Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  February 2014

“Máa Rí Adùn Jèhófà”

“Máa Rí Adùn Jèhófà”

Àwọn ipò tó ń fa ìrora ọkàn lè bà wá lọ́kàn jẹ́ gidigidi. Wọ́n lè mú ká máa ro àròkàn, kí wọ́n tán wa lókun, kí wọ́n sì mú ká máa ro èrò òdì nípa ìgbésí ayé. Ọ̀pọ̀ ìnira ló dé bá Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì. Báwo ló ṣe kojú àwọn ìnira náà? Nínú sáàmù kan tó wọni lọ́kàn, Dáfídì dáhùn pé: “Jèhófà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí fi ohùn mi ké pè fún ìrànlọ́wọ́; Jèhófà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí fi ohùn mi ké bá fún ojú rere. Mo ń bá a nìṣó ní títú ìdàníyàn mi jáde níwájú rẹ̀; mo ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ nípa wàhálà mi níwájú rẹ̀. Nígbà tí àárẹ̀ mú ẹ̀mí mi nínú mi. Nígbà náà, ìwọ alára mọ òpópónà mi.” Dáfídì fìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́.—Sm. 142:1-3.

Nígbà ìṣòro, Dáfídì gbàdúrà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́

Nínú sáàmù míì tí Dáfídì kọ, ó sọ pé: “Ohun kan ni mo béèrè lọ́wọ́ Jèhófà—ìyẹn ni èmi yóò máa wá, kí n lè máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, kí n lè máa rí adùn Jèhófà. Kí n sì lè máa fi ẹ̀mí ìmọrírì wo tẹ́ńpìlì rẹ̀.” (Sm. 27:4) Dáfídì kì í ṣe ọmọ Léfì, àmọ́ fojú inú wò ó pé ó dúró níwájú àgbàlá mímọ́ nítòsí ibi tó jẹ́ ojúkò ìjọsìn tòótọ́. Ohun tí Dáfídì rí wú u lórí débi pé ó fẹ́ lo ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ níbẹ̀ kó sì tipa bẹ́ẹ̀ máa “rí adùn Jèhófà.”

Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “adùn” ní í ṣe pẹ̀lú kéèyàn wà ní ipò kan tó fi hàn pé nǹkan “tẹ́ ẹ lọ́rùn tàbí pé ó dùn mọ́ ọn.” Gbogbo ìgbà tí Dáfídì bá ń ronú lórí ètò tí Ọlọrun ṣe fún ìjọsìn ló máa ń mọrírì rẹ̀ gan-an. Àwa náà lè bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ èmi náà máa ń mọrírì ìjọsìn Jèhófà bíi ti Dáfídì?’

MÁA FI HÀN PÉ O MỌRÍRÌ ÈTÒ TÍ ỌLỌ́RUN ṢE

Lóde òní, ètò tí Jèhófà ṣe ká lè máa jọ́sìn rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ilé tá a fọwọ́ kọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wé mọ́ tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Ọlọ́run, ìyẹn ètò mímọ́ tí Ọlọ́run ṣe fún ìjọsìn tòótọ́. * Tá a bá ń fi hàn pé a mọrírì ètò tí Ọlọ́run ṣe yìí, àwa pẹ̀lú á lè “máa rí adùn Jèhófà.”

Ronú nípa pẹpẹ bàbà ti ọrẹ ẹbọ sísun tó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn. (Ẹ́kís. 38:1, 2; 40:6) Pẹpẹ náà ṣàpẹẹrẹ bí Ọlọ́run ṣe múra tán láti tẹ́wọ́ gba ẹbọ tí Jésù fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn rú. (Héb. 10:5-10) Ẹ sì wo ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí fún wa! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà tí àwa jẹ́ ọ̀tá, a mú wa padà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ ikú Ọmọ rẹ̀.” (Róòmù 5:10) Tá a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ tí Jésù ta sílẹ̀, Ọlọ́run máa fojúure wò wá, á sì fọkàn tán wa torí pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. A óò wá tipa bẹ́ẹ̀ ní “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.”—Sm. 25:14.

Torí pé Jèhófà ti ‘pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́, a ní àwọn àsìkò títunilára láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.’ (Ìṣe 3:19) Ńṣe lọ̀rọ̀ wa dà bíi ti ẹlẹ́wọ̀n kan tó kábàámọ̀ àwọn ìwà tó ti hù sẹ́yìn tó wá ṣe ìyípadà kánmọ́kánmọ́ bó ṣe ń dúró de ìgbà tí wọ́n máa pa á. Nígbà tí adájọ́ kan tó jẹ́ aláàánú rí ìyípadà tó ṣe yìí, ó bá fagi lé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti ṣẹ̀, ó sì wọ́gi lé ẹjọ́ ikú tí wọ́n dá fún un. Ẹ wo bí ara ṣe máa tu ẹlẹ́wọ̀n yẹn tó tí ìdùnnú á sì ṣubú láyọ̀ fún un! Bíi ti adájọ́ yẹn, Jèhófà ń fi ojúure hàn sí àwọn èèyàn tó bá ronú pìwà dà ó sì ń dá wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú.

