Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  March 2014

Bó O Ṣe Lè Máa Fi Ojú Tó Tọ́ Wo Nǹkan

Bó O Ṣe Lè Máa Fi Ojú Tó Tọ́ Wo Nǹkan

“Bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ wà láàyè fún ọ̀pọ̀ ọdún, kí ó máa fi gbogbo rẹ̀ yọ̀.”—ONÍW. 11:8.

1. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà fi jíǹkí wa tó lè mú ká láyọ̀?

JÈHÓFÀ fẹ́ ká máa láyọ̀, ó sì ń rọ̀jò ìbùkún táá mú ká máa láyọ̀ lé wa lórí. Ohun kan ni pé Ọlọ́run mú ká wà láàyè. Torí náà, a lè máa lo ìgbésí ayé wa láti yin Ọlọ́run lógo níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ló mú ká wá sínú ìsìn tòótọ́. (Sm. 144:15; Jòh. 6:44) Jèhófà mú kó dá wa lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń mú ká lè máa fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (Jer. 31:3; 2 Kọ́r. 4:16) À ń jọlá Párádísè tẹ̀mí, níbi tá a ti ń gbádùn ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí àti àjọṣe alárinrin pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ará. Yàtọ̀ síyẹn, a tún ní ìrètí àgbàyanu nípa ọjọ́ iwájú.

2. Èrò òdì wo ló máa ń wá sọ́kàn àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin?

2 Lóòótọ́, àwọn ìdí tá a sọ yìí ń fúnni láyọ̀, síbẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin ṣì ń ní èrò òdì nípa ara wọn. Wọ́n máa ń ronú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan, iṣẹ́ ìsìn àwọn ò sì já mọ́ pàtàkì lójú Jèhófà. Ńṣe ló máa ń dà bí àlá tí kò lè ṣẹ lójú àwọn tó sábà máa ń ní èrò òdì pé èèyàn ò lè gbádùn “ọ̀pọ̀ ọdún” láyé. Lọ́dọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ó dà bíi pé ọjọ́ gbogbo ni nǹkan ṣókùnkùn.—Oníw. 11:8.

3. Kí ló lè mú kéèyàn máa ní èrò òdì?

3 Lára ohun tó ṣeé ṣe kó fà á tí àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin  wa yìí fi ń ní èrò òdì ni ìjákulẹ̀, àìsàn, tàbí àwọn ìṣòro kan tó máa ń bá ọjọ́ ogbó rìn. (Sm. 71:9; Òwe 13:12; Oníw. 7:7) Bákan náà, gbogbo Kristẹni pátá gbọ́dọ̀ gbà pé ọkàn máa ń ṣe àdàkàdekè, ó sì lè máa dá wa lẹ́bi bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú Ọlọ́run ń dùn sí wa. (Jer. 17:9; 1 Jòh. 3:20) Èṣù máa ń fi ẹ̀sùn èké kan àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Àwọn tó sì ń ronú bíi ti Sátánì lè fẹ́ mú ká máa fi ojú tí Élífásì fi wo nǹkan wo ara wa, pé a ò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run. Irọ́ funfun báláú nìyẹn jẹ́ lọ́jọ́ Jóòbù, bẹ́ẹ̀ náà sì ni lónìí.—Jóòbù 4:18, 19.

4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Jèhófà mú kó ṣe kedere nínú Ìwé Mímọ́ pé òun á máa wà pẹ̀lú àwọn tó ń “rìn ní àfonífojì ibú òjìji.” (Sm. 23:4) Ọ̀kan lára ọ̀nà tó gbà ń wà pẹ̀lú wa jẹ́ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bíbélì jẹ́ “alágbára láti ọwọ́ Ọlọ́run fún dídojú àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in dé,” títí kan irọ́ àti àwọn èrò òdì. (2 Kọ́r. 10:4, 5) Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè lo Bíbélì lọ́nà táá mú ká máa fi ojú tó tọ́ wo nǹkan ká sì máa bá a lọ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Ìjíròrò yìí máa ṣe ẹ́ láǹfààní, wàá sì tún mọ bó o ṣe lè máa fún àwọn míì níṣìírí.

