Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Báwo La Ṣe Lè Máa Ní “Ẹ̀mí Ìdúródeni”?

Báwo La Ṣe Lè Máa Ní “Ẹ̀mí Ìdúródeni”?

“Èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn.”—MÍKÀ 7:7.

1. Kí ló lè mú ká di aláìnísùúrù?

ÌGBÀ tí Ìjọba Mèsáyà bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 ni àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò Sátánì bẹ̀rẹ̀. Jésù bá Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jagun ní ọ̀run, ó sì fi wọ́n sọ̀kò sí sàkáání ayé. (Ka Ìṣípayá 12:7-9.) Sátánì mọ̀ pé “sáà àkókò kúkúrú” ni òun ní. (Ìṣí. 12:12) Àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá látìgbà tí “sáà àkókò” náà ti bẹ̀rẹ̀, èyí sì lè mú kí àwọn kan máa rò pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn náà ti gùn jù. Bá a ṣe ń dúró de Jèhófà pé kó gbé ìgbésẹ̀, ṣé a ò ti di aláìnísùúrù?

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Àìnísùúrù léwu, torí pé ó lè mú ká hùwà láìronú jinlẹ̀. Báwo la ṣe lè máa ní ẹ̀mí ìdúródeni? Àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé ó máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: (1) Kí la lè kọ́ nípa sùúrù látinú àpẹẹrẹ wòlíì Míkà? (2) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló máa jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò tá a fi ń dúró ti parí? (3) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì sùúrù Jèhófà?

KÍ LA LÈ KỌ́ LÁTINÚ ÀPẸẸRẸ MÍKÀ?

3. Báwo ni nǹkan ṣe rí ní Ísírẹ́lì nígbà ayé Míkà?

3 Ka Míkà 7:2-6. Míkà tó jẹ́ wòlíì Jèhófà rí i tí ìjọsìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí Ọlọ́run túbọ̀ ń jó rẹ̀yìn títí tí ipò wọn fi wà burú jáì nígbà àkóso Áhásì Ọba búburú. Míkà fi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ yẹn wé “ẹ̀gún ọ̀gàn” àti “ọgbà ẹ̀gún.” Bí ọgbà tí wọ́n fi igi ẹ̀gún ṣe tàbí ẹ̀gún ọ̀gàn ti máa ń ṣe ẹni tó bá fara kàn wọ́n léṣe, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì burúkú yẹn ṣe ń ṣèpalára fún ẹnikẹ́ni tó bá ní àjọṣe pẹ̀lú wọn. Ìwà ìbàjẹ́ wọn pọ̀ débi pé àwọn ìdílé pàápàá ń tú ká. Míkà mọ̀ pé òun ò lè yí bí ipò nǹkan ṣe rí pa dà, torí náà, ó sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún Jèhófà. Ó wá ń fi sùúrù dúró de Jèhófà pé kó ṣe nǹkan sí ọ̀ràn náà. Ó dá Míkà lójú pé Jèhófà máa dá sí i nígbà tí àkókò bá tó lójú Rẹ̀.

4. Àwọn ìṣòro wo là ń dojú kọ?

 4 Bíi ti Míkà, àárín àwọn tí kò mọ̀ ju tára wọn là ń gbé. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ “aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tím. 3:2, 3) Ó máa ń dùn wá nígbà tí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ iléèwé wa àti àwọn aládùúgbò wa bá hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan. Àmọ́ ìṣòro táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan ń dojú kọ le ju èyí lọ. Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa dojú kọ àtakò láti ọ̀dọ̀ ìdílé wọn, ó sì lo irú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Míkà 7:6 láti ṣàlàyé ipa tí iṣẹ́ rẹ̀ máa ní lórí àwọn èèyàn. Jésù sọ pé: “Mo wá láti fa ìpínyà, láti pín ọkùnrin níyà sí baba rẹ̀, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, àti ọ̀dọ́ aya sí ìyá ọkọ rẹ̀. Ní tòótọ́, àwọn ọ̀tá ènìyàn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn agbo ilé òun fúnra rẹ̀.” (Mát. 10:35, 36) Kò rọrùn rárá láti fara dà á nígbà tí àwọn ará ilé wa tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà bá ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ń ta kò wá! Tá a bá dojú kọ irú àdánwò yìí, ẹ má ṣe jẹ́ ká juwọ́ sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká dúró ṣinṣin ká sì máa fi sùúrù dúró de Jèhófà pé kó yanjú ọ̀ràn náà. Tá a bá ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ nígbà gbogbo, á fún wa ní okun àti ọgbọ́n ká lè fara dà á.