JẸ́ KÍ ÌJỌSÌN TÒÓTỌ́ MÁA MÚNÚ RẸ DÙN

Àwọn ohun kan wà tí Dáfídì lè kíyè sí pé wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn tòótọ́ nílé Jèhófà. Lára wọn ni ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tiẹ̀ tí wọ́n pé jọ síbẹ̀, bí àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì ṣe ń kàwé  ní gbangba àti bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé Òfin, bí wọ́n ṣe ń sun tùràrí àti bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́. (Ẹ́kís. 30:34-38; Núm. 3:5-8; Diu. 31:9-12) Àwọn apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ìjọsìn tòótọ́ pín sí ní Ísírẹ́lì ìgbàanì yìí ní àfijọ lóde òní.

Ó dára nígbà àtijọ́ pé “kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan,” bẹ́ẹ̀ náà ló sì rí lóde òní. (Sm. 133:1) Iye àwa tá a wà nínú “ẹgbẹ́ àwọn ará” wa kárí ayé ti pọ̀ sí i lọ́nà tó gadabú. (1 Pét. 2:17) À ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní gbangba láwọn ìpàdé wa, a sì ń ṣàlàyé rẹ̀. Jèhófà ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ fún wa ní ìtọ́ni tó ń ṣeni láǹfààní ní àwọn ìpàdé wa. A tún ń rí ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí gbà nípasẹ̀ àwọn ìwé tí wọ́n tẹ̀ ká lè máa lò wọ́n nígbà ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ pé: “Bí mo ṣe máa ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Jèhófà, tí mò ń ronú lórí ohun tó túmọ̀ sí, tí mo sì ń sapá kí n lè ní òye àti ìjìnlẹ̀ òye, ó máa ń mú kí ojúmọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan kún fún àwọn ohun dídọ́ṣọ̀ nípa tẹ̀mí, mo sì tún ní ìtẹ́lọ́rùn.” Dájúdájú, ‘ìmọ̀ lè dùn mọ́ ọkàn wa.’—Òwe 2:10.

Lóde òní, ojoojúmọ́ ni àdúrà tó ṣètẹ́wọ́gbà táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń gbà ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Jèhófà. Jèhófà ka irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ sí tùràrí olóòórùn dídùn tó ń ta sánsán. (Sm. 141:2) Ẹ sì wo bí inú wa ṣe dùn tó pé inú Jèhófà Ọlọ́run máa ń dùn sí wa gan-an tá a bá gbàdúrà sí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀!

Mósè gbàdúrà pé: “Kí adùn Jèhófà Ọlọ́run wa sì wà lára wa, kí o sì fìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.” (Sm. 90:17) Bá a ṣe ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ wa. (Òwe 10:22) Ó ṣeé ṣe ká ti kọ́ àwọn kan lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó sì ṣeé ṣe ká ti fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà fún ọ̀pọ̀ ọdún láìka ìdágunlá, àìlera, ẹ̀dùn ọkàn, tàbí inúnibíni sí. (1 Tẹs. 2:2) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó dájú pé a ti rí “adùn Jèhófà,” a sì ti wá mọ̀ pé Baba wa ọ̀run mọrírì ìsapá wa gan-an. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Dáfídì sọ pé: “Jèhófà ni ìpín tí ó kàn mí àti ti ife mi. Ìwọ di ìpín mi mú ṣinṣin. Àwọn ibi tí ó wuni ni okùn ìdiwọ̀n ti bọ́ sí fún mi.” (Sm. 16:5, 6) Inú Dáfídì dùn fún “ìpín” tirẹ̀, ìyẹn bó ṣe ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà tó sì ní àǹfààní láti máa sìn ín. Bíi ti Dáfídì, àwa náà lè fojú winá ọ̀pọ̀ ìṣòro, àmọ́ ìbùkún tẹ̀mí tá a ní pọ̀ gan-an! Torí náà, ẹ jẹ́ kí inú wa máa dùn bá a ṣe ń lọ́wọ́ nínú ìjọsìn tòótọ́ ká sì máa ‘fi ìmọrírì wo’ tẹ́ńpìlì tẹ̀mí Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 6 Wo Ilé Ìṣọ́nà July 1, 1996, ojú ìwé 14 sí 24.