MÁA LO BÍBÉLÌ LỌ́NÀ TÍ WÀÁ FI NÍ ÈRÒ TÓ TỌ́

5. Ìwádìí wo ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá a ní èrò tó tọ́?

5 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé àwọn ohun kan tó lè mú ká ní èrò tó tọ́. Ó rọ àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́.” (2 Kọ́r. 13:5, Bíbélì Mímọ́) “Ìgbàgbọ́” tí ibí yìí ń sọ ni àpapọ̀ ohun tí àwa Kristẹni gbà gbọ́, bó ṣe wà nínú Bíbélì. Bí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa bá bá àwọn ohun tá a gbà gbọ́ mu, a jẹ́ pé a ti yege nínú ìwádìí náà nìyẹn, a sì fi hàn pé a wà “nínú ìgbàgbọ́.” Àmọ́, a tún gbọ́dọ̀ máa ṣe ìwádìí ká lè mọ̀ bóyá ìgbésí ayé wa bá gbogbo apá tí ẹ̀kọ́ Kristẹni pín sí mu. A ò kàn lè máa yan èyí tó bá wù wá lára àwọn ẹ̀kọ́ náà.—Ják. 2:10, 11.

6. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wádìí ara wa wò ‘bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́’? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

6 O lè máa lọ́ tìkọ̀ láti wádìí ara rẹ wò, pàápàá tó o bá rò pé o lè fìdí rẹmi. Síbẹ̀, ojú tí Jèhófà fi ń wò wá ló ṣe pàtàkì ju ojú tá a fi ń wo ara wa, èrò rẹ̀ sì ga fíofío ju èrò wa lọ. (Aísá. 55:8, 9) Jèhófà kì í wádìí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ torí kó lè dá wọn lẹ́bi, ibi tí wọ́n dára sí ló ń wá, ó sì fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Tó o bá ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wádìí ara rẹ wò ‘bóyá o wà nínú ìgbàgbọ́,’ ojú tí Ọlọ́run fi ń wò ẹ́ ni wàá máa fi wo ara rẹ. Ìyẹn á jẹ́ kó o mú èrò èyíkéyìí tó o bá ní pé o ò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run kúrò, wàá sì fi ọ̀rọ̀ tó fini lọ́kàn balẹ̀ tí Bíbélì sọ rọ́pò rẹ̀, ìyẹn ni pé, O ṣeyebíye lójú Jèhófà. Ńṣe ló máa wá dà bíi pé o ká aṣọ kúrò lójú wíńdò kí oòrùn lè tan ìmọ́lẹ̀ sínú yàrá tó ṣókùnkùn.

7. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ àwọn adúróṣinṣin tó wà nínú Bíbélì?

7 Ọ̀nà kan tó dáa tá a lè gbà wádìí ara wa ni pé ká máa ṣe àṣàrò lórí àpẹẹrẹ àwọn adúróṣinṣin tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn. Máa fi bí nǹkan ṣe rí fún wọn àti èrò wọn wé tìrẹ, kó o wá ronú nípa bó o ṣe máa ṣe ká ní ìwọ lo wà nípò wọn. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ mẹ́ta yẹ̀ wò kó o lè mọ bí wàá ṣe fi Bíbélì wádìí ara rẹ wo bóyá o wà “nínú ìgbàgbọ́” kó o sì wá tipa bẹ́ẹ̀ máa ní èrò tó tọ́ nípa ara rẹ.

OPÓ ALÁÌNÍ

8, 9. (a) Báwo ni nǹkan ṣe rí fún opó aláìní kan? (b) Èrò òdì wo ló ṣeé ṣe kí opó náà ní?

