” lọ. (Héb. 11:26) Jèhófà yan Mósè gẹ́gẹ́ bíi “Kristi,” tàbí “Ẹni Àmì Òróró,” ní ti pé òun ni Jèhófà yàn pé kó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Mósè mọ̀ pé ó máa ṣòro láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní kí òun ṣe yìí, kódà ó máa mú kí wọ́n ‘kẹ́gàn’ òun. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tiẹ̀ ti kàn án lábùkù rí nígbà tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ta ní yàn ọ́ ṣe ọmọ aládé àti onídàájọ́ lórí wa?” (Ẹ́kís. 2:13, 14) Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè fúnra rẹ̀ bi Jèhófà pé: “Báwo sì ni Fáráò yóò ṣe fetí sí mi láé?” (Ẹ́kís. 6:12) Kí Mósè bàa lè múra sílẹ̀ kó sì mọ ohun tó máa ṣe nígbà tí wọ́n bá kẹ́gàn rẹ̀, ó sọ ohun tó ń bà á lẹ́rù àtàwọn àníyàn rẹ̀ fún Jèhófà. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Mósè lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tó nira tó ní kó ṣe?

10. Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí Mósè gbára dì fún iṣẹ́ tó gbé fún un?

10 Lákọ̀ọ́kọ́, Jèhófà fi Mósè lọ́kàn balẹ̀ pé: “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ.” (Ẹ́kís. 3:12) Ìkejì, Jèhófà mú un lọ́kàn le. Ó ṣàlàyé ọ̀kan lára ohun tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí fún un. Ó ní: “Èmi Yóò Jẹ́ Ohun Tí Èmi Yóò Jẹ́.” * (Ẹ́kís. 3:14) Ìkẹta, ó fún Mósè ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu káwọn èèyàn lè mọ̀ pé Ọlọ́run ló rán an lóòótọ́. (Ẹ́kís. 4:2-5) Ìkẹrin, Jèhófà yan Áárónì gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́ àti agbọ̀rọ̀sọ fún Mósè kó lè ràn án lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní kó ṣe. (Ẹ́kís. 4:14-16) Kódà, nígbà tí Mósè di arúgbó, ó dá a lójú gbangba pé Ọlọ́run máa ń mú kí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ gbára dì láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá ní kí wọ́n ṣe. Ìyẹn ló mú kó fi ìdánilójú sọ fún Jóṣúà tó máa gbapò lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Jèhófà sì ni ẹni tí ń lọ níwájú rẹ. Òun fúnra rẹ̀ ni yóò máa wà pẹ̀lú rẹ nìṣó. Òun kì yóò kọ̀ ọ́ tì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ pátápátá. Má fòyà tàbí kí o jáyà.”—Diu. 31:8.

11. Kí nìdí tí Mósè fi mọyì iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní kó ṣe gan-an?

11 Lọ́lá ìtìlẹ́yìn Jèhófà, Mósè mọyì iṣẹ́ ńlá tí Ọlọ́run ní kó ṣe gan-an, ó wò ó gẹ́gẹ́ bí “ọrọ̀ tí ó tóbi ju àwọn ìṣúra Íjíbítì” lọ. Ẹ gbọ́ ná, èwo ló bọ́gbọ́n mu jù, kéèyàn jẹ́ ẹrú Ọlọ́run Olódùmarè àbí kéèyàn jẹ́ ẹrú Fáráò? Àǹfààní kí ló wà nínú kí Mósè jẹ́ ọmọ ọba Íjíbítì nígbà tó láǹfààní láti jẹ́ “Kristi,” tàbí ẹni àmì òróró Jèhófà? Ọlọ́run san Mósè lẹ́san torí pé ó ní ẹ̀mí ìmoore. Ó ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà, ẹni tó mú kó fi “ìṣe oníbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ títóbi” hàn bó ṣe ń darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí.—Diu. 34:10-12.

12. Àwọn àǹfààní tí Jèhófà fún wa wo ló yẹ ká fi ìmọrírì hàn fún?

12 Àwa pẹ̀lú ní iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní ká ṣe. Jèhófà ti gbé iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lé wa lọ́wọ́ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ bó ṣe ṣe fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì. (Ka 1 Tímótì 1:12-14.) Gbogbo wa la ní àǹfààní láti máa wàásù ìhìn rere. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Àwọn kan ń sìn  gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi tí wọ́n sì dàgbà nípa tẹ̀mí ń sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà nínú ìjọ. Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kí àwọn ìbátan rẹ tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí àti àwọn míì máa bi ẹ́ pé kí lò ń rí gbà nínú iṣẹ́ Ọlọ́run tó ò ń ṣe tàbí kí wọ́n tiẹ̀ kẹ́gàn rẹ torí àwọn ohun tó o yááfì. (Mát. 10:34-37) Tó o bá jẹ́ kí wọ́n kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé bóyá ló tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu bó o ṣe yááfì àwọn nǹkan tàbí kó máa ṣe ẹ́ bíi pé bóyá ni wàá lè máa ṣe iṣẹ́ náà nìṣó. Bí ọ̀rọ̀ bá wá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa forí tì í?

