Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

“Kí Ìjọba Rẹ Dé”—Àmọ́, Nígbà Wo?

“Kí Ìjọba Rẹ Dé”—Àmọ́, Nígbà Wo?

“Nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn.”—MÁT. 24:33.

1, 2. (a) Kí ló lè mú kí ọkàn wa fo ohun tá a fojú ara wa rí? (b) Kí lohun tó dá wa lójú nípa Ìjọba Ọlọ́run?

Ó ṢEÉ ṣe kó o ti kíyè sí i pé táwọn èèyàn bá ń ròyìn kúlẹ̀kúlẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣojú gbogbo wọn, àlàyé wọn máa ń yàtọ̀ síra. Bákan náà, ó lè ṣòro fún ẹnì kan láti rántí ní pàtó ohun tí dókítà sọ lẹ́yìn tó ṣe àyẹ̀wò rẹ̀. Tàbí kí ẹnì kan máa dààmú kiri bó ṣe ń wá kọ́kọ́rọ́ tàbí awò ojú rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Gẹ́gẹ́ bí àwọn olùṣèwádìí kan ṣe sọ, ìgbà míì wà tí ọkàn èèyàn lè fo nǹkan tí ọwọ́ rẹ̀ bá dí. Èèyàn sì lè ṣàì fọkàn sí nǹkan bí ohun míì bá gbà á lọ́kàn. Wọ́n ní bí ọpọlọ ṣe máa ń ṣiṣẹ́ nígbà míì nìyẹn.

2 Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò fọkàn sí bí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ti ṣe pàtàkì tó. Wọ́n lè gbà pé ayé ti yí pa dà gan-an látọdún 1914, àmọ́ wọn ò mọ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣe pàtàkì tó. Àwa tá a jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé lọ́nà kan, Ìjọba Ọlọ́run dé lọ́dún 1914, nígbà tí Ọlọ́run fi Jésù jọba lókè ọ̀run. Ṣùgbọ́n, a mọ̀ pé ìyẹn kọ́ ni ìdáhùn kíkún sí àdúrà tá à ń gbà pé, “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mát. 6:10) Àdúrà yìí tún kan pé kí Ọlọ́run mú ètò nǹkan búburú ìsinsìnyí wá sópin. Torí pé ìgbà yẹn ni ìfẹ́ Ọlọ́run tó lè di ṣíṣe láyé bíi ti ọ̀run.

3. Àǹfààní wo la ní torí pé à ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

 3 Torí pé à ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, à ń rí i pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ń ní ìmúṣẹ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Ẹ ò rí bí ìyẹn ṣe mú ká yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé! Ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé wọn àtàwọn nǹkan tí wọ́n ń lépa gbà wọ́n lọ́kàn débi pé wọn ò fọkàn sí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Kristi ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso látọdún 1914 àti pé ó máa tó mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ. Àmọ́, ronú lórí ìbéèrè tó kan ẹnì kọ̀ọ̀kan wa yìí: Tó o bá ti ń sin Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún, ṣé bó o ṣe ń fojú pàtàkì wo àkókò tá à ń gbé yìí nígbà yẹn lọ́hùn-ún náà lo ṣì ń ṣe títí dòní? Ṣé o ṣì ń fọkàn sí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀? Tó bá sì jẹ́ pé àìpẹ́ yìí lo di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí lohun tó gbà ẹ́ lọ́kàn? Ohun yòówù kó jẹ́ ìdáhùn wa, ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí pàtàkì mẹ́ta tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Ọba tí Ọlọ́run fòróró yàn máa tó gbé àwọn ìgbésẹ̀ míì tó máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe ní kíkún lórí ilẹ̀ ayé.

ÀWỌN AGẸṢIN NÁÀ TI DÉ

4, 5. (a) Kí ni Jésù ti ń ṣe látọdún 1914? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí ni àwọn agẹṣin mẹ́ta náà dúró fún? Kí ni àbájáde ẹṣin tí wọ́n ń gùn?