8 Nígbà tí Jésù wà nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, ó kíyè sí opó aláìní kan. Àpẹẹrẹ opó náà lè mú ká máa fi ojú tó tọ́ wo nǹkan láìka kùdìẹ̀-kudiẹ wa sí. (Ka Lúùkù 21:1-4.) Ronú nípa bí nǹkan ṣe rí fún  opó yẹn ná. Ó ṣì ń ṣọ̀fọ̀ ọkọ rẹ̀ tó kú, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣe “ń jẹ ilé àwọn opó run” dípò tí wọn ì bá fi máa ràn wọ́n lọ́wọ́ torí ẹ̀dùn ọkàn wọn. (Lúùkù 20:47) Obìnrin náà tòṣì débi pé gbogbo ohun tó lè fi tọrẹ ní tẹ́ńpìlì kò ju ohun tí alágbàṣe kan máa gbà láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ.

9 Fojú inú wo ohun tí opó náà lè máa rò nígbà tó wọnú àgbàlá tẹ́ńpìlì tòun ti ẹyọ owó kéékèèké méjì tó wà lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣé ó ṣeé ṣe kó máa ronú pé owó tí òun fẹ́ fi ṣètọrẹ kò tó iye tí òun ti máa ń mú wá nígbà tí ọkọ òun ṣì wà láàyè? Ǹjẹ́ ojú lè máa tì í torí pé owó ńláńlá ni àwọn tó wà níwájú rẹ̀ fẹ́ fi ṣètọrẹ, kó wá máa ronú pé bóyá ni ọrẹ tí òun mú wá tiẹ̀ já mọ́ nǹkan kan? Tó bá tiẹ̀ ní irú èrò bẹ́ẹ̀ lọ́kàn, síbẹ̀ ó ṣe ohun tó lè ṣe kó lè ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn.

10. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé Ọlọ́run mọyì opó náà?

10 Jésù fi hàn pé Jèhófà mọyì opó náà àti ọrẹ tó mú wá. Ó sọ pé obìnrin náà “sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo [àwọn olówó yẹn] lọ.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n máa da owó tí obìnrin náà fi ṣètọrẹ pọ̀ mọ́ ti àwọn èèyàn yòókù, síbẹ̀ Jésù dìídì yìn ín. Nígbà tí àwọn tó ń bójú tó owó nínú tẹ́ńpìlì bá wá rí ẹyọ owó kéékèèké náà, kò dájú pé wọ́n á mọ bí owó náà àti ẹni tó fi tọrẹ ti ṣeyebíye tó lójú Jèhófà. Síbẹ̀, ojú tí Ọlọ́run fi wo opó náà ló ṣe pàtàkì, kì í ṣe ohun tí àwọn èèyàn rò nípa rẹ̀ tàbí ojú tí opó náà alára fi wo ara rẹ̀. Ǹjẹ́ o lè fi ìtàn yìí wádìí ara rẹ wò láti mọ̀ bóyá o wà nínú ìgbàgbọ́?

Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ opó aláìní náà? (Wo ìpínrọ̀ 8 sí 10)

11. Kí lo lè rí kọ́ nínú ìtàn opó náà?

11 Ipò tó o wà lè nípa lórí ohun tí wàá lè ṣe fún Jèhófà. Àwọn ará wa kan kì í lè pẹ́ lóde ẹ̀rí mọ́ torí àìlera tàbí ọjọ́ ogbó. Ǹjẹ́ ó tọ́ kí wọ́n máa ronú pé iṣẹ́ tí àwọn ṣe kò tó ohun tí àwọn lè ròyìn rẹ̀? Kódà bí kò bá tiẹ̀ sí ohun tó ń dí ẹ lọ́wọ́, o lè máa ronú pé bóyá ní ìsapá rẹ tẹ̀wọ̀n nínú òbítíbitì wákàtí táwọn èèyàn Ọlọ́run  fi ń jọ́sìn rẹ̀ lọ́dọọdún. Síbẹ̀, ohun tá a kọ́ nínú ìtàn opó aláìní yẹn fi hàn pé Jèhófà máa ń kíyè sí gbogbo ohun tá à ń ṣe fún un, ó sì mọyì wọn, pàápàá tó bá jẹ́ pé nǹkan ò fara rọ fún wa. Ronú nípa bó o ṣe lo ara rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ní ọdún tó kọjá. Ǹjẹ́ a rí àwọn àkókò kan tó gba pé kó o yááfì nǹkan kan kó o tó lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì ohun tó o ṣe fún un nírú àkókò bẹ́ẹ̀. Bíi ti opó yẹn, tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lò ń ṣe, ìdí tó ṣe gúnmọ́ wà tó fi yẹ kó o gbà pé o wà “nínú ìgbàgbọ́.”

