NÍGBÀ àkànṣe iṣẹ́ ìwàásù kan tó gba ọjọ́ mẹ́sàn-an gbáko ní oṣù August sí oṣù September ọdún 1929, àwọn oníwàásù tí iye wọn ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] pín ara wọn káàkiri orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Iye àwọn ìwé ńlá àti ìwé kékeré tí wọ́n pín fún àwọn èèyàn jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìlá àtààbọ̀ [250,000]. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àwọn apínwèé-ìsìn-kiri ló wà lára àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run yìí. Ẹ wo bí iye wọn ti yára pọ̀ tó! Ìtẹ̀jáde wa tó ń jẹ́ Bulletin * sọ pé “ó ṣòroó gbà gbọ́” pé iye àwọn aṣáájú-ọ̀nà lọ́dún 1927 ti di ìlọ́po mẹ́ta lọ́dún 1929.

Ní ìparí ọdún 1929, ọrọ̀ ajé àgbáyé ṣàdédé dẹnu kọlẹ̀. Ní òòjọ́ October 29, 1929, tí wọ́n wá ń pè ní Tuesday Burúkú, iye tí wọ́n ń ta àwọn ìpín ìdókòwò já wálẹ̀ pátápátá látọ̀dọ̀ àjọ ìdókòwò, ìyẹn New York Stock Exchange. Èyí ló fa Ìlọsílẹ̀ Gígadabú Nínú Ọrọ̀ Ajé kárí ayé. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé ìfowópamọ́ wọko gbèsè. Ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀ ló dáwọ́ iṣẹ́ dúró lóko wọn. Àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá kógbá sílé. Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn èèyàn ni iṣẹ́ bọ́ mọ́ lọ́wọ́. Nígbà kan lọ́dún 1933, ẹgbẹ̀rún kan ilé làwọn ayánilówó ń gbẹ́sẹ̀ lé lójoojúmọ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Báwo làwọn oníwàásù alákòókò kíkún ṣe ń gbọ́ bùkátà ara wọn nígbà yánpọnyánrin yẹn? Ọgbọ́n kan tí wọ́n dá ni pé wọ́n ń lo ilé alágbèérìn. Ẹni tó bá ń lo ọkọ̀ tí wọ́n ṣe ilé sẹ́yìn rẹ̀ tàbí ọkọ̀ àfiṣelé kò ní sanwó ilé àti owó orí, èyí sì mú kí ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà lè máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn lọ láìsí ìnáwó rẹpẹtẹ. * Dípò kí wọ́n máa gba yàrá sí òtẹ́ẹ̀lì nígbà àpéjọ àgbègbè, ilé alágbèérìn ni wọ́n máa ń lò. Lọ́dún 1934, ìtẹ̀jáde Bulletin ṣàlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣe irú ilé yìí tí á sì máa móoru nígbà òtútù, tí á ní omi, sítóòfù ìdáná àti ibùsùn tó ṣeé ká.

Kárí ayé, àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó já fáfá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ilé alágbèérìn fúnra wọn. Arákùnrin Victor Blackwell sọ pé, “Nóà kò kan ọkọ̀ ojú omi tẹ́lẹ̀ rí, èmi náà ò sì ṣe ọkọ̀ àfiṣelé kankan rí, mi ò tilẹ̀ mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe é.” Àmọ́, ó ṣe ọkọ̀ náà.

Wọ́n fẹ́ gbé ọkọ̀ àfiṣelé kan sọdá odò ní àkókò tí òjò máa ń pọ̀ ní orílẹ̀-èdè Íńdíà

Tọkọtaya Avery àti Lovenia Bristow ní ilé alágbèérìn kan. Arákùnrin Avery sọ pé: “Mò ń gbé ilé mi kiri bí ìgbín.” Arákùnrin àti Arábìnrin Bristow ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà pẹ̀lú tọkọtaya Harvey àti Anne Conrow, tó jẹ́ pé bébà ni wọ́n fi ṣe ara ilé alágbèérìn tiwọn. Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń gbé e kiri sì ni àjákù bébà máa ń jábọ́ lára rẹ̀. Arákùnrin Avery sọ pé: “Kó sẹ́ni tó rí irú ọkọ̀ àfiṣelé yìí rí ṣáájú ìgbà yẹn, kò sì sẹ́ni tó tíì rí irú rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn!” Àmọ́, ó fi kún un pé Arákùnrin àti Arábìnrin Conrow àtàwọn ọmọkùnrin wọn méjèèjì ni “ìdílé tó láyọ̀ jù lọ tí mo tíì rí rí.” Arákùnrin Harvey Conrow sọ pé: “A kò fìgbà kan ṣaláìní ohunkóhun tá a nílò, ọkàn wa balẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bó ṣe ń fìfẹ́ tọ́jú wa.” Nígbà tó yá, tọkọtaya Conrow àtàwọn ọmọ wọn méjèèjì lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n di míṣọ́nnárì, a sì rán wọn lọ sìn lórílẹ̀-èdè Peru.