4 Ní ọdún 1914, Ọlọ́run gbé Jésù Kristi gorí ìtẹ́ lókè ọ̀run, òun sì ni Bíbélì ṣàpèjúwe pé ó ń gun ẹṣin funfun. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ sí í jagun kó lè ṣẹ́gun ètò búburú Sátánì yìí pátápátá. (Ka Ìṣípayá 6:1, 2.) Àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìṣípayá orí 6 tó ṣàpèjúwe àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ jẹ́ ká rí ìdí tá a fi lè retí pé lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀, pẹ̀lú ìyára kánkán ni ipò àwọn nǹkan á fi máa burú sí í nínú ayé. Lára ohun táá máa ṣẹlẹ̀ ni ogun, àìtó oúnjẹ, àjàkálẹ̀ àrùn àtàwọn nǹkan míì táá máa ṣokùnfà ikú. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni àwọn agẹṣin mẹ́ta tí wọ́n ń tẹ̀ lé Jésù Kristi lẹ́yìn náà dúró fún.—Ìṣí. 6:3-8.

5 Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, a “mú àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé,” láìka àwọn ìlérí táwọn orílẹ̀-èdè ń ṣe láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n sì ní àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́. Bí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí nínú ayé ṣe fi hàn, ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni Ogun Àgbáyé Kìíní jẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ètò ìṣòwò àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti tẹ̀ síwájú gan-an látọdún 1914, àìtó oúnjẹ tó gbòde kan ṣì ń ba àwọn èèyàn lẹ́rù. Síwájú sí i, ta ló máa sọ pé òun ò mọ̀ pé onírúurú àjàkálẹ̀ àrùn, ìjábá àtàwọn “ìyọnu àjàkálẹ̀” mìíràn “tí ń ṣekú pani” ṣì ń pa ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́dọọdún? Látọjọ́ táláyé ti dáyé, kò tíì sí ìṣẹ̀lẹ̀ tó délé dóko, tó ń wáyé lemọ́lemọ́, tó sì ṣe ọṣẹ́ ńláǹlà tó báyìí rí. Ǹjẹ́ o fọkàn sí ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí?

Bí àwọn ẹlẹ́ṣin náà ṣe ń gẹṣin wọn lọ bẹ́ẹ̀ ni ipò àwọn nǹkan nínú ayé ń burú sí i (Wo ìpínrọ̀ 4 àti 5)

6. Àwọn wo ló fiyè sí bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ní ìmúṣẹ, kí sì nìyẹn sún wọn láti ṣe?

6 Ogun Àgbáyé Kìíní tó jà nígbà yẹn àti àrùn gágá tó ṣàdédé gbilẹ̀ ló gba ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn. Àmọ́ ní ti àwọn ẹni àmì òróró, wọ́n ti ń fi ìháragàgà fojú sọ́nà pé ọdún 1914 ni àwọn Àkókò Kèfèrí tàbí “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” máa dópin. (Lúùkù 21:24) Gbogbo nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ pátá kọ́ ni wọ́n mọ̀. Síbẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ohun tuntun kan máa ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914 nípa ìṣàkóso Ọlọ́run. Gbàrà tí wọ́n ti fòye mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yẹn ti ṣẹ, wọ́n fìgboyà kéde fáwọn èèyàn pé ìṣàkóso Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń sapá láti máa polongo Ìjọba Ọlọ́run yìí mú kí wọ́n ṣe inúnibíni sí wọn lọ́nà tó múná. Ti pé irú inúnibíni bẹ́ẹ̀ wáyé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè túbọ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé àsọtẹ́lẹ̀ náà ní ìmúṣẹ. Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, ńṣe làwọn ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run ń “fi àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n.” Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n lu àwọn ará wa, wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n, kódà wọ́n pa àwọn míì, yálà nípa síso wọ́n rọ̀, nípa yíyìnbọn lù wọ́n tàbí kí wọ́n bẹ́ wọn lórí.—Sm. 94:20; Ìṣí. 12:15.

7. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ kò fi fòye mọ ohun táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé túmọ̀ sí ní ti gidi?

