Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  September 2013

Máa Fi Ọgbọ́n Ṣe Ìpinnu

Máa Fi Ọgbọ́n Ṣe Ìpinnu

“Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.”—ÒWE 3:5.

1, 2. Ṣó máa ń yá ẹ lára láti ṣèpinnu? Ojú wo lo sì fi ń wo àwọn ìpinnu kan tó o ti ṣe?

ÌPINNU! Ìpinnu! Ojúmọ́ ọjọ́ kan kò lè mọ́ kéèyàn má ṣe ìpinnu. Tó bá di pé kó o ṣe ìpinnu, báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ? Ó máa ń yá àwọn kan lára láti pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe. Wọ́n gbà pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tí wọ́n fẹ́, wọ́n sì kórìíra pé kí ẹnì kan máa pinnu fún wọn. Àmọ́, ẹ̀rù máa ń ba àwọn kan tó bá di pé kí wọ́n ṣe ìpinnu lórí àwọn nǹkan tó yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n sábà máa ń ṣe. Ìwé atọ́nà tàbí àwọn olùgbani-nímọ̀ràn làwọn kan máa ń wá kiri, wọ́n sì lè san owó gọbọi torí kí wọ́n lè rí ìmọ̀ràn tí wọ́n fẹ́ gbà.

2 Ọ̀pọ̀ nínú wa ló jẹ́ pé nígbà míì ó máa ń yá wa lára láti ṣèpinnu, ìgbà míì sì rèé kì í yá wa lára láti ṣe bẹ́ẹ̀. A gbà pé àwọn nǹkan kan wà tó kọjá agbára wa, tá ò sì lè ṣe nǹkan kan nípa wọn; síbẹ̀, inú wa dùn pé a lè ṣe ìpinnu tó wù wá lórí ọ̀pọ̀ nǹkan tó kàn wá nígbèésí ayé. (Gál. 6:5) Àmọ́, ó ṣeé ṣe ká gbà pé kì í ṣe ìgbà gbogbo la máa ń ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, àwọn ìpinnu wa míì sì máa ń bẹ́yìn yọ.

3. Tó bá di ká ṣe ìpinnu, ìtọ́sọ́nà wo là ń rí gbà, àmọ́ ìṣòro wo la ṣì ní?

3 Inú àwa èèyàn Jèhófà máa ń dùn torí pé Jèhófà ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere lórí àwọn nǹkan pàtàkì tá à ń ṣe nígbèésí ayé wa. A mọ̀ pé tá a bá tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà tó fún wa, àwọn ìpinnu wa máa múnú rẹ̀ dùn, á sì ṣe wá láǹfààní. Àmọ́ o, àwọn ìṣòro tàbí ipò kan lè yọjú tó jẹ́ pé a ò lè rí ìsọfúnni pàtó nípa wọn nínú Bíbélì. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe máa pinnu ohun tó yẹ ká ṣe? Bí àpẹẹrẹ, a mọ̀ pé kò yẹ ká jalè. (Éfé. 4:28) Àmọ́ kí ló lè mú ká pe ẹnì kan ní olè? Ṣé bí ohun tí onítọ̀hún jí ṣe níye lórí tó ni? Àbí ohun tó sún un láti jalè? Àbí torí ìdí míì? Kí la máa ń ṣe tó bá di pé kò sí ìlànà kan pàtó tó sọ ohun tá a lè ṣe lórí ohun kan? Kí ló lè tọ́ wa sọ́nà?

 JẸ́ ALÁRÒJINLẸ̀

4. Ìmọ̀ràn wo ló ṣeé ṣe kí ẹnì kan ti fún wa nígbà tá a fẹ́ ṣe ìpinnu?

4 Tá a bá sọ fáwọn ará wa pé a fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan, ẹnì kan lè gbà wá níyànjú pé ká ro ọ̀rọ̀ náà jinlẹ̀ dáadáa ká tó ṣèpinnu. Ó dájú pé ìmọ̀ràn rere nìyẹn. Bíbélì pàápàá rọ̀ wá pé ká má ṣe máa kánjú ṣe nǹkan, ó sọ pé: “Àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” (Òwe 21:5) Àmọ́ kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ aláròjinlẹ̀ tàbí pé kéèyàn yè kooro ní èrò inú? Ṣé ohun tó túmọ̀ sí ni pé kéèyàn máa fara balẹ̀ rò ọ̀rọ̀ síwá-sẹ́yìn, kéèyàn mọ ibi tágbára òun dé tàbí kéèyàn lo làákàyè? Gbogbo nǹkan yìí ló ṣe pàtàkì téèyàn bá máa ṣe ìpinnu tó dára, àmọ́ ohun tó gbà tó bá di kéèyàn ní àròjinlẹ̀ ju ìyẹn lọ fíìfíì.—Róòmù 12:3; 1 Pét. 4:7.

5. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé a ṣì máa ń ṣàṣìṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní àròjinlẹ̀?

5 A gbọ́dọ̀ gbà pé kò sí bá a ṣe lè ní àròjinlẹ̀ tó tí a ò ní ṣe àṣìṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé inú ẹ̀ṣẹ̀ la bí wa sí, aláìpé sì ni wá. Torí náà kò sí bá ò ṣe ní ṣàṣìṣe lérò, lọ́rọ̀ àti níṣe. (Sm. 51:5; Róòmù 3:23) Láfikún síyẹn, ọ̀pọ̀ lára wa ló ti wà tẹ́lẹ̀ rí nínú àwùjọ àwọn èèyàn tí Sátánì ti “fọ́” ojú inú wọn. Nígbà yẹn, a ò mọ Jèhófà, a ò sì mọ ìlