Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Máa Fi Hàn Pé O Ní Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ

Máa Fi Hàn Pé O Ní Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ

“Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀.”—MÁT. 16:24.

1. Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ nípa béèyàn ṣe lè ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ?

NÍGBÀ tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ nípa béèyàn ṣe lè ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Ó yááfì àwọn nǹkan tó wù ú àti àwọn nǹkan tó dẹ̀ ẹ́ lọ́rùn kó bàa lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Jòh. 5:30) Ó tún jẹ́ olóòótọ́ dé ojú ikú lórí òpó igi oró. Nípa bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí òun ní kò láàlà.—Fílí. 2:8.

2. Báwo la ṣe lè ní irú ẹ̀mí tí Jésù ní yìí? Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?

2 Torí pé Jésù ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ, ó yẹ kí àwa tá a jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ náà ní irú ẹ̀mí yìí. Kí ló túmọ̀ sí láti ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ? Ní kúkúrú, ó túmọ̀ sí pé kéèyàn múra tán láti yááfì àwọn nǹkan tó wù ú torí àtiran àwọn míì lọ́wọ́. Èyí tó já sí pé ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ jẹ́ òdì kejì ìmọtara-ẹni-nìkan. (Ka Mátíù 16:24.) Tá a bá jẹ́ ẹni tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan, a ó máa ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tiwa. (Fílí. 2:3, 4) Jésù tiẹ̀ kọ́ wa pé ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ ẹni tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan nínú ìjọsìn wa. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìfẹ́ tí àwa Kristẹni ní wà lára ohun tó ń mú kéèyàn ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ, ìfẹ́ yìí la sì fi ń dá àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ̀. (Jòh. 13:34, 35) Ẹ sì wo bí ìbùkún tá à ń gbádùn ṣe pọ̀ tó torí pé ara ẹgbẹ́ ará kárí ayé tó ní irú ẹ̀mí tí Jésù ní yìí ni wá!

3. Kí ló lè mú ká máà ní irú ẹ̀mí tí Jésù ní yìí mọ́?

3 Síbẹ̀, ọ̀tá kan wà tó lè mú ká máà ní irú ẹ̀mí tí Jésù ní yìí  mọ́ láìfura. Ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tí wọ́n bí mọ́ wa ni ọ̀tá náà. Rántí pé Ádámù àti Éfà ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan. Ìmọtara-ẹni-nìkan yìí ló mú kí Éfà fẹ́ dà bí Ọlọ́run. Òun náà ló sì mú kí ọkọ rẹ̀ ṣe ohun tó wù ú. (Jẹ́n. 3:5, 6) Lẹ́yìn tí Èṣù mú kí Ádámù àti Éfà fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀ ló ti ń tan àwọn èèyàn kí wọ́n lè jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. Ó tiẹ̀ gbìyànjú láti sọ Jésù di onímọtara-ẹni-nìkan nígbà tó ń dẹ ẹ́ wò. (Mát. 4:1-9) Ní àkókò tá à ń gbé yìí, Sátánì ti ṣi èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn lọ́nà, ó ń mú kí wọ́n máa fi hàn lónírúurú ọ̀nà pé àwọn ní ẹmí ìmọtara-ẹni-nìkan. Ó yẹ ká kíyè sára gidigidi torí pé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tó gbayé kan lè sọ àwa náà di onímọtara-ẹni-nìkan.—Éfé. 2:2.

4. (a) Ṣé a lè mú ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan kúrò pátápátá ní báyìí? Ṣàlàyé. (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò?

4 A lè fi ìmọtara-ẹni-nìkan wé ìpẹtà tó máa ń mú kí irin dógùn-ún. Tí irin bá wà níbi tí òjò àti oòrùn ti lè pa á, ńṣe ló máa bẹ̀rẹ̀ sí í dógùn-ún. Èyí tó tún wá léwu jù ni pé kéèyàn fi ìpẹtà náà sílẹ̀ láìwa nǹkan ṣe sí i. Ńṣe ló máa bá irin náà jẹ́, kò sì ní wúlò mọ́. Bí ìmọtara-ẹni-nìkan àti àìpé tá a jogún náà ṣe rí nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè mú wọn kúrò ní báyìí, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé wọ́n léwu. Torí náà, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò, ká sì máa sá fún ohun tó bá máa mú ká di onímọtara-ẹni-nìkan. (1 Kọ́r. 9:26, 27) Báwo la ṣe lè mọ̀ tá a bá ti ń ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan? Báwo la sì ṣe lè túbọ̀ máa fi hàn pé a ní irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí Jésù ní?

