Nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún ń parí lọ, wọ́n gbé fíìmù kan jáde tó fani mọ́ra gan-an. Àwòrán nìkan ló wà nínú fíìmù náà, àmọ́ àwọn tó wò ó ní ìlú San Francisco, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gbádùn rẹ̀ gan-an. Àkọlé fíìmù náà ni A Trip Down Market Street, ó sì dá lórí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ohun tí àwọn tó gbé fíìmù yìí jáde ṣe ni pé wọ́n gbé kámẹ́rà aláfọwọ́yí kan sí iwájú ọkọ̀ kan tó ń rìn lára okùn irin tí wọ́n ta sára àwọn òpó gíga. Wọ́n wá dojú kámẹ́rà náà kọ ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ táwọn èèyàn ń gbà lọ gbà bọ̀. Lára àwọn nǹkan tí kámẹ́rà náà gbé jáde láti ibi tí wọ́n gbé e sí ni àwọn kẹ̀kẹ́ tí wọ́n ń fi ẹṣin fà, àwọn ọkọ̀ tí wọ́n ń lò nígbà yẹn, àtàwọn tó ń ṣe káràkátà, tó fi mọ́ àwọn tó ń ta ìwé ìròyìn.

Ohun tó bani nínú jẹ́ nípa fíìmù náà ni pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé oṣù April, ọdún 1906 ni wọ́n ya àwọn àwòrán tó wà níbẹ̀, tó sì wá jẹ́ pé ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, ìyẹn ọjọ́ kejìdínlógún [18] nínú oṣù April kan náà ni ìsẹ̀lẹ̀ runlé-rùnnà kan àti iná wáyé ní ìlú yẹn gangan, ó sì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn. Ìsẹ̀lẹ̀ náà fẹ́rẹ̀ẹ́ run apá ibi tó ti wáyé nínú ìlú náà. Kò sẹ́ni tó mọ̀ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fi hàn nínú fíìmù náà ò ní pẹ́ kú. Ọ̀gbẹ́ni Scott Miles tó jẹ́ ọ̀kan lára àtọmọdọ́mọ àwọn tó ṣe fíìmù náà sọ pé: “Mo kàn ń wo àwọn èèyàn tó wà nínú fíìmù náà ni. Wọn ò mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí wọn. Ńṣe ni àánú wọn ń ṣe mí.”

Láìròtẹ́lẹ̀, ìsẹ̀lẹ̀ ọdún 1906 àti iná tó wáyé látàrí ìsẹ̀lẹ̀ náà ba ọ̀pọ̀ ibi jẹ́ ní ìlú San Francisco

Tá a bá fi ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn wé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò tá à ń gbé yìí, ó tó láti mú ká ronú jinlẹ̀ dáadáa. Ńṣe ló yẹ kí àánú àwọn aládùúgbò tiwa náà máa ṣe wá. Oníkálùkù wọn ń wá àtijẹ àtimu kiri láìmọ̀ pé dùgbẹ̀dùgbẹ̀ kan ń fì lókè tó máa tó já bọ́, ìyẹn ìparun ètò àwọn nǹkan búburú yìí àti ọ̀nà táwọn èèyàn búburú ń gbà gbé ìgbé ayé wọn. Àmọ́, ìparun yìí yàtọ̀ sí ti ìsẹ̀lẹ̀ tó máa ń dé báni lójijì. A ṣì ní àkókò kúkúrú tá a fi lè kìlọ̀ fún àwọn aládùúgbò wa nípa ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà tó ń bọ̀ lọ́nà. Ó ṣeé ṣe kó o máa ya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti máa wàásù fáwọn èèyàn láti ilé dé ilé. Àmọ́, ṣé wàá túbọ̀ máa kìlọ̀ fáwọn èèyàn?

KÌ Í SÚ JÉSÙ LÁTI WÀÁSÙ

Àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ fún wa ṣe pàtàkì gan-an torí pé kì í sú u láti wàásù. Gbogbo àwọn tó bá bá pàdé ló máa ń wàásù fún. Ó wàásù fún agbowó òde kan tó bá pàdé lójú ọ̀nà àti obìnrin kan tó rí lọ́sàn-án ọjọ́ kan nígbà tó ń sinmi nídìí kànga. (Lúùkù 19:1-5; Jòh. 4:5-10, 21-24) Kódà, nígbà tó bá ya àkókò sọ́tọ̀ láti sinmi, ó máa ń fínnú-fíndọ̀ pa ìsinmi náà tì kó lè wàásù fáwọn èèyàn. Àánú àwọn aládùúgbò Jésù máa ń ṣe é, ìyẹn sì ń mú kó wàásù fún wọn ní gbogbo ìgbà tó bá láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Máàkù 6:30-34) Báwo la ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ní ti bó ṣe jára mọ́ iṣẹ́ ìwàásù?

