Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sin Jèhófà, Ọba

Sin Jèhófà, Ọba

“Ọba ayérayé . . . ni kí ọlá àti ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé.”—1 TÍM. 1:17.

1, 2. (a) Ta ni “Ọba ayérayé,” kí sì nìdí tí orúkọ oyè yẹn fi tọ́ sí i? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Báwo ni ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣàkóso ṣe mú ká sún mọ́ ọn?

Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ tó ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta [61] tí Ọba Sobhuza Kejì ti orílẹ̀-èdè Swaziland fi ṣàkóso. Lóde òní, kò wọ́pọ̀ pé kí ọba kan pẹ́ tóyẹn lórí àlééfà. Bó ti wù kí iye ọdún tí Ọba Sobhuza lò lórí àlééfà jọni lójú tó, síbẹ̀ ó kú. Àmọ́, ọba kan wà tí kò ní kú láéláé. Kódà, Bíbélì pè é ní “Ọba ayérayé.” (1 Tím. 1:17) Onísáàmù kan tiẹ̀ sọ orúkọ Ọba Aláṣẹ yìí, ó ní: “Jèhófà ni Ọba fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—Sm. 10:16.

2 Òótọ́ ni pé a kò lè fi gígùn ìṣàkóso Ọlọ́run wé ti èèyàn èyíkéyìí. Àmọ́, ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣàkóso ló mú ká sún mọ́ ọn. Nígbà tí ọba kan tó ṣàkóso orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì fún ogójì [40] ọdún ń fi orin yin Ọlọ́run lógo, ó ní: “Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Jèhófà tìkára rẹ̀ ti fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ọ̀run gan-an; àkóso rẹ̀ sì ń jọba lórí ohun gbogbo.” (Sm. 103:8, 19) Kì í ṣe pé Jèhófà wulẹ̀ jẹ́ Ọba wa nìkan ni, ó tún jẹ́ Baba wa ọ̀run àti Baba onífẹ̀ẹ́. A lè wá bi ara wa pé: Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà jẹ́ Baba fún wa? Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba látìgbà tí ìṣọ̀tẹ̀ ti wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì? Ìdáhùn sí ìbéèrè méjèèjì yìí máa mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ká sì fi gbogbo ọkàn wa sìn ín.

 ỌBA AYÉRAYÉ SỌ ÀWỌN KAN DI ARA ÌDÍLÉ RẸ̀ LÓRÍ ILẸ̀ AYÉ ÀTI LÓKÈ Ọ̀RUN

3. Ta ló kọ́kọ́ di ara ìdílé Jèhófà lókè ọ̀run? Àwọn míì wo ló tún di “ọmọ” Ọlọ́run?

3 Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe ní láti dùn tó nígbà tó dá Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo! Ọlọ́run ò fojú kéré àkọ́bí rẹ̀ yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí baba ṣe ń nífẹ̀ẹ́ Ọmọ, ó sì jẹ́ kó bá òun kópa nínú iṣẹ́ tó máa mú kó láyọ̀, ìyẹn dídá àwọn ẹ̀dá pípé mìíràn. (Kól. 1:15-17) Ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì sì wà lára àwọn ẹ̀dá pípé náà. Bíbélì pe àwọn áńgẹ́lì yìí ní àwọn “òjíṣẹ́” Ọlọ́run “tí [wọ́n] ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.” Wọ́n ń fayọ̀ sin Ọlọ́run, ó sì yẹ́ wọn sí nípa pípè wọ́n ní “ọmọ” òun. Wọ́n jẹ́ ara ìdílé Jèhófà.—Sm. 103:20-22; Jóòbù 38:7.

4. Báwo ni àwa èèyàn ṣe wá di ara ìdílé Ọlọ́run?

4 Lẹ́yìn tí Jèhófà ti dá ọ̀run àti ayé, ó mú kí àwọn míì di ara ìdílé rẹ̀. Lọ́nà wo? Jèhófà ṣe ayé ní ibùgbé ẹlẹ́wà tó lè gbé ìwàláàyè ró, lẹ́yìn náà, ó dé iṣẹ́ rẹ̀ ládé ní ti pé ó dá Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, ní àwòrán ara Rẹ̀. (Jẹ́n 1:26-28) Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti retí pé kí Ádámù máa ṣègbọràn sí òun. Bí Baba sì ṣe máa ń fi ìfẹ́ àti inúure fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ìtọ́ni ló ṣe fún un ní ìtọ́ni. Àwọn ìtọ́ni yẹn ò sì ká èèyàn lọ́wọ́ kò láìnídìí.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17.

