Bàbá kan ní orílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Tá a bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé, ìjíròrò yẹn máa ń wọra débi pé tí mi ò bá dá a dúró, a máa ṣe é di òru ni.” Olórí ìdílé kan ní orílẹ̀-èdè Japan sọ pé: “Kò jọ pé ọmọkùnrin mi tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá máa ń wo ojú aago, lójú tiẹ̀ ká ṣáà máa ṣe é lọ ni.” Kí ló fà á? Bàbá rẹ̀ sọ pé: “Ìjíròrò náà ń mú ara rẹ̀ yá gágá, ó sì máa ń pa kún ayọ̀ rẹ̀.”

Ohun kan ni pé, kì í ṣe gbogbo ọmọ lara wọn máa ń yá gágá nígbà ìjọsìn ìdílé, àwọn ọmọ kan kì í tiẹ̀ gbádùn ìjọsìn ìdílé. Kí nìdí? Òdodo ọ̀rọ̀ tí bàbá kan ní orílẹ̀-èdè Tógò sọ rèé: “Kò yẹ kí ìjọsìn Jèhófà máa súni.” Bí ìjọsìn ìdílé bá ń sú àwọn ọmọ, ṣé kì í ṣe pé bí ẹni tó ń darí rẹ̀ ṣe ń ṣe é ló fà á? Aísáyà sọ pé Sábáàtì lè mú kéèyàn ní “inú dídùn kíkọyọyọ.” Ọ̀pọ̀ ìdílé ti rí i pé ìjọsìn ìdílé náà lè mú kí inú àwọn dùn.—Aísá. 58:13, 14.

Àwọn bàbá tó jẹ́ Kristẹni ti rí i pé bí ìjọsìn ìdílé bá máa gbádùn mọ́ àwọn tó wà nínú ìdílé, àfi kí àwọn ṣe é ní àsìkò tí ara bá tu olúkúlùkù. Arákùnrin Ralf tó ní ọmọbìnrin mẹ́ta àti ọmọkùnrin kan sọ pé ìjọsìn ìdílé tàwọn kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ ìbéèrè àti ìdáhùn. Ó ní ńṣe làwọn jọ máa ń jíròrò, tí kálukú sì máa ń sọ tinú ẹ̀. Ká sòótọ́, kì í sábà rọrùn láti darí ìjọsìn ìdílé lọ́nà tí àwọn tó wà nínú ìdílé á fi gbádùn rẹ̀ tí wọ́n á sì pọkàn pọ̀. Ìyá kan sọ pé: “Agbára mi kì í gbé e ní gbogbo ìgbà láti mú kí ìjọsìn ìdílé wa dùn mọ́ni tó bí mo ṣe fẹ́.” Ṣó o lè borí ìpèníjà yìí?

Ẹ MÁA ṢE É NÍ ONÍRÚURÚ Ọ̀NÀ

Bàbá ọlọ́mọ méjì kan ní orílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Ó di dandan ká máa ṣe é ní onírúurú ọ̀nà.” Ìyá ọlọ́mọ méjì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Natalia sọ pé: “Nínú ìdílé wa, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ká máa yí bá a ṣe ń ṣe é àti àkókò tá à ń ṣe é  pa dà.” Ńṣe ni ọ̀pọ̀ ìdílé pín ìjọsìn ìdílé wọn sí apá bíi mélòó kan. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Cleiton ní orílẹ̀-èdè Brazil, tí àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì ò tíì pé ogún ọdún. Ó sọ pé: “Bá a ṣe pín in sí apá bíi mélòó kan ló mú ká lè máa jíròrò oríṣiríṣi nǹkan kí gbogbo wa sì máa lóhùn sí i.” Tí àwọn òbí bá pín àkókò tí wọ́n fi ń ṣe ìjọsìn ìdílé, wọ́n á lè fiyè sí ohun tí ọmọ kọ̀ọ̀kan nílò tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọjọ́ orí wọ́n jìnnà síra. Èyí á mú kí àwọn òbí lè bójú tó àìní ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé, wọ́n á lè máa yan onírúurú kókó ẹ̀kọ́, wọ́n á sì lè máa jíròrò wọn lọ́nà tó yàtọ̀ síra.

Kí làwọn ìdílé kan tún máa ń ṣe ní tiwọn? Àwọn kan máa ń bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn ìdílé wọn nípa kíkọrin sí Jèhófà. Bàbá kan tó ń jẹ́ Juan lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ pé: “Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kí ara tu gbogbo wa, ká sì máa ronú nípa ohun tá a fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” Àwọn fúnra wọn ni wọ́n máa ń mú orín tó bá ohun tí wọ́n máa jíròrò ní ọjọ́ náà mu.

Orílẹ̀-èdè Sri Lanka

Àwọn ìdílé kan máa ń ka apá kan nínú Bíbélì pa pọ̀. Kí gbogbo wọ́n lè lóhùn sí i, olúkúlùkù wọn máa ń ka ọ̀rọ̀ ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú orí Bíbélì náà. Bàbá kan lórílẹ̀-èdè Japan sọ pé “kò kọ́kọ́ rọrùn láti máa ka Bíbélì lọ́nà yẹn.” Àmọ́, inú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì dùn pé àwọn àti àwọn òbí wọn jọ ń gbádùn rẹ̀. Àwọn ìdílé kan tiẹ̀ máa ń ṣe àṣefihàn àwọn ìtàn inú Bíbélì. Ní orílẹ̀-èdè South Africa, Arákùnrin Roger tó ní ọmọkùnrin méjì sọ pé àwọn ọmọ wa “sábà máa ń rí àwọn kókó tí àwa òbí ò rí nínú ìtàn Bíbélì tá a bá kà.”

Orílẹ̀-èdè South Africa

Ọ̀nà míì tẹ́ ẹ lè gbà ṣe ìjọsìn ìdílé ni pé kẹ́ ẹ jọ ṣe nǹkan pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè ṣe ohun tó jọ ọkọ̀ áàkì tí Nóà kàn tàbí tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́. Èyí lè gba pé kẹ́ ẹ ṣe àwọn ìwádìí tó máa mú yín láyọ̀. Àpẹẹrẹ kan ni ti ìdílé kan ní ilẹ̀ Éṣíà. Nínú pálọ̀ wọn, ọmọbìnrin ọlọ́dún márùn-ún kan, àwọn òbí rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà máa ń lo páálí tó ní àwòrán ilẹ̀, wọ́n á wá máa fa ìlà láti ṣàmì sí àwọn ibi tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ nínú ìrìn-àjò míṣọ́nnárì rẹ̀. Àwọn ìdílé míì máa ń lo irú páálí kan náà yìí, wọ́n á máa fa ìlà sí i láti fi ṣàmì sí àwọn ibi tí wọ́n dárúkọ bí wọ́n ṣe ń ka ìtàn tó wà nínú ìwé Ẹ́kísódù. Ní orílẹ̀-èdè Tógò, Arákùnrin Donald tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlógún sọ pé, bá a ṣe ń ṣe ìjọsìn ìdílé wa ní onírúurú ọ̀nà ti “sọ ìjọsìn ìdílé wa àti ìdílé wa alára dọ̀tun.” Ǹjẹ́ ìwọ náà lè ronú ohun kan tẹ́ ẹ lè jọ ṣe nínú ìdílé yín tó máa mú kí ìjọsìn ìdílé yín túbọ̀ gbádùn mọ́ni?

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

ÌMÚRASÍLẸ̀ ṢE PÀTÀKÌ

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọsìn ìdílé máa ń gbádùn mọ́ni téèyàn bá ń ṣe é ní onírúurú ọ̀nà, ó gba pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé múra sílẹ̀ kó tó lè kún fún ẹ̀kọ́. Torí pé nǹkan máa ń tètè sú àwọn ọmọdé nígbà míì, ó yẹ kí ẹ̀yin bàbá máa ronú ṣáájú nípa ohun tẹ́ ẹ máa jíròrò kẹ́ ẹ sì máa wá àyè láti múra sílẹ̀ dáadáa. Bàbá kan sọ pé, “Tí mo bá múra sílẹ̀, gbogbo wa pátá la máa ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.” Bàbá kan ní orílẹ̀-èdè Jámánì ti máa ń jẹ́ kí ìdílé rẹ̀ mọ ohun tí wọ́n máa jíròrò láwọn ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú. Ní orílẹ̀-èdè Benin, bàbá kan tí àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá ti máa ń ṣètò àwọn ìbéèrè tí wọ́n máa lò tó bá jẹ́ pé àwo DVD tó dá lórí Bíbélì ni wọ́n fẹ́ wò. Ká sòótọ́, bí ìjọsìn ìdílé bá máa gbéṣẹ́, ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn múra sílẹ̀.

Bí ìdílé bá ti mọ ohun tí wọ́n máa jíròrò ṣáájú, wọ́n á ti máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ìyẹn á sì jẹ́ kí wọ́n máa fojú sọ́nà fún un. Bí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá sì ní apá tó máa bójú tó, á mú kó rí i bí ìjọsìn ìdílé òun.

Ẹ SAPÁ LÁTI MÁA ṢE É DÉÉDÉÉ

Ọ̀pọ̀ ìdílé ló máa ń ṣòro fún láti máa ṣe ìjọsìn ìdílé wọn déédéé.

Ọ̀pọ̀ àwọn bàbá ni wọ́n ní láti ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí kí wọ́n tó lè gbọ́ bùkátà ìdílé wọn. Bí àpẹẹrẹ, aago mẹ́fà àárọ̀ ni bàbá kan ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ti máa ń jí kúrò nílé, ó sì di aago mẹ́jọ alẹ́ kó tó wọlé. Síwájú sí i, ìgbà míì lè wà tó máa gba pé kí wọ́n yí àkókò Ìjọsìn Ìdílé pa dà torí ìgbòkègbodò tẹ̀mí mìíràn.

Síbẹ̀, ó yẹ ká pinnu pé a máa sa gbogbo ipá wa ká lè máa ṣe ìjọsìn ìdílé wa déédéé. Ní orílẹ̀-èdè Tógò, ọmọbìnrin ọlọ́dún mọ́kànlá kan tó ń jẹ́ Loïs sọ pé ìdílé àwọn ti pinnu pé: “Bá a bá tiẹ̀ pẹ́ ká tó bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn ìdílé wa, a máa rí i pé a ṣe é.” Ó lè jẹ́ ìyẹn ló fà á tí àwọn ìdílé kan fi fi ìjọsìn ìdílé wọn sí apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀. Bí ohun àìròtẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, wọ́n á lè wá ọjọ́ míì láàárín ọ̀sẹ̀ láti fi ṣe é.

Orúkọ náà “ìjọsìn ìdílé” fi hàn pé ìṣètò yìí jẹ́ apá kan ìjọsìn rẹ sí Jèhófà. Ẹ jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé yín máa mú “ẹgbọrọ akọ màlúù ètè” rẹ̀ wá fún Jèhófà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (Hós. 14:2) Ǹjẹ́ kí àkókò ìjọsìn ìdílé jẹ́ àkókò aláyọ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé “nítorí ìdùnnú Jèhófà ni odi agbára yín.”—Neh. 8:9, 10.