Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

“Ẹ Máa Ṣe Èyí Ní Ìrántí Mi”

“Ẹ Máa Ṣe Èyí Ní Ìrántí Mi”

“Lẹ́yìn dídúpẹ́, ó [bu ìṣù búrẹ́dì], ó sì wí pé: ‘Èyí túmọ̀ sí ara mi tí ó wà nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.’”—1 KỌ́R. 11:24.

1, 2. Kí ló ṣeé ṣe káwọn àpọ́sítélì máa rò nípa ìgbà tí ìrìn-àjò wọn sí Jerúsálẹ́mù bọ́ sí?

‘NÍ BÁYÌÍ tí kùrukùru kò sí lójú ọ̀run mọ́, a lè rí òṣùpá tó lé sójú sánmà. Ó ní láti jẹ́ pé ìrọ̀lẹ́ àná ni àwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà ní Jerúsálẹ́mù rí òṣùpá náà nígbà tó kọ́kọ́ yọ. Gbàrà tí ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn sì ti gbọ́ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti polongo pé oṣù tuntun, ìyẹn oṣù Nísàn, ti bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni wọ́n tan ìròyìn náà kálẹ̀ nípa gbígbé iná káàkiri gẹ́gẹ́ bí àmì tàbí kí wọ́n rán àwọn èèyàn jáde. Kódà, àwọn àpọ́sítélì náà gbọ́ pé oṣù Nísàn ti bẹ̀rẹ̀. Ó dájú pé Jésù á fẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù kó bàa lè débẹ̀ kí Ìrékọjá tó bẹ̀rẹ̀.’

2 Ó lè jẹ́ pé ohun tí díẹ̀ lára àwọn tó wà pẹ̀lú Jésù náà ń rò nìyẹn. Pèríà (ní òdì kejì odò Jọ́dánì) ni wọ́n wà pẹ̀lú Jésù bó ṣe ń múra ìrìn àjò rẹ̀ tó kẹ́yìn sí Jerúsálẹ́mù. (Mát. 19:1; 20:17, 29; Máàkù 10:1, 32, 46) Tí wọ́n bá ti mọ ìgbà tí ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú oṣù Nísàn bẹ̀rẹ̀, ọjọ́ mẹ́tàlá lẹ́yìn náà ni wọ́n máa ṣe Ìrékọjá, ìyẹn ní Nísàn 14 lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀.

3. Kí nìdí tó fi tọ̀nà pé kí àwa Kristẹni mọ̀ nípa ọjọ́ Ìrékọjá?

3 Ọjọ́ tí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa máa bọ́ sí ni April 14, 2014, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀, ó sì ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ọjọ́ Ìrékọjá. Ọjọ́ pàtàkì nìyẹn máa jẹ́ fún àwọn Kristẹni tòótọ́ àti àwọn olùfìfẹ́hàn. Kí nìdí? Ó jẹ́ nítorí ohun tá a kà nínú 1 Kọ́ríńtì 11:23-25 pé: “Jésù Olúwa mú ìṣù búrẹ́dì ní òru tí a ó fi í léni lọ́wọ́, àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó bù ú, ó sì wí pé: ‘Èyí túmọ̀ sí ara mi tí ó wà nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.’ Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ti ife náà pẹ̀lú.”

4. (a) Kí la lè bi ara wa nípa Ìrántí Ikú Kristi? (b) Báwo la ṣe máa ń mọ ìgbà tí Ìrántí Ikú Kristi máa bọ́ sí lọ́dọọdún? (Wo àpótí náà,  “Ìrántí Ikú Kristi Lọ́dún 2014.”)

4 Kò sí iyè méjì pé wàá fẹ́ wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣoṣo tí Jésù sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe ní ìrántí òun lọ́dọọdún. Kó tó di ọjọ́ náà, bi ara rẹ pé: ‘Báwo ló ṣe yẹ kí n múra sílẹ̀ dé ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn? Àwọn nǹkan wo la máa lò? Ọ̀nà wo la máa gbà bójú tó ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì  náà? Kí nìdí tó fi yẹ kí n ka ìṣẹ̀lẹ̀ náà àtàwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a máa lò níbẹ̀ sí pàtàkì?’

