Nínú ayé àìdánilójú tó nira láti bá lò yìí, kò sẹ́ni tó mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́la. Ṣùgbọ́n, Jèhófà máa ń bù kún àwọn tí kò gbára lé òye tara wọn, àmọ́ tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e. Bí ọ̀rọ̀ èmi àti ìyàwó mi sì ṣe rí nìyẹn. Ó ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà, ó sì ń bù kún wa torí pé a gbẹ́kẹ̀ lé e. Díẹ̀ rèé nínú ìtàn ìgbésí ayé wa.

ÀPÉJỌ àgbègbè tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a mọ̀ sí International Bible Students ṣe ní Cedar Point, ní ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni bàbá àti ìyá mi ti jọ pàdé. Ọdún 1919 ni àpéjọ yẹn wáyé, ọdún yẹn náà sì ni wọ́n ṣe ìgbéyàwó. Ọdún 1922 ni wọ́n bí mi, ọdún méjì lẹ́yìn náà ni wọ́n sì bí àbúrò mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Paul. Ọdún 1930 ni wọ́n bí Grace ìyàwó mi. Orúkọ àwọn òbí rẹ̀ ni Roy àti Ruth Howell. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n, Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì làwọn òbí rẹ̀ àgbà pẹ̀lú, wọ́n sì tún jẹ́ ọ̀rẹ́ Arákùnrin Charles Taze Russell.

Ọdún 1947 ni mo pàdé Grace, a sì ṣe ìgbéyàwó ní July 16, ọdún 1949. Ká tó ṣe ìgbéyàwó la ti jọ bára wa sọ òkodoro ọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe fẹ́ gbé ìgbésí ayé wa. A pinnu láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún àti pé a ò ní bímọ. Ní October 1, ọdún 1950, a jọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó sì di ọdún 1952, wọ́n ní ká wá máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká.

A ṢE IṢẸ́ ARÌNRÌN-ÀJÒ A SÌ TÚN LỌ SÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍLÍÁDÌ

Èmi àti ìyàwó mi rí i pé a nílò ìrànlọ́wọ́ ká tó lè ṣe dáadáa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa tuntun yìí. Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni mo tún wá ẹni tó máa ran ìyàwó mi lọ́wọ́. Mo lọ bá Arákùnrin Marvin Holien tó ti ṣe díẹ̀ tó ti ń bá ìdílé wa ṣọ̀rẹ́. Ó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò. Mo sọ fún un pé: “Ìyàwó mi kéré lọ́jọ́ orí, kò sì ní ìrírí. Ǹjẹ́ ẹ lè dámọ̀ràn ẹnì kan tó lè bá ṣiṣẹ́ fún àkókò díẹ̀ kó fi gba ìdálẹ́kọ̀ọ́?” Ó dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” Ó tún wá sọ pé: “Aṣáájú-ọ̀nà tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ni Edna Winkle, ó sì lè ràn án lọ́wọ́ gan-an.” Nígbà tó yá ìyàwó mi sọ nípa Edna pé: “Ó máa ń mú kí ọkàn mi balẹ̀ lọ́dọ̀ onílé, ó mọ béèyàn ṣe ń fèsì ọ̀rọ̀, ó sì jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè máa tẹ́tí sí onílé kí n lè mọ ìdáhùn tó tọ́ láti fún un. Ìrànlọ́wọ́ tí mo nílò gan-an ló fún mi!”

Láti apá òsì: Nathan Knorr, Malcolm Allen, Fred Rusk, Lyle Reusch, Andrew Wagner

Àyíká méjì ni èmi àti ìyàwó mi ti sìn ní ìpínlẹ̀ Iowa, tó fi mọ́ àwọn apá ibì kan ní ìpínlẹ̀ Minnesota àti South Dakota. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé wa lọ sí àyíká New York Circuit 1, lára àyíká yìí ni àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ Brooklyn àti Queens wà. A ṣì máa ń rántí bó ṣe rí lára wa nígbà yẹn pé a ò tóótun  fún iṣẹ́ náà. Lára àwọn ìjọ tó wà ní àyíká náà ni ìjọ Brooklyn Heights, Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nínú Bẹ́tẹ́lì ni wọ́n ti ń ṣe ìpàdé. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti pẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì sì wà nínú ìjọ náà. Lẹ́yìn tí mo sọ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìsìn àkọ́kọ́ tán, Arákùnrin Nathan Knorr wá bá mi, ó sì sọ fún mi pé: “Malcom, ó sọ àwọn ohun díẹ̀ tó yẹ ká ṣiṣẹ́ lé lórí, ìyẹn sì dára gan-an ni. Àmọ́, tó ò bá máa ràn wá lọ́wọ́ nípa fífi ìfẹ́ gbà wá níyànjú, o ò ní fi bẹ́ẹ̀ wúlò fún ètò Ọlọ́run. Kò ní rẹ̀ ọ́ o!” Lẹ́yìn tí ìpàdé parí mo sọ ọ̀rọ̀ yìí fún ìyàwó mi. A wá pa dà sínú yàrá tá a dé sí ní Bẹ́tẹ́lì, àmọ́ torí pé ó ti rẹ̀ wá tá a sì ń ṣàníyàn, ńṣe la bú sẹ́kún.