5. Kí ni Ọlọ́run ṣe kí àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá èèyàn lè kún orí ilẹ̀ ayé?

5 Jèhófà kò dà bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọba ayé yìí. Lọ́nà wo? Ó máa ń wù ú láti fa iṣẹ́ lé àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, torí ó kà wọ́n sí ẹni tó ṣeé fọkàn tán nínú ìdílé rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó fún Ádámù láṣẹ lórí àwọn ẹ̀dá alààyè mìíràn, kódà òun ló ní kó sọ àwọn ẹranko lórúkọ. Iṣẹ́ yẹn gba ìsapá àmọ́ ó mú kó láyọ̀. (Jẹ́n. 1:26; 2:19, 20) Ọlọ́run ò dá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn pípé lẹ́ẹ̀kan náà láti kún orí ilẹ̀ ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yàn láti dá ẹni pípé kan gẹ́gẹ́ bí àṣekún fún Ádámù, ìyẹn ni obìnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Éfà. (Jẹ́n. 2:21, 22) Lẹ́yìn náà, ó fún tọkọtaya yìí ní àǹfààní láti fi àwọn ọmọ tí wọ́n máa bí kún orí ilẹ̀ ayé. Láìsí àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kankan, ó máa ṣeé ṣe fún wọn láti mú kí Párádísè tí Ọlọ́run fi wọ́n sí máa gbòòrò díẹ̀díẹ̀ títí tí gbogbo ilẹ̀ ayé á fi di Párádísè. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n á lè máa sin Jèhófà títí láé, ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ara ìdílé Ọlọ́run lókè ọ̀run. Ìrètí àgbàyanu mà lèyí o! Ẹ sì wo bí èyí ṣe fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀!

ÀWỌN ỌLỌ̀TẸ̀ ỌMỌ KỌ ÌṢÀKÓSO ỌLỌ́RUN

6. (a) Báwo ni ìwà ọ̀tẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ nínú ìdílé Ọlọ́run? (b) Kí nìdí tí ìwà ọ̀tẹ̀ náà kò fi túmọ̀ sí pé Jèhófà ò lè ṣàkóso àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ mọ́?

6 Ó bani nínú jẹ́ pé kò tẹ́ Ádámù àti Éfà lọ́rùn pé kí Jèhófà jẹ́ Ọba Aláṣẹ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n yàn láti lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú áńgẹ́lì kan tó ya ọlọ̀tẹ̀, ìyẹn Sátánì. (Jẹ́n. 3:1-6) Bí wọ́n ṣe kúrò lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run ló fa ìrora, ìjìyà àti ikú fún wọn. Ohun tó sì ń ṣẹlẹ̀ sí àwa ọmọ wọn náà nìyẹn. (Jẹ́n. 3:16-19; Róòmù 5:12) Bó ṣe di pé kò sí ẹni tó ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé mọ́ nígbà náà nìyẹn o! Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ò lè ṣàkóso mọ́, tàbí pé kì í tún ṣe ọba aláṣẹ lórí ayé àtàwọn tó ń gbé inú rẹ̀ mọ́? Rárá o, Ọlọ́run ṣì ni aláṣẹ lórí ayé! Bí àpẹẹrẹ, ọlá àṣẹ rẹ̀ ló lò nígbà tó lé ọkùnrin àti obìnrin náà jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì, tó sì fi àwọn kérúbù ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ọgbà náà kí wọ́n má bàa pa dà wọ ibẹ̀. (Jẹ́n. 3:23, 24) Àmọ́, torí pé Ọlọ́run jẹ́ baba onífẹ̀ẹ́, ó mú kó ṣe kedere pé òun ṣì máa mú ohun tí òun ní lọ́kàn ṣẹ. Ìyẹn ni láti sọ àwọn áńgẹ́lì tó wà lókè ọ̀run àtàwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn lórí ilẹ̀ ayé di ara ìdílé rẹ̀. Ó ṣèlérí “irú-ọmọ” kan tó máa pa Sátánì run tó sì máa ṣàtúnṣe gbogbo aburú tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:15.