5, 6. Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún Míkà, àmọ́ kí ni Míkà ò rí?

5 Jèhófà bù kún Míkà nítorí pé Míkà ní sùúrù. Ojú Míkà ló ṣe nígbà tí Áhásì Ọba kú, tí ìṣàkóso búburú rẹ̀ sì dópin. Ó rí i tí ọmọ Áhásì, ìyẹn Hesekáyà tó jẹ́ ọba rere, gorí ìtẹ́ tó sì mú ìjọsìn mímọ́ bọ̀ sípò. Bákan náà, ìdájọ́ Jèhófà tí Míkà kéde lòdì sí àwọn ará Samáríà ṣẹ nígbà tí àwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun ìjọba Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá.—Míkà 1:6.

6 Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà mí sí Míkà láti sọ tẹ́lẹ̀ ló ṣẹ lójú Míkà. Bí àpẹẹrẹ, Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ . . . òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ síbẹ̀. Dájúdájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà.’” (Míkà 4:1, 2) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Míkà ti kú ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí tó ṣẹ. Síbẹ̀, Míkà pinnu pé òun máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà títí di ọjọ́ ikú òun, láìka ohunkóhun tí àwọn èèyàn bá ṣe sí. Nítorí náà, Míkà sọ pé: “Gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Míkà 4:5) Ohun tó jẹ́ kí Míkà lè fi sùúrù dúró ní àkókò tí nǹkan le koko yẹn ni pé, ó dá a lójú láìsí iyè méjì kankan pé Jèhófà máa mú gbogbo ìlérí Rẹ̀ ṣẹ. Wòlíì olóòótọ́ yìí gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

7, 8. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (b) Kí ló máa mú kí àkókò yára lọ?

7 Ṣé àwa náà ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé yìí nínú Jèhófà? Ìdí pàtàkì wà tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. A ti rí bí àsọtẹ́lẹ̀ Míkà ṣe ń ṣẹ lójú wa. Ní “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n ti rọ́ lọ sí “òkè ńlá ilé Jèhófà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n wá látinú àwọn orílẹ̀-èdè tó ń figa gbága, àwọn olùjọsìn yìí ti “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀,” wọn kò sì “kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” (Míkà 4:3) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a wà lára àwọn èèyàn Jèhófà tó ní àlàáfíà!

8 Kò burú pé ó ń ṣe wá bíi kí Jèhófà ti fòpin sí ètò búburú yìí. Àmọ́ ká tó lè fi sùúrù dúró, ó ṣe pàtàkì pé ká máa wo nǹkan bí Jèhófà ṣe ń wò ó. Ó ti dá ọjọ́ tó máa ṣèdájọ́ aráyé “nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò,” ìyẹn Jésù Kristi. (Ìṣe 17:31)  Ṣùgbọ́n kó tó dìgbà yẹn, Ọlọ́run ń fún gbogbo onírúurú èèyàn láǹfààní láti gba “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́,” kí wọ́n sì ṣe ohun tó bá ìmọ̀ náà mu kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Ẹ̀mí àwọn èèyàn wà nínú ewu. (Ka 1 Tímótì 2:3, 4.) Tá a bá ń fi gbogbo àkókò wa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, ńṣe ni àkókò tó ṣẹ́ kù kí ìdájọ́ Jèhófà dé á túbọ̀ yára kọjá lọ. Láìpẹ́, àní lójijì, ni ọjọ́ náà máa dé. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó pé a ti ṣiṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà kárakára!

ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ WO LÓ JẸ́ ÀMÌ PÉ ÀKÓKÒ TÁ A FI Ń DÚRÓ TI PARÍ?

9-11. Ṣé ọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Tẹsalóníkà 5:3 ti ṣẹ? Ṣàlàyé.

9 Ka 1 Tẹsalóníkà 5:1-3. Láìpẹ́ sí ìgbà tá a wà yìí, àwọn orílẹ̀-èdè máa sọ pé, “Àlàáfíà àti ààbò!” Tá ò bá fẹ́ kí ìkéde yìí bá wa lójijì, a gbọ́dọ̀ “wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.” (1 Tẹs. 5:6) Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ ká mọ̀ pé kò ní pẹ́ mọ́ tá a fi máa gbọ́ ìkéde yìí. Èyí á jẹ́ ká lè wà lójúfò nínú ìjọsìn Ọlọ́run.

10 Ní ìparí ọ̀kọ̀ọ̀kan ogun àgbáyé méjì tó ti jà, àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè sọ pé àwọn ń fẹ́ àlàáfíà. Lẹ́yìn ogun àgbáyé kìíní, wọ́n dá àjọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀, wọ́n sì retí pé á mú àlàáfíà wá. Lẹ́yìn náà, nígbà tí ogun àgbáyé kejì parí, gbogbo aráyé retí pé àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè máa mú àlàáfíà wá sáyé. Àwọn ìjọba àti àwọn aṣáájú ẹ̀sìn retí pé kí àwọn àjọ yẹn mú kí aráyé máa gbé ní àlàáfíà. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1986, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé kí wọ́n pòkìkí Ọdún Àlàáfíà Kárí Ayé. Lọ́dún yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn olórí orílẹ̀-èdè àti aṣáájú ẹ̀sìn lọ sí ìlú Assisi, lórílẹ̀-èdè Ítálì kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ aṣáájú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì láti gbàdúrà fún àlàáfíà.

11 Àmọ́ ìkéde àlàáfíà àti ààbò yẹn, àti àwọn míì tó jọ ọ́, kò mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú 1 Tẹsalóníkà 5:3 ṣẹ. Kí nìdí? Ìdí ni pé “ìparun òjijì” tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ kò tíì wáyé.

12. Kí la mọ̀ nípa ìkéde “Àlàáfíà àti ààbò”?

 12 Lọ́jọ́ iwájú, ta ló máa ṣe ìkéde pàtàkì yìí nípa “Àlàáfíà àti ààbò”? Ipa wo ni àwọn aṣáájú Ṣọ́ọ̀ṣì àti ti àwọn ẹ̀sìn míì máa kó? Báwo ni àwọn olórí ìjọba lóríṣiríṣi ṣe máa lọ́wọ́ nínú ìkéde náà? Bíbélì ò sọ fún wa. Ohun tá a mọ̀ ni pé, ọ̀nà yòówù kí ìkéde yìí gbà wáyé àti bó ti wù kó dà bí òtítọ́ tó, ẹ̀tàn lásán ló máa jẹ́. Sátánì ni yóò ṣì máa ṣàkóso ètò ògbólógbòó yìí. Ètò náà ti bàjẹ́ pátápátá, kò sì ní yí pa dà. Ẹ wo bó ṣe máa burú tó tí ẹnikẹ́ni nínú wa bá gba àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí Sátánì ń tàn kálẹ̀ gbọ́, tó sì lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú ayé!

13. Kí nìdí tí àwọn áńgẹ́lì fi di àwọn ẹ̀fúùfù ìparun mú?

13 Ka Ìṣípayá 7:1-4. Bá a ṣe ń dúró de ìmúṣẹ 1 Tẹsalóníkà 5:3, ńṣe ni àwọn áńgẹ́lì alágbára di àwọn ẹ̀fúùfù ìparun ti ìpọ́njú ńlá mú. Kí ni wọ́n ń dúró dè? Àpọ́sítélì Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan, ìyẹn fífi èdìdì ìkẹyìn di àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ “àwọn ẹrú Ọlọ́run wa.” * Nígbà tí wọ́n bá ti fi èdìdì ìkẹyìn dì wọ́n tán, àwọn áńgẹ́lì náà á wá tú ẹ̀fúùfù ìparun sílẹ̀. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀?