ÀWỌN OHUN ÌṢÀPẸẸRẸ

5. Ìmúrasílẹ̀ wo ni Jésù ní kí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe ṣáájú Ìrékọjá tí wọ́n jọ ṣe kẹ́yìn?

5 Nígbà tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì pé kí wọ́n ṣètò yàrá kan sílẹ̀ fún oúnjẹ Ìrékọjá, kò sọ pé kí wọ́n ṣe yàrá náà lọ́ṣọ̀ọ́ rẹpẹtẹ; kàkà bẹ́ẹ̀, ó jọ pé ohun tí Jésù fẹ́ ni yàrá kan tó bójú mu, tó mọ́ tónítóní, tó sì ní àyè tó láti gba gbogbo àwọn tí wọ́n pè síbẹ̀. (Ka Máàkù 14:12-16.) Wọ́n máa ṣètò àwọn ohun kan sílẹ̀ fún oúnjẹ náà, títí kan búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì pupa. Lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ oúnjẹ Ìrékọjá tán, Jésù yíjú sí àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ méjì yẹn.

6. (a) Lẹ́yìn oúnjẹ Ìrékọjá, kí ni Jésù sọ nípa búrẹ́dì náà? (b) Irú búrẹ́dì wo la máa ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi?

6 Àpọ́sítélì Mátíù wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, ó sì sọ lẹ́yìn ìgbà náà pé: “Jésù mú ìṣù búrẹ́dì kan, lẹ́yìn sísúre, ó bù ú, ní fífi í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì wí pé: ‘Ẹ gbà, ẹ jẹ.’” (Mát. 26:26) Irú búrẹ́dì aláìwú tí wọ́n lò fún Ìrékọjá ni “ìṣù búrẹ́dì” náà. (Ẹ́kís. 12:8; Diu. 16:3) Ìyẹ̀fun àlìkámà tí wọ́n fi omi pò ni wọ́n fi ṣe búrẹ́dì náà, kò sì ní ìwúkàrà tàbí èròjà kankan, irú bí iyọ̀. Búrẹ́dì náà kò ní wú torí pé wọn kò fi ìwúkàrà sí i. Ìyẹ̀fun nìkan ni, ó máa gbẹ bí ìpékeré, kò sì ní ṣòro kán sí wẹ́wẹ́. Lóde òní, kó tó di àkókò Ìrántí Ikú Kristi, àwọn alàgbà lè ní kí ẹnì kan fi ìyẹ̀fun àlìkámà àti omi ṣe irú búrẹ́dì bẹ́ẹ̀, kó wá gbé e kaná nínú agbada tí wọ́n fi òróró pa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. (Bí kò bá rí ìyẹ̀fun àlìkámà, ó lè fi ìrẹsì, báálì, àgbàdo, tàbí irú nǹkan oníhóró míì tí wọ́n lọ̀ ṣe é.) Ó sì lè lo irú búrẹ́dì aláìwú kan táwọn Júù máa ń pè ní matzoth, èyí tí wọn kò fi ọkà malt, ẹyin, tàbí àlùbọ́sà sí.

7. Irú wáìnì wo ni Jésù ń sọ, irú wáìnì wo la sì lè lò tá a bá ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi lódè òní?