“Tó ò bá máa ràn wá lọ́wọ́ nípa fífi ìfẹ́ gbà wá níyànjú, o ò ní fi bẹ́ẹ̀ wúlò fún ètò Ọlọ́run. Kò ní rẹ̀ ọ́ o!”

Lẹ́yìn oṣù mélòó kan, a gba lẹ́tà kan tí wọ́n fi pè wá sí kíláàsì kẹrìnlélógún [24] Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì tí wọ́n máa parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wọn ní oṣù February 1955. Wọ́n sọ fún wa ká tó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà pé kì í ṣe torí ká lè di míṣọ́nnárì la ṣe fẹ́ lọ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà máa mú ká túbọ̀ tóótun lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò. Ohun àgbàyanu ló jẹ́ fún wa láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà, ṣe ló máa ń mú kéèyàn túbọ̀ rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀.

Fern àti George Couch pẹ̀lú Grace àti èmi ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní ọdún, 1954

Nígbà tá a parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà, wọ́n ní ká lọ máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àgbègbè. Àwọn ìpínlẹ̀ Indiana, Michigan àti Ohio wà lára àwọn àgbègbè tí à ń bẹ̀ wò. Nígbà tó di oṣù December ọdún 1955, a gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ Arákùnrin Knorr. Ohun tó sì wà níbẹ̀ yà wá lẹ́nu gan-an ni. Ó sọ nínú lẹ́tà yẹn pé: “Bí ọ̀rọ̀ bá ṣe rí lọ́kàn yín ni kẹ́ ẹ sọ fún mi, ẹ má sì ṣe fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Mo fẹ́ mọ̀ bóyá ẹ máa fẹ́ láti wá sí Bẹ́tẹ́lì . . . tàbí ẹ máa fẹ́ láti lọ sìn ní ilẹ̀ àjèjì lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ṣiṣẹ́ díẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì. Tó bá sì jẹ́ iṣẹ́ alábòójútó àgbègbè tàbí ti àyíká ló wù yín, ẹ ṣáà jẹ́ kí n mọ̀.” A dá èsì pa dà pé tayọ̀tayọ̀ la máa fi sìn níbi yòówù tí wọ́n bá ní ká lọ. Gbàrà tí lẹ́tà náà tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ ni wọ́n ní ká máa bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì.

ÀWỌN ỌDÚN ALÁRINRIN TÁ A LÒ NÍ BẸ́TẸ́LÌ

Lára àwọn ọdún tó lárinrin jù lọ nígbà tí mo wà ní Bẹ́tẹ́lì ni àwọn ìgbà tí mo sọ àsọyé láwọn ìjọ, láwọn àpéjọ àgbègbè, àpéjọ àyíká àti ti àkànṣe láwọn àgbègbè tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Mo tún fún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́kùnrin ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ mo sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i nínú ètò Jèhófà. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn mo di akọ̀wé Arákùnrin Knorr ní ọ́fíìsì tí wọ́n ti ń ṣètò iṣẹ́ ìwàásù tó ń lọ kárí ayé.

Nígbà tí mò ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn ní ọdún, 1956

Mo tún wá gbádùn àwọn ọdún tí mo lò ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Mo láǹfààní láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Arákùnrin T. J. (Bud) Sullivan níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi ṣe àbójútó ẹ̀ka yẹn. Ọ̀pọ̀ àwọn míì ló tún wà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Lára wọn ni Arákùnrin Fred  Rusk tí wọ́n yàn pé kí ó dá mi lẹ́kọ̀ọ́. Mo fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára mi gan-an hàn án nígbà tí mo bi í pé: “Fred, kí ló dé tó o fi máa ń ṣe ọ̀pọ̀ àtúnṣe sí àwọn lẹ́tà mi kan?” Ó rẹ́rìn-ín, ó sì fún mi ní èsì tó mú mi ronú jinlẹ̀. Ó ní: “Malcolm, ọ̀rọ̀ ẹnu ṣeé ṣàlàyé, àmọ́ téèyàn bá kọ ọ̀rọ̀ sílẹ̀, pàápàá jù lọ ní ẹ̀ka tá a wà yìí, àfi kó jóòótọ́ kó sì péye dáadáa.” Lẹ́yìn náà ló wá fìfẹ́ sọ pé: “Jẹ́ onígboyà gidi gan-an. Ò ń ṣe dáadáa gan-an ni, kò sì ní pẹ́ tí ìwọ náà á fi mọwọ́ iṣẹ́ yìí.”

