Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) April 2014

Ẹ̀dà yìí jíròrò bá a ṣe lè lo ìgbàgbọ́ bíi ti Mósè. Ojú wo ni Jèhófà fẹ́ ká máa fi wo ojúṣe wa nínú ìdílé, báwo ló sì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe náà?

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Mósè

Báwo ni ìgbàgbọ́ tí Mósè ní ṣe mú kó kọ àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara sílẹ̀ ó sì mọrírì àǹfààní iṣẹ́ ìsìn rẹ̀? Kí nìdí tí Mósè fi “tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà”?

Ǹjẹ́ Ò Ń Rí “Ẹni Tí A Kò Lè Rí”?

Báwo ni ìgbàgbọ́ tí Mósè ní nínú Ọlọ́run ṣe gbà á lọ́wọ́ ìbẹ̀rù èèyàn tó sì mú kó lo ìgbàgbọ́ nínú ìlérí Ọlọ́run? Fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun kó o lè rí Jèhófà bí Ẹni gidi tó ń fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Ibi Tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún Gbé Mi Dé

Mọ ìdí tí Robert Wallen fi sọ pé bóun ṣe bojú wo ọdún 65 tòun ti lò lẹ́nu iṣẹ́ alákòókò kíkún, òun rí i pé ayé òun nítumọ̀, òun sì rí ìbùkún.

Kò Sí Ẹni Tó Lè Sin Ọ̀gá Méjì

Àwọn kan ti lọ sí òkè òkun kí wọ́n lè rí towó ṣe. Báwo ni gbígbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ torí àtijẹ ṣe lè pa ìgbéyàwó, àwọn ọmọ àti àjọṣe ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run lára?

Jẹ́ Onígboyà Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Rẹ!

Báwo ni bàbá kan tí iṣẹ́ ti mú kó pa ìdílé rẹ̀ tì ṣe mú àjọṣe wọn pa dà gún régé? Báwo ni Jèhófà ṣe mú kó lè bójú tó wọn ní ìlú tí nǹkan ò ti rọ̀ṣọ̀mù?

Ǹjẹ́ O Mọyì Bí Jèhófà Ṣe Ń Fìfẹ́ Ṣọ́ Wa?

Wo ọ̀nà márùn-ún tí Ọlọ́run gbà ń f ìfẹ́ bójú tó wa àti bá a ṣe lè jàǹfààní látinú bí Jèhófà ṣe dìídì nífẹ̀ẹ́ wa.

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, bí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya, kí ló túmọ̀ sí?