7 Mátíù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “[Jésù] mú ife kan àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó fi í fún wọn, ó wí pé: ‘Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín.’” (Mát. 26:27, 28) Ohun tí Jésù mú dání ni ife kan tó kún fún wáìnì pupa. (Kò lè jẹ́ omi èso àjàrà tuntun, torí pé ó pẹ́ tí ìkórè èso àjàrà ti parí.) Kò sí wáìnì lára oúnjẹ Ìrékọjá tí wọ́n kọ́kọ́ jẹ ní Íjíbítì, síbẹ̀ Jésù kò lòdì sí bí wọ́n ṣe ń lo wáìnì nígbà Ìrékọjá. Kódà,  ó lo díẹ̀ lára wáìnì náà nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Ìdí nìyẹn tí wáìnì fi máa ń wà níbi Ìrántí Ikú Kristi tí àwa Kristẹni máa ń ṣe. Níwọ̀n bí kò ti sí ìdí láti fi kún ìníyelórí ìtóye ẹ̀jẹ̀ Jésù tàbí láti mú kó túbọ̀ lágbára sí i, a kì í lo irú wáìnì tí wọ́n ti da brandy mọ́ tàbí èyí tí wọ́n fi àwọn èròjà amóúnjẹ-ta-sánsán sí. Wáìnì pupa tí kò dùn ni kí ẹ lò. Ó lè jẹ́ wáìnì tí ẹ̀yin fúnra yín ṣe tàbí wáìnì tí wọ́n ń tà lọ́jà, irú bíi Beaujolais, Burgundy, tàbí Chianti.

ÀWỌN OHUN ÌṢÀPẸẸRẸ TÓ NÍTUMỌ̀

8. Kí nìdí tí àwa Kristẹni fi máa ń fẹ́ mọ ìjẹ́pàtàkì búrẹ́dì àti wáìní náà?

8 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú kó ṣe kedere pé, yàtọ̀ sí àwọn àpọ́sítélì, ó yẹ kí àwọn Kristẹni yòókù máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ó kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti gba èyíinì tí èmi pẹ̀lú fi lé yín lọ́wọ́, pé Jésù Olúwa mú ìṣù búrẹ́dì . . . àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó bù ú, ó sì wí pé: ‘Èyí túmọ̀ sí ara mi tí ó wà nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.’” (1 Kọ́r. 11:23, 24) Èyí ló fà á tó fi jẹ́ pé títí dòní, àwa Kristẹni máa ń rántí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí lọ́dọọdún, a sì máa ń fẹ́ mọ ìjẹ́pàtàkì búrẹ́dì àti wáìní náà.

9. Èrò tí kò tọ̀nà wo làwọn kan ní nípa búrẹ́dì tí Jésù lò?

9 Àwọn kan tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ṣàlàyé pé ohun tí Jésù sọ ní tààràtà ni pé: ‘Èyí ni ara mi,’ torí náà wọ́n gbà gbọ́ pé búrẹ́dì yẹn yí pa dà lọ́nà ìyanu, ó sì di ẹran ara Jésù gangan. Àmọ́, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. * Ara Jésù wà níbẹ̀ níwájú àwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ náà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni búrẹ́dì aláìwú tí wọ́n máa jẹ. Ó ṣe kedere nígbà náà pé èdè ìṣàpẹẹrẹ ni Jésù lò, bó ti ṣe láwọn ìgbà míì.—Jòh. 2:19-21; 4:13, 14; 10:7; 15:1.

10. Kí ni búrẹ́dì tá a máa ń lò nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa dúró fún?

10 Búrẹ́dì tó wà níwájú àwọn àpọ́sítélì  tí wọ́n sì máa tó jẹ nínú rẹ̀ túmọ̀ sí ara Jésù. Ara wo? Ní ìgbà kan, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run rò pé níwọ̀n bí Jésù ti bu búrẹ́dì náà tó sì jẹ́ pé wọ́n kò ṣẹ́ èyíkéyìí nínú egungun rẹ̀, a jẹ́ pé búrẹ́dì náà túmọ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró lápapọ̀, èyí tí Bíbélì pè ní “ara Kristi.” (Éfé. 4:12; Róòmù 12:4, 5; 1 Kọ́r. 10:16, 17; 12:27) Àmọ́, nígbà tó yá, a wá rí i pé téèyàn bá rò ó dáadáa, tó sì wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, á rí i pé ńṣe ni búrẹ́dì náà ṣàpẹẹrẹ ara ẹ̀dá èèyàn tí Jésù ní, èyí ti a ti pèsè sílẹ̀ fún un. Jésù “jìyà nínú ẹran ara,” kódà wọ́n kàn án mọ́gi. Torí náà, nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, búrẹ́dì náà ṣàpẹẹrẹ ara ẹ̀dá èèyàn tí Jésù fi “ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”—1 Pét. 2:21-24; 4:1; Jòh. 19:33-36; Héb. 10:5-7.