7 Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí fi hàn pé Ọlọ́run ti gbé Ìjọba  rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run, àmọ́ kí nìdí tí ọ̀pọ̀ kò fi fara mọ́ ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí? Kí nìdí tí wọn ò fi lè fòye gbé e pé ńṣe làwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé yìí ń mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtó kan nínú Bíbélì ṣẹ? Ó ṣe tán, àsọtẹ́lẹ̀ yìí làwọn èèyàn Ọlọ́run ti ń kéde rẹ̀ látọjọ́ pípẹ́. Ṣé kìkì ohun táwọn èèyàn bá lè fojú ara wọn rí nìkan ló máa ń gbà wọ́n lọ́kàn? (2 Kọ́r. 5:7) Ṣé ọ̀ràn ayé náà ló gbà wọ́n lọ́kàn débi tí wọn ò fi rí ohun tí Ọlọ́run ń ṣe? (Mát. 24:37-39) Àbí àwọn ìpolongo èké tí Sátánì ń mú káwọn èèyàn pariwo rẹ̀ ni kò jẹ́ káwọn kan nínú wọn pọkàn pọ̀? (2 Kọ́r. 4:4) Ó gba pé kéèyàn ní ìgbàgbọ́ àti ojú tẹ̀mí kéèyàn tó lè mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run. A mà dúpẹ́ o pé à ń rí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an!

ÌWÀ IBI Ń PELÉKE SÍ I

8-10. (a) Báwo ni 2 Tímótì 3:1-5 ṣe ń ní ìmúṣẹ? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìwà ibi ń peléke sí i?

8 Ìdí kejì tá a fi mọ̀ pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Ìjọba Ọlọ́run á fi máa ṣàkóso gbogbo ayé ni pé ńṣe ni ìwà ibi ń peléke sí i láwùjọ. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí tí ohun tí 2 Tímótì 3:1-5 sọ ti ń ṣẹlẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i débi pé wọ́n ti délé dóko, wọn ò kásẹ̀ nílẹ̀, wọ́n sì ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́. Àbí ẹ̀yin náà ò kíyè sí i pé ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún ti légbá kan? Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ tó fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí.—Ka 2 Tímótì 3:1, 13.

9 Ẹ fi ohun táwọn èèyàn kà sí ohun tí kò bójú mu ní nǹkan bí ọgọ́ta [60] ọdún tàbí àádọ́rin [70] ọdún sẹ́yìn wéra pẹ̀lú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde oní níbi iṣẹ́, lágbo eré ìnàjú, nínú eré ìdárayá àti nínú ọ̀rọ̀ oge ṣíṣe. Ìwà ipá àti ìṣekúṣe tó burú jáì ti wọ́pọ̀ báyìí. Àwọn èèyàn ń figa gbága kí wọ́n lè mọ ẹni tó rorò jù, tó ya oníṣekúṣe jù, tàbí tó dájú jù. Ohun táwọn èèyàn kà sí ìwòkuwò lórí tẹlifíṣọ̀n ní nǹkan bí ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn ti wá di ohun àgbéléwò báyìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn sì ti wá rí i pé àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ lè dá sí ọ̀rọ̀ eré ìnàjú àti oge ṣíṣe, tí wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀  máa gbé ìwàkiwà wọn lárugẹ ní gbangba. A mà dúpẹ́ o pé a mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀!—Ka Júúdà 14, 15.

10 Kristẹni kan sì lè fi ohun táwọn èèyàn kà sí ìwà tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun táwọn ọ̀dọ́ ń hù ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn wéra pẹ̀lú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde onì. Ìgbà kan làwọn òbí máa ń ṣàníyàn pé bóyá àwọn ọmọ wọn ń mu sìgá tàbí igbó, bóyá wọ́n ń mutí tàbí wọ́n ń jó ijókíjó. Ó sì tọ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, lóde òní, ojoojúmọ́ là ń gbọ́ àwọn ìròyìn tó ń bani lẹ́rù. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] kan yìnbọn lu àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀, ó pa méjì, ó sì ṣe àwọn mẹ́tàlá léṣe. Àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ kan tí kò tíì pé ogún ọdún àmọ́ tí wọ́n ti mutí yó pa ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́sàn-án kan nípakúpa wọ́n sì lu bàbá ọmọ náà àti ìbátan rẹ̀ kan ní àlùbolẹ̀. Ìròyìn sọ pé ìdajì nínú gbogbo ìwà ọ̀daràn tó wáyé lórílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Éṣíà lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn ló jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ ló fà á. Ṣé a wá rí ẹni tó máa sọ pé òun ò gbà pé ńṣe layé yìí ń burú sí i?

11. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi mọ̀ pé àwọn nǹkan ń burú sí i?