Láwọn ọdún tá a lò ní Bẹ́tẹ́lì, oríṣiríṣi iṣẹ́ ni ìyàwó mí ṣe. Lára wọn ni iṣẹ́ ìtọ́jú ilé tó gba pé kó máa tọ́jú yàrá táwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ń gbé. Ó gbádùn iṣẹ́ yẹn gan-an ni. Títí dòní, nígbà míì tá a bá pàdé àwọn tó jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin ní Bẹ́tẹ́lì nígbà yẹn, wọ́n máa ń sọ fún ìyàwó mi pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ pé: “Ẹ̀yin lẹ kọ́ mi béèyàn ṣe ń tẹ́ bẹ́ẹ̀dì. Inú màmá mi dùn sí nǹkan tẹ́ ẹ ṣe yẹn gan-an.” Ó tún gbádùn iṣẹ́ tó ṣe ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìwé Ìròyìn, Ẹ̀ka Tó Ń Fèsì Lẹ́tà àti Ẹ̀ka Tó Ń Ṣe Ẹ̀dà Kásẹ́ẹ̀tì. Onírúurú iṣẹ́ tó ṣe níbẹ̀ jẹ́ kó rí i pé iṣẹ́ yòówù kí wọ́n fún wa ṣe nínú ètò Ọlọ́run, àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ló jẹ́, a sì máa rí ìbùkún gbà. Títí dòní, èrò rẹ̀ ò tíì yàtọ̀.

ÀWỌN ÌYÍPADÀ TÁ A ṢE

Nígbà tó di ọdún 1975 a bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí i pé àwọn òbí wa tó ti darúgbó máa nílò ìtọ́jú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn a ní láti ṣe ìpinnu tó lágbára. A ò fẹ́ fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀, a ò sì fẹ́ kúrò láàárín àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà tá a ti jọ nífẹ̀ẹ́ ara wa gan-an. Síbẹ̀, mo mọ̀ pé ojúṣe mi ni láti bójú tó àwọn òbí mi. Nígbà tó ṣe, a kúrò ní Bẹ́tẹ́lì, a sì ní in lọ́kàn pé a máa pa dà wá bí nǹkan bá yí pa dà.

Ká lè máa rówó gbọ́ bùkátà ara wa, mo di aṣojú ilé iṣẹ́ ìbánigbófò, mo sì máa ń lọ káàkiri láti rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá jàǹfààní látinú ètò ìbánigbófò wa. Mo máa ń rántí ohun tí máníjà kan sọ fún mi nígbà tí wọ́n ń fún mi ní ìdálẹ́kọ̀ọ́. Ó sọ pé: “Iṣẹ́ yìí máa gba pé kí o máa lọ sí ọ̀dọ́ àwọn èèyàn nírọ̀lẹ́, nítorí ìgbà yẹn lo lè bá wọn nílé. Kò sí ohun míì tó tún ṣe pàtàkì ju pé kó o máa wá àwọn èèyàn lọ ní gbogbo ìrọ̀lẹ́.” Mo wá dá a lóhùn pé: “Mo mọ̀ pé ìrírí tẹ́ ẹ ní ló jẹ́ kẹ́ ẹ sọ bẹ́ẹ̀, mo sì mọrírì ohun tẹ́ ẹ sọ yẹn. Àmọ́, ohun kan wà tó kan àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run. Mi ò ṣàì náání rẹ̀ rí, mi ò sì ṣe tán láti ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí. Màá máa wá àwọn èèyàn lọ ní ìrọ̀lẹ́ o, àmọ́ mo gbọ́dọ̀ máa lọ sí àwọn ìpàdé pàtàkì kan ní ìrọ̀lẹ́ Tuesday àti ìrọ̀lẹ́ Thursday.” Jèhófà sì bú kùn mi torí pé mi ò tìtorí iṣẹ́ pa ìpàdé jẹ.

Ẹ̀gbẹ́ ìyá mi la wà ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó nígbà tó dákẹ́ ní oṣù July, ọdún 1987. Ọ̀gá nọ́ọ̀sì sọ fún ìyàwó mi pé: “Ìyáàfin Allen, máa lọ sílé kó o lọ sinmi. Gbogbo èèyàn tó wà níbí ló mọ̀ pé o ò fi ìyá ọkọ rẹ̀ yìí sílẹ̀ rárá. Fi ọkàn balẹ̀, sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o ti ṣe ìwọ̀n tó o lè ṣe.”

