NÍ KÙTÙKÙTÙ òwúrọ̀ ọjọ́ kan, bí obìnrin kan ṣe jáde síta látinú ilé rẹ̀, ó bá ẹrù kan lẹ́nu ọ̀nà. Ó gbé ẹrù náà, ó wò yí ká, àmọ́ ńṣe ni ojú pópó dá páropáro. Ó ní láti jẹ́ pé àlejò kan ló gbé ẹrù náà síbẹ̀ lóru. Ó rọra já ohun tí wọ́n fi di ẹrù náà kó lè mọ ohun tó wà nínú rẹ̀, kíá ló fi ẹ̀yìn rìn wọlé, ó sì ti ìlẹ̀kùn. Abájọ! Ìwé wa tí wọ́n ti fòfin dè ló wà níbẹ̀! Ó gbá ẹrù náà mọ́ra, ó gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún oúnjẹ tẹ̀mí ṣíṣeyebíye náà.

Irú nǹkan báyìí wọ́pọ̀ gan-an nílẹ̀ Jámánì láwọn ọdún 1931 sí 1939. Lẹ́yìn tí ìjọba Násì gorí àlééfà lọ́dún 1933, ìjọba fi òfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn ibi tó pọ̀ lórílẹ̀-èdè náà. Arákùnrin Richard Rudolph tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rùn-ún ọdún * báyìí sọ pé: “Ó dá wa lójú pé kò sí òfin táwọn èèyàn lè ṣe tó máa mú ká dẹ́kun láti máa polongo Jèhófà àti orúkọ rẹ̀. Tá a bá fẹ́ máa kẹ́kọ̀ọ́ ká sì tún máa wàásù fáwọn èèyàn, ó ṣe pàtàkì pé ká ní àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Àmọ́ látìgbà tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, kò rọrùn rárá láti máa rí ìwé lò. A wá ń ronú nípa bá a ṣe lè máa bá iṣẹ́ náà nìṣó.” Kò pẹ́ tí Richard fi wá mọ̀ pé ọ̀nà àrà míì wà tí òun lè gbà mú káwọn ará máa rí ìwé gbà. Ó rí i pé òun lè máa ṣe é lábẹ́ òjìji àwọn òkè ńlá.—Oníd. 9:36.

WỌ́N TỌ OJÚ Ọ̀NÀ ÀWỌN ONÍFÀYÀWỌ́

Tó o bá forí lé ibi tí odò Elbe (tàbí, Labe) ti ń ṣàn bọ̀, ibi tí àwọn òkè gàgàrà tí wọ́n pè ní Giant Mountains (Krkonoše) wà lo máa lọ já sí. Àwọn òkè yìí ló wà ní ẹnu ààlà tó wà láàárín orílẹ̀-èdè olómìnira Czech àti orílẹ̀-èdè Poland báyìí. Àwọn òkè yìí ga tó ilé alájà ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mẹ́rìnlélógún [524]. Èyí kéré ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn òkè tó yí i ká, ìyẹn ló mú káwọn èèyàn máa pè é ní erékùṣù tí òtútù ti ń mú nini tó wà láàárín ilẹ̀ Yúróòpù. Yìnyín tó ga tó ilé máa ń bo àwọn òkè yẹn mọ́lẹ̀ ṣíbáṣíbá fún oṣù mẹ́fà lọ́dún. Téèyàn bá fojú di ojú ọjọ́ tó máa ń tètè yí pa dà níbẹ̀, ó lè ṣe kòńgẹ́ kùrukùru tó máa ń ṣàdédé bo àwọn òkè náà.

Fún ọ̀pọ̀ ọdún làwọn òkè yìí ti pààlà sáàárín àwọn ẹkùn-ìpínlẹ̀, ilẹ̀ ọba àtàwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn ibi tó ṣeé rìn láàárín àwọn òkè yẹn léwu, torí bẹ́ẹ̀ ó ṣòro fáwọn agbófinró láti máa ṣọ́ àwọn tó ń gbabẹ̀.  Ìyẹn ló fà á tó fi jẹ́ pé nígbà pípẹ́ sẹ́yìn, àwọn òkè yẹn làwọn onífàyàwọ́ fi ń bojú nígbà tí wọ́n bá ń kẹ́rù kọjá. Láwọn ọdún 1931 sí 1939, nígbà tí àwọn òkè gàgàrà yìí pààlà sáàárín orílẹ̀-èdè Czechoslovakia àti Jámánì, àwọn Ẹlẹ́rìí tó gbóyà máa ń lo ojú ọ̀nà táwọn onífàyàwọ́ ti pa tì yẹn. Kí ni wọ́n ń lò ó fún? Ibẹ̀ ni wọ́n máa ń kó àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì gbà tí wọ́n bá ń kó wọn bọ̀ láti ìlú tí wọn ò ti fòfin de ìwé wa. Arákùnrin Richard wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà, nígbà tó ṣì kéré.