11 Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an ni àpọ́sítélì Pétérù sọ, ó ní: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọn yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò sì máa wí pé: ‘Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.’” (2 Pét. 3:3, 4) Kí ló lè mú káwọn kan ní irú èrò yìí? Ó jọ pé bí nǹkan bá ti ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́, àwọn èèyàn kì í sábàá fiyè sí i mọ́. Bí ìwà rere ṣe ń jó rẹ̀yìn láwùjọ lè má fi bẹ́ẹ̀ káni lára bíi kó jẹ́ pé ojúlùmọ̀ ẹni ló ṣàdédé hùwà tó ṣàjèjì. Síbẹ̀, ìwà rere tó ń jó rẹ̀yìn ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ yìí léwu.

12, 13. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì torí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé? (b) Kí lo dá wa lójú tó máa jẹ́ kó rọrùn fún wa láti kojú àwọn ipò tó “nira láti bá lò”?

12 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún wa pé “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ipò àwọn nǹkan máa “nira láti bá lò.” (2 Tím. 3:1) Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé wọn ò ní ṣeé bá lò, torí náà kò sídìí fún wa láti máa bẹ̀rù àtikojú àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀. Lọ́lá Jèhófà, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ìjọ Kristẹni, a lè borí ìjákulẹ̀ èyíkéyìí tó bá dé bá wa tàbí ohunkóhun tó ń bà wá lẹ́rù. A lè jẹ́ adúróṣinṣin. Ó ṣe tán, Ọlọ́run ló ni “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” kì í ṣe àwa.—2 Kọ́r. 4:7-10.

13 Ó yẹ ká kíyè sí i pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ó lo gbólóhùn náà “mọ èyí.” Gbólóhùn yẹn fi òté lé e pé ọ̀rọ̀ tó sọ lẹ́yìn náà máa rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Kò sí àní-àní pé ńṣe ni ìwà àwọn èèyàn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run á túbọ̀ máa burú sí i títí dìgbà tí Jèhófà fi máa dá sí ọ̀rọ̀ ayé yìí láti fòpin sí i. Àkọsílẹ̀ àwọn òpìtàn fi hàn pé ibi yòówù kí wọ́n yíjú sí láyé, wọ́n rí í pé ńṣe ni ìwà búburú àwùjọ àwọn èèyàn tàbí orílẹ̀-èdè ń peléke sí í títí wọ́n fi kógbá sílé. Àmọ́ ṣá o, kò sí ìgbà kankan rí nínú ìtàn tí ìwà aráyé lápapọ̀ tíì burú tó bó ṣe rí lóde òní. Ọ̀pọ̀ èèyàn lè má kọbi ara sí ohun tó máa jẹ́ àbárèbábọ̀ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yìí, àmọ́ àwọn nǹkan àrà ọ̀tọ̀ tó ti ń wáyé látọdún 1914 mú kó ṣe kedere pé a lè ní ìdánilójú pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó fòpin sí ayé búburú yìí.

ÌRAN YÌÍ KÌ YÓÒ KỌJÁ LỌ

14-16. Kí ni ìdí kẹta tá a fi lè gbà gbọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run máa “dé” láìpẹ́?

14 Síbẹ̀, ìdí kẹta wà tá a fi lè gbà gbọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run máa dé láìpẹ́. Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run ń fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé. Bí àpẹẹrẹ, kí Ọlọ́run tó gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀  lókè ọ̀run, àwùjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kan wà tí wọ́n ń sin Ọlọ́run láìyẹsẹ̀. Nígbà tí díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí wọ́n rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914 kò ṣẹlẹ̀, kí ni wọ́n ṣe? Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn di ìwà títọ́ wọn mú lábẹ́ ìpọ́njú àti inúnibíni, wọ́n sì ń sin Jèhófà nìṣó. Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, gbogbo àwọn ẹni àmì òróró yẹn, tàbí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn, ti fi ìṣòtítọ́ parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé.

15 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù ti sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní ìparí ètò àwọn nǹkan yìí, ó sọ pé: “Ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀.” (Ka Mátíù 24:33-35.) Ó yé wa pé àwùjọ méjì ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ “ìran yìí.” Àwọn tó wà nínú àwùjọ àkọ́kọ́ ṣì wà láàyè lọ́dún 1914, wọ́n sì fòye mọ àmì tó fi hàn pé Kristi ti wà níhìn-ín lọ́dún yẹn. Kì í ṣe pé àwọn tó wà nínú àwùjọ àkọ́kọ́ yìí wà láàyè lọ́dún 1914 nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn tí Ọlọ́run ti fẹ̀mí yàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀, lọ́dún yẹn tàbí ṣáájú ọdún náà.—Róòmù 8:14-17.

