Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  March 2014

Bá A Ṣe Lè Máa Tọ́jú Àwọn Àgbàlagbà

Bá A Ṣe Lè Máa Tọ́jú Àwọn Àgbàlagbà

“Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.”—1 JÒH. 3:18.

1, 2. (a) Àwọn ìṣòro wo ni ọ̀pọ̀ ìdílé ń ní, àwọn ìbéèrè wo ló sì lè jẹ yọ? (b) Kí ni àwọn òbí àtàwọn ọmọ lè ṣe nípa àwọn ìṣòro tó bá ń wáyé?

Ó MÁA ń bani nínú jẹ́ gan-an táwọn òbí ẹni, tí wọ́n lè lọ sókè sódò, tí wọ́n sì lè bójú tó ara wọn tẹ́lẹ̀ kò bá lè ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. Ó lè ṣẹlẹ̀ pé Bàbá tàbí Ìyá àwọn kan ṣubú tí itan rẹ̀ sì yẹ̀, tàbí pé òbí wọn ò rántí ibi tó ń lọ tó sì ṣìnà, tàbí kí wọ́n gbọ́ pé àìsàn ńlá kan kọ lù wọ́n. Ìṣòro tí àwọn míì ní sì lè yàtọ̀ sóhun tá a sọ yìí. Ó lè nira fún àwọn àgbàlagbà kan láti gbà pé ara ti di ara àgbà tàbí pé àwọn ti dẹni táá máa nílò ìrànlọ́wọ́. (Jóòbù 14:1) Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí la lè ṣe? Báwo la ṣe lè máa tọ́jú wọn?

2 Àpilẹ̀kọ kan nípa ìtọ́jú àwọn àgbàlagbà sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn láti sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro tí àwọn arúgbó máa ń ní, bí ìdílé bá jíròrò onírúurú ọ̀nà tí wọ́n lè gbé nǹkan gbà, tí wọ́n sì pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe, ó máa túbọ̀ rọrùn fún wọn láti yanjú ìṣòro tó bá yọjú.” Èèyàn á túbọ̀ rí i pé ó ṣe pàtàkì kí irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ wáyé téèyàn bá gbà pé ìṣòro tó ń bá ọjọ́ ogbó rìn kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Síbẹ̀, a lè múra àwọn nǹkan kan sílẹ̀ kó tó di pé ìṣòro máa yọjú ká sì ti pinnu ohun tá a máa ṣe. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò bí àwọn ìdílé ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n lè pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe bí àwọn ìṣòro kan bá yọjú.

BÍ A ṢE LÈ MÚRA SÍLẸ̀ DE “ÀWỌN ỌJỌ́ ONÍYỌNU ÀJÁLÙ”

3. Kí ló máa pọn dandan pé kí àwọn ìdílé ṣe tó bá di pé àwọn òbí tó ti di àgbàlagbà ń nílò ìrànlọ́wọ́ lemọ́lemọ́? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

3 Ó máa ń tó àkókò kan tí àwọn àgbàlagbà ò ní lè bójú tó ara  wọn dáadáa mọ́, táá wá gba pé ká máa ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ka Oníwàásù 12:1-7.) Tí àwọn òbí tó ti di arúgbó ò bá lè dá tọ́jú ara wọn mọ́, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn àtàwọn ọmọ wọn tó ti dàgbà pinnu irú ìrànlọ́wọ́ tó máa ṣàǹfààní jù lọ fún wọn, kí wọ́n sì ṣe ohun tí agbára wọ́n ká. Ohun tó sábà máa ń bọ́gbọ́n mu ni pé kí ìdílé náà pe ìpàdé, kí wọ́n jíròrò ohun tó ń fẹ́ àbójútó, ọ̀nà tí wọ́n á gbé nǹkan gbà àti bí wọ́n ṣe máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Kí olúkúlùkù sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ láìfọ̀rọ̀-sábẹ́-ahọ́n, ní pàtàkì àwọn òbí, kí wọ́n sì gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa. Wọ́n lè jíròrò bóyá tí àwọn bá ṣètò àwọn ìrànwọ́ kan, àwọn òbí náà á lè máa gbé ilé tí wọ́n wà nìṣó láìséwu. * Wọ́n sì lè jíròrò bí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé á ṣe máa ṣe ohun tí agbára rẹ̀ gbé kí àwọn òbí lè rí àbójútó tí wọ́n nílò gbà. (Òwe 24:6) Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lára wọn lè máa ṣètọ́jú tó yẹ fún àwọn òbí lójoojúmọ́, ó sì lè rọrùn fún àwọn míì láti máa fi owó ṣèrànwọ́. Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn mọ ojúṣe tirẹ̀, àmọ́ ojúṣe náà lè yí pa dà bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, kí wọ́n sì máa gbà á ṣe láàárín ara wọn.