14. Kí ló fi hàn pé ìparun Bábílónì Ńlá ti sún mọ́lé?

14 Bábílónì Ńlá, ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé máa pa run, ohun tó sì tọ́ sí i nìyẹn. “Àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n” kò ní lè ràn án lọ́wọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, à ń rí àwọn àmì tó fi hàn pé ìparun rẹ̀ ti sún mọ́lé. (Ìṣí. 16:12; 17:15-18; 18:7, 8, 21) Kódà, à ń rí àmì pé àwọn tó ń tì í lẹ́yìn ti ń dín kù, nítorí à ń gbọ́ àwọn ìròyìn nípa bí àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń fẹ̀sùn kan ìsìn àti àwọn aṣáájú rẹ̀. Àmọ́ àwọn aṣáájú Bábílónì Ńlá ò gbà pé ewu ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí àwọn. Ẹ ò rí i pé ńṣe ni wọ́n ń tan ara wọn jẹ! Lẹ́yìn ìkéde “Àlàáfíà àti ààbò!” àwọn olóṣèlú inú ètò Sátánì máa gbéjà ko ìsìn èké lójijì, wọ́n á sì pa á run. A ò ní pa dà rí Bábílónì Ńlá mọ́ láé! Dájúdájú, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí tó nǹkan téèyàn ń fi sùúrù dúró dè.—Ìṣí. 18:8, 10.

BÁWO LA ṢE LÈ FI HÀN PÉ A MỌRÍRÌ SÙÚRÙ ỌLỌ́RUN?

15. Kí nìdí tí Jèhófà ṣì fi ń ní sùúrù kó tó gbé ìgbésẹ̀?

15 Láìka bí àwọn èèyàn ṣe ń tàbùkù sí orúkọ Jèhófà, ó ṣì ń fi sùúrù dúró de àsìkò tó tọ́ láti gbé ìgbésẹ̀. Jèhófà ò fẹ́ kí olóòótọ́ ọkàn kankan pa run. (2 Pét. 3:9, 10) Ṣé èrò tiwa náà nìyẹn? Kí ọjọ́ Jèhófà tó dé, a lè fi hàn pé a mọrírì sùúrù rẹ̀ tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tá a fẹ́ jíròrò yìí.

16, 17. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ láti ran àwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́? (b) Kí nìdí tí àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ fi gbọ́dọ̀ tètè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà?

16 Ran àwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́. Jésù sọ pé ayọ̀ máa ń wà lọ́run tí a bá pa dà rí ẹyọ àgùntàn kan tó ti sọ nù. (Mát. 18:14; Lúùkù 15:3-7) Èyí fi hàn kedere pé Jèhófà bìkítà gan-an nípa àwọn tó ti fìfẹ́ hàn sí orúkọ rẹ̀, kódà bí wọn ò tilẹ̀ sìn ín ní lọ́wọ́lọ́wọ́. Nígbà tá a bá ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti pa dà wá sínú ìjọ, ńṣe là ń mú kí Jèhófà àti àwọn áńgẹ́lì máa yọ̀.

17 Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, ṣé o wà lára àwọn tí kò sin Ọlọ́run tọkàntara? Bóyá torí pé ẹnì kan nínú ìjọ ṣe nǹkan tó dùn ẹ́ lo ṣe sọ pé o kò ní dara pọ̀ mọ́ ètò Jèhófà mọ́. Ó ṣeé ṣe kó ti pẹ́ díẹ̀ tí ọ̀ràn náà ti ṣẹlẹ̀, torí náà bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ìgbésí ayé mi ti wá túbọ̀ dára, tí ayọ̀ mi sì pọ̀ sí i? Ṣé Jèhófà ló ṣẹ̀ mí ni àbí èèyàn aláìpé? Ǹjẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tiẹ̀ ti ṣe ohun kan tó pa mí lára rí?’ Ká sòótọ́, ohun rere ni  Jèhófà máa ń ṣe fún wa nígbà gbogbo. Kódà ó ṣì ń jẹ́ ká gbádùn àwọn nǹkan rere tó ń pèsè, bá ò tiẹ̀ máa ṣe àwọn ohun tó bá ìyàsímímọ́ wa mu. (Ják. 1:16, 17) Ọjọ́ Jèhófà máa dé láìpẹ́. Àkókò nìyí láti pa dà sọ́dọ̀ Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa àti sínú ìjọ tó jẹ́ ibì kan ṣoṣo tí ààbò wà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.—Diu. 33:27; Héb. 10:24, 25.