16 Àwùjọ kejì tó wà nínú “ìran yìí” ni àwọn ẹni àmì òróró tó ń gbé ayé nígbà tí àwọn tó wà nínú àwùjọ ti àkọ́kọ́ ṣì wà láàyè. Kì í ṣe pé wọ́n gbé láyé nígbà tí àwùjọ ti àkọ́kọ́ ṣì wà láàyè nìkan ni, àmọ́ a ti fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n lásìkò táwọn tó wà nínú àwùjọ ti àkọ́kọ́ ṣì wà láyé. Nípa bẹ́ẹ̀, kì í ṣe gbogbo ẹni àmì òróró tó wà láyé lónìí ló wà nínú “ìran yìí” tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ní báyìí, àwọn tó wà nínú àwùjọ kejì náà ti ń di àgbà ọlọ́jọ́ orí. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 24:34 mú kó dá wa lójú pé, ó kéré tán, àwọn kan lára “ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà” kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀. Ó yẹ kí èyí mú ká túbọ̀ gbà pé àkókò díẹ̀ ló kù tí Ọba Ìjọba Ọlọ́run fi máa pa àwọn ẹni búburú run, táá sì mú ayé tuntun òdodo wá.—2 Pét. 3:13.

KRISTI MÁA TÓ PARÍ ÌṢẸ́GUN RẸ̀

17. Ibo la lè parí èrò sí ní báyìí tá a ti gbé ẹ̀rí mẹ́ta yìí yẹ̀ wò?

17 Ní báyìí tá a ti gbé ẹ̀rí mẹ́ta yẹ̀ wò, ibo la lè parí èrò sí? Rántí pé Jésù ti sọ pé a ò lè mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà gan-an, ó sì dájú pé a kò mọ̀ ọ́n. (Mát. 24:36; 25:13) Àmọ́, a lè mọ “àsìkò” náà, bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, ó sì dájú pé a mọ̀ ọ́n. (Ka Róòmù 13:11.) Àsìkò ọ̀hún là ń gbé yìí, ìyẹn àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Tá a bá ń fi gbogbo ọkàn wa sí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti sí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ń ṣe, kò sí bá ò ṣe ní rí àwọn ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé òótọ́ la ti sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan.

18. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò gbà pé Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso?

18 Àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run ti gbé agbára ńlá wọ Jésù Kristi, Agẹṣin funfun tí ń jagunmólú náà, máa tó gbà ní dandan pé àwọn ti ṣàṣìṣe. Kò ní sí ọ̀nà àbáyọ fún wọn. Nígbà yẹn, jìnnìjìnnì máa bo ọ̀pọ̀ èèyàn, wọ́n á figbe ta pé: ‘Ta ni ó lè dúró?’ (Ìṣí. 6:15-17) Síbẹ̀, orí tó tẹ̀ lé e nínú ìwé Ìṣípayá fún wa ní ìdáhùn. Ó dájú pé àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn tó ní ìrètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé máa “dúró” lọ́jọ́ yẹn, wọ́n á sì rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti àwọn àgùntàn mìíràn máa la ìpọ́njú ńlá náà já.—Ìṣí. 7:9, 13-15.

19. Níwọ̀n bó o ti rí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé ọjọ́ ìkẹyìn máa tó dópin, tó o gbà bẹ́ẹ̀, tí ìwà rẹ sì bá ẹ̀rí yìí mu, kí lò ń fojú sọ́nà fún?

19 Bá a ṣe ń fi gbogbo ọkàn kíyè sí bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ń ṣẹ láwọn ọjọ́ mánigbàgbé yìí, ariwo inú ayé Sátánì ò ní gbà wá lọ́kàn, kò sì ní mú ká gbọ́kàn kúrò lórí ohun ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé túmọ̀ sí. Kristi máa tó parí ìṣẹ́gun rẹ̀ nígbà tó bá bá àwọn èèyàn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run jà nínú ogun òdodo tó máa jà kẹ́yìn. (Ìṣí. 19:11, 19-21) Ẹ wá wo bí àwọn ohun tí Bíbélì sọ pé a máa gbádùn lẹ́yìnwá ọ̀la ṣe máa múnú wa dùn tó!—Ìṣí. 20:1-3, 6; 21:3, 4.