Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  November 2013

Ẹ̀yin Olùṣọ́ Àgùntàn, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá náà

Ẹ̀yin Olùṣọ́ Àgùntàn, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá náà

“Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.”—1 PÉT. 2:21.

1, 2. (a) Kí ló máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀ tí wọ́n bá tọ́jú àwọn àgùntàn dáadáa? (b) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà ayé Jésù fi dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn?

BÍ OLÙṢỌ́ àgùntàn bá ń bójú tó agbo ẹran rẹ̀ bó ṣe yẹ, àwọn àgùntàn máa ń dàgbà dáadáa wọ́n sì máa ń pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn àgùntàn ṣe sọ, “tí ọkùnrin kan bá ń mú àwọn ẹran rẹ̀ lọ jẹko àmọ́ tí kì í ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn ọdún mélòó kan àwọn àgùntàn tó lárùn tí kò sì lè mówó wá ló máa ní.” Àmọ́ tí olùṣọ́ àgùntàn bá tọ́jú àwọn àgùntàn rẹ̀ dáadáa, ara àwọn ẹran náà á le dáadáa.

2 Bí ìtọ́jú àti àkíyèsí tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ń fún àgùntàn kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ Ọlọ́run bá ṣe pọ̀ tó máa nípa lórí bí àwọn ará ìjọ á ṣe máa ṣe dáadáa sí nínú ìjọsìn Ọlọ́run. O lè rántí bí àánú àwọn èèyàn rẹpẹtẹ ṣe ṣe Jésù torí pé “a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mát. 9:36) Kí nìdí tí wọ́n fi wà nínú irú ipò tó ń bani nínú jẹ́ yìí? Ìdí ni pé àwọn tó jẹ́ ojúṣe wọn láti máa kọ́ àwọn èèyàn náà ní Òfin Ọlọ́run ti di òǹrorò, wọ́n ń béèrè ohun tí kò yẹ, wọ́n sì jẹ́ alágàbàgebè. Kàkà kí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn nílẹ̀ Ísírẹ́lì máa fún àwọn àgùntàn Ọlọ́run tó wà níkàáwọ́ wọn lóúnjẹ kí wọ́n sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́, ńṣe ni wọ́n di “àwọn ẹrù wíwúwo” lé èjìká àwọn èèyàn náà.—Mát. 23:4.

3. Kí ló yẹ káwọn alàgbà ìjọ mọ̀ bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ?

3 Lóde òní, iṣẹ́ kékeré kọ́ ló wà lọ́rùn àwọn olùṣọ́ àgùntàn, ìyẹn àwọn alàgbà tá a yàn sípò. Àwọn  àgùntàn tó wà nínú agbo tí wọ́n ń bójú tó jẹ́ ti Jèhófà àti ti Jésù tó sọ pé òun ni “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà.” (Jòh. 10:11) Jésù ti fi “ẹ̀jẹ̀ iyebíye” ara rẹ̀ ra àwọn àgùntàn náà “ní iye kan.” (1 Kọ́r. 6:20; 1 Pét. 1:18, 19) Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn àgùntàn náà gan-an débi pé ó fínnúfíndọ̀ fẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ fún wọn. Àwọn alàgbà ní láti máa rántí pé wọ́n jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn lábẹ́ àbójútó Ọmọ Ọlọ́run, ìyẹn Jésù Kristi tó nífẹ̀ẹ́ wa. Òun ni “olùṣọ́ àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn.”—Héb. 13:20.

4. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Látàrí èyí, báwo ló ṣe yẹ kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ìjọ máa ṣe sí àwọn àgùntàn Ọlọ́run? Bíbélì rọ àwọn ará ìjọ pé kí wọ́n “jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín” wọn. Ó tún gba àwọn alàgbà níyànjú pé kí wọ́n má ṣe máa “jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí.” (Héb. 13:17; ka 1 Pétérù 5:2, 3.) Báwo wá ni àwọn alàgbà á ṣe máa múpò iwájú tí wọ́n kò sì ní jẹ olúwa lé agbo Ọlọ́run lórí? Ká sọ ọ́ lọ́nà míì, báwo ni àwọn alàgbà ṣe máa bójú tó àwọn àgùntàn láìlo àṣẹ tí Ọlọ́run fún wọn nílòkulò?

