JÉSÙ Kristi sọ fún ọkùnrin kan tó fẹ́ di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Lọ sí ilé lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, kí o sì ròyìn fún wọn gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ọ àti àánú tí ó ní sí ọ.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Gádárà, ní gúúsù ìlà oòrùn Òkun Gálílì, ni Jésù wà nígbà tó sọ̀rọ̀ yìí. Ohun tí Jésù sọ sì fi hàn pé ó mọ ohun kan táwa èèyàn sábà máa ń fẹ́ ṣe, ìyẹn ni pé, ká sọ àwọn nǹkan tó wù wá àti ohun tá a kà sí pàtàkì fún àwọn ìbátan wa.—Máàkù 5:19.

Irú ẹ̀ náà wọ́pọ̀ lóde òní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wọ́pọ̀ láwọn ibì kan ju ibòmíì lọ. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé bí ẹnì kan bá di olùjọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, ó sábà máa ń fẹ́ láti sọ ohun tó gbà gbọ́ fún àwọn ìbátan rẹ̀. Àmọ́ ọ̀nà wo ló yẹ kó gbé e gbà? Báwo ló ṣe lè mú kí àwọn ìbátan rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsìn wọn yàtọ̀, tàbí bóyá wọn ò tiẹ̀ ní ẹ̀sìn kankan? Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn tó ń gbéni ró, èyí tó lè wúlò fún wa.

“ÀWA TI RÍ MÈSÁYÀ NÁÀ”

Ní ọ̀rúndún kìíní, Áńdérù wà lára àwọn tó kọ́kọ́ dá Jésù mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tó kọ́kọ́ lọ sọ fún? “[Áńdérù] rí arákùnrin tirẹ̀, Símónì, ó sì wí fún un pé: ‘Àwa ti rí Mèsáyà náà’ (èyí tí ó túmọ̀ sí ‘Kristi,’ nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀).” Áńdérù mú Pétérù lọ sọ́dọ̀ Jésù, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí Pétérù ní àǹfààní láti di ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù.—Jòh. 1:35-42.

Ní nǹkan bí ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà, tí Pétérù wà nílùú Jópà, ọ̀gá ológun kan tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù ní kó wá sílé òun tó wà ní apá àríwá ní Kesaréà. Àwọn wo ni Pétérù bá tí wọ́n kóra jọ sínú ilé náà? “Kọ̀nílíù ti ń fojú sọ́nà fún [Pétérù àtàwọn tó bá a  rìnrìn àjo], ó sì ti pe àwọn ìbátan rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ jọ.” Kọ̀nílíù tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù, kí wọ́n wá gbé ìpinnu wọn karí ohun tí wọ́n gbọ́.—Ìṣe 10:22-33.

Kí la lè rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Áńdérù àti Kọ̀nílíù gbà ran àwọn ìbátan wọn lọ́wọ́?

Áńdérù àti Kọ̀nílíù ò kàn fi ọwọ́ lẹ́rán láìṣe nǹkan kan. Áńdérù ló fi Pétérù mọ Jésù, Kọ̀nílíù sì ṣètò bí àwọn ìbátan rẹ̀ á ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù. Àmọ́ Áńdérù àti Kọ̀nílíù ò fipá mú àwọn ìbátan wọn, wọn ò sì dọ́gbọ́n tàn wọ́n kí wọ́n lè di ọmọlẹ́yìn Kristi. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa? Ó kọ́ wa pé káwa náà máa sọ àwọn nǹkan tá a mọ̀ fáwọn ìbátan wa, ká wá bí wọ́n ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kí wọ́n sì tún mọ àwọn ará. Síbẹ̀, a ò ní gbàgbé pé wọ́n ní òmìnira láti yan ohun tó wù wọ́n, a ò sì ní máa fipá mú wọn. Ká lè mọ bá a ṣe lè máa ran àwọn ìbátan wa lọ́wọ́, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ tọkọtaya kan ní orílẹ̀-èdè Jámánì, ìyẹn Jürgen àti Petra.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ Petra lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà tó sì yá ó ṣèrìbọmi. Ọ̀gá ni Jürgen ọkọ rẹ̀ jẹ́ nínú iṣẹ́ ológun. Inú rẹ̀ ò kọ́kọ́ dùn sí ìpinnu tí ìyàwó rẹ̀ ṣe. Àmọ́, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, òun náà wá rí i pé òtítọ́ inú Bíbélì làwọn Ẹlẹ́rìí fi ń kọ́ni. Ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì ti di alàgbà ìjọ báyìí. Kí ló sọ nípa béèyàn ṣe lè mú kí àwọn ìbátan rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́?