4. Ibo ni àwọn tó wà nínú ìdílé ti lè rí ìrànlọ́wọ́?

4 Ní báyìí tẹ́ ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jú àwọn òbí yín, ẹ wá bẹ́ ẹ ṣe máa túbọ̀ lóye ohun tó ń ṣe wọ́n. Tó bá jẹ́ pé àìsàn tó máa ń sọ ara di hẹ́gẹhẹ̀gẹ ló ń ṣe àwọn òbí yín, ẹ sapá láti mọ nǹkan míì tí irú àìsàn bẹ́ẹ̀ lè yọrí sí lọ́jọ́ iwájú. (Òwe 1:5) Ẹ kàn sí àwọn iléeṣẹ́ ìjọba tó ń tọ́jú àwọn àgbàlagbà. Ẹ wádìí àwọn ètò tí ìlú ṣe fún àwọn àgbàlagbà táá jẹ́ kó túbọ̀ rọ̀ yín lọ́rùn láti tọ́jú àwọn òbí yín. Bẹ́ ẹ ṣe ń ronú nípa ìyípadà tí ipò àwọn òbí yín máa mú wá yìí, ọ̀rọ̀ náà lè kó ìpayà bá yín, kẹ́ ẹ máa banú jẹ́, kí ẹ̀rù máa bà yín, tàbí kí ọkàn yín dà rú. Sọ bó ṣe rí lára rẹ fún ọ̀rẹ́ kan tó o fọkàn tán. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún Jèhófà. Jèhófà lè fún ẹ ní àlàáfíà ọkàn táá jẹ́ kó o lè bójú tó ipò èyíkéyìí tó bá yọjú.—Sm. 55:22; Òwe 24:10; Fílí. 4:6, 7.

5. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kẹ́ ẹ ti ní ìsọfúnni lọ́wọ́ nípa onírúurú ìtọ́jú tó wà fún àwọn àgbàlagbà kó tó di pé ìṣòro dé?

5 Àwọn àgbàlagbà kan àtàwọn ìdílé wọn máa ń ṣe ohun kan tó mọ́gbọ́n dání. Kí ìṣòro tó dé ni wọ́n ti máa ń ní ìsọfúnni lọ́wọ́ nípa onírúurú ìtọ́jú tó wà fún àwọn àgbàlagbà, irú bíi kí òbí máa gbé pẹ̀lú ọmọ wọn ọkùnrin tàbí obìnrin, kí wọ́n máa gbé ní ilé tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn arúgbó, tàbí bí wọ́n ṣe lè rí ìrànwọ́ tó wà fún àwọn àgbàlagbà gbà. Wọ́n ti fòye gbé “ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́” tó lè wáyé lọ́jọ́ iwájú wọ́n sì ti múra sílẹ̀ dè é. (Sm. 90:10) Ọ̀pọ̀ ìdílé ni kì í fi bẹ́ẹ̀ múra sílẹ̀, á wá di dandan pé kí wọ́n ṣe àwọn ìpinnu tó nira nígbà tí ìṣòro bá dé. Ògbógi kan sọ pé irú àkókò bẹ́ẹ̀ ni “àkókò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ burú jù lọ pé kéèyàn ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀.” Bí àwọn tó wà nínú ìdílé bá ṣe ìpinnu nígbà tí nǹkan ti bọ́ sórí, wọ́n lè máa kanra, wọ́n sì lè wojú ara wọn. Àmọ́ bí wọ́n bá ti wéwèé ohun tí wọ́n máa ṣe ṣáájú, bí nǹkan ò bá gba ibi tí wọ́n fi ojú sí, kò ní ṣòro láti ṣe ìyípadà tó bá yẹ.—Òwe 20:18.