FI BÍBÉLÌ YẸ ARA RẸ WÒ BÓYÁ O NÍ Ẹ̀MÍ ÌMỌTARA-ẸNI-NÌKAN

5. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe dà bíi dígí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Tá a bá ń yẹ ara wa wò bóyá a ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan, kí la gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún?

5 Bá a ṣe lè wo ara wa nínú dígí ká sì ṣàtúnṣe tó yẹ, bẹ́ẹ̀ náà la ṣe lè lo Bíbélì láti yẹ irú ẹni tá a jẹ́ ní inú wò ká sì tún ohun tá a bá rí pé ó kù díẹ̀ káàtó ṣe. (Ka Jákọ́bù 1:22-25.) Àmọ́ o, àyàfi tá a bá lo dígí lọ́nà tó tọ́ nìkan ló fi lè mú ká mọ bá a ṣe rí. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá kàn wo dígí fìrí, a lè ṣàì kíyè sí àbùkù tí kò tó nǹkan àmọ́ tó ṣe pàtàkì. Tó bá sì jẹ́ pé ẹ̀gbẹ́ kan la dúró sí tá a ti ń wo dígí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹlòmíì la máa rí. Bákan náà, tá a bá fẹ́ fi Bíbélì ṣe àwárí àléébù kan, irú bí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan, a ò wulẹ̀ ní kà á ní ṣákálá tàbí ká fi wá ìkùdíẹ̀-káàtó àwọn ẹlòmíì.

6. Báwo la ṣe lè ‘tẹpẹlẹ mọ́’ wíwo òfin pípé náà?

6 Bí àpẹẹrẹ, a lè máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, kódà lójoojúmọ́, ká má sì rí i pé a ti bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan. Báwo nìyẹn ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Wò ó báyìí ná: Nínú àpẹẹrẹ tí Jákọ́bù mú wá, kì í ṣe pé ọkùnrin náà kò fara balẹ̀ wo dígí náà. Ohun tí Jákọ́bù sọ ni pé ọkùnrin náà “wo ara rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Jákọ́bù lò níbí yìí túmọ̀ sí kéèyàn ṣe àyẹ̀wò fínnífínní tàbí kéèyàn fara balẹ̀ ṣe nǹkan. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí wá ni ìṣòro ọkùnrin náà? Jákọ́bù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé ọkùnrin náà “lọ, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbàgbé irú ènìyàn tí òun jẹ́.” Ó kúrò níwájú dígí náà lẹ́yìn tó wò ó tán, kò sì ṣe ohunkóhun nípa nǹkan tó kíyè sí. Ṣùgbọ́n, kì í wulẹ̀ ṣe pé ẹni tó mọ ohun tó ń ṣe “wo inú òfin pípé” nìkan ni, àmọ́ ó tún “tẹpẹlẹ mọ́ ọn.” Dípò tó fi máa fọwọ́ rọ́ òfin pípé tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sẹ́yìn, ńṣe ló tẹpẹlẹ mọ́ fífi ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ sílò. Jésù náà mẹ́nu ba kókó yìí nígbà tó sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́.”—Jòh. 8:31.