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó múra bí àwọn tó máa ń rìn lórí òkè ń gba àárín àwọn òkè gàgàrà kọjá lọ sí ilẹ̀ Jámánì pẹ̀lú ẹrù ìwé tí wọ́n dì sẹ́yìn

ÌRÌN-ÀJÒ TÓ LÉWU LÓRÍ ÀWỌN ÒKÈ ŃLÁ

Arákùnrin Richard sọ pé: “Láwọn òpin ọ̀sẹ̀, àwa ọ̀dọ́kùnrin máa múra bí àwọn tó máa ń rìn lórí òkè, a máa pín ara wa sí méje-méje tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ó sì forí lé ibi òkè náà. Tá a bá bá apá ọ̀dọ̀ àwọn Jámánì wọlé, ó máa ń gbà wá tó wákàtí mẹ́ta láti rin òkè náà já ká tó dé ibi ìṣeré kan tí wọ́n ń pè ní Špindlerův Mlýn.” Ibi ìṣeré yìí fi nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rìndínlógún àtààbọ̀ jìn sí apá ọ̀dọ̀ àwọn Czech. Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn ará Jámánì ló ń gbé ní àgbègbè náà. Ọ̀kan lára wọn ni àgbẹ̀ kan tó gbà láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará. Ó ní ọkọ̀ kan tí wọ́n máa ń fi ẹṣin fà, èyí tó fi máa ń gbé àwọn tó ń wá fún ìsinmi. Tí wọ́n bá ti bá wa fi ọkọ ojú irin kó àwọn ìwé wá láti ìlú Prague, wọ́n á já wọn sí ìlú kan tó wà nítòsí, á wá lọ bá wa fi ọkọ̀ yìí kó wọn látibẹ̀. Ó máa ń ko àwọn ìwé náà sínú oko rẹ̀, á sì tọ́jú wọn pa mọ́ sábẹ́ koríko gbígbẹ títí táwọn ará wa á fi wá kó wọn lọ sílẹ̀ Jámánì.

Richard tún sọ síwájú sí i pé: “Tá a bá ti dé oko yìí, a máa kó ìwé kún àpò tí wọ́n dìídì ṣe fún gbígbé ẹrù tó wúwo, a ó sì gbé wọn kọ́ ẹ̀yìn. Ẹrù tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ń gbé máa ń wúwo tó báàgì sìmẹ́ǹtì kan.” Káwọn èèyàn má bàa fura sí wọn, wọ́n máa ń fi òkùnkùn bojú. Wọ́n á gbéra ní ìrọ̀lẹ́, wọ́n á fi gbogbo òru rìn, wọ́n á sì dé ilé kí ilẹ̀ tó mọ́. Arákùnrin Ernst Wiesner, tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká ní ilẹ̀ Jámánì nígbà yẹn, sọ ohun tí wọ́n máa ń ṣe kí wọ́n má bàa bọ́ sọ́wọ́ ìjọba. Ó ní: “Àwọn arákùnrin méjì máa ń lọ níwájú, tí wọ́n bá kófìrí ẹnikẹ́ni, wọ́n á yára tán iná tọ́ọ̀ṣì láti fi ta àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn lólobó. Àmì yìí ló máa mú káwọn arákùnrin tó di ẹrù sẹ́yìn, tí wọ́n wà ní nǹkan bí òpó mẹ́wàá sí wọn, fara pa mọ́ sínú igbó tó wà lẹ́bàá ọ̀nà títí táwọn arákùnrin méjì náà á fi pa dà wá tí wọ́n á sì sọ ọ̀rọ̀ àjọmọ̀ kan. Wọ́n máa ń yí ọ̀rọ̀ àjọmọ̀ yìí pa dà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.” Àmọ́ o, kì í ṣe torí àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Jámánì  tí wọ́n ń wọ aṣọ búlúù nìkan ni wọ́n fi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra.

Arákùnrin Richard rántí ohun kan tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Ó pẹ́ mi díẹ̀ kí n tó parí iṣẹ́ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, torí náà àwọn ará ti lọ kí n tó gbéra láti máa lọ sí apá orílẹ̀-èdè Czech. Ilẹ̀ ti ṣú, kùrukùru sì ti bojú ọjọ́, bẹ́ẹ̀ ni mò ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ bí mo ṣe ń rìn lọ nínú òjò tó tútù nini. Àfi bí mo ṣe ṣìnà láàárín àwọn igi ahóyaya kan báyìí, ọ̀pọ̀ wákàtí ni mo sì fi rìn káàkiri láìjánà. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣìnà bíi tèmi yìí ló ti kú. Ìgbà táwọn arákùnrin mi ń pa dà bọ̀ lọ́wọ́ ìdájí ni mo tó rìnnà kò wọ́n.”

Fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni àwùjọ kékeré àwọn arákùnrin onígboyà yìí máa ń gba àwọn òkè yẹn kọjá. Lásìkò òtútù, wọ́n máa ń lo bàtà téèyàn fi máa ń rìn lórí yìnyín nígbà tí wọ́n bá lọ kó àwọn ẹrù náà. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn arákùnrin tí wọ́n tó ogún nínú àwùjọ kọ̀ọ̀kan máa ń sọdá ẹnu ààlà náà lójúmọmọ, wọ́n á sì tọ ipasẹ̀ tó wà lórí yìnyín. Kí àwọn èèyàn lè rò pé àwọn tó kàn máa ń lọ sórí òkè ni wọ́n, àwọn arábìnrin mélòó kan máa ń bá wọn lọ. Àwọn kan lára àwọn arábìnrin náà máa ń wà níwájú. Tí wọ́n bá fura pé ewu kan ń bọ̀, wọ́n á ju fìlà wọn sókè.

Bí yìnyín ṣe bo àwọn Òkè Gàgàrà yìí mú kó léwu gan-an láti gba àárín wọn kọjá

Kí làwọn ará náà máa ń ṣe tí wọ́n bá dé láti ìrìn-àjò wọn? Ètò ti wà nípa bí wọ́n ṣe máa pín àwọn ìwé náà láìjáfara. Báwo ni wọ́n ṣe máa ń ṣe é? Wọ́n máa di àwọn ìwé náà bí ìgbà téèyàn di ọṣẹ, wọ́n á sì kó wọn lọ sí ibùdókọ̀ ojú irin nílùú Hirschberg. Wọ́n á fi àwọn ẹrù náà ránṣẹ́ sí ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nílẹ̀ Jámánì, látibẹ̀ làwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti máa kó wọn tí wọ́n á sì fọgbọ́n pín ẹrù náà sílé àwọn ará yòókù, bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Iṣẹ́ táwọn ará náà ń ṣe so kọ́ra débi pé tí ètò tí wọ́n ń ṣe lábẹ́lẹ̀ náà bá fi lu síta pẹ́nrẹ́n, àbájáde rẹ̀ kò ní dáa rárá. Síbẹ̀, ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan tó mú ìfàsẹ́yìn wá.

Lọ́dún 1936, àwọn ọlọ́pàá rí ibì kan tá à ń já ìwé sí nítòsí ìlú Berlin. Lára ohun tí wọ́n rí ni ẹrù mẹ́ta tó wà ní dídì tẹ́nì kan tí wọn ò mọ orúkọ rẹ̀ fi ránṣẹ́ láti Hirschberg. Àwọn ọlọ́pàá lo ẹ̀rọ tó máa ń ṣàyẹ̀wò bí olúkúlùkù ṣe máa ń kọ̀wé láti mọ ẹni tó lè jẹ́. Ìyẹn ni wọ́n fi mọ ọ̀kan lára àwọn ará náà, tí wọ́n sì lọ fàṣẹ ọba mú un. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, wọ́n tún fàṣẹ ọba mú àwọn méjì míì tí wọ́n fura sí, Richard Rudolph jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Àwọn ará tí wọ́n mú náà gbà pé àwọn nìkan làwọn ń ṣe iṣẹ́ náà, torí bẹ́ẹ̀, àwọn yòókù ń bá iṣẹ́ tó túbọ̀ ń léwu náà nìṣó ní rabidun.

OHUN TÁ A RÍ KỌ́

Fún àwọn àkókò kan, báàgì táwọn ará ń pọ̀n sẹ́yìn gba àwọn ibi òkè gàgàrà yẹn ni wọ́n fi máa ń kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílẹ̀ Jámánì ń lò. Àmọ́, kì í ṣe ibi àwọn òkè gàgàrà yẹn nìkan ni wọ́n máa ń gbà. Títí di ọdún 1939, táwọn ọmọ ogun Jámánì gba ilẹ̀ Czechoslovakia, irú àwọn ọ̀nà bẹ́ẹ̀ tún wà láwọn ààlà orílẹ̀-èdè méjèèjì. Ní àwọn orílẹ̀-èdè míì tó bá ilẹ̀ Jámánì pààlà, irú bí ilẹ̀ Faransé, Netherlands àti Switzerland, àwọn ará tó wà ní ààlà ilẹ̀ méjèèjì máa ń forí la ikú kí wọ́n bàa lè fún àwọn ará wọn tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ni oúnjẹ tẹ̀mí.

Lónìí, ó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ nínú wa láti gba iye ìtẹ̀jáde Bíbélì tá a fẹ́ lónírúurú. Ì báà jẹ́ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba lo ti gba ìtẹ̀jáde tuntun tàbí ńṣe lo wà á jáde látorí ìkànnì jw.org, ǹjẹ́ kò ní dáa kó o ronú nípa iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ṣe kó tó tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́? Àwọn tó ṣètò ìtẹ̀jáde náà lè má gba àwọn òkè tí yìnyín bò kọjá lóru, àmọ́ iṣẹ́ takuntakun làwọn ará wa ń ṣe bí wọ́n ṣe ń lo ara wọn láti rí i pé àwọn ìtẹ̀jáde yìí tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́.

^ ìpínrọ̀ 3 Ìjọ tó wà nílùú Hirschberg ní àgbègbè Silesia ló ti sìn. Jelenia Góra ni wọ́n ń pe ìlú náà báyìí, ó sì wà ní apá gúúsù ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Poland.