Ẹ lè pe ìpàdé ìdílé láti sọ bẹ́ ẹ ṣe máa tọ́jú àwọn òbí yín (Wo ìpínrọ̀ 6 sí 8)

6. Báwo ló ṣe máa ṣe àwọn òbí àtàwọn ọmọ láǹfààní bí wọ́n bá jíròrò nípa ibi tí àwọn òbí tó ti ń di arúgbó á máa gbé?

6 Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún ẹ láti bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ nípa ibi tí wọ́n ń gbé báyìí àti pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n kúrò níbẹ̀ tó bá yá. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ti rí i pé irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Kí nìdí? Ìdí ni pé bí wọ́n ṣe jíròrò ọ̀rọ̀ náà kí ìṣòro tó dé mú kí wọ́n gbọ́ra wọn yé, wọn ò tahùn síra, wọ́n sì ṣe ètò tó ṣe gúnmọ́. Wọ́n rí i pé bí àwọn ṣe tètè fikùn lukùn, tí àwọn sì fi ìfẹ́ àti inúure bá ara àwọn lò mú kó túbọ̀ rọrùn láti ṣe ohun tí wọ́n pinnu nígbà tó yá. Kódà táwọn àgbàlagbà bá sọ pé àwọn ò fẹ́ gbé lọ́dọ̀ ọmọ àwọn àti pé àwọn á máa bójú tó ara àwọn débi tí àwọn bá lè ṣe é  dé, ó dájú pé àǹfààní ṣì wà nínú bí wọ́n ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn mọ irú ìtọ́jú tí wọ́n máa fẹ́ tí ìṣòro bá dé.

7, 8. Àwọn nǹkan wo ló máa dára kí àwọn ìdílé jíròrò? Kí nìdí?

7 Ẹ̀yin òbí, nígbà tí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín bá jọ ń jíròrò, ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tẹ́ ẹ fẹ́, ibi tágbára yín mọ ni ti ọ̀rọ̀ owó àti irú ìtọ́jú tó wù yín. Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé àgbà wá dé pátápátá, àwọn ọmọ yín á lè ṣe àwọn ìpinnu tó yẹ. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n gba ohun tẹ́ ẹ fẹ́ rò, kí wọ́n sì fàyè gbà yín láti ṣe ohun tó wù yín bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Éfé. 6:2-4) Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ẹ retí pé kí ọ̀kan lára àwọn ọmọ yín mú yín sọ́dọ̀ àbí ètò míì lẹ retí pé kí wọ́n ṣe? Ẹ gba ti àwọn ọmọ yín náà rò, kẹ́ ẹ sì fi sọ́kàn pé ojú tí wọ́n fi wo ọ̀rọ̀ náà lè yàtọ̀ sí tiyín. Àti pé, kì í rọrùn fún gbogbo èèyàn, yálà òbí tàbí àwọn ọmọ, láti yí èrò wọn pa dà.

