Ṣó o ti fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

Ìgbà wo ni Jésù “wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú ẹ̀wọ̀n”? (1 Pét. 3:19)

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí Jésù jíǹde ló sọ ìdájọ́ Ọlọ́run fún àwọn ẹ̀mí burúkú náà, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run máa tó fìyà tó tọ́ jẹ wọ́n.6/15, ojú ìwé 23.

Ohun mẹ́tà wo ló máa ń mú kó ṣòro fáwọn tó tún ìgbéyàwó ṣe láti ṣàṣeyọrí?

Èkínní, bí wọ́n á ṣe gbé ọ̀rọ̀ ẹni tí wọ́n fẹ́ tẹ́lẹ̀ kúrò lọ́kàn. Ìkejì, bí wọ́n á ṣe mọwọ́ àwọn ọ̀rẹ́ ẹni tí wọ́n fẹ́ báyìí. Ìkẹtà, bí wọ́n á ṣe fọkàn tán ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni ẹni tí wọ́n fẹ́ tẹ́lẹ̀ já wọn kulẹ̀.7/1, ojú ìwé 9 àti 10.

Ìgbà wo ni Jésù máa ṣèdájọ́ àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́? (Mát. 25:32)

Ó máa jẹ́ nígbà tí Jésù bá dé láti ṣèdájọ́ àwọn èèyàn nígbà ìpọ́njú ńlá, lẹ́yìn ìparun ìsìn èké.7/15, ojú ìwé 6.

Ìgbà wo làwọn oníwà àìlófin tí Jésù mẹ́nu kàn nínú àkàwé àlìkámà àti àwọn èpò máa payín keke? (Mát. 13:36, 41, 42)

Wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá, nígbà tí wọ́n bá rí i pé kò sí ibi táwọn lè sá sí mọ́.7/15, ojú ìwé 13.

Ìgbà wo ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa ẹrú olóòótọ́ àti olóye ní ìmúṣẹ? (Mát. 24:45-47)

Lẹ́yìn ọdún 1914 ni ọ̀rọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ, kì í ṣe ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Lọ́dún 1919, Jésù yan ẹrú náà sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀, ìyẹn gbogbo Kristẹni tó ń jẹ nínú oúnjẹ tẹ̀mí náà.7/15, ojú ìwé 21 sí 23.

Ìgbà wo ni Jésù máa yan ẹrú olóòótọ́ sípò lórí gbogbo nǹkan ìní rẹ̀?

Ìyẹn máa jẹ́ lọ́jọ́ iwájú, nígbà ìpọ́njú ńlá tí ẹrú olóòótọ́ náà bá gba èrè rẹ̀ ní ọ̀run.7/15, ojú ìwé 25.

Ṣé torí pé àwọn kan jẹ́ èèyàn burúkú tàbí pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan ni Bíbélì ò ṣe dárúkọ wọn?

Kò yẹ ká rò bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé àwọn èèyàn rere kan wà tí Bíbélì ò dárúkọ, àwọn èèyàn burúkú kan sì wà tí kò dárúkọ. (Rúùtù 4:1-3; Mát. 26:18) Méjì péré ni Bíbélì dárúkọ lára àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́.8/1, ojú ìwé 10.

Yàtọ̀ sí agbára tí Ọlọ́run fún ọgbọ̀nlérúgba [230] àwọn ará wa kí wọ́n lè la ìrìn-àjò gígùn láti àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen já, kí ló tún ràn wọ́n lọ́wọ́?

Bó tílẹ̀ jẹ́ pé ebi àti àìsàn ti jẹ́ kí àárẹ̀ mú wọn, ṣe ni wọ́n ń fún ara wọn níṣìírí pé káwọn ṣáà máa forí tì í.8/15, ojú ìwé 18.

Kí nìdí tí ìtàn bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kọjá Odò Jọ́dánì bọ́ sí Ilẹ̀ Ìlérí fi jẹ́ ohun ìṣírí fún wa?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé odò náà ti kún àkúnya, Jèhófà dá omi náà dúró kí àwọn èèyàn rẹ̀ lè kọjá. Kò sí àní-àní pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára, kí wọ́n sì túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e. Láfikún, ìtàn náà múnú wa dùn.9/15, ojú ìwé 16.

Kí ló ṣe kedere nínú bí Bíbélì ṣe sọ̀rọ̀ nípa àwọ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà?

Bí Bíbélì ṣe fi àwọ̀ ṣàlàyé nǹkan fi hàn pé Ọlọ́run mọ̀ pé àwọ̀ máa ń ní ipa lórí bí nǹkan ṣe ń rí lára àwa èèyàn, ó sì tún máa ń jẹ́ ká lè rántí àwọn nǹkan.10/1, ojú ìwé 14 àti 15.

Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ inú Míkà 5:5 nípa àwọn olùṣọ́ àgùntàn àti mọ́gàjí ṣe ń ní ìmúṣẹ lónìí?

Ó yé wa pé àwọn alàgbà ìjọ ni ‘àwọn olùṣọ́ àgùntàn méje àtàwọn mọ́gàjí mẹ́jọ’ tí ìwé Míkà 5:5 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àwọn ló sì ń múra àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀ de ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí ọ̀tá ṣe máa gbéjà kò wọ́n lọ́jọ́ iwájú.11/15, ojú ìwé 20.

Kí ni díẹ̀ lára ìdí tá a fi nílò Ọlọ́run?

A nílò ìtọ́sọ́nà tó dára àti ojútùú sí àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Méjèèjì sì ni Ọlọ́run ń pèsè. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa láyọ̀ ká sì máa gbé ìgbé ayé rere. Kí èyí bàa lè ṣeé ṣe, ó máa mú àwọn ìlérí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.12/1, ojú ìwé 4 sí 6.