7. Báwo la ṣe lè fi Bíbélì yẹ ara wa wò bóyá a ti bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan?

7 Torí náà, tó ò bá fẹ́ máa hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan, ohun àkọ́kọ́ ni pé kó o máa fara balẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìyẹn á jẹ́ kó o lè mọ ibi tó o kù sí. Àmọ́ kò mọ síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kó o ṣèwádìí, kó o lè  túbọ̀ lóye. Tó o bá ti ní òye tó ṣe kedere nípa ìtàn kan tó o kà nínú Bíbélì, wo ara rẹ bí ẹni pé ìwọ ni ìtàn náà ṣẹlẹ̀ sí, kó o wá bi ara rẹ pé: ‘Kí ni ǹ bá ṣe ká ní èmi ni mo wà nírú ipò yìí? Ǹjẹ́ màá ṣe ohun tó tọ́?’ Ohun tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, lẹ́yìn tó o bá ti ṣe àṣàrò lórí ohun tó o kà, sapá láti fi ẹ̀kọ́ ibẹ̀ sílò. (Mát. 7:24, 25) Ẹ jẹ́ ká jíròrò bí ohun tí Bíbélì sọ nípa Sọ́ọ̀lù Ọba àti àpọ́sítélì Pétérù ṣe lè mú ká máa yááfì ohun tó wù wá ká lè máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run.

KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍNÚ OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ SỌ́Ọ̀LÙ ỌBA

8. Irú èèyàn wo ni Sọ́ọ̀lù nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jọba? Báwo la ṣe mọ̀?

8 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù, Ọba Ísírẹ́lì jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa nípa bí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ṣe lè mú kó ṣòro fún wa láti yááfì ohun tó wù wá. Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni Sọ́ọ̀lù nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jọba, ó sì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. (1 Sám. 9:21) Kò gbà kí wọ́n fìyà jẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ṣáátá rẹ̀ nígbà tó di ọba, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ronú pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti fìyà jẹ wọ́n kí òun lè dáàbò bo ipò tí Ọlọ́run gbé òun sí. (1 Sám. 10:27) Sọ́ọ̀lù Ọba gbà kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí òun láti ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jagun. Lẹ́yìn ogun náà kò gbé ara rẹ̀ ga, àmọ́ ó gbé ògo fún Jèhófà pé Òun ló jẹ́ kí àwọn ṣẹ́gun.—1 Sám. 11:6, 11-13.

9. Báwo ni Sọ́ọ̀lù ṣe fàyè gba ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan?

9 Nígbà tó yá, Sọ́ọ̀lù fàyè gba ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìgbéraga èyí tá a lè fi wé ìpẹtà tó ń jẹ́ kí irin dógùn-ún. Nígbà tó ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámálékì lójú ogun, ó ṣe ohun tó wù ú dípò kó pa àṣẹ Jèhófà mọ́. Sọ́ọ̀lù fi ìwọra kó ẹrù tó rí lójú ogun dípò tí ì bá fi pa wọn run gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ fún un. Yàtọ̀ síyẹn, ìgbéraga tún mú kí Sọ́ọ̀lù gbé ohun kan nàró tí àwọn èèyàn á fi máa rántí rẹ̀. (1 Sám. 15:3, 9, 12) Nígbà tí wòlíì Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé inú Jèhófà ò dùn sí ohun tó ṣe, ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í dá ara rẹ̀ láre pé ohun ṣáà ti lọ jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán òun, ó wá di ẹ̀bi àṣìṣe rẹ̀ ru àwọn míì. (1 Sám. 15:16-21) Ìgbéraga tún mú kí Sọ́ọ̀lù fẹ́ láti gbayì lójú àwọn èèyàn dípò kó wá bó ṣe máa rí ojú rere Ọlọ́run. (1 Sám. 15:30) Báwo la ṣe lè lo ìtàn Sọ́ọ̀lù yìí bíi dígí ká má bàa máa ṣe tinú wa?

10, 11. (a) Tó bá di pé ká máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run, kí la rí kọ́ látinú ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe? (b) Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa hùwà tí kò dára bíi ti Sọ́ọ̀lù?