8 Ó dára kí gbogbo yín fi sọ́kàn pé tẹ́ ẹ bá wéwèé ohun tẹ́ ẹ máa ṣe tẹ́ ẹ sì jọ jíròrò, kò ní fi bẹ́ẹ̀ sí ìṣòro. (Òwe 15:22) Lára ohun tó yẹ kẹ́ ẹ jíròrò ni ọ̀rọ̀ ìtọ́jú ìṣègùn àti ohun tí àwọn òbí yín fẹ́. Ẹ má sì ṣe gbàgbé láti jíròrò àwọn kókó tó wà nínú káàdì tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lò láti gbẹnu sọ fún wa lórí ọ̀ràn ìtọ́jú ìṣègùn, ìyẹn Health Care Proxy. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ irú ìtọ́jú tó wà, ó sì lẹ́tọ̀ọ́ láti yan èyí tó fẹ́ àtèyí tí kò fẹ́. Àwọn ohun téèyàn fẹ́ àtèyí tí kò fẹ́ ló wà nínú káàdì Advance Medical Directive, tí àwọn kan ń pè ní káàdì mi-ò-gbẹ̀jẹ̀. Tẹ́ ẹ bá yan ẹni tó lè ṣojú fún yín nínú ọ̀ràn ìtọ́jú ìṣègùn (níbi tó bá ti ṣeé ṣe tí òfin sì fàyè gbà yín láti ṣe bẹ́ẹ̀), ọkàn yín á balẹ̀ pé tó bá pọn dandan, ẹni tẹ́ ẹ fi ọkàn tán yẹn máa ṣe àwọn ìpinnu tó bá yẹ. Á dára kí gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ yìí kàn ní ẹ̀dà káàdì àtàwọn àkọsílẹ̀ míì lọ́wọ́ torí ọjọ́ ìdágìrì. Àwọn kan máa ń fi ẹ̀dà irú àwọn àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ sínú ìwé ìhágún wọn àtàwọn àkọsílẹ̀ pàtàkì míì nípa ètò ìbánigbófò, ìnáwó, ọ̀ràn tó kan àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

BẸ́ Ẹ ṢE LÈ BÓJÚ TÓ ÌṢÒRO TÓ BÁ YỌJÚ

9, 10. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí àgbàlagbà kan tó máa nípa lórí ìrànwọ́ tí àwọn ọmọ ń ṣe?

9 Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn àgbàlagbà máa ń fẹ́ láti máa bójú tó ara wọn, àwọn ọmọ náà kì í sì í janpata, bó bá ṣẹlẹ̀ pé agbára àwọn òbí ṣì gbé e. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣì lè máa dá se oúnjẹ, kí wọ́n máa dá tún ilé ṣe, kí wọ́n máa dá lo oògùn wọn, kí wọ́n sì lè máa sọ bó ṣe ń ṣe wọ́n. Èyí á mú kó dá àwọn ọmọ wọn lójú pé wọ́n ṣì lè dá bójú tó ara wọn. Àmọ́, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún àwọn òbí láti máa lọ sókè sódò mọ́, wọ́n lè má lè lọ sọ́jà mọ́ tàbí kí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣarán. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á gba pé kí àwọn ọmọ yí ètò tí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ pa dà.

10 Lára ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé tó bá di ọjọ́ ogbó, àwọn arúgbó lè má mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe, wọ́n lè ní ìsoríkọ́, wọ́n lè máa tọ̀ tàbí kí wọ́n máa yàgbẹ́ sára. Òmíràn ni pé ojú wọn lè di bàìbàì, kí wọ́n máà gbọ́ràn mọ́, tàbí kí wọ́n máa gbàgbé nǹkan. Bí èyíkéyìí nínú ohun tá a sọ yìí bá ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n ṣì lè rí ìtọ́jú tó dáa gbà. Torí náà, ní gbàrà tí irú àwọn àìlera bẹ́ẹ̀ bá ti yọjú  ni kẹ́ ẹ ti gbé wọn lọ sí ilé ìwòsàn. Ó lè jẹ́ pé ẹ̀yin ọmọ lẹ máa kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀. Ó tiẹ̀ lè wá di pé ẹ̀yin ọmọ lẹ máa bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn òbí yín ṣe ìpinnu tí wọ́n ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Kí ìtọ́jú tí àwọn òbí ń rí gbà lè túbọ̀ ṣe wọ́n láǹfààní, ó lè gba pé kí àwọn ọmọ máa gbẹnu sọ fún wọn, kí wọ́n máa bá wọn ṣe àkọsílẹ̀, kí wọ́n sì máa gbé wọn lọ síbi tí wọ́n bá fẹ́ lọ.—Òwe 3:27.

11. Àwọn nǹkan wo lẹ lè ṣe táwọn ìyípadà tó ń yọjú kò fi ní kó yín sí ìdààmú púpọ̀?