7, 8. (a) Báwo ni ipò àwọn nǹkan ṣe burú tó lọ́jọ́ Nóà? (b) Kí ni Jèhófà ṣe kó bàa lè fọ ayé mọ́ kó sì dá àwọn èèyàn sí?

 7 Ní ọ̀pọ̀ ọ̀gọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin kan yàn láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Lára wọn ni Ébẹ́lì àti Énọ́kù. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn kò gba pé Jèhófà ní Baba àti Ọba àwọn. Nígbà ayé Nóà, ayé “kún fún ìwà ipá.” (Jẹ́n. 6:11) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé apá Jèhófà ò ká bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ayé ni? Kí ni ìtàn fi hàn?

8 Ronú lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa Nóà. Jèhófà fún un ní ìtọ́ni àti àwòrán tó sọ gbogbo bó ṣe máa kọ́ áàkì gìrìwò kan, tó máa fi gba ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ là. Ọlọ́run tún fi ìfẹ́ ńláǹlà hàn sí gbogbo èèyàn tó wà nígbà náà ní ti pé ó pàṣẹ fún Nóà pé kó jẹ́ “oníwàásù òdodo.” (2 Pét. 2:5) Ó dájú pé lára iṣẹ́ tí Nóà jẹ́ fáwọn èèyàn ni pé kí wọ́n ronú pìwà dà, ó sì tún kìlọ̀ fún wọn nípa ìparun tó ń bọ̀ wá, àmọ́ wọn ò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ fi gbé nínú ayé táwọn èèyàn ti ń hùwà ipá tí wọ́n sì ń ṣe ìṣekúṣe lọ́nà tó bùáyà. Àmọ́ torí pé Baba aláàánú ni Jèhófà, ó dáàbò bo àwọn ọkàn mẹ́jọ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin yẹn, ó sì bù kún wọn. Jèhófà wá fi àjùlọ han àwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì burúkú yẹn nípa mímú Ìkún-omi tó kárí ayé wá. Ìyẹn sì mú kó dájú gbangba pé ọwọ́ Jèhófà ṣì ni agbára ìṣàkóso wà.—Jẹ́n. 7:17-24.

Ọba ni Jèhófà lọ́jọ́ gbogbo (Wo ìpínrọ̀ 6, 8, 10, 12, 17)

ÌṢÀKÓSO JÈHÓFÀ LẸ́YÌN ÌKÚN-OMI

9. Àǹfààní wo ni Jèhófà fún aráyé lẹ́yìn Ìkún-omi?

9 Bí Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe jáde látinú áàkì, tí wọ́n rí ayé tí Ọlọ́run ti fọ̀ mọ́ náà tí wọ́n sì mí afẹ́fẹ́ atura símú, ó dájú pé ọkàn wọn kún fún ọpẹ́ sí Jèhófà torí bó ṣe tọ́jú wọn tó sì dáàbò bò wọ́n. Nóà yára kọ́ pẹpẹ kan, ó sì jọ́sìn Jèhófà nípa rírú ẹbọ lórí pẹ́pẹ́ náà. Ọlọ́run bù kún Nóà àti ìdílé rẹ̀, ó sì fún wọn ní ìtọ́ni pé kí wọ́n ‘máa so èso, kí wọ́n sì di púpọ̀, kí wọ́n sì kún ilẹ̀ ayé.’ (Jẹ́n. 8:20–9:1) Lẹ́ẹ̀kan sí i, aráyé ní àǹfààní láti máa sin Ọlọ́run ní ìṣọ̀kan kí wọ́n sì kún ilẹ̀ ayé.