 WỌ́N Ń WÀÁSÙ NÍ GBOGBO ÌGBÀ TÍ ÀǸFÀÀNÍ BÁ ṢÍ SÍLẸ̀

Ilé kan tó ní àwọn ẹ̀ṣọ́ lẹ́nu géètì ni Melika ń gbé. Àwọn tó wá kàwé nílẹ̀ òkèèrè ni ọ̀pọ̀ lára àwọn aládùúgbò rẹ̀. Nọ́ńbà fóònù alágbèékà wọn ò sí nínú ìwé tí wọ́n máa ń to nọ́ńbà fóònù sí, orúkọ wọn ò sì fara hàn nínú àkọsílẹ̀ orúkọ àti nọ́ńbà fóònù tó máa ń wà ní ibi àbáwọlé. Inú rẹ̀ máa ń dùn nígbà tó bá bá àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ayálégbé pàdé ní ibi àbáwọlé tàbí nínú ẹ̀rọ agbéniròkè, ó sì máa ń lo àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tó ní yìí láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò Bíbélì pẹ̀lú wọn. Ó sọ pé: “Mo máa ń wo ibẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀ ìwàásù mi.” Melika máa ń kó ìwé dání lónírúurú èdè, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì máa ń gba ìwé àṣàrò kúkúrú àti ìwé ìròyìn lọ́wọ́ rẹ̀. Ó tún máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè lọ sórí ìkànnì wa tó wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn jw.org. Ó ti bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Sonia náà máa ń wà lójúfò láti jẹ́rìí fún ẹnikẹ́ni tó bá bá pàdé. Dókítà kan ló gbà á síṣẹ́, àfojúsùn rẹ̀ sì ni pé òun á jẹ́rìí kúnnákúnná fún gbogbo àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Ó kọ́kọ́ máa ń fara balẹ̀ láti mọ ohun tí wọ́n fẹ́ àti ohun tó ń jẹ wọ́n lógún. Lẹ́yìn náà, tó bá di àkókò ìsinmi oúnjẹ ọ̀sán á lọ bá wọn níkọ̀ọ̀kan, á sì bá wọn jíròrò látinú Bíbélì. Sonia tipa bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjì. Kódà, ó tún ń wéwèé láti máa lo díẹ̀ lára àkókò ìsinmi rẹ̀ láti bá àwọn tó ṣì ń dúró de dókítà sọ̀rọ̀ níbi tí wọ́n máa ń jókòó sí.

WÀÁSÙ NÍ GBOGBO ÌGBÀ TÍ ÀǸFÀÀNÍ BÁ ṢÍ SÍLẸ̀

Ọkùnrin kan tó la ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé lọ́dún 1906 yẹn já sọ pé òun ni “ìsẹ̀lẹ̀ tó tíì burú jù lọ tó wáyé ní ìpínlẹ̀ kan tàbí nínú ìlú kan.” Síbẹ̀, láìpẹ́ kékeré ni gbogbo àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ láyé yìí máa jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọjọ́ ẹ̀san Jèhófà tó ń bọ̀ wá sórí gbogbo “àwọn tí kò mọ Ọlọ́run.” (2 Tẹs. 1:8) Ó wu Jèhófà gan-an pé kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà kí wọ́n sì fetí sí ìkìlọ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ń fún wọn.—2 Pét. 3:9; Ìṣí. 14:6, 7.

Ṣó o lè máa wàásù fún gbogbo àwọn tó ò ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀?

O ní àǹfààní láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àkókò líle koko là ń gbé yìí, kí wọ́n dẹ́kun wíwá ire ti ara wọn kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà. (Sef. 2:2, 3) Ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀, ṣó o lè máa wàásù fún àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn aládùúgbò rẹ, àtàwọn tó ò ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ lójoojúmọ́? Ṣé wàá túbọ̀ máa kìlọ̀ fáwọn èèyàn?