10 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìrírí Sọ́ọ̀lù yìí jẹ́ ká rí i pé a kò gbọ́dọ̀ jọ ara wa lójú, ká máa rò pé ọjọ́ pẹ́ tá a ti máa ń ṣe ohun tó wu Ọlọ́run, báá sì ṣe máa rí lọ náà nìyẹn. (1 Tím. 4:10) Ẹ rántí pé ní àwọn àkókò díẹ̀ tí Sọ́ọ̀lù fi ṣe dáadáa ó rí ojú rere Ọlọ́run, àmọ́ dípò tí ì bá fi sá fún ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ńṣe ló fàyè gbà á. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín Jèhófà kọ Sọ́ọ̀lù sílẹ̀ torí pé ó ṣàìgbọràn.

11 Ẹ̀kọ́ kejì ni pé ká ṣọ́ra kó má di pé ibi tá a dára sí nìkan là ń gbájú mọ́, tá a sì ń gbójú fo àwọn ibi tá a kù sí. Ńṣe ló máa dà bí ìgbà tá à ń yẹ aṣọ tuntun tá a wọ̀ wò nínú dígí àmọ́ tá ò kíyè sí ìdọ̀tí kékeré tó wà lójú wa. Tá ò bá tiẹ̀ tíì jọra wa lójú bíi ti Sọ́ọ̀lù, ó pọn dandan pé ká sapá gidigidi ká lè sá fún ohunkóhun tó bá máa mú ká ṣe ohun tí kò dára bíi tiẹ̀. Tí wọ́n bá gbà wá nímọ̀ràn, ẹ jẹ́ ká kíyè sára ká má ṣe máa dá ara wa láre, ká wá máa sọ pé ohun tá a ṣe náà kò fi bẹ́ẹ̀ burú, tàbí ká máa dá àwọn míì lẹ́bi àṣìṣe wa. Dípò tá a fi máa ṣe bíi ti Sọ́ọ̀lù, ohun tó dára jù ni pé ká gba ìbáwí.—Ka Sáàmù 141:5.

12. Tá a bá fẹ́ máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run, kí la máa ṣe tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì?

12 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé a dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ńkọ́? Sọ́ọ̀lù fẹ́ kóun gbayì lójú àwọn èèyàn náà, ìyẹn ni kò jẹ́ kó ṣe ohun táá mú kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà pa dà gún régé. Àmọ́  tó bá jẹ́ pé ohun tó wu Ọlọ́run la fẹ́ ṣe, a ó pa ìtìjú tì ká lè rí ìrànlọ́wọ́ tó yẹ gbà. (Òwe 28:13; Ják. 5:14-16) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí arákùnrin kan ti wà ní ọmọ ọdún méjìlá [12] ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwòrán oníhòòhò, ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́wàá, láìjẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀. Ó sọ pé: “Ó nira fún mi gan-an láti sọ ohun tí mò ń ṣe fún ìyàwó mi àtàwọn alàgbà. Àmọ́ ní báyìí tí mo ti sọ, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ti gbé ẹrù wíwúwo kúrò lórí mi. Ó dun àwọn ọ̀rẹ́ mi kan nígbà tí wọ́n gbọ́ pé mi kì í ṣe ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ mọ́, ó ṣe wọ́n bíi pé mo já wọn kulẹ̀. Àmọ́, ó dá mi lójú pé inú Jèhófà dùn sí iṣẹ́ ìsìn tí mò ń ṣe báyìí ju ti ìgbà tí mò ń wo àwòrán oníhòòhò. Ní tèmi, ojú tí Jèhófà fi ń wò mí ni mo gbà pé ó ṣe pàtàkì jù.”

PÉTÉRÙ BORÍ Ẹ̀MÍ ÌMỌTARA-ẸNI-NÌKAN

13, 14. Kí ni Pétérù ṣe tó fi hàn pé ó ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan?