10. (a) Lẹ́yìn Ìkún-omi, ibo làwọn èèyàn ti dìtẹ̀ sí Jèhófà? Báwo ni ìdìtẹ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀? (b) Kí ni Jèhófà ṣe kí ìfẹ́ rẹ̀ bàa lè di ṣíṣe?

10 Àmọ́ Ìkún-omi náà kò gbá àìpé ẹ̀dá lọ, àwọn èèyàn ṣì ní láti máa sapá kí Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ má bàa máa darí wọn lábẹ́lẹ̀. Kò sì pẹ́ tí àwọn èèyàn tún fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀ sí ìṣàkóso Jèhófà tó ń ṣe wọ́n láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, Nímírọ́dù tó jẹ́ ọmọ ọmọ Nóà ta ko ìṣàkóso Jèhófà lọ́nà tó pabanbarì. Ìyẹn ni Bíbélì ṣe pe Nímírọ́dù ní “ọdẹ alágbára ńlá ní ìlòdì sí Jèhófà.” Ó kọ́ àwọn ìlú ńlá, bíi Bábélì, ó sì sọ ara rẹ̀ di ọba “ní ilẹ̀ Ṣínárì.” (Jẹ́n. 10:8-12) Kí ni Ọba ayérayé máa ṣe fún ọlọ̀tẹ̀ ọba yìí, kí ló sì máa ṣe nípa bó ṣe ń ta ko ète Ọlọ́run pé kí àwọn èèyàn “kún ilẹ̀ ayé”? Ohun tí Ọlọ́run ṣe ni pé ó da èdè àwọn èèyàn náà rú. Èyí kó ìdààmú bá àwọn tí Nímírọ́dù ń ṣàkóso lé lórí, wọ́n sì tú ká “sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ni wọ́n mú ìsìn èké wọn lọ, wọ́n sì ń bá ìṣàkóso tó ti mọ́ wọn lára tẹ́lẹ̀ lọ níbẹ̀.—Jẹ́n. 11:1-9.

11. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ̀?

11 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ń bọ òrìṣà lẹ́yìn Ìkún-omi, àwọn ọkùnrin olóòótọ́ kan ń bá a nìṣó láti máa bọlá fún Jèhófà. Ọ̀kan lára wọn ni Ábúráhámù, ó ṣègbọràn sí Ọlọ́run nípa fífi Úrì, ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ tó ti mọ́ ọn lára sílẹ̀, ó sì gbé nínú àgọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Jẹ́n. 11:31; Héb. 11:8, 9) Ní gbogbo ìgbà tí Ábúráhámù fi ń ṣí kiri yìí, àwọn ìlú tó sábà máa ń yí i ká jẹ́ ìlú tó lọ́ba, ọ̀pọ̀ lára àwọn ìlú náà ló sì jẹ́ ìlú olódi. Àmọ́ Jèhófà ló ń dáàbò bo Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ bí baba ṣe ń dáàbò bo ọmọ. Onísáàmù sọ nípa ààbò Jèhófà yìí, ó ní: “[Ọlọ́run] kò gba ẹ̀dá ènìyàn kankan láyè láti lù wọ́n ní jìbìtì, ṣùgbọ́n ó fi ìbáwí tọ́ àwọn ọba sọ́nà ní tìtorí wọn.”  (Sm. 105:13, 14) Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin sí Ábúráhámù, ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì ṣèlérí fún un pé: “Àwọn ọba yóò sì ti inú rẹ jáde wá.”—Jẹ́n. 17:6; Ják. 2:23.

12. Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí orílẹ̀-èdè Íjíbítì mọ̀ pé òun ni Ọba Aláṣẹ, ipa wo lèyí sì ní lórí àwọn àyànfẹ́ rẹ̀?