Jürgen sọ pé: “A kò gbọ́dọ̀ máa wàásù fáwọn ìbátan wa ní gbogbo ìgbà ṣáá débi tí wọn ò fi ní rímú mí. Wọ́n lè tìtorí ìyẹn sọ pé àwọn ò ní gbọ́rọ̀ wa. Torí náà, ohun tó máa sàn jù ni pé ká rọra máa bá wọn sọ ọ́ lóòrèkóòrè. Ó tún dára ká fojú àwọn ìbátan wa mọ àwọn ará tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́ tí wọ́n sì jọ nífẹ̀ẹ́ sí ohun kan náà. Èyí lè mú kí wọ́n gbọ́ ohun táwa ò ní àǹfààní láti sọ fún wọn.”

“A kò gbọ́dọ̀ máa wàásù fáwọn ìbátan wa ní gbogbo ìgbà ṣáá débi tí wọn ò fi ní rímú mí.”—Jürgen

Kò pẹ́ rárá tí àpọ́sítélì Pétérù àtàwọn ìbátan Kọ̀nílíù fi gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n gbọ́. Àmọ́, ó gba àwọn kan tí wọ́n rí òtítọ́ ní ọ̀rúndún kìíní lákòókò díẹ̀ kí wọ́n tó dórí ìpinnu.

ÀWỌN IYÈKAN JÉSÙ ŃKỌ́?

Àwọn mélòó kan lára àwọn ìbátan Jésù gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́ nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí àpọ́sítélì Jákọ́bù àti Jòhánù jẹ́ ẹbí Jésù, kí Sàlómẹ̀ ìyá wọn sì jẹ́ ẹ̀gbọ́n Màríà tó jẹ́ ìyá Jésù. Ó ṣeé ṣe kí Sàlómẹ̀ yìí jẹ́ ọ̀kan lára “ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin mìíràn, àwọn ẹni tí ń ṣèránṣẹ́ fún [Jésù àtàwọn àpọ́sítélì] láti inú àwọn nǹkan ìní wọn.”—Lúùkù 8:1-3.

Àmọ́, àwọn míì wà lára ìdílé Jésù tí wọn kò tètè gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, ní ohun tó lé lọ́dún kan lẹ́yìn ìrìbọmi Jésù, ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn èrò kóra jọ sínú ilé kan láti gbọ́rọ̀ rẹ̀. “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n jáde lọ láti gbá a mú, nítorí wọ́n ń wí pé: ‘Orí rẹ̀ ti yí.’” Kò pẹ́ púpọ̀ sígbà yẹn táwọn àbúrò Jésù béèrè ìgbà tó máa rìnrìn àjò kan, àmọ́ kò fún wọn lésì kan tó ṣe gúnmọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé “ní ti tòótọ́, àwọn arákùnrin rẹ̀ kì í lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.”—Máàkù 3:21; Jòh. 7:5.

Kí la rí kọ́ nípa ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn ìbátan rẹ̀? Kò bínú nígbà táwọn kan sọ pé orí rẹ̀ ti yí. Kódà lẹ́yìn ikú àti àjíǹde rẹ̀, ó tún fún àwọn ìbátan rẹ̀ níṣìírí nígbà tó fara han Jákọ́bù àbúrò rẹ̀. Ó ní láti jẹ́ pé bí Jésù ṣe fara han Jákọ́bù yẹn mú kó  dá a lójú pé Òun ni Mèsáyà ní tòótọ́, àmọ́ òun nìkan kọ́, àwọn àbúrò Jésù míì náà gbà bẹ́ẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n wà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì nínú yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù, ó sì dájú pé àwọn náà rí ẹ̀mí mímọ́ gbà. Nígbà tó ṣe, Jákọ́bù àti Júdà tí àwọn náà jẹ́ àbúrò Jésù ní àwọn àǹfààní àgbàyanu nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.—Ìṣe 1:12-14; 2:1-4; 1 Kọ́r. 15:7.

Ó LÈ PẸ́ KÁWỌN KAN TÓ KẸ́KỌ̀Ọ́

“Kò sóhun téèyàn ò lè ṣe láṣeyọrí téèyàn bá ní sùúrù, sùúrù àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù.”—Roswitha

Bíi tàwọn kan ní ọ̀rúndún kìíní, ó lè pẹ́ kí àwọn ìbátan wa kan tó bẹ̀rẹ̀ sí í rìn lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Ẹ wo àpẹẹrẹ obìnrin kan tó ń jẹ́ Roswitha. Ìjọ Kátólíìkì ló ń lọ nígbà tí ọkọ rẹ̀ ṣèrìbọmi tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1978. Níwọ̀n bí Roswitha ti gbà pé ẹ̀sìn Kátólíìkì tóun ń ṣe ló tọ̀nà, ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun ti ọkọ rẹ̀. Àmọ́ bí ọdún ṣe ń gorí ọdún kò fi bẹ́ẹ̀ ta ko ọkọ rẹ̀ mọ́, ó sì wá gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí ló ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Òun náà sì ṣèrìbọmi lọ́dún 2003. Kí ló mú kí Roswitha yí pa dà? Kàkà kí ọkọ rẹ̀ gbaná jẹ ní gbogbo ìgbà tó fi ń ṣàtakò sí i, ńṣe ló fún un láǹfààní láti yí èrò rẹ̀ pa dà. Kí ni Roswitha fúnra rẹ̀ wá sọ? Ó ní: “Kò sóhun téèyàn ò lè ṣe láṣeyọrí téèyàn bá ní sùúrù, sùúrù àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù.”