“GBA ỌKÀN MI KÚRÒ”

12-14. (a) Ipa wo ni èrò òdì ní lórí Èlíjà? (b) Kí ló lè fà á tí Èlíjà fi bara jẹ́?

12 Adúróṣinṣin ni wòlíì Èlíjà, ó sì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. Síbẹ̀, ìgbà kan wà tí ọkàn rẹ̀ bà jẹ́ débi pé ó bẹ Jèhófà pé kó pa òun, ó sọ pé: “Ó tó gẹ́ẹ́! Wàyí o, Jèhófà, gba ọkàn mi kúrò.” (1 Ọba 19:4) Ó ṣeé ṣe kí àwọn tí kò nírú ìbànújẹ́ bẹ́ẹ̀ rí sọ pé “ọ̀rọ̀ ẹhànnà” lásán ni àdúrà tí Èlíjà gbà yẹn. (Jóòbù 6:3) Àmọ́ o, bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn rẹ̀ ló sọ yẹn. Sì kíyè sí i pé dípò kí Jèhófà bá Èlíjà wí torí pé ó gbàdúrà pé kí òun kú, ńṣe ló ràn án lọ́wọ́.

13 Kí ló fà á tí Èlíjà fi bara jẹ́? Ṣáájú ìgbà yẹn, Èlíjà ni abẹnugan níbi ọ̀rọ̀ kan tó wáyé nílẹ̀ Ísírẹ́lì tí wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, tí ìyẹn sì mú kí wọ́n pa àádọ́ta-lé-nírínwó [450] àwọn wòlíì Báálì. (1 Ọba 18:37-40) Ó ṣeé ṣe kí Èlíjà retí pé àwọn èèyàn Ọlọ́run á tìtorí ìyẹn pa dà sẹ́nu ìjọsìn mímọ́, àmọ́ wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Jésíbẹ́lì ayaba búburú tún wá ránṣẹ́ sí Èlíjà pé òun ti ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa pa á. Ẹ̀rù ba Èlíjà, ló bá sá gba ìhà gúúsù orílẹ̀-èdè náà lọ sí Júdà, ó sì gba ibẹ̀ sá lọ sínú aginjù, níbi aṣálẹ̀ tó dá páropáro.—1 Ọba 19:2-4.

14 Níbi tí Èlíjà dá jókòó sí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé iṣẹ́ wòlíì tòun ń ṣe kò dà bí èyí tó já mọ́ nǹkan kan. Ó sọ fún Jèhófà pé: “Èmi kò sàn ju àwọn baba ńlá mi.” Ohun tó ń sọ ni pé kò sí nǹkan tí òun fi yàtọ̀ sí erùpẹ̀ àti eegun àwọn baba ńlá òun tó ti kú. Lédè míì, ó ti yẹ ara rẹ̀ wò, ó sì ti gbà lójú ara rẹ̀ pé aláṣetì lòun, pé òun ò wúlò fún Jèhófà tàbí fún ẹnikẹ́ni.