Ńṣe ni tọkọtaya Giusto àti Vincenza Battaino náà ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tí Arábìnrin Vincenza lóyún, wọ́n sọ ọkọ̀ 1929 Model A Ford wọn di ilé tó  “dà bí òtẹ́ẹ̀lì” tá a bá fi wé àwọn àgọ́ tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bí ọmọbìnrin wọn, wọ́n ń bá iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n fẹ́ràn lọ, ìyẹn wíwàásù fáwọn ará Ítálì tó ń gbé ní Amẹ́ríkà.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tẹ́tí sí ìhìn rere náà, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí kò lówó lọ́wọ́ tí wọn kò sì níṣẹ́ lọ́wọ́ kì í lè fowó ṣètìlẹyìn fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n bá gbà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń fi onírúurú nǹkan tó bá owó ìwé náà mu ṣe pàṣípààrọ̀. Aṣáájú-ọ̀nà méjì kan ṣàkọsílẹ̀ onírúurú nǹkan mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64] táwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì fún wọn. Ńṣe ni ìwé náà “dà bí èyí tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀jà tó wà nínú ṣọ́ọ̀bù abúlé.”

Arákùnrin Fred Anderson pàdé àgbẹ̀ kan tó fi awò ojú tí ìyá rẹ̀ ń lò tẹ́lẹ̀ ṣe pàṣípààrọ̀ fún díẹ̀ lára àwọn ìwé wa. Nígbà tí arákùnrin náà dé oko míì, ọkùnrin kan tó fẹ́ láti gba àwọn ìwé wa sọ pé, “Mi ò ní awò ojú tí mo lè fi kà wọ́n.” Àmọ́, nígbà tí Arákùnrin Fred fún un ní awò ojú aládùúgbò rẹ̀ yẹn, geerege ló ka àwọn ìwé náà, ó sì ṣètìlẹyìn fún àwọn ìwé àti awò ojú náà.

Arákùnrin Herbert Abbott máa ń gbé àgò adìyẹ sẹ́yìn ọkọ̀ rẹ̀. Tó bá ti rí adìyẹ mẹ́ta tàbí mẹ́rin gbà, á lọ tà wọ́n lọ́jà, á sì fi owó náà ra epo sínú ọkọ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ a rí ìgbà tí owó fẹ́rẹ̀ẹ́ tán pátápátá lọ́wọ́ wa? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ a kì í jẹ́ kí ìyẹn dá wa dúró. Tí epo bá wà nínú ọkọ̀ wa, àá máa bá iṣẹ́ lọ, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà máa pèsè fún wa.”

Ohun tó jẹ́ kí àwọn èèyàn Jèhófà lè fara da àwọn ọdún tí nǹkan nira yẹn ni pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, wọ́n sì ti pinnu pé àwọn kò ní dáwọ́ iṣẹ́ dúró. Nígbà òjò àti ìjì líle kan, bí tọkọtaya Maxwell àti Emmy Lewis ṣe sá jáde nínú ọkọ̀ àfiṣelé wọn ni igi kan wó lu ọkọ̀ náà, tó sì gé e sí méjì. Arákùnrin Maxwell sọ pé: “Irú àwọn nǹkan yìí kì í ṣe ìdíwọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ lásán la kà wọ́n sí, a kò fìgbà kan ronú pé a máa dáwọ́ iṣẹ́ dúró. Iṣẹ́ pọ̀ tó yẹ ká ṣe, a sì ti pinnu pé a máa ṣe é.” Láìbẹ̀rù, tọkọtaya Lewis tún ilé alágbèérìn wọn kọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ wọn.

Ní àkókò wa tí nǹkan ṣòro yìí, irú ẹ̀mí yìí ni ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní, torí à ń fi ìtara lo ara wa fún àwọn èèyàn. Ó ṣe tán, àwa náà ti pinnu bíi ti àwọn tó kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà yẹn pé a ó máa wàásù lọ títí Jèhófà á fi sọ pé ó tó.

^ ìpínrọ̀ 3 Òun là ń pè ní Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa nísinsìnyí.

^ ìpínrọ̀ 5 Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn aṣáájú-ọ̀nà ni kì í ṣe iṣẹ́ míì yàtọ̀ sí iṣẹ́ ìwàásù. Wọ́n máa ń rí àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì gbà ní ẹ̀dínwó, wọ́n á fún àwọn èèyàn, wọ́n á sì fi ìtìlẹ́yìn owó táwọn èèyàn bá ṣe gbọ́ bùkátà ara wọn.