“Èyí kọjá fọ́tò Arákùnrin Russell, Arákùnrin Russell gangan nìyí!”—Ẹnì kan tó wo sinimá “Photo-Drama” lọ́dún 1914 ló sọ̀rọ̀ yìí.

ỌDÚN yìí ló pé ọgọ́rùn-ún ọdún tá a kọ́kọ́ gbé sinimá “Photo-Drama of Creation” jáde, ìyẹn àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá. Ní àkókò tí sinimá náà jáde sí, ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ti dòkú torí pé wọ́n gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́, wọ́n ń ṣe lámèyítọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń ṣiyè méjì. Ṣùgbọ́n torí káwọn èèyàn lè gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì la ṣe gbé sinimá gígùn náà jáde. Ó tún jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá.

Ìgbà gbogbo ni Arákùnrin Charles T. Russell tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn máa ń wá ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tó sì yára jù lọ láti mú òtítọ́ Bíbélì dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn. Kó tó dìgbà yẹn, ó ti lé ní ọgbọ̀n [30] ọdún táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń tẹ àwọn ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, wọ́n wá rí i pé ohun míì táwọn lè ṣe ni pé káwọn máa lo sinimá tó ń gbé ohùn jáde.

WỌ́N FI SINIMÁ TÓ Ń GBÉ OHÙN JÁDE WÀÁSÙ ÌHÌN RERE

Láàárín ọdún 1890 sí 1899 ni aráyé ti bẹ̀rẹ̀ sí í wo sinimá tí kì í gbé ohùn jáde. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1903, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kan fi sinimá kan tó dá lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn hàn ní ìlú New York City. Nípa bẹ́ẹ̀, a lè sọ pé ilé iṣẹ́ sinimá tó ń gbé ohùn jáde ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni lọ́dún 1912 nígbà tí Arákùnrin Russell bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá náà. Ó rí i pé sinimá yìí á lè ṣàlàyé òtítọ́ Bíbélì lọ́nà tó yàtọ̀ sí ti ìwé.

Wákàtí mẹ́jọ ló máa ń gbà kéèyàn tó wo sinimá yẹn tán, torí bẹ́ẹ̀, wọ́n sábà máa ń pín in sí apá mẹ́rin. Àwọn àlàyé Bíbélì tó ṣe ṣókí mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún [96] ni wọ́n ṣe sínú rẹ̀. Ìlúmọ̀ọ́ká sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan táwọn èèyàn mọ ohùn rẹ̀ dáadáa nígbà yẹn ló ka àwọn àlàyé náà sínú ẹ̀rọ. Ọ̀pọ̀ lára àwọn àwòrán náà ni wọ́n kọ orin tó lòde sí. Bí wọ́n ṣe ń fi àwọn fọ́tò aláwọ̀ mèremère àtàwọn ìtàn Bíbélì táwọn èèyàn mọ̀ dunjú hàn nínú sinimá náà ni àwọn ọ̀jáfáfá nídìí iṣẹ́ ẹ̀rọ ń fi giramafóònù gbé ohùn àti orin tó ń lọ lábẹ́lẹ̀ sí i.

“Àwòrán bí nǹkan ṣe rí látìgbà tí Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn ìràwọ̀ títí di ìparí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi ló wà nínú rẹ̀.”—F. Stuart Barnes, tó jẹ́ ọmọ ọdún 14 lọ́dún 1914

Ọwọ́ àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe fíìmù la ti ra ọ̀pọ̀ jù lọ lára fíìmù àtàwọn gíláàsì tá a lò fún àwòrán ara ògiri. Àwọn tó ń fi àwòrán àfọwọ́yà ṣiṣẹ́ ṣe ní ìlú Filadẹ́fíà, New York, Paris àti London wá fi ọwọ́ ya àwòrán sórí fíìmù àtàwọn gíláàsì tá a lò fún àwòrán ara ògiri náà níkọ̀ọ̀kan.  Yàtọ̀ síyẹn, àwùjọ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Àwòrán Yíyà ní Bẹ́tẹ́lì náà ṣe púpọ̀ lára iṣẹ́ náà, wọ́n ya àwọn àwòrán míì rọ́pò àwọn fọ́tò tó ti bà jẹ́. Yàtọ̀ sí àwọn fíìmù tí wọ́n rà, wọ́n tún mú kí àwọn kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì lọ sí ìlú Yonkers tó wà nítòsí ìlú New York. Wọ́n á ní kí wọ́n ṣe Ábúráhámù, Ísákì tàbí áńgẹ́lì tí kò jẹ́ kí Ábúráhámù fi ọmọ rẹ̀ rúbọ, kí wọ́n lè gba ohùn wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì ya àwòrán wọn.—Jẹ́n. 22:9-12.