13. Báwo ni Jèhófà ṣe ń mú ká gbára dì láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ìjọsìn rẹ̀?

13 Jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú Jèhófà mú kó o bẹ̀ ẹ́ pé kó tì ẹ́ lẹ́yìn. Sọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù àtohun tó ò ń ṣàníyàn lé lórí fún un. Ó ṣe tán, Jèhófà ló rán ẹ níṣẹ́, òun náà ló máa mú kó o ṣàṣeyọrí. Lọ́nà wo? Lọ́nà kan náà tó gbà ran Mósè lọ́wọ́ ni. Lákọ̀ọ́kọ́, Jèhófà mú kó dá ẹ lójú pé: “Èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.” (Aísá. 41:10) Ìkejì, ó rán ẹ létí pé àwọn ìlérí òun ṣeé gbára lé, ó ní: “Mo ti sọ ọ́; èmi yóò mú un wá pẹ̀lú. Mo ti gbé e kalẹ̀, èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.” (Aísá. 46:11) Ìkẹta, Jèhófà ń fún ẹ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” kó o lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láṣeyọrí. (2 Kọ́r. 4:7) Ìkẹrin, kó o bàa lè máa fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní kó o ṣe, Baba wa onífẹ̀ẹ́ mú kó o wà lára ẹgbẹ́ ará kárí ayé, tí wọ́n jẹ́ olùjọsìn tòótọ́, tí wọ́n ń ‘tu ara wọn nínú lẹ́nì kìíní-kejì tí wọ́n sì ń gbé ara wọn ró lẹ́nì kìíní-kejì.’ (1 Tẹs. 5:11) Bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tó ní kó o ṣe, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ tó o ní nínú rẹ̀ á máa lágbára sí i, wàá sì wá mọyì rẹ̀ pé àwọn àǹfààní tó o ní nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ níye lórí ju ìṣúra èyíkéyìí tó o lè ní lórí ilẹ̀ ayé lọ.

“Ó TẸJÚ MỌ́ SÍSAN Ẹ̀SAN NÁÀ”

14. Kí nìdí tó fi dá Mósè lójú pé Ọlọ́run máa san òun lẹ́san?

14 Mósè “tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà.” (Héb. 11:26) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà yẹn, ìwọ̀nba ni òye tí Mósè ní nípa ọjọ́ iwájú, síbẹ̀ ó jẹ́ kí ohun tó mọ̀ yẹn nípa lórí ojú tó fi ń wo nǹkan. Bó ṣe dá Ábúráhámù baba ńlá Mósè lójú náà ló dá Mósè lójú pé Jèhófà lè jí òkú dìde. (Lúùkù 20:37, 38; Héb. 11:17-19) Torí pé Mósè mọ̀ pé Jèhófà máa bù kún òun lọ́jọ́ iwájú, kò wo ogójì ọdún tó fi ń rìn kiri àti ogójì ọdún tó lò nínú aginjù gẹ́gẹ́ bí àṣedànù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀nà tí Ọlọ́run  máa gbà mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó fi ojú ìgbàgbọ́ rí èrè tó ń dúró dè é.

15, 16. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká tẹjú mọ́ èrè tó ń dúró dè wá? (b) Àwọn ìbùkún wo lò ń fojú sọ́nà fún lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run?

15 Ǹjẹ́ ò ń “tẹjú mọ́ sísan” èrè tó ń dúró de ìwọ náà? Bíi ti Mósè, a kò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, a kò “mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀” fún ìpọ́njú ńlá máa bọ́ sí. (Máàkù 13:32, 33) Síbẹ̀, ohun tá a mọ̀ nípa Párádísè tó ń bọ̀ pọ̀ ju ti Mósè lọ. Kódà, bá ò tiẹ̀ mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí ìgbésí ayé ṣe máa rí lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, èyí tá a mọ̀ lára àwọn ìlérí Ọlọ́run mú ká “tẹjú mọ́” ọn. Bí a bá ń fi ọkàn yàwòrán ayé tuntun, á mú ká máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́. Báwo nìyẹn ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Wò ó báyìí ná: Ǹjẹ́ wàá ra ilé kan tó bá jẹ́ pé ohun tó o mọ̀ nípa ilé náà kò tó nǹkan? Ó dájú pé o kò ní rà á! Bákan náà, a kò ní fẹ́ máa fi ìgbésí ayé wa lépa ìrètí kan tí kò dájú. A gbọ́dọ̀ máa fi ojú ìgbàgbọ́ rí bí ìgbésí ayé ṣe máa rí lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tó ṣe kedere, láìṣiyèméjì rárá.