11, 12. (a) Kí ni Jésù sọ nípa wáìnì náà? (b) Kí ni wáìnì tá a máa ń lò níbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ṣàpẹẹrẹ?

11 Ìyẹn wá jẹ́ ká lóye ohun tí Jésù sọ nípa wáìnì náà. A kà pé: “Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ti ife náà pẹ̀lú, lẹ́yìn tí ó ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó wí pé: ‘Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi.’” (1 Kọ́r. 11:25) Ọ̀pọ̀ Bíbélì ló túmọ̀ gbólóhùn yìí ní olówuuru bíi ti Bíbélì Robert Young. Wọ́n ní: “Ife yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi.” (Àwa la kọ ọ́ lọ́nà tó dúdú yàtọ̀.) Ṣé ife tí Jésù mú dání yẹn ni májẹ̀mú tuntun lóòótọ́? Rárá o. Ọ̀rọ̀ náà “ife” túmọ̀ sí ohun tó wà nínú ife yẹn, ìyẹn wáìnì. Kí wá ni Jésù sọ pé wáìnì náà túmọ̀ sí tàbí ṣàpẹẹrẹ? Ó túmọ̀ sí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó fi ṣèrúbọ.

12 Nínú Ìhìn Rere Máàkù, Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú’ mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Máàkù 14:24) Ó dájú pé ẹ̀jẹ̀ Jésù ni a óò “tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.” (Mát. 26:28) Torí náà, ó bá a mu wẹ́kú pé wáìnì pupa náà ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ Jésù. Nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ yẹn, a lè rí ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà, lédè mìíràn “ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa.”—Ka Éfésù 1:7.

Àwọn àpọ́sítélì mu nínú wáìnì tó dúró fún ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú Jésù (Wo ìpínrọ̀ 11 àti 12)

ṢÍṢE ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI

13. Ṣàlàyé bí a ṣe máa ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi tó máa ń wáyé lọ́dọọdún.

13 Kí ni wàá rí ní ìgbà àkọ́kọ́ tó o bá lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe? Ó ṣeé ṣe kí irú ìkórajọ bẹ́ẹ̀ wáyé ní ibì kan tó fani mọ́ra, tó mọ́ tónítóní, táwọn èèyàn ti lè jókòó pẹ̀sẹ̀ kí wọ́n sì gbádùn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì náà. Wọ́n lè to òdòdó síbẹ̀ níwọ̀nba, àmọ́ kì í ṣe ibi tí àwọn aṣọ aláràbarà tí wọ́n ta káàkiri lọ́nà ṣekárími tàbí àríyá ò ti ní lè jẹ́ kó o pọkàn pọ̀. Alàgbà kan tó tóótun máa ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì náà lọ́nà tó ṣe kedere tó sì fi ọ̀wọ̀ hàn. Ó máa jẹ́ kí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ mọrírì ohun tí Kristi ṣe fún wa. Ó kú ikú ìrúbọ kí àwa lè máa wà láàyè. (Ka Róòmù 5:8-10.) Olùbánisọ̀rọ̀ náà máa ṣàlàyé ìrètí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Bíbélì sọ pé ó wà fun àwa Kristẹni.