Àwọn èèyàn Jèhófà ń sa gbogbo ipá wọn láti ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 16, 17)

18. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣètìlẹyìn fún àwọn tó ń mú ipò iwájú?

18 Fi ìṣòtítọ́ ṣètìlẹyìn fún àwọn tó ń mú ipò iwájú. Olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ wa ni Jèhófà, ó ń tọ́ wa sọ́nà, ó sì ń dáàbò bò wá. Ó ti yan Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ Olórí Olùṣọ́ Àgùntàn agbo rẹ̀. (1 Pét. 5:4) Ní àwọn ìjọ tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000], àwọn alàgbà ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àgùntàn Ọlọ́run. (Ìṣe 20:28) Tá a bá ń fi ìṣòtítọ́ ṣètìlẹyìn fún àwọn tí Jèhófà yàn láti máa mú ipò iwájú, ńṣe là ń fi han Jèhófà àti Jésù pé a mọrírì gbogbo nǹkan tí wọ́n ṣe fún wa.

19. Báwo la ṣe lè sún mọ́ ara wa pẹ́kípẹ́kí?

19 Ẹ jẹ́ ká ṣe ara wa lọ́kan. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá gbéjà ko ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun tó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, ńṣe làwọn ọmọ ogun náà á túbọ̀ sún mọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí, ìyẹn ni pé wọ́n á ṣe ara wọn lọ́kan. Èyí máa ń jẹ́ kó ṣòro fún àwọn ọ̀tá láti wọ àárín wọn. Ńṣe ni Sátánì túbọ̀ ń gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run. Àkókò yìí kọ́ ló yẹ ká máa bára wa jà. Ní báyìí, ńṣe ló yẹ ká ṣe ara wa lọ́kan, ká máa gbójú fo àìpé àwọn ará wa, ká sì gbà pé bí Jèhófà ṣe ń darí wa ló dára jù lọ.

Ìsinsìnyí ló yẹ ká sún mọ́ ara wa pẹ́kípẹ́kí, ká má ṣe jẹ́ kí Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù wọ àárín wa (Wo ìpínrọ̀ 19)

20. Kí ló yẹ ká máa ṣe báyìí?

20 Kí gbogbo wa yáa wà lójúfò nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ká sì máa ní ẹ̀mí ìdúródeni. Ẹ jẹ́ ká máa fi sùúrù dúró de ìkéde “Àlàáfíà àti ààbò!” àti fífi èdìdì ìkẹyìn di àwọn àyànfẹ́. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin náà máa tú àwọn ẹ̀fúùfù ìparun sílẹ̀, Bábílónì Ńlá á sì pa run. Bá a ṣe ń dúró pé kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa gba ìtọ́ni tí àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ètò Jèhófà ń fún wa. Ẹ jẹ́ ká sún mọ́ ara wa pẹ́kípẹ́kí, ká má ṣe jẹ́ kí Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ wọ àárín wa! Àkókò rèé fún wa láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí onísáàmù kan sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígboyà, kí ọkàn-àyà yín sì jẹ́ alágbára, gbogbo ẹ̀yin tí ń dúró de Jèhófà.”—Sm. 31:24.

^ ìpínrọ̀ 13 Láti mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín fífi èdìdì ìṣáájú àti èdìdì ìkẹyìn di àwọn ẹni àmì òróró, wo Ilé Ìṣọ́ January 1, 2007, ojú ìwé  30-31.