Ní oṣù December, ọdún 1987, a tún béèrè fún àǹfààní láti sìn lẹ́ẹ̀kan sí i ní Bẹ́tẹ́lì torí pé a fẹ́ràn ibẹ̀ gan-an ni. Àmọ́ ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà ni  àyẹ̀wò fi hàn pé ìyàwó mi ní àrùn jẹjẹrẹ inú ìfun. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún un, ó kọ́fẹ pa dà, wọ́n sì sọ pé kò ní àrùn jẹjẹrẹ lára mọ́. Àárín ìgbà yẹn náà la gba lẹ́tà kan láti Bẹ́tẹ́lì pé ká máa bá iṣẹ́ ìsìn wa lọ ní ìjọ àdúgbò tá a wà. A sì pinnu láti tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.

Nígbà tó yá, mo rí iṣẹ́ kan ní ìpínlẹ̀ Texas. A ronú pé bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń móoru níbẹ̀ máa dára fún wa gan-an ni. Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn. Láti nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tá a ti wà ní ìpínlẹ̀ Texas, àwọn ará lọkùnrin àti lóbìnrin tó wà níbí ń tọ́jú wa gan-an ni, a sì ti jọ mọwọ́ ara wa.

OHUN TÁ A TI KỌ́

Grace máa ń ní ìṣòro àrùn jẹjẹrẹ inú ìfun àti jẹjẹrẹ ọrùn. Kódà lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó tún ní àrùn jẹjẹrẹ ọmú. Síbẹ̀ kò ṣàròyé rí nípa ipò tó bára rẹ̀, ó máa ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ó sì máa ń kọ́wọ́ ti àwọn ìpinnu tó bá ṣe. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn máa ń bi í pé, “Kí lohun náà gan-an tó mú kí ìgbéyàwó yín kẹ́sẹ járí, tí ẹ̀yin méjèèjì sì ń láyọ̀?” Ohun mẹ́rin ló máa ń sọ fún wọn. Ó máa ń sọ pé, “Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni wá. A jọ máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa lójoojúmọ́. A kì í yan ara wa lódì. Tá a bá bínú síra wa, a kì í sùn láì kọ́kọ́ yanjú ẹ̀.” Ká sòótọ́, a máa ń ṣẹra wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ a máa ń dárí ji ara wa a sì máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tán síbẹ̀. Ìyẹn sì ti ràn wá lọ́wọ́ gan-an ni.

“Máa gbára lé Jèhófà ní gbogbo ìgbà, kó o sì fara mọ́ ohun tó bá fàyè gbà”

Ọ̀pọ̀ nǹkan la ti kọ́ látinú àwọn àdánwò tó dé bá wa:

  1.  Kéèyàn máa gbára lé Jèhófà ní gbogbo ìgbà, kéèyàn sì fara mọ́ ohun tó bá fàyè gbà. Kéèyàn má ṣe gbára lé òye tirẹ̀.—Òwe 3:5, 6; Jer. 17:7.

  2.  Kéèyàn jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Jèhófà máa tọ́ òun sọ́nà nínú ohun gbogbo. Ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa pa òfin Jèhófà mọ́. Yíyàn kan ṣoṣo ló wà: Kéèyàn jẹ́ onígbọràn tàbí kó jẹ́ aláìgbọràn.—Róòmù 6:16; Héb. 4:12.

  3.  Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé ni pé kéèyàn ní orúkọ rere pẹ̀lú Jèhófà. Kéèyàn fi àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní, kó má sì ṣe kó ohun ìní tara jọ.—Òwe 28:20; Oníw. 7:1; Mát. 6:33, 34.

  4.  Kéèyàn gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kóun lè máa kó ipa tó jọjú kóun sì máa ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ débi tó bá ṣeé ṣe dé. Kéèyàn máa pọkàn pọ̀ sórí ohun tó lè ṣe, kì í ṣe ohun tí kò lè ṣe.—Mát. 22:37; 2 Tím. 4:2.

  5.  Kéèyàn jẹ́ kó dá òun lójú pé kò sí ètò míì tí Jèhófà ń ṣe ojúure sí tó sì ń bù kún.—Jòh. 6:68.

Ó ti lé ní ọdún márùndínlọ́gọ́rin [75] tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ti fi sin Jèhófà. Àmọ́, nǹkan bí ọdún márùndínláàádọ́rin [65] la ti lò pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya. Ní gbogbo ẹ̀wádún yìí, a ti jọ gbádùn bá a ṣe jọ sin Jèhófà. Ó wù wá, a sì gbà á ládùúrà pé kí gbogbo àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, káwọn náà sì rí èrè tó máa ń mú wá.