Àwọn amojú ẹ̀rọ ṣe nǹkan lọ́nà tó ṣe wẹ́kú. Àwòrán àti ohùn jáde lákòókò kan náà. Síbẹ̀, gígùn fíìmù náà ju kìlómítà mẹ́ta lọ, àwo giramafóònù jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] tí àwòrán ara gíláàsì tá à ń fi hàn lára ògiri sì tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500]

Ẹnì kan tó bá Arákùnrin Russell ṣiṣẹ́ sọ fún àwọn oníwèé ìròyìn pé “kò sí ohun táwọn èèyàn tíì ṣe láti tan ẹ̀sìn kálẹ̀ tó máa mú kí àìmọye èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí Ìwé Mímọ́ bíi ti fíìmù yìí.” Ǹjẹ́ inú àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì dùn sí ọ̀nà tuntun táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń gbà mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn tí ebi tẹ̀mí ń pa yìí? Rárá o! Ńṣe ni àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì bu ẹnu àtẹ́ lu sinimá náà, àwọn kan tiẹ̀ lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tàbí ìwà ọ̀dájú káwọn èèyàn má bàa wò ó. Níbì kan tí wọ́n ti fẹ́ fi sinimá náà hàn, ẹgbẹ́ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì rí sí i pé wọn ò rí iná mànàmáná lò.

Ìjọ àdúgbò làwọn arábìnrin yìí ti wá, àwọn ló sì ń mú èrò lọ jókòó. Wọ́n fún àwọn èèyàn ni àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ ìwé pẹlẹbẹ tí wọ́n ya àwòrán inú sinimá “Photo-Drama” sí

Àwọn òǹwòran tún gba pín-ìnnì “Pax,” tí wọ́n ya àwòrán ìgbà tí Jésù wà ní kékeré sí. Pín-ìnnì náà máa ń rán ẹni tó bá lò ó létí pé kí ó jẹ́ “ọmọ àlàáfíà”

Síbẹ̀, ńṣe làwọn èèyàn máa ń kún gbọ̀ngàn ìṣeré ní àkúnya kí wọ́n lè wo sinimá náà lọ́fẹ̀ẹ́. Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó tó ọgọ́rin [80] ìlú tí wọ́n ti máa ń fi sinimá náà han àwọn èèyàn lójoojúmọ́. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí ọ̀pọ̀ lára wọn máa rí sinimá tó ń gbé ohùn jáde, ó sì yà wọ́n lẹ́nu. Torí pé wọ́n lo ọgbọ́n fọ́tò yíyà tó ń mú kí ohun tó gba àkókò gígùn yára kánkán, àwọn èèyàn náà rí bí òròmọdìyẹ ṣe jáde látinú ẹyin àti bí òdòdó ṣe yọ ìtànná lọ́nà tó fani mọ́ra. Apá tó dá lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nínú sinimá náà mú káwọn èèyàn rí i pé àgbàyanu ni ọgbọ́n Jèhófà. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, nígbà tí Arákùnrin Russell fara hàn nínú sinimá náà tó sì bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọ̀kan lára àwọn tó ń wòran sọ pé “èyí kọjá fọ́tò Arákùnrin Russell, Arákùnrin Russell gangan nìyí!”

OHUN PÀTÀKÌ LÈYÍ NÍNÚ IṢẸ́ ÌKỌ́NILẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ

Ní January 11, ọdún 1914 ni wọ́n kọ́kọ́ fi sinimá “Photo Drama” tó sọ nípa ìṣẹ̀dá han àwọn èèyàn ní gbọ̀ngàn ìṣeré tó rẹwà yìí ní ìlú New York City. Àwọn International Bible Students Association (I.B.S.A) ló ni gbọ̀ngàn yẹn, àwọn òṣìṣẹ́ wọn ló sì ń gbébẹ̀

Ọ̀gbẹ́ni Tim Dirks tó jẹ́ òǹkọ̀wé àti òpìtàn nípa sinimá sọ pé àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá ni “eré orí ìtàgé àkọ́kọ́ tó jẹ́ àpapọ̀ sinimá tó ń gbóhùn jáde tó sì tún ní àwòrán ara ògiri aláwọ̀ mèremère.” Àwọn èèyàn kan ti gbé sinimá jáde lọ́nà yìí rí kó tó di pé àwa ṣe sinimá “Photo-Drama,” àmọ́ kò sẹ́ni tó tíì lò ó bá a ṣe lò ó yẹn, kí gbogbo rẹ̀ máa jáde lápapọ̀, pàápàá tó bá kan sinimá tó dá lórí Bíbélì. Kò sì sí sinimá náà tí èrò pé jọ tó bẹ́ẹ̀ láti wò bíi sinimá yìí. Torí pé ó tó mílíọ̀nù mẹ́sàn-án èèyàn tó wò ó ní Amẹ́ríkà ti Àríwá, Yúróòpù, Ọsirélíà àti New Zealand, ní ọdún tá a kọ́kọ́ gbé e jáde!

Ní January 11, ọdún 1914 ni wọ́n kọ́kọ́ fi sinimá tó sọ nípa ìṣẹ̀dá yìí han àwọn èèyàn ní ìlú New York City. Ní oṣù méje lẹ́yìn náà ni àjálù kan ṣẹlẹ̀ tí wọ́n wá pè ní Ogun Àgbáyé Kìíní. Síbẹ̀ ńṣe ni ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn kárí ayé ń kóra jọ pọ̀ ṣáá kí wọ́n lè wo sinimá náà, torí pé ó ń tù wọ́n nínú bí wọ́n ṣe ń rí àwọn àwòrán tí wọ́n sì ń gbọ́ àlàyé nípa ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá. Tá a bá fi ojú pé ọdún 1914 ni wọ́n gbé irú sinimá bẹ́ẹ̀ jáde wò ó, ohun àgbàyanu ni lóòótọ́.

Gbogbo àpótí ohun èlò sinimá “Photo-Drama” tí àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lò jákèjádò Amẹ́ríkà ti Àríwá jẹ́ ogún