12 Ọlọ́run tún ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù sọ fún ọmọ rẹ̀ Ísákì àti ọmọ ọmọ rẹ̀ Jékọ́bù. Ó ní òun máa bù kún wọn, lára ìbùkún náà sì ni pé àwọn ọba máa ti inú àwọn àtọmọdọ́mọ wọn jáde wá. (Jẹ́n. 26:3-5; 35:11) Àmọ́, kí àwọn ọba tó bẹ̀rẹ̀ sí í ti inú àwọn àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù jáde wá, wọ́n kọ́kọ́ di ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Jèhófà kò ní mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ tàbí pé kì í ṣe ọba aláṣẹ lórí ayé mọ́? Rárá o! Nígbà tí àkókò tó lójú Jèhófà, ó fi bí agbára rẹ̀ ṣe tó han Fáráò olóríkunkun, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé Òun ni Ọba Aláṣẹ. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lóko ẹrú ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, ó sì dá wọn nídè lọ́nà àgbàyanu nípa mímú kí wọ́n gba àárín Òkun Pupa kọjá. Èyí mú kó ṣe kedere pé Jèhófà ṣì ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run àti pé gẹ́gẹ́ bíi Baba aláàánú, ó lo agbára ńlá rẹ̀ láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀.—Ka Ẹ́kísódù 14:13, 14.

JÈHÓFÀ DI ỌBA ÍSÍRẸ́LÌ

13, 14. (a) Nínú orin táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ, kí ni wọ́n sọ nípa ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba? (b) Ìlérí wo ni Ọlọ́run ṣe fún Dáfídì nípa ìṣàkóso rẹ̀?

13 Gbàrà tí Ọlọrun dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò nílẹ̀ Íjíbítì lọ́nà ìyanu, wọ́n kọ orin ìṣẹ́gun kan láti fi yin Jèhófà. Inú Ẹ́kísódù orí kẹẹ̀ẹ́dógún [15] ni orin yẹn wà. Lára ohun tí wọ́n kọ lórin lèyí tó wà ní ẹsẹ kejìdínlógún [18] níbi tí wọ́n ti sọ pé: “Jèhófà yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” Jèhófà sì di Ọba lórí orílẹ̀-èdè tuntun náà ní tòótọ́. (Diu. 33:5) Àmọ́, kò tẹ́ àwọn èèyàn náà lọ́rùn bí Jèhófà tí wọn ò lè fojú rí ṣe jẹ́ Alákòóso wọn. Ní nǹkan bí irínwó [400] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, wọ́n ní kí Ọlọ́run fún àwọn ní ọba táá máa ṣàkóso àwọn bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tó yí wọn ká. (1 Sám. 8:5) Síbẹ̀, Jèhófà ṣì ni Ọba wọn. Ẹ̀rí èyí sì fara hàn kedere nígbà ìṣàkóso Dáfídì, tó jọba ṣìkejì ní Ísírẹ́lì.

14 Dáfídì ló gbé àpótí májẹ̀mú mímọ́ wá sí Jerúsálẹ́mù. Ní àkókò àjọyọ̀ yìí, àwọn ọmọ Léfì kọ orin ìyìn kan tó ní gbólóhùn kan tó gbàfiyèsí nínú. Orin náà wà nínú 1 Kíróníkà 16:31 tó sọ pé:  “Kí wọ́n sì wí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: ‘Jèhófà . . . ti di ọba!’” Ṣùgbọ́n ẹnì kan lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ni Ọba ayérayé, ó ṣe wá jẹ́ pé ìgbà yẹn ló di Ọba?’ A lè sọ pé Jèhófà di Ọba nígbà tó bá lo agbára ìṣàkóso rẹ̀ tàbí tó bá ṣètò pé kí ẹnì kan ṣojú fún òun ní àkókò kan pàtó tàbí pé kó bójú tó ọ̀ràn kan pàtó. Bí Jèhófà ṣe ń di ọba ní irú ọ̀nà yìí ní ìtumọ̀ tó gbòòrò. Kí Dáfídì tó kú, Jèhófà ṣèlérí fún un pé ìṣàkóso rẹ̀ yóò máa bá a lọ títí gbére. Ó ní: “Èmi yóò gbé irú-ọmọ rẹ dìde lẹ́yìn rẹ dájúdájú, tí yóò jáde wá láti ìhà inú rẹ . . . èmi yóò fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (2 Sám. 7:12, 13) Ọlọ́run mú ìlérí yìí ṣẹ ní ohun tó ju ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún lọ lẹ́yìn náà, nígbà tí “irú-ọmọ” Dáfídì yìí fara hàn. Ta wá ni irú-ọmọ náà, ìgbà wo ló sì máa di Ọba?