Ẹ wo bó ṣe máa dùn mọ́ni tó láti bá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bíi Mósè tó jẹ́ adúróṣinṣin sọ̀rọ̀! (Wo ìpínrọ̀ 16)

16 Kí àwòrán Ìjọba Ọlọ́run lè túbọ̀ ṣe kedere lọ́kàn rẹ, ńṣe ni kó o “tẹjú mọ́,” tàbí kó o máa ronú nípa irú ìgbésí ayé tí wàá gbé nínú Párádísè. Máa fọkàn yàwòrán àwọn nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn tó gbé láyé kí ẹ̀sìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀, máa ronú nípa ohun tí wàá bi wọ́n nígbà tí wọ́n bá jíǹde. Ronú nípa ohun tí wọ́n lè béèrè lọ́wọ́ rẹ nípa bí nǹkan ṣe rí fún ẹ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Fi ọkàn yàwòrán bí inú rẹ ṣe máa dùn tó láti rí àwọn baba ńlá rẹ tó ti kú tipẹ́ kó o sì kọ́ wọn ní gbogbo ètò tí Ọlọ́run ti ṣe fún àǹfààní wọn. Wo bó ṣe máa dùn mọ́ ẹ tó láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ẹranko inú igbó bó o ṣe ń rí i tí wọ́n ń gbé pọ̀ ní àlàáfíà nígbà yẹn. Ronú lórí bí wàá ṣe túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà bó o ṣe ń sún mọ́ ìjẹ́pípé.

17. Báwo ni fífi ojú inú wo èrè tá a máa gbà lọ́jọ́ ọ̀la ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nísinsìnyí?

17 Tá a bá ń fojú inú wo èrè tá a máa rí gbà lọ́jọ́ ọ̀la, kò ní jẹ́ kí nǹkan sú wa, a ó máa láyọ̀, àwọn ìpinnu tá à ń ṣe á sì fi hàn pé òótọ́ la fẹ́ nípìn-ín nínú ọjọ́ ọ̀la ayérayé tó ń bọ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó jẹ́ ẹni àmì òróró pé: “Bí a bá ń retí ohun tí a kò rí, a óò máa bá a nìṣó ní dídúró dè é pẹ̀lú ìfaradà.” (Róòmù 8:25) Ìlànà inú ọ̀rọ̀ yìí kan gbogbo àwọn Kristẹni tó ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wa kò tíì tẹ èrè náà, ìgbàgbọ́ wa lágbára débi pé a ṣì ń fi sùúrù dúró de “sísan ẹ̀san náà.” Bíi ti Mósè, a kì í wo iye ọdún yòówù ká ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bí àṣedànù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dá wa lójú pé “àwọn ohun tí a ń rí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ohun tí a kò rí jẹ́ fún àìnípẹ̀kun.”—Ka 2 Kọ́ríńtì 4:16-18.

18, 19. (a) Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ jà fitafita kí ìgbàgbọ́ wa má bàa yingin? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 Ìgbàgbọ́ ń jẹ́ ká fi òye mọ àwọn ẹ̀rí tó fara hàn nípa “àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Héb. 11:1) Ẹni tó ń fi ojú ti ara wo nǹkan kì í rí àǹfààní ṣíṣeyebíye tó wà nínú sísin Jèhófà. Lójú irú ẹni bẹ́ẹ̀, ńṣe ni àwọn ìṣúra tẹ̀mí dà bí “ọ̀rọ̀ òmùgọ̀.” (1 Kọ́r. 2:14) Àmọ́, a nírètí pé a máa gbádùn àwọn nǹkan tí aráyé ò lè gbádùn rẹ̀, irú bí ìyè àìnípẹ̀kun, a sì tún máa rí bí Ọlọ́run ṣe máa jí àwọn òkú dìde. Bíi ti àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ìgbà ayé Pọ́ọ̀lù tí wọ́n pè é ní “onírèégbè,” ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ń ronú pé ìsọkúsọ lásán ni àwọn ohun tá à ń wáàsù pé Ọlọ́run máa ṣe.—Ìṣe 17:18.

19 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ayé táwọn èèyàn kò ti nígbàgbọ́ là ń gbé, a gbọ́dọ̀ jà fitafita kí ìgbàgbọ́ wa má bàa yingin. Bẹ Jèhófà pé kó má ṣe jẹ́ kí ‘ìgbàgbọ́ rẹ yẹ̀.’ (Lúùkù 22:32) Má ṣe fojú kéré ohun tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ tó o bá dẹ́ṣẹ̀, máa ronú nípa àǹfààní tó o máa rí bó o ṣe ń sin Jèhófà àti ìyè ayérayé tó ń dúró dè ẹ́. Àmọ́ o, ohun tí Mósè rí látàrí ìgbàgbọ́ tó ní kọjá gbogbo èyí. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò bí ìgbàgbọ́ tí Mósè ní ṣe mú kó máa rí “Ẹni tí a kò lè rí.”—Héb. 11:27.

^ ìpínrọ̀ 10 Ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan ṣàlàyé lórí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nínú Ẹ́kísódù 3:14 pé: “Kò sí ohun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó fẹ́ . . . Odi agbára ni orúkọ náà [Jèhófà] jẹ́ fún Ísírẹ́lì, ó sì tún jẹ́ orísun ìrètí àti ìtùnú tí kò nípẹ̀kun.”