15. Báwo ni Ọlọ́run ṣe fi Èlíjà lọ́kàn balẹ̀ pé Òun ṣì mọyì rẹ̀?

15 Àmọ́ ojú tí Olódùmarè fi wo Èlíjà yàtọ̀ pátápátá. Jèhófà Ọlọ́run ṣì mọyì Èlíjà gan-an, ó sì ṣe ohun tó fi í lọ́kàn balẹ̀ pé òun mọyì rẹ̀. Ọlọ́run rán áńgẹ́lì kan pé kó fún Èlíjà lókun. Jèhófà tún pèsè oúnjẹ àti omi fún Èlíjà kó lè rin ìrìn-àjo ológójì ọjọ́ lọ sí Òkè Hórébù níhà gúúsù. Bákan náà, Ọlọ́run fìfẹ́ tún ojú ìwòye Èlíjà ṣe, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì míì wà tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. Ó jọni lójú gan-an pé Ọlọ́run tún gbé iṣẹ́ míì fún Èlíjà, òun náà sì fayọ̀ gbà á. Èlíjà mọrírì ìrànwọ́ tí Jèhófà ṣe fún un, ó sì pa dà sẹ́nu iṣẹ́ wòlíì rẹ̀ lákọ̀tun.—1 Ọba 19:5-8, 15-19.

16. Àwọn ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe kí Ọlọ́run ti gbà bójú tó ẹ?

16 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà lè mú kó o yẹ ara rẹ wò bóyá o wà nínú ìgbàgbọ́, ó sì lè mú kó o ní èrò tó tọ́ nípa ara rẹ. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ronú nípa àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ti gba bójú tó ẹ. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, bóyá alàgbà tàbí Kristẹni kan tó dàgbà dénú, ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà kan tó o nílò ìrànlọ́wọ́? (Gál. 6:2) Ǹjẹ́ òye òtítọ́ ti túbọ̀ ṣe kedere sí ẹ nítorí ohun tó o ka nínú Bíbélì, nínú àwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run ṣe tàbí ohun tó o gbọ́ ní ìpàdé ìjọ? Nígbà míì tó o bá tún jàǹfààní nínú èyíkéyìí lára àwọn ìpèsè yìí, máa rántí Ẹni náà tó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nínú àdúrà.—Sm. 121:1, 2.

17. Kí ni Jèhófà máa ń mọyì lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?

 17 Èkejì, máa fi sọ́kàn pé èrò òdì lè ṣini lọ́nà. Ojú tí Ọlọ́run fi ń wò wá ló ṣe pàtàkì. (Ka Róòmù 14:4.) Jèhófà mọyì ìfọkànsìn àti ìṣòtítọ́ wa gan-an; kì í ṣe iṣẹ́ tá a bá ṣe ló fi ń díwọ̀n irú ẹni tá a jẹ́. Ó sì lè jẹ́ pé ìwọ náà ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan fún Jèhófà bíi ti Èlíjà, kó o má sì mọ bí àwọn nǹkan tó o ṣe ti pọ̀ tó. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan wà nínú ìjọ tó jẹ́ pé ìwọ ni Ọlọ́run lò láti mú kí wọ́n máa ṣe dáadáa, ó sì lè jẹ́ pé ìsapá rẹ ló mú kí àwọn kan ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

18. Kí ni iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wa ń fi hàn?

18 Paríparí rẹ̀, máa wo iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tí Jèhófà bá gbé fún ẹ bí ẹ̀rí tó fi hàn pé ó wà pẹ̀lú rẹ. (Jer. 20:11) Bíi ti Èlíjà, o lè rẹ̀wẹ̀sì torí pé iṣẹ́ ìsìn rẹ lè dà bí èyí tí kò méso jáde, tàbí torí pé ọwọ́ rẹ kò tẹ àwọn àfojúsùn kan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Síbẹ̀, àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ tí ẹnikẹ́ni lè ní lo ní báyìí, ìyẹn ni pé ò ń wàásù ìhìn rere a sì ń fi orúkọ Ọlọ́run pè ọ́. Má ṣe jẹ́ kó rẹ̀ ọ́. Tó bá yá, ìwọ náà lè wá wà lára àwọn tí a ó sọ irú ọ̀rọ̀ inú àkàwé Jésù náà fún pé: “Bọ́ sínú ìdùnnú ọ̀gá rẹ.”—Mát. 25:23.

“ÀDÚRÀ ẸNI TÍ ÌṢẸ́ Ń ṢẸ́”

19. Ìṣòro wo lẹni tó kọ Sáàmù kejìlélọ́gọ́rùn-ún ní?