JÈHÓFÀ YAN ỌBA TUNTUN

15, 16. Ìgbà wo ni Ọlọ́run fẹ̀mí yan Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba Lọ́la? Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ètò wo ló ṣe sílẹ̀ de ìgbà tó máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso?

15 Ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, Jòhánù Arinibọmi bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pé “ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” (Mát. 3:2) Nígbà tí Jòhánù ṣèrìbọmi fún Jésù, Jèhófà fẹ̀mí yan Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tó ṣèlérí àti gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀. Jèhófà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ sí Jésù nínú ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.”—Mát. 3:17.

16 Ní gbogbo ìgbà tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ńṣe ló máa ń yin Baba rẹ̀ lógo. (Jòh. 17:4) Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nípa wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 4:43) Ó tiẹ̀ tún kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Ìjọba náà dé. (Mát. 6:10) Torí pé Jésù ni Ọba Lọ́la ló ṣe lè sọ fún àwọn alátakò rẹ̀ pé: “Ìjọba Ọlọ́run wà ní àárín yín.” (Lúùkù 17:21) Lẹ́yìn ìyẹn, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí wọ́n máa pa Jésù ó bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dá ‘májẹ̀mú fún ìjọba kan.’ Ó wá tipa bẹ́ẹ̀ fún díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́ ní àǹfààní láti bá òun jọba nínú Ìjọba Ọlọ́run.—Ka Lúùkù 22:28-30.

17. Báwo ni Jésù ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í jọba lórí àwọn èèyàn kéréje ní ọ̀rúndún kìíní, ṣùgbọ́n kí ni ó ní láti dúró dè?

17 Ìgbà wo ni Jésù máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run? Kò ṣeé ṣe fún un láti bẹ̀rẹ̀ lójú ẹsẹ̀ nígbà yẹn torí pé ọ̀sán ọjọ́ kejì ni wọ́n pa á, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sì tú ká. (Jòh. 16:32) Àmọ́, bíi ti àtẹ̀yìnwá, ọwọ́ Jèhófà ṣì ni agbára ìṣàkóso wà. Ní ọjọ́ kẹta, ó jí Ọmọ rẹ̀ dìde, nígbà tó sì di ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lórí ìjọ Kristẹni tó ní nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ ẹni àmì òróró. (Kól. 1:13) Síbẹ̀, Jésù ní láti dúró dìgbà tí Ọlọ́run máa gbé gbogbo agbára lé e lọ́wọ́ pé kó máa ṣàkóso ayé gẹ́gẹ́ bí “irú-ọmọ” tá a ṣèlérí náà. Torí náà, Jèhófà sọ fún Ọmọ rẹ̀ pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.”—Sm. 110:1.

MÁA SIN ỌBA AYÉRAYÉ

18, 19. Kí ló wù wá láti ṣe, kí la sì máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún ni wọ́n fi gbéjà ko ìṣàkóso Jèhófà ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. Síbẹ̀, kò sí ìgbà tí Jèhófà kì í ṣe Ọba Aláṣẹ; ọwọ́ rẹ̀ ṣì ni agbára ìṣàkóso wà. Torí pé ó jẹ́ Bàbá onífẹ̀ẹ́, ó dáàbò bo àwọn adúróṣinṣin bíi Nóà, Ábúráhámù àti Dáfídì tí wọ́n fi ara wọn sábẹ́ rẹ̀, ó sì bójú tó wọn. Ǹjẹ́ kò wù wá láti tẹrí ba fún Ọba wa ká sì túbọ̀ sún mọ́ ọn?

19 Wàyí o, a wá lè béèrè pé: Báwo ni Jèhófà ṣe di Ọba lóde òní? Gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ Ìjọba Jèhófà, báwo la ṣe lè fi hàn pé adúróṣinṣin ni wá, ká sì di ẹni pípé nínú ìdílé Jèhófà? Kí ló túmọ̀ sí láti máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.