Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) November 2013

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì sùúrù Ọlọ́run bá a ṣe ń dúró de Jèhófà pé kó pa ètò búburú yìí run? Báwo ni Jèhófà àti Jésù ṣe ń ṣolùṣọ́ àwọn àgùntàn wọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lónìí?

Ẹ Wà Lójúfò Kí Ẹ Lè Máa Gbàdúrà

Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ máa gbàdúrà nígbà gbogbo? Ta ló máa jàǹfààní nígbà tó o bá ń gbàdúrà fún àwọn ẹlòmíì?

Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fún Àwọn Èèyàn

Mọ bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé láti pèsè ohun tara táwọn èèyàn nílò, ká sì mú kí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run.

Báwo La Ṣe Lè Máa Ní “Ẹ̀mí Ìdúródeni”?

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló máa jẹ́ àmì pé àkókò tá a fi ń dúró kí Jèhófà pa ètò búburú yìí run ti parí? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì sùúrù Ọlọ́run?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Sísin Ọlọ́run Ni Oògùn Àìsàn Rẹ̀!

Wọ́n bí Onesmus pẹ̀lú àìsàn osteogenesis imperfecta tí kì í jẹ́ kí egungun lágbára. Báwo ni àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe tó wà nínú Bíbélì ṣe ràn án lọ́wọ́?

Olùṣọ́ Àgùntàn Méje àti Mọ́gàjí Mẹ́jọ ti Òde Òní

Báwo ni Hesekáyà, Aísáyà, Míkà, àtàwọn ọmọ aládé Jerúsálẹ́mù ṣe jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn àtàtà? Ta ni olùṣọ́ àgùntàn méje àti mọ́gàjí mẹ́jọ lóde òní?

Ṣègbọràn sí Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn tí Jèhófà Yàn

Ẹ̀mí mímọ́ ló yàn àwọn alábòójútó láti máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run. Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn àgùntàn máa ṣègbọràn sí wọn?

Ẹ̀yin Olùṣọ́ Àgùntàn, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá náà

Nígbà tí ẹnì kan nínú ìjọ bá nílò ìrànlọ́wọ́ nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, kí ni àwọn alàgbà lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́? Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi tó jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn ńlá” náà?

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

“Mò Ń Gbé Ilé Mi Kiri bí Ìgbín”

Níparí ọdún 1929, ọrọ̀ ajé dojú rú kárí ayé. Báwo làwọn oníwàásù alákòókò kíkún ṣe gbọ́ bùkátà ara wọn nígbà yánpọnyánrin yẹn?