14. Nígbà àsọyé Ìrántí Ikú Kristi, ìrètí méjì wo ni olùbánisọ̀rọ̀ máa jíròrò?

14 Ọ̀kan lára rẹ̀ ni ìrètí láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run. Ìrètí yìí ni ìwọ̀nba kéréje lára àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ń fojú sọ́nà fún, irú bí àwọn àpọ́sítélì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. (Lúùkù 12:32; 22:19, 20; Ìṣí. 14:1) Ìrètí kejì ni èyí tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni tó ń fi ìdúróṣinṣin sin Ọlọ́run ní àkókò wa yìí ní. Wọ́n ní ìrètí láti máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, nínú Párádísè tá a mú pa dà bọ̀ sípò. Nígbà náà làwọn èèyàn á máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run, èyí sì ni ohun kan tí àwa Kristẹni ti ń gbàdúrà fún tipẹ́tipẹ́. (Mát. 6:10) Ìwé Mímọ́ sì ṣàlàyé tó múni lọ́kàn yọ̀ nípa àwọn nǹkan àgbàyanu tí wọ́n máa gbádùn títí ayérayé.—Aísá. 11:6-9; 35:5, 6; 65:21-23.

15, 16. Kí la máa ṣe sí búrẹ́dì náà nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?

15 Bí ìjíròrò náà bá ń parí lọ, olùbánisọ̀rọ̀ á jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò ti tó wàyí láti ṣe ohun tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n ṣe. Bí a ṣe sọ lókè, ohun ìṣàpẹẹrẹ  méjì ni a máa lò, búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì pupa. Àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà lè wà lórí tábìlì lẹ́gbẹ̀ẹ́ olùbánisọ̀rọ̀. Ó máa pe àfiyèsí sí ẹsẹ Bíbélì kan tó ṣàlàyé ohun tí Jésù sọ àti ohun tó ṣe nígbà tó dá ìṣẹ̀lẹ̀ àkànṣe náà sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, a rí i kà nínú ìwé Mátíù pé: “Jésù mú ìṣù búrẹ́dì kan, lẹ́yìn sísúre, ó bù ú, ní fífi í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì wí pé: ‘Ẹ gbà, ẹ jẹ. Èyí túmọ̀ sí ara mi.’” (Mát. 26:26) Jésù bu búrẹ́dì aláìwú náà kó lè fún àwọn àpọ́sítélì tó jókòó sí apá ọ̀tún àti apá òsì rẹ̀. Tó o bá dé ìpàdé yẹn ní April 14, wàá rí búrẹ́dì aláìwú mélòó kan tí wọ́n ti kán sí wẹ́wẹ́ tí wọ́n sì kó sínú àwo tí wọ́n á fi gbé e káàkiri.

16 A máa lo àwo tó pọ̀ tó, kí wọ́n bàa lè tètè gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó bá wá. Tá a bá sì ń gbé e kiri, kò ní sí onírúurú ààtò ẹ̀sìn. A óò kọ́kọ́ gbàdúrà ṣókí, lẹ́yìn náà ní wọ́n á máa gbé ohun ìṣàpẹẹrẹ náà kiri lọ́nà tó wà létòlétò, bó bá ṣe bọ́gbọ́n mu jù lọ níbi tí wọ́n bá ti ṣe é. Ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló máa jẹ nínú búrẹ́dì náà (tàbí kí ẹnikẹ́ni má tiẹ̀ jẹ ẹ́), bó ṣe rí ní ìjọ tó pọ̀ jù lọ nígbà tí wọ́n gbé búrẹ́dì náà dé ọ̀dọ̀ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tá a ṣe lọ́dún 2013.

17. Nígbà Ìrántí Ikú Kristi, báwo la ṣe máa ṣe ohun tí Jésù sọ nípa wáìnì?

17 Lẹ́yìn èyí ni olùbánisọ̀rọ̀ máa darí àfiyèsí sí ohun tí Mátíù tún sọ. Ó ní: “[Jésù] mú ife kan àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó fi í fún wọn, ó wí pé: ‘Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín; nítorí èyí túmọ̀ sí “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.’” (Mát. 26:27, 28) Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí Jésù fi lélẹ̀ yìí, a óò tún gba àdúrà míì, lẹ́yìn yẹn ni wọ́n á gbé ‘ife’ wáìnì pupa náà lọ sọ́dọ̀ gbogbo àwọn tó bá wà níbẹ̀.