19 Ẹni tó kọ Sáàmù kejìlélọ́gọ́rùn-ún [102] nílò ìrànlọ́wọ́ lójú méjèèjì. “Ìṣẹ́ ń ṣẹ́” onísáàmù náà, ó ní ìrora àti ìdààmú ọkàn, kò sì ní okun tó fi lè fàyà rán àwọn ìṣòro rẹ̀. (Sm. 102, àkọlé) Ohun tó sọ nínú sáàmù náà fi hàn pé ó wà nínú ìrora, ó dá nìkan wà, kò sì ní alábàárò. (Sm. 102:3, 4, 6, 11) Ó gbà pé ńṣe ni Jèhófà fẹ́ pa òun tì.—Sm. 102:10.

20. Báwo ni àdúrà ṣe lè ran ẹnì kan tó ń ní èrò òdì lọ́wọ́?

20 Síbẹ̀, onísáàmù náà ṣì lè lo ìgbésí ayé rẹ̀ láti máa yin Jèhófà. (Ka Sáàmù 102:19-21.) Ìwé Sáàmù kejìlélọ́gọ́rùn-ún jẹ́ kó ṣe kedere pé èèyàn lè wà nínú ìgbàgbọ́ síbẹ̀ kó wà nínú ìrora, kó má sì rí nǹkan míì rò ju ìyẹn lọ. Onísáàmù náà sọ pé òun dà “bí ẹyẹ tí ó dá wà lórí òrùlé,” bí ẹni pé kò sí ohun míì tó ń rí yàtọ̀ sí àwọn ìṣòro rẹ̀. (Sm. 102:7) Bí irú èrò bẹ́ẹ̀ bá ti wá sí ẹ lọ́kàn rí, sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún Jèhófà, bí onísáàmù náà ti ṣe. Àdúrà àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, ìyẹn àdúrà rẹ, máa jẹ́ kó o lè borí èrò òdì. Má ṣe jẹ́ kí ìdààmú ọkàn bá ẹ torí pé o nírú èrò bẹ́ẹ̀. Jèhófà ṣèlérí pé ‘òun máa yíjú sí àdúrà àwọn tí a kó gbogbo nǹkan ìní wọn lọ, òun kì yóò sì tẹ́ńbẹ́lú àdúrà wọn.’ (Sm. 102:17) Fọkàn tán ìlérí yẹn.

21. Báwo ni ẹnì kan tó ń ní èrò òdì ṣe lè máa ní èrò tó tọ́?

21 Ìwé Sáàmù kejìlélọ́gọ́rùn-ún tún sọ bó o ṣe lè máa ní èrò tó tọ́. Ohun tó mú kí onísáàmù náà máa ní èrò tó tọ́ ni pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. (Sm. 102:12, 27) Ọkàn rẹ̀ balẹ̀ nígbà tó mọ̀ pé Jèhófà máa ń dúró ti àwọn èèyàn Rẹ̀ lọ́jọ́ dídùn àti lọ́jọ́ kíkan. Torí náà, bó bá ṣẹlẹ̀ pé fún àwọn àkókò kan, èrò òdì ò jẹ́ kó o lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, gbàdúrà nípa rẹ̀. Bẹ Ọlọ́run pé kó gbọ́ àdúrà rẹ, kì í ṣe nítorí kó o lè rí ìtura kúrò nínú ìrora ọkàn tó o ní nìkan ni o, àmọ́ nítorí “kí a lè polongo orúkọ Jèhófà” pẹ̀lú.—Sm. 102:20, 21.

22.  Báwo ni ẹnì kọ̀ọ̀kàn wa ṣe lè máa mú inú Jèhófà dùn?

22 Ó ṣe kedere pé a lè máa fi Bíbélì wádìí ara wa ká lè mọ̀ bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́ àti pé Jèhófà mọyì wa. Òótọ́ ni pé ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti mú gbogbo èrò òdì àti ìrẹ̀wẹ̀sì kúrò pátápátá nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Síbẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè múnú Jèhófà dùn ká sì rí ìgbàlà tá a bá fara dà á nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láìbọ́hùn.—Mát. 24:13.