‘OÓKAN ÀYÀ RẸ̀ NI YÓÒ GBÉ WỌN SÍ’

5. Kí ni àpèjúwe tó wà ní Aísáyà 40:11 jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?

5 Wòlíì Aísáyà sọ nípa Jèhófà pé: “Bí olùṣọ́ àgùntàn ni yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Apá rẹ̀ ni yóò fi kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọpọ̀; oókan àyà rẹ̀ sì ni yóò gbé wọn sí. Àwọn tí ń fọ́mọ lọ́mú ni yóò máa rọra dà.” (Aísá. 40:11) Ohun tí àpèjúwe yìí ń sọ nípa Jèhófà ni pé ó máa ń bójú tó àwọn aláìlera àtàwọn tó jẹ́ ẹlẹgẹ́ nínú ìjọ. Bíi ti olùṣọ́ àgùntàn tó mọ ohun tí àgùntàn kọ̀ọ̀kan nílò nínú agbo tó sì ṣe tán láti bójú tó wọn, Jèhófà mọ ìtọ́jú tí àwọn ará ìjọ nílò, ó sì ń fẹ́ láti pèsè rẹ̀ fún wọn. Bí olùṣọ́ àgùntàn kan ṣe máa ń gbé àṣẹ̀ṣẹ̀bí ọmọ àgùntàn mọ́ àyà nígbà tó bá di dandan, ni Jèhófà tó jẹ́ “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” ṣe máa ń gbé wa nígbà àdánwò. Ó máa tù wá nínú nígbà tá a bá dojú kọ ìdánwò ńlá tàbí tá a bá nílò ohun kan lákànṣe.—2 Kọ́r. 1:3, 4.

6. Báwo ni alàgbà kan ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà tó yàn án sípò olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ?

6 Ẹ wo ẹ̀kọ́ pàtàkì tí olùṣọ́ àgùntàn kan nínú ìjọ lè kọ́ lára Bàbá wa ọ̀run! Bíi ti Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ máa pèsè ohun tí àwọn àgùntàn nílò. Bí alàgbà kan bá mọ ìṣòro tó dojú kọ àwọn ará ìjọ àti ohun tó ń fẹ́ àbójútó ní kíákíá, á lè fún àwọn ará ìjọ ní ìṣírí àti ìtìlẹ́yìn tó yẹ. (Òwe 27:23) Ó ṣe kedere pé alàgbà kan gbọ́dọ̀ máa bá àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ sọ̀rọ̀ déédéé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní máa tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀, síbẹ̀ á máa fọkàn sí ohun tó ń rí àtèyí tó ń gbọ́ nínú ìjọ, á sì máa fìfẹ́ yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti “ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlera.”—Ìṣe 20:35; 1 Tẹs. 4:11.

7. (a) Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe sáwọn àgùntàn Ọlọ́run nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì àti Jeremáyà? (b) Kí la lè rí kọ́ nínú ẹ̀bi tí Jèhófà dá àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí kò ṣòótọ́?

7 Ronú nípa ìwà tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí Ọlọ́run dá lẹ́bi ń hù. Nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì àti Jeremáyà, Jèhófà dẹ́bi fún àwọn tó yẹ kí wọ́n bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀ dáadáa ṣùgbọ́n tí wọn kò bójú tó wọ́n. Nígbà tí wọ́n fi àwọn àgùntàn náà sílẹ̀ láì dáàbò bò wọ́n, àwọn ẹranko ẹhànnà pa lára wọn, wọ́n sì tú wọn ká. Kàkà kí wọ́n máa bọ́ àwọn àgùntàn náà, ńṣe làwọn olùṣọ́ àgùntàn ń fi wọ́n ṣèfà jẹ tí wọ́n sì “ń bọ́ ara wọn.” (Ìsík. 34:7-10; Jer. 23:1) Ó bá a mu tá a bá sọ pé bí Ọlọ́run ṣe dẹ́bi fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn yẹn jẹ́ ìbáwí fún àwọn olórí ṣọ́ọ̀ṣì. Àmọ́, ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn alàgbà ìjọ máa fìfẹ́ bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà lọ́nà tó tọ́.

 “MO FI ÀWÒṢE LÉLẸ̀ FÚN YÍN”

8. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ nípa bá a ṣe ń tọ́ni sọ́nà?

8 Nítorí àìpé ẹ̀dá, àwọn kan lára àwọn àgùntàn Ọlọ́run lè má tètè lóye ohun tí Jèhófà ní kí wọ́n ṣe. Wọ́n lè má ṣe ohun tó bá ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ mu tàbí kí wọ́n ṣe nǹkan lọ́nà tó fi hàn pé òtítọ́ kò jinlẹ̀ nínú wọn. Kí làwọn alàgbà máa ṣe? Ó yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó ní sùúrù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tí wọ́n fẹ́ mọ ẹni tó máa ní ipò tó ga jù lọ láàárín wọn nínú Ìjọba Ọlọ́run. Jésù ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn sú òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló n kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nìṣó, ó sì ń fún wọn ní ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ nípa bí wọ́n ṣe lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (Lúùkù 9:46-48; 22:24-27) Jésù wẹ ẹsẹ̀ wọn, ó sì fìyẹn kọ́ wọn ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ìwà tó yẹ kí àwọn alábòójútó ìjọ ní.—Ka Jòhánù 13:12-15; 1 Pét. 2:21.

9. Èrò wo ni Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní?

9 Èrò Jésù nípa ojúṣe àwọn olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ yàtọ̀ sí èrò tí Jákọ́bù àti Jòhánù ní nígbà kan. Àwọn àpọ́sítélì méjì yìí ń wá ipò ńlá nínú Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ Jésù yí èrò wọn pa dà, ó ní: “Ẹ mọ̀ pé àwọn olùṣàkóso orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn ènìyàn ńlá a sì máa lo ọlá àṣẹ lórí wọn. Báyìí kọ́ ni láàárín yín; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín.” (Mát. 20:25, 26) Àwọn àpọ́sítélì náà ní láti dènà bó ṣe ń wù wọ́n láti “jẹ olúwa lórí” àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tàbí kí wọ́n máa pàṣẹ fún àwọn èèyàn.

10. Báwo ni Jésù ṣe fẹ́ káwọn alàgbà máa ṣe sí àwọn àgùntàn Ọlọ́run, àpẹẹrẹ wo sì ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí?

10 Jésù ń fẹ́ káwọn alàgbà máa ṣe sí àwọn àgùntàn Ọlọ́run bóun ṣe ṣe sí wọn. Wọ́n gbọ́dọ̀ múra tán láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọn kò ní jẹ ọ̀gá lé wọn lórí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nírú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yẹn, nítorí ó sọ fún àwọn àgbà ọkùnrin ní ìjọ Éfésù pé: “Ẹ̀yin mọ̀ dunjú, bí ó ti jẹ́ pé láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mo dé sí àgbègbè Éṣíà ni mo ti wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àkókò, tí mo ń sìnrú fún Olúwa pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú títóbi jù lọ.” Àpọ́sítélì yìí fẹ́ kí àwọn alàgbà yẹn ran àwọn yòókù lọ́wọ́ tọkàntọkàn pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀. Ó sọ pé: “Mo ti fi hàn yín nínú ohun gbogbo pé nípa ṣíṣe òpò lọ́nà yìí, ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlera.” (Ìṣe 20:18, 19, 35) Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé òun kò jẹ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ kí wọ́n lè ní ìdùnnú. (2 Kọ́r. 1:24) Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn alàgbà òde òní nípa béèyàn ṣe lè níwà ìrẹ̀lẹ̀, kó sì máa ṣiṣẹ́ kára.

‘DI Ọ̀RỌ̀ TÓ ṢEÉ GBÍYÈ LÉ MÚ ṢINṢIN’

11, 12. Báwo ni alàgbà kan ṣe lè ran onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu?

11 Alàgbà ìjọ gbọ́dọ̀ ‘di ọ̀rọ̀ tó ṣeé gbíyè lé mú ṣinṣin ní ti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.’ (Títù 1:9) Àmọ́, ó ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú “ẹ̀mí ìwà tútù.” (Gál. 6:1) Kàkà kó máa gbìyànjú láti fipá mú àwọn ará ìjọ ṣe nǹkan, ńṣe ni olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ máa ń ro bó ṣe máa pàrọwà fún wọn. Alàgbà kan lè fa àwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́ yọ fún arákùnrin kan pé kó gbé wọn yẹ̀ wò nígbà tó bá fẹ́ ṣe ìpinnu tó ṣe pàtàkì. Wọ́n sì lè jọ ṣàyẹ̀wò ohun tí ètò Ọlọ́run ti tẹ̀ jáde lórí kókó náà. Alàgbà náà tún lè rọ ẹni náà láti ronú lórí ipa tí àwọn ohun tó bá ṣe máa ní lórí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Ó lè tẹnu mọ́ ọn fún arákùnrin náà bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn fi àdúrà wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run kéèyàn tó ṣe ìpinnu. (Òwe 3:5, 6) Lẹ́yìn tí alàgbà náà bá ti bá onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yìí jíròrò tán, á wá jẹ́ kó dá ṣèpinnu fúnra rẹ̀.—Róòmù 14:1-4.

12 Àṣẹ tí àwọn alàgbà ìjọ ní kò ju èyí tí Bíbélì fún wọn lọ. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n lo Bíbélì lọ́nà tó já fáfá, kí  wọ́n sì di ohun tó sọ mú ṣinṣin. Tí àwọn alàgbà bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní jẹ́ kí wọ́n ṣi agbára lò. Ó ṣe tán, wọ́n kàn jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ ni, ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ ló máa jíhìn fún Jèhófà àti Jésù nítorí ìpinnu tó bá ṣe.—Gál. 6:5, 7, 8.

“ÀPẸẸRẸ FÚN AGBO”

Àwọn alàgbà máa ń ran ìdílé wọn lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 13)

13, 14. Àwọn ọ̀nà wo ni alàgbà kan ní láti gbà jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo Ọlọ́run?

13 Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù ti gba àwọn alàgbà ìjọ nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe ‘jẹ olúwa lé àwọn tó wà níkàáwọ́ wọn lórí,’ ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n “di àpẹẹrẹ fún agbo.” (1 Pét. 5:3) Báwo ni alàgbà kan ṣe lè jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo? Ẹ jẹ́ ká gbé méjì yẹ̀ wò lára ohun tá à ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó “ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó.” Ó ní láti jẹ́ ẹni tó “yè kooro ní èrò inú,” ó sì gbọ́dọ̀ máa “ṣe àbójútó agbo ilé tirẹ̀ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.” Bí alàgbà kan bá ní ìdílé, ó gbọ́dọ̀ máa bójú tó o lọ́nà tó ṣeé fi ṣe àpẹẹrẹ, nítorí “bí ọkùnrin èyíkéyìí kò bá mọ agbo ilé ara rẹ̀ bójú tó, báwo ni yóò ṣe bójú tó ìjọ Ọlọ́run?” (1 Tím. 3:1, 2, 4, 5) Kí ọkùnrin kan tó kúnjú ìwọ̀n láti di alábòójútó, ó gbọ́dọ̀ yè kooro ní èrò inú ní ti pé á lóye àwọn ìlànà Ọlọ́run dáadáa, á sì mọ bí á ṣe máa tẹ̀ lé wọn nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tára rẹ̀ balẹ̀, tí kì í sì í fi ìkánjú ṣèpinnu. Tí àwọn ará ìjọ bá rí i pé àwọn alàgbà ní àwọn ànímọ́ yìí, wọ́n á lè fọkàn tán wọn.