18. Bó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé àwọn díẹ̀ ló jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ náà tàbí ẹnikẹ́ni ò jẹ níbẹ̀, kí nìdí tó fi yẹ ká máa wà níbi Ìrántí Ikú Kristi?

18 Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi máa ń kọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ láti jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà nígbà tí wọ́n bá gbé e dé ọ̀dọ̀ wọn. Ìdí ni pé Jésù sọ pé kìkì àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú òun nínú Ìjọba ọ̀run nìkan ló yẹ kí wọ́n jẹ nínú rẹ̀. (Ka Lúùkù 22:28-30; 2 Tím. 4:18) Ńṣe ni gbogbo àwọn yòókù máa ń wà níbẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, wọ́n á máa wo ohun tó ń lọ. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa pésẹ̀ síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, torí pé bí wọ́n ṣe wà níbẹ̀ ló ń fi hàn bí wọ́n ṣe ka ẹbọ Jésù sì pàtàkì tó. Nígbà Ìrántí Ikú Kristi, wọ́n á lè ronú lórí àwọn ìbùkún tí wọ́n lè rí gbà lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. Wọ́n nírètí láti wà lára “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó máa la “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀ wá já. Ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí ni àwọn olùjọsìn tí wọ́n á ti ‘fọ aṣọ wọn, tí wọ́n á sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.’—Ìṣí. 7:9, 14-17.

19. Kí lo lè ṣe láti múra sílẹ̀ de Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa kó o sì jàǹfààní nínú rẹ̀?

19 Kárí ayé ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń múra sílẹ̀ fún ìpàdé àkànṣe yìí. Bó bá ti ku ọ̀sẹ̀ mélòó kan kó wáyé la ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í pe gbogbo èèyàn kí wọ́n lè pésẹ̀ síbẹ̀. Síwájú sí i, bó bá ti ku ọjọ́ mélòó kan ká ṣe Ìrántí Ikú Kristi, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa máa ka ìtàn Bíbélì tó sọ ohun tí Jésù ṣe àtohun tó wáyé láwọn ọjọ́ yẹn lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni. A ó ti ṣètò àwọn ìgbòkègbodò wa ká lè rí i dájú pé a wà níbẹ̀. Ó dára ká ti débẹ̀ ṣáájú orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀ ká bàa lè kí àwọn àlejò káàbọ̀ ká sì gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látòkèdélẹ̀. Gbogbo àwa ará àtàwọn àlejò máa jàǹfààní kíkún tá a bá ń fojú bá a lọ nínú Bíbélì wa bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé àwọn kókó náà. Èyí tó tún wá ṣe pàtàkì jù lọ ni pé tá a bá pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi, ńṣe la máa fi hàn pé a mọrírì ẹbọ Jésù tọkàntọkàn, a sì ń ṣègbọràn sí àṣẹ tó pa pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—1 Kọ́r. 11:24.

^ ìpínrọ̀ 9 Ọ̀mọ̀wé ará Jámánì kan, Heinrich Meyer, sọ pé: “Níwọ̀n bí àwọn àlejò [àwọn àpọ́sítélì] ti rí i pé ara Jésù ṣì wà digbí (pé ó ṣì wà láàyè), àti pé, títí dìgbà yẹn, wọn ò tíì ta ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ sílẹ̀, kò sí èyíkéyìí lára wọn tó jẹ́ gbà . . . ní ti gidi pé ara Olúwa làwọn ń jẹ àti pé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gangan làwọn ń mu, [torí náà] Jésù Alára kò retí pé kí wọ́n ṣi ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tí kò díjú lóye, torí pé wọn ò sọ́ fún un nígbà yẹn pé kò yé àwọn.”