11 Tẹ́ ò bá tíì rí ojútùú sí ìṣòro àwọn òbí yín, ó lè gba pé kẹ́ ẹ yí ìtọ́jú tẹ́ ẹ̀ ń fún wọn tàbí ibi tí wọ́n ń gbé pa dà. Ẹ fi sọ́kàn pé bí ìyípadà tẹ́ ẹ ṣe ò bá pọ̀ jù, ó máa rọrùn fún wọn láti fara mọ́ ọn. Ká sọ pé ibi tó jìnnà sí àwọn òbí rẹ lò ń gbé, tí àwọn ará tàbí aládùúgbò kan bá ń bá ẹ yọjú sí wọn látìgbàdégbà tí wọ́n sì ń jẹ́ kó o mọ bí nǹkan ṣe ń lọ, ìyẹn ńkọ́? Ṣé ẹni táá máa bá wọn se oúnjẹ táá sì máa tọ́jú ilé nìkan ni wọ́n nílò? Tẹ́ ẹ bá ṣe àwọn àtúnṣe díẹ̀ nínú ilé ńkọ́, ṣé ó máa mú kó túbọ̀ rọrùn fún wọn láti rìn yí ká nínú ilé, láti wẹ kí wọ́n sì tún ṣe àwọn nǹkan míì láìfi ara pa? Bóyá gbogbo ohun tí àwọn àgbàlagbà náà nílò ò sì ju ọmọ kan tí wọ́n á máa rí rán níṣẹ́ kí wọ́n má bàa máa yọ yín lẹ́nu. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ó léwu fún wọn láti máa dá gbé, ó máa gbà pé kẹ́ ẹ ṣètò míì tó máa wà pẹ́ títí fún wọn. Irú ìṣòro yòówù kó yọjú, ẹ wádìí àwọn ètò ìrànwọ́ tó wà ládùúgbò yín. *Ka Òwe 21:5.

BÍ ÀWỌN KAN ṢE BÓJÚ TÓ ÌṢÒRO TÓ YỌJÚ

12, 13. Báwo ni àwọn ọmọ tó ti dàgbà tí wọ́n ń gbé níbi tó jìn sí àwọn òbí ṣe ń bọlá fún àwọn òbí wọn tí wọ́n sì ń tọ́jú wọn láìdáwọ́ dúró?

12 Àwọn ọmọ tó nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn kì í fẹ́ kí wọ́n ráre. Ọkàn wọn máa ń balẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé àwọn ń tọ́jú òbí àwọn. Àmọ́ torí àwọn ojúṣe míì, ọ̀pọ̀ ọmọ tó ti dàgbà ni kì í gbé nítòsí àwọn òbí wọn. Àwọn ọmọ kan tó bára wọn nírú ipò yìí máa ń bẹ àwọn òbí wọn wò lásìkò ìsinmi kí wọ́n lè bójú tó wọn kí wọ́n sì bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí wọn ò lè ṣe mọ́. Ẹ lè mú kó dá àwọn òbí yín lójú pé ẹ nífẹ̀ẹ́ wọn tẹ́ ẹ bá ń bá wọn sọ̀rọ̀ déédéé lórí fóònù, tó bá ṣeé ṣe lójoojúmọ́, tàbí kẹ́ ẹ máa kọ lẹ́tà àfọwọ́kọ tàbí lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà sí wọn.—Òwe 23:24, 25.

