Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  November 2013

Sísin Ọlọ́run Ni Oògùn Àìsàn Rẹ̀!

Sísin Ọlọ́run Ni Oògùn Àìsàn Rẹ̀!

Nígbà tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì wàásù dé ilé kan ní orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, ẹnu yà wọ́n gan-an nígbà tí wọ́n rí ọkùnrin kan lórí ibùsùn, èèyàn kékeré ni. Ọwọ́ rẹ̀ kúrú, ara rẹ̀ sì kéré gan-an. Nígbà tí wọ́n sọ ìlérí Ọlọ́run fún un pé, “àwọn ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe,” inú ọkùnrin náà dùn, ó sì rẹ́rìn-ín.—Aísá. 35:6.

Àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà wá mọ̀ pé ńṣe ni wọ́n bí ọkùnrin tó ń jẹ́ Onesmus yìí pẹ̀lú àìsàn kan tí kì í jẹ́ kí egungun lágbára, ìyẹn osteogenesis imperfecta. Egungun rẹ̀ gbẹgẹ́ débi pé nǹkan kékeré lè mú kó ṣẹ́. Nítorí pé kò tíì sí oògùn tó lè wo àìsàn náà, Onesmus ti gba kámú láti máa jẹ̀rora kí ó sì máa wà lórí kẹ̀kẹ́ àwọn aláàbọ̀ ara ní gbogbo ìyókù ayé rẹ̀.

Onesmus gbà pé kí wọ́n kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ ìyá rẹ̀ kò gbà pé kó máa lọ sí ìpàdé, nítorí ó wò ó pé ó ṣeé ṣe kó fara pa kí èyí sì dá kún ìrora rẹ̀. Nítorí náà, àwọn arákùnrin náà máa ń gba ohùn àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé sílẹ̀, wọ́n á sì mú un lọ fún Onesmus pé kó gbọ́ ọ. Lẹ́yìn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ fún oṣù márùn-ún, Onesmus pinnu pé òun á máa lọ sí àwọn ìpàdé láìka ìṣòro tó lè jẹ yọ sí.

Ǹjẹ́ lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni dá kún ìrora Onesmus? Rárá o, ńṣe ló dín in kù. Onesmus sọ pé: “Ńṣe ló máa ń dà bíi pé ìrora mi ń dín kù nígbà tí mo bá wà nípàdé.” Ó rò pé ẹ̀kọ́ tóun ń kọ́ ló ń mú kára tu òun. Ìyá Onesmus kíyè sí bí ìṣesí ọmọ rẹ̀ ṣe yí pa dà, inú rẹ̀ sì dùn débi pé ó gbà kí wọ́n kọ́ òun náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìyá Onesmus máa ń sọ pé, “Sísin Ọlọ́run ni oògùn àìsàn ọmọ mi.”

Láìpẹ́, Onesmus di akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ó ṣèrìbọmi, ó ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ báyìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lè gbé ọwọ́ rẹ̀ kan àti ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì, ó fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Onesmus fẹ́ ṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà, ṣùgbọ́n ó lọ́ tìkọ̀ láti gba fọ́ọ̀mù iṣẹ́ náà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó mọ̀ pé òun ò lè yí kẹ̀kẹ́ tóun ń lò, àfi kí ẹlòmíràn bá òun yí i. Nígbà tó sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún àwọn ará, wọ́n ṣèlérí pé àwọn á ràn án lọ́wọ́. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Wọ́n ran Onesmus lọ́wọ́ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

Irú ẹ̀dùn ọkàn yìí tún bá Onesmus nígbà tó fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àmọ́ nígbà tó yá, ẹsẹ ojoojúmọ́ kan fún un ní ìṣírí tó nílò. Ẹsẹ náà ni Sáàmù 34:8 tó sọ pé: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.” Lẹ́yìn tí Onesmus ṣàṣàrò lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, ó pinnu láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ní báyìí, ó ń fi ọjọ́ mẹ́rin wàásù lọ́sẹ̀, ó sì ní àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ní ọdún 2010, Onesmus lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà. Ẹ wo bí inú rẹ̀ ṣe dùn tó pé olùkọ́ rẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin méjì tó kọ́kọ́ wàásù fún un!

Onesmus ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ogójì ọdún báyìí, àwọn òbí rẹ̀ kò sì sí mọ́, ṣùgbọ́n àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ rẹ̀ ń pèsè ohun tó nílò lójoojúmọ́. Ó ń dúpẹ́ nítorí gbogbo ìbùkún tó ń rí gbà báyìí, ó sì ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí ‘kò ní sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé, àìsàn ń ṣe mí.’—Aísá. 33:24.