Ọdún 1974 ni Monika ṣèrìbọmi, àmọ́ nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà làwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì tó wá di Ẹlẹ́rìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Hans kò ta kò ó, ọdún 2006 ló tó ṣèrìbọmi. Kí ni ìdílé náà ní í sọ látinú ìrírí tí wọ́n ní? Wọ́n sọ pé: “Ẹ rọ̀ mọ́ Jèhófà, ẹ má sì ṣe ohunkóhun tí kò bá ìgbàgbọ́ yín mu.” Àmọ́ ṣá o, wọ́n mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn máa fi dá Hans lójú nígbà gbogbo pé àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Wọn ò sì sọ̀rètí nù pé bópẹ́bóyá ó máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

OMI ÒTÍTỌ́ LÈ MÚ KÍ ARA TÙ WỌ́N

Nígbà kan, Jésù fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ tá à ń wàásù rẹ̀ wé omi tó ń fúnni ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 4:13, 14) A fẹ́ kí omi òtítọ́ tó tutù lóló tó sì mọ́ gaara tu àwọn ìbátan wa lára. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ kí omi yìí sá pá wọn lórí torí pé wọn ò tíì gbé tẹnu mì tá a fi ń bu òmíràn sí i. Yálà ọ̀rọ̀ òtítọ́ máa tù wọ́n lára tàbí wọ́n máa gbà á sódì sinmi lórí bí a bá ṣe ń ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn. Bíbélì sọ pé “ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn” àti pé “ọkàn-àyà ọlọ́gbọ́n ń mú kí ẹnu rẹ̀ fi ìjìnlẹ̀ òye hàn, èyí sì ń fi ìyíniléròpadà kún ètè rẹ̀.” Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò?—Òwe 15:28; 16:23.

Aya kan lè fẹ́ ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fún ọkọ rẹ̀. Tó bá ṣe “àṣàrò láti lè dáhùn,” á fọgbọ́n gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀, kò sì ní fìkánjú sọ̀rọ̀. Kò ní fẹ́ kò dà bíi pé òun jẹ́ olódodo tàbí pé òun gbọ́n ju ọkọ òun lọ. Ọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání tó sọ máa tu ọkọ náà lára, kò sì ní fa ìjà. Àwọn ìbéèrè díẹ̀ tó yẹ kí aya ronú lé lórí rèé: Ìgbà wo ni ara máa ń tu ọkọ mi táá sì ṣeé bá sọ̀rọ̀? Kí ló máa ń fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí tàbí kó kà nípa rẹ̀? Ṣé ọ̀rọ̀ sáyẹ́ǹsì ló fẹ́ràn láti máa sọ ni àbí ti òṣèlú, àbí ti eré ìdárayá? Báwo ni obìnrin náà ṣe lè mú kí ọkọ rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì, síbẹ̀ kó sì bọ̀wọ̀ fún èrò rẹ̀ àti ojú tó fi ń wo nǹkan? Bí obìnrin náà bá ronú lórí àwọn nǹkan yìí, á mọ bó ṣe lè lo ìjìnlẹ̀ òye lọ́rọ̀ àti níṣe.

Tá a bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn ìdílé wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lọ́kàn, kì í wulẹ̀ ṣe pé ká máa dọ́gbọ́n wàásù fún wọn díẹ̀díẹ̀ nìkan ni, ó tún yẹ ká fi ìwà rere ti ohun tá a bá ń sọ lẹ́yìn.

JẸ́ ÀWÒFIṢÀPẸẸRẸ

Arákùnrin Jürgen tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ó yẹ ká máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbà gbogbo. Ìyẹn gan-an ló máa mú kí àwọn ìbátan wa ronú jinlẹ̀ kí wọ́n sì kíyè sí ohun tí à ń ṣe, bí wọn ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ gbà pẹ̀lú wa.” Hans, tó ṣèrìbọmi ní ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn tí ìyàwó rẹ̀ ṣe ìrìbọmi sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì kéèyàn jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, kí àwọn ìbátan lè rí ipa rere tí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá à ń kọ́ ń ní lórí ìgbésí ayé àwa fúnra wa.” Bí àwọn ìbátan wa bá máa tọ́ka sí àwọn ohun tó mú ká yàtọ̀ sáwọn míì, ó yẹ kó jẹ́ àwọn àyípadà rere tí wọ́n kíyè sí kì í ṣe àwọn nǹkan tí kò gbéni ró.