13 Bó ti wù kí ìṣòro náà rí, ó lè gba pé kó o kíyè sí bí ìtọ́jú tó o ṣètò fún àwọn òbí rẹ ṣe gbéṣẹ́ tó. Tó ò bá sí nítòsí àwọn òbí rẹ, tí wọ́n sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí, o lè bi àwọn alàgbà ìjọ tí wọ́n wà bóyá wọ́n mọ àwọn nǹkan míì tó o lè ṣe. Má sì gbàgbé láti máa fi ọ̀rọ̀ náà sádùúrà. (Ka Òwe 11:14.) Bó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé àwọn òbí rẹ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, ó yẹ kó o máa “bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Ẹ́kís. 20:12; Òwe 23:22) Ká sòótọ́, gbogbo ìdílé ò lè ṣe irú ìpinnu kan náà. Àwọn kan ṣètò pé kí àwọn òbí wọn tó ti di àgbàlagbà kó wá sílé àwọn, tàbí kí wọ́n máa gbé nítòsí. Àmọ́, kì í rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Torí pé ó wu àwọn òbí kan láti máa dá gbé, wọn ò fẹ́ láti máa gbé pẹ̀lú ìdílé àwọn ọmọ wọn tó ti dàgbà kí wọ́n má bàa ni àwọn ọmọ náà lára. Àwọn òbí kan lè rí já jẹ, kí wọ́n sì yàn láti máa sanwó fẹ́ni tó ń tọ́jú wọn dípò tí wọ́n fi máa kó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ wọn.—Oníw. 7:12.

14. Ìṣòro wo ni àwọn tó dìídì ń tọ́jú àwọn òbí máa ń ní?

14 Nínú ọ̀pọ̀ ìdílé, ọmọ tó wà nítòsí àwọn òbí ló sábà máa ń ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú ìtọ́jú àwọn òbí. Síbẹ̀, ó yẹ kí wọ́n ṣètò ìtọ́jú àwọn òbí wọn lọ́nà tí kò fi ní pa àbójútó ìdílé tiwọn gan-an lára. Ó ní ibi tí agbára ẹnì kọ̀ọ̀kan mọ, a sì ní àkókò jura wa lọ. Àti pé ẹni tó ń tọ́jú òbí lónìí lè máà ráyè mọ́ tó bá yá, èyí tó máa mú kó pọn dandan pé kí ìdílé tún ètò wọn ṣe. Ṣé  kì í ṣe pé ọrùn ti fẹ́ máa wọ ẹnì kan jù nínú ìdílé náà? Ṣé àwọn ọmọ yòókù lè ṣe púpọ̀ sí i, bóyá kí wọ́n jọ máa pín iṣẹ́ àbójútó náà ṣe?

15. Kí ni àwọn tó ń tọ́jú òbí lè ṣe kó má bàa sú wọn?

15 Tó bá di pé gbogbo ìgbà ṣáá ni òbí tó ti dàgbà ń fẹ́ kí wọ́n ṣe nǹkan fóun, kò sígbà tí ọrùn ò ní wọ ẹni tó ń tọ́jú òbí náà. (Oníw. 4:6) Àwọn ọmọ tó fẹ́ràn àwọn òbí wọn máa ń fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe, àmọ́ tó bá ti ń di lemọ́lemọ́ jù, ó lè sú wọn. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí àwọn tó ń tọ́jú òbí ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu, bóyá kí wọ́n ní kí àwọn míì ran àwọn lọ́wọ́. Tí irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ bá ń wáyé látìgbàdégbà, kò ní sí pé wọ́n ń yára gbé òbí lọ sílé ìtọ́jú àwọn arúgbó.

16, 17. Àwọn ìṣòro wo ni àwọn ọmọ lè ní bí wọ́n ṣe ń tọ́jú àwọn arúgbó wọn? Báwo ni wọ́n ṣe lè borí ìṣòro náà? (Tún wo àpótí tá a pè ní “Ìtọ́jú Tí Wọ́n Ṣe Tọkàntọkàn.”)

16 Ó máa ń bani nínú jẹ́ pé àwọn òbí wa ọ̀wọ́n ń jẹ̀rora nítorí ọjọ́ ogbó. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń tọ́jú òbí wọn máa ń banú jẹ́, wọ́n máa ń ṣàníyàn, ọkàn wọn máa ń dà rú, wọ́n máa ń bínú, wọ́n máa ń dára wọn lẹ́bi, tàbí kí wọ́n máa kanra mọ́ àwọn míì. Ìgbà míì wà tí òbí tó ti darúgbó á sọ̀rọ̀ kòbákùngbé tàbí hùwà àìmoore. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe tètè gbaná jẹ. Ògbógi kan lórí ọ̀rọ̀ ìlera ọpọlọ sọ pé: “Bí ohun kan bá dùn ẹ́, má ṣe díbọ́n bí ẹni pé kò dùn ẹ́. Tó o bá gbà pé ó dùn ẹ́ lóòótọ́, á rọrùn fún ẹ láti gbé kúrò lọ́kàn. Síbẹ̀, má ṣe máa dá ara rẹ̀ lẹ́bi pé kí ló dé tó o fi bínú lọ́nà yẹn.” Sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ fún ọkọ tàbí aya rẹ, o sì lè sọ fún ẹlòmíì nínú ìdílé yín tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan tó o fi ọkàn tán. Irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, á sì jẹ́ kó o lè túbọ̀ máa mú sùúrù.

