Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) March 2014

Nínú ìwé yìí, kọ́ bó o ṣe lè máa fi hàn pé o ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ àti bó o ṣe lè máa fojú tó tọ́ wo nǹkan. Báwo la ṣe lè máa bójú tó àwọn àgbàlagbà?

Bá A Ṣe Lè Mú Kí Ìbátan Wa Tí Kì í Ṣe Ẹlẹ́rìí Nífẹ̀ẹ́ Òtítọ́

Kí ni bí Jésù ṣe bá àwọn ìbátan lò kọ́ wa? Bá a ṣe lè sọ ohun tá a gbà gbọ́ fún ìbátan wa tí ìsìn rẹ̀ yàtọ̀, tàbí tí kò ní ẹ̀sìn kankan

Máa Fi Hàn Pé O Ní Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ

Ọ̀tá ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́ kan wà tó lè mú ká dẹni tí kò ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ mọ́. Àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ ká mọ ọ̀tá náà, àá mọ báa ṣe lè fi Bíbélì kojú rẹ̀.

Bó O Ṣe Lè Máa Fi Ojú Tó Tọ́ Wo Nǹkan

Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi máa ń ní èrò òdì? Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí bá a ṣe lè lo Bíbélì ká lè máa fi ojú tó tọ́ wo ara wa.

Ìjọsìn Ìdílé—Ǹjẹ́ O Lè Mú Kó Túbọ̀ Gbádùn Mọ́ni?

Wo ọ̀nà táwọn kan ń gba ṣe ìjọsìn ìdílé wọn ní onírúurú orílẹ̀-èdè, kó o lè mọ ọ̀nà tó dára láti gbà ṣe é.

Ẹ Máa Bọlá fún Àwọn Àgbàlagbà Tó Wà Láàárín Yín

Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn àgbàlagbà? Kí lojúṣe àwọn ọmọ tó ti dàgbà sáwọn òbí wọn àgbà? Báwo làwọn ará ṣe lè máa bọlá fáwọn àgbàlagbà?

Bá A Ṣe Lè Máa Tọ́jú Àwọn Àgbàlagbà

Àwọn òbí àgbà àtàwọn ọmọ tó ti dàgbà lè ṣèpinnu kí wọ́n sì múra sílẹ̀ de “àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù.” Báwo ni wọ́n ṣe lè yanjú ìṣòro tó bá yọjú?

Ǹjẹ́—“Bẹ́ẹ̀ Ni” Rẹ Kì Í Di “Bẹ́ẹ̀ Kọ́”?

Ó yẹ kí Kristẹni ṣeé gbára lé, kí bẹ́ẹ̀ ni rẹ̀ má máa dí bẹ́ẹ̀ kọ́. Tá a bá ní láti wọ́gi lé àdéhùn tá a ṣe ńkọ́? Kẹ́kọ̀ọ́ lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.