“Ó ṣe pàtàkì kéèyàn jẹ́ àwòkọ́ṣe, kí àwọn ìbátan lè rí ipa rere tí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá à ń kọ́ ń ní lórí ìgbésí ayé àwa fúnra wa.”—Hans

Àpọ́sítélì Pétérù fún àwọn aya tí ọkọ wọn ò sí nínú òtítọ́ nímọ̀ràn tó ṣeyebíye. Ó ní: “Ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀. Kí ọ̀ṣọ́ yín má sì jẹ́ ti irun dídì lóde ara àti ti  fífi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára tàbí ti wíwọ àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù, èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.”—1 Pét. 3:1-4.

Pétérù sọ pé ìwà rere ìyàwó kan lè yí ọkọ rẹ̀ lérò padà. Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ìwé Mímọ́ yìí, látìgbà ti arábìnrin kan tó ń jẹ́ Christa ti ṣèrìbọmi lọ́dún 1972 ló ti ń sapá láti hùwà táá mú kí ọkọ rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé láàárín kan, àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọkọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, kò tíì sọ òtítọ́ di tirẹ̀. Kódà, ó ti bá wọn lọ sí ìpàdé láwọn ìgbà mélòó kan, tó sì ti mọ àwọn ará dáadáa. Síbẹ̀, àwọn ará gbà pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti yan ohun tó wù ú. Báwo ni ìyàwó rẹ̀ ṣe mú kí ó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́?

Ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Mo ti pinnu pé ọ̀nà tí Jèhófà bá fẹ́ kí n tọ̀ ni màá tọ̀. Lẹ́sẹ̀ kan náà, mo gbìyànjú láti jèrè ọkọ mi “láìsọ ọ̀rọ̀ kan” nípasẹ̀ ìwà rere mi. Gbogbo ohun tó bá fẹ́ ni mò ń ṣe, bí ò bá ṣáà ti lòdì sí ìlànà Bíbélì. Mo sì gbà pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti yan ohun tó wù ú. Torí náà, ṣe ni mo fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́.”

Ohun tí Christa sọ pé òun máa ń ṣe yìí jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa gba tàwọn ẹlòmíì rò. Ìgbòkègbodò tẹ̀mí rẹ̀ kì í já létí, irú bíi lílọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí déédéé. Síbẹ̀, ó ń fi òye bá ọkọ rẹ̀ lò, ó gbà pé ó yẹ kí òun máa fìfẹ́ hàn sí i, kóun máa lo àkókò pẹ̀lú rẹ̀, kóun sí máa wáyè gbọ́ tirẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni nínú wa bá ní àwọn ìbátan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, kò yẹ ká máa rin kinkin mọ́ wọn, ó sì yẹ ká máa fòye bá wọn lò. Bíbélì ṣáà sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.” Èyí sì kan àkókò tá à ń lò pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ ara ìdílé wa, ní pàtàkì ọkọ tàbí aya wa tí kò sí nínú òtítọ́. Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ lẹ jọ máa sọ tẹ́ ẹ bá ń wà pa pọ̀. Ìrírí tiẹ̀ fi hàn pé tẹ́ ẹ bá jọ ń bára yín sọ̀rọ̀ déédéé, kò ní máa ṣe ẹnì kejì yín bíi pé ó dá wà, bíi pé ẹ ò rí tiẹ̀ rò, kò sì ní máa jowú.—Oníw. 3:1.

MÁ ṢE SỌ̀RÈTÍ NÙ

Ogún ọdún lẹ́yìn tí àwọn tó kù nínú ìdílé ti ṣèrìbọmi ni bàbá Arákùnrin Holger tó ṣèrìbọmi. Arákùnrin Holger sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn àti pé a máa ń gbàdúrà fún wọn.” Arábìnrin Christa tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, òun ‘ò ní sọ̀rètí nù láé pé ọkọ òun ṣì máa wá sin Jèhófà.’ Gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa ní ẹ̀mí pé nǹkan ṣì máa dáa, pé àwọn ìbátan wa tí kò tíì sí nínú òtítọ́ ṣì máa wá sin Jèhófà.

Ó yẹ ká pinnu pé a fẹ́ túbọ̀ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn ìbátan wa, kí wọ́n lè rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kí ẹ̀kọ́ Bíbélì sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Ó sì yẹ ká máa hùwà “pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” nínú ohun gbogbo.—1 Pét. 3:15.