13 Nígbà tí Jésù ń dá àpọ́sítélì Pétérù lẹ́kọ̀ọ́, Pétérù fi hàn pé òun ṣe tán láti yááfì ohun tó wu òun kí òun bàa lè ṣe ohun tó wu Ọlọ́run. (Lúùkù 5:3-11) Síbẹ̀, ó ní láti sapá láti mú ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan kúrò. Bí àpẹẹrẹ, inú bí Pétérù nígbà tí àpọ́sítélì Jákọ́bù àti Jòhánù ń wá bí wọ́n ṣe máa wà ní ipò ọlá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì Jésù nínú Ìjọba Ọlọ́run. Bóyá Pétérù rò pé òun ni ọ̀kan lára ipò yẹn tọ́ sí torí Jésù ti sọ pé òun máa fún un ní ojúṣe àrà ọ̀tọ̀. (Mát. 16:18, 19) Bó ti wù kó rí, Jésù kìlọ̀ fún Jákọ́bù, Jòhánù àti Pétérù alára, títí kan àwọn àpọ́sítélì tó kù pé kí wọ́n ṣọ́ra fún ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tó lè mú kí wọ́n fẹ́ láti “jẹ olúwa lé” àwọn arákùnrin wọn lórí.—Máàkù 10:35-45.

14 Kódà lẹ́yìn tí Jésù ti tún ojú ìwòye Pétérù ṣe, Pétérù ṣì ń sapá kó lè máa fi ojú tó tọ́ wo ara rẹ̀. Nígbà tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì pé wọ́n máa fi òun sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, Pétérù bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn yòókù pé bí wọ́n bá tiẹ̀ pa Jésù tì, òun máa dúró tì í ní tòun. (Mát. 26:31-33) Kò sí ìdí fún Pétérù láti dára ẹ̀ lójú jù, torí pé lálẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an ló ṣe ohun tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sẹ́ Jésù, torí kó lè dáàbò bo ara rẹ̀.—Mát. 26:69-75.

15. Tá a bá wo ìgbésí ayé Pétérù látòkèdélẹ̀, kí nìdí tí àpẹẹrẹ rẹ̀ fi wúni lórí?

 15 Láìka bí Pétérù ṣe ń tiraka àti bó ṣe ń kùnà sí, ó ṣì jẹ́ àpẹẹrẹ tó wúni lórí. Lọ́lá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run àti ìsapá Pétérù alára, ó borí kùdìẹ̀-kudiẹ rẹ̀, ó sì wá ní ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìfẹ́ tó ń mú kó ṣe ohun tó wu Ọlọ́run. (Gál. 5:22, 23) Ó fara da àwọn àdánwò tá a lè sọ pé ó nira ju àwọn àdánwò tó mú kó ṣàṣìṣe nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Bó ṣe fara mọ́ ìbáwí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún un ní gbangba fi hàn pé ó ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. (Gál. 2:11-14) Kò di Pọ́ọ̀lù sínú lẹ́yìn ìgbà yẹn, kó wá máa bínú pé ńṣe ló wọ́ òun nílẹ̀. Pétérù ń bá a nìṣó láti máa nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù. (2 Pét. 3:15) Àpẹẹrẹ Pétérù lè mú kí àwa náà máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run.

Kí ni Pétérù ṣe lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù bá a wí? Ṣé ohun tí àwa náà máa ṣe nìyẹn? (Wo ìpínrọ̀ 15)

16. Tá a bá wà nínú ìṣòro, báwo la ṣe lè máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run?

16 Ronú nípa ohun tó o máa ṣe tó o bá wà nínú ìṣòro. Nígbà tí wọ́n fi Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì sẹ́wọ̀n tí wọ́n sì nà wọ́n torí pé wọ́n ń wàásù, ńṣe ni wọ́n ń yọ̀ “nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ [Jésù].” (Ìṣe 5:41) Ìwọ náà lè wò ó pé inúnibíni á fún ẹ ní àǹfààní láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pétérù kó o sì máa tọ ipasẹ̀ Jésù nípa ṣíṣe ohun tó wu Ọlọ́run. (Ka 1 Pétérù 2:20, 21.) Tó o bá ń ronú lọ́nà yìí, á mú kó o lè ṣàtúnṣe tó yẹ tí àwọn alàgbà bá bá ẹ wí. Bí Pétérù ti ṣe ni kí ìwọ náà ṣe, dípò tí wàá fi gba ọ̀rọ̀ náà sí ìbínú.—Oníw. 7:9.