17 Ó lè ṣẹlẹ̀ pé apá ẹnì kankan nínú ìdílé yín kò ká a mọ́ láti máa tọ́jú òbí tó ti di arúgbó nìṣó nínú ilé. Ó lè pọn dandan pé kẹ́ ẹ mú àwọn òbí náà lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni arábìnrin kan máa ń lọ wo màmá rẹ̀ ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó. Ó sọ nípa ìdílé rẹ̀ pé: “Kò ṣeé ṣe fún wa láti máa tọ́jú Màámi látàárọ̀ ṣúlẹ̀ àti látòru mọ́jú. Kì í ṣe pé ó wù wá pé kí wọ́n máa gbé nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó. Inú wa ò dùn rárá àti rárá ni nígbà tá à ń ṣe ìpinnu yẹn. Àmọ́, a gbà pé tá a bá fẹ́ kí wọ́n gbádùn ìyókù ìgbésí ayé wọn, ohun tó máa dára jù nìyẹn, àwọn náà sì gbà bẹ́ẹ̀.”

18. Ìdánilójú wo làwọn tó ń tọ́jú òbí wọn lè ní?

18 Iṣẹ́ ńlá ni kéèyàn máa tọ́jú àwọn òbí tó ti darúgbó, kò rọrùn ó sì lè tánni lókun. Kò sí ọ̀nà kan pàtó tá a lè tọ́ka sí pé òun ló gbéṣẹ́ jù láti tọ́jú àwọn àgbàlagbà. Síbẹ̀, tẹ́ ẹ bá fi ọgbọ́n wéwèé ohun tẹ́ ẹ máa ṣe, tẹ́ ẹ fi ọwọ́ sowọ́ pọ̀, tẹ́ ẹ fikùn lukùn, àti ní pàtàkì jù lọ, tẹ́ ẹ gbàdúrà, á ṣeé ṣe fún yín láti ṣe ojúṣe tẹ́ ẹ ní pé kẹ́ ẹ bọlá fún àwọn òbí yín. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, inú yín á dùn pé àwọn òbí yín ń rí ìtọ́jú àti àbójútó tí wọ́n nílò gbà. (Ka 1 Kọ́ríńtì 13:4-8.) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé ẹ máa ní àlàáfíà ọkàn tí Jèhófà fi máa ń jíǹkí àwọn tó bá bọlá fún àwọn òbí wọn.—Fílí. 4:7.

^ ìpínrọ̀ 3 Àṣà ìbílẹ̀ lè nípa lórí irú ìtọ́jú tí òbí fẹ́ tàbí ohun tí àwọn ọmọ máa lè ṣe. Ní àwọn ibì kan, ó wọ́pọ̀ pé kí àwọn ìdílé láti ìrandíran máa gbé pọ̀ tàbí kí wọ́n máa rí ara wọn déédéé. Ohun tí àwọn kan sì fẹ́ nìyẹn.

^ ìpínrọ̀ 11 Tí àwọn òbí yín bá ṣì ń dá gbé, ẹ rí i pé ẹ wá àwọn tó ṣeé fọkàn tán láti máa bójú tó wọn. Kẹ́ ẹ fún àwọn tó ń tọ́jú wọn ní kọ́kọ́rọ́ tí wọ́n fi lè ṣílẹ̀kùn bí ohun àìròtẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí àgbàlagbà náà.