14 Mímú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìsìn pápá jẹ́ ọ̀nà míì tí àwọn alábòójútó lè gbà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni. Nínú ọ̀ràn yìí, Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn alábòójútó. Apá pàtàkì nínú iṣẹ́ tí Jésù ṣe nígbà tó wà láyé ni iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ó fi bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe máa ṣe iṣẹ́ náà hàn wọ́n. (Máàkù 1:38; Lúùkù 8:1) Lóde òní, ẹ wo bó ṣe ń fún àwọn akéde níṣìírí tó nígbà tí wọ́n bá ń wàásù pẹ̀lú àwọn alàgbà, tí wọ́n ń wo bí àwọn alàgbà ṣe ń fìtara ṣe iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí, tí wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú bí àwọn alàgbà ṣe ń kọ́ni! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ àwọn alábòójútó máa ń dí, bí wọ́n ṣe ń fi àkókò àti okun wọn wàásù ìhìn rere náà pẹ̀lú ìtara ń fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti ní irú ìtara kan náà. Àwọn alàgbà tún lè fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn ará nípa mímúra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀, kí wọ́n sì máa kópa nípàdé àti nínú àwọn iṣẹ́ míì bíi mímú Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní.—Éfé. 5:15, 16; ka Hébérù 13:7.

Àwọn alábòójútó ń fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá (Wo ìpínrọ̀ 14)

“Ẹ MÁA ṢÈTÌLẸYÌN FÚN ÀWỌN ALÁÌLERA”

15. Kí ni díẹ̀ lára ohun tó ń mú kí àwọn alàgbà ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn?

15 Olùṣọ́ àgùntàn tó dáa tètè máa ń tọ́jú àgùntàn tó bá fara pa tàbí tó ń ṣàìsàn. Lọ́nà kan náà, àwọn alàgbà ìjọ ní láti tètè bójú tó ará ìjọ tí ìyà ń jẹ tàbí tó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ nínú ìjọsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run. Àwọn àgbàlagbà àtàwọn tó ń ṣàìsàn lè nílò nǹkan ti ara, àmọ́ ní pàtàkì wọ́n nílò  ohun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run tó sì máa fún wọn níṣìírí. (1 Tẹs. 5:14) Àwọn ọ̀dọ́ nínú ìjọ lè máa kojú ìṣòro, irú bí wọ́n á ṣe dènà “àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.” (2 Tím. 2:22) Nítorí náà, iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn táwọn alàgbà ń ṣe kan bíbẹ àwọn ará ìjọ wò lóòrèkóòrè kí wọ́n lè mọ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ kí wọ́n sì fún wọn ní ìṣírí látinú ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́. Tí wọ́n bá ń yanjú irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lákòókò, ọ̀pọ̀ ìṣòro lá máa yanjú kí wọ́n tó di ńlá.

16. Nígbà tí ẹnì kan nínú ìjọ bá nílò ìrànlọ́wọ́ kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run lè dára sí i, kí ni àwọn alàgbà lè ṣe?

16 Bí ìṣòro ẹnì kan nínú ìjọ bá le débi pé àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run kò dán mọ́rán ńkọ́? Jákọ́bù tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì béèrè pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà tí ń ṣàìsàn láàárín yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà. Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ó bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀, a óò dárí rẹ̀ jì í.” (Ják. 5: 14, 15) Kódà, bí àjọṣe ẹni kan pẹ̀lú Ọlọ́run kò bá dán mọ́rán mọ́, tí kò sì “pe àwọn àgbà ọkùnrin,” ó yẹ kí wọ́n tètè ràn án lọ́wọ́ ní gbàrà tí wọ́n bá ti mọ̀ nípa ipò tó wà. Tí àwọn alàgbà bá gbàdúrà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn, tí wọ́n sì tún gbàdúrà nítorí wọn, tí wọ́n dúró tì wọ́n lákòókò ìṣòro, wọ́n á máa mú kí ara tu àwọn tí wọ́n ń bójú tó, wọ́n á sì máa fún wọn ní ìṣírí.—Ka Aísáyà 32:1, 2.

17. Bí àwọn alàgbà bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ “olùṣọ́ àgùntàn ńlá” náà, kí ló máa yọrí sí?

17 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ìjọ ní láti sapá láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ “olùṣọ́ àgùntàn ńlá” náà, Jésù Kristi nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe nínú ètò Jèhófà. Àwọn àgùntàn inú ìjọ á jàǹfààní gan-an, wọ́n á sì máa pọ̀ sí i bí àwọn ọkùnrin tó ń ṣàbójútó ìjọ bá ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run. A ń dúpẹ́, á sì ń fìyìn fún Jèhófà, Olùṣọ́ Àgùntàn wa tí kò lẹ́gbẹ́ fún gbogbo oore tó ṣe fún wá yìí.