17, 18. (a) Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa tá a bá ní àwọn àfojúsùn tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run? (b) Kí la lè ṣe tá a bá kíyè sí i pé a ti fẹ́ máa ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan?

17 Àpẹẹrẹ Pétérù tún lè ṣe ẹ́ láǹfààní tó bá kan ohun tó o fi ṣe àfojúsùn rẹ. O lè máa fojú sun ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run lọ́nà tó fi hàn pé ohun tó wu Ọlọ́run lo fẹ́ máa ṣe. Àmọ́ ṣọ́ra o, kó má di pé torí kó o lè wà nípò ọlá lo ṣe ní irú àfojúsùn bẹ́ẹ̀. Torí náà, bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ kì í ṣe torí kí n lè gbayì lójú àwọn èèyàn tàbí kí n lè wà nípò àṣẹ ni mo ṣe ń wá ọ̀nà láti sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Ó jọ pé ohun tí Jákọ́bù àti Jòhánù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tí wọ́n ní kí Jésù jẹ́ kí àwọn jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì rẹ̀.’

18 Tó o bá kíyè sí i pé ó dà bíi pé o ti fẹ́ máa ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè yí èrò rẹ àti ojú tó o fi ń wo nǹkan pa dà; lẹ́yìn náà kó o wá sapá gan-an láti máa wá ògo Ọlọ́run dípò ògo tìrẹ. (Sm. 86:11) O tiẹ̀ lè máa fi àwọn nǹkan tí kò ní mú kó o máa pe àfiyèsí síra rẹ ṣe àfojúsùn rẹ. Bí àpẹẹrẹ, o lè wá bí wàá ṣe túbọ̀ ní àwọn kan lára èso tẹ̀mí, bóyá àwọn tó ṣòro fún ẹ láti fi sílò. Ó ṣeé ṣe kó o máa múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ dáadáa àmọ́ kó má fi bẹ́ẹ̀ wù ẹ́ pé kó o máa lọ́wọ́ nínú títọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba, o lè fi ṣe àfojúsùn rẹ pé wàá fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Róòmù 12:16 sílò.—Kà á.

19. Kí la lè ṣe tí ohun tá a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó dà bíi dígí kò fi ní mú ká rẹ̀wẹ̀sì?

19 Tá a bá fara balẹ̀ wo ara wa nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó dà bíi dígí, tá a sì rí àléébù, tàbí tá a kíyè sí i pé a ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan, ìyẹn lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Bó bá ṣe ẹ́ bíi pé kó o rẹ̀wẹ̀sì, ronú nípa ọkùnrin tí Jákọ́bù lò nínú àkàwé rẹ̀. Kì í ṣe bí ọkùnrin yẹn ṣe tètè bójú tó ìṣòro tó rí ni Jákọ́bù tẹnu mọ́, kò sì sọ pé gbogbo àbùkù tó rí ló yanjú pátápátá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Jákọ́bù sọ ni pé ọkùnrin náà ‘tẹpẹlẹ mọ́ òfin pípé náà.’ (Ják. 1:25) Ó rántí ohun tó rí nínú dígí, ó sì ń ṣiṣẹ́ lé e lórí kó lè sunwọ̀n sí i. Torí náà, má ṣe ro ara rẹ pin, kó o sì máa fi í sọ́kàn pé aláìpé lo ṣì jẹ́. (Ka Oníwàásù 7:20.) Tẹra mọ́ wíwo òfin pípé náà, kó o sì máa fi hàn pé o ní irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí Jésù ní. Jèhófà ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, bó ṣe ran àìmọye àwọn arákùnrin rẹ lọ́wọ́. Aláìpé ni àwọn náà, àmọ́ wọ́n lè rí ojú rere àti ìbùkún Ọlọ́run. Òótọ́ ibẹ̀ tiẹ̀ ni pé, wọ́n ń rí ojúure Ọlọ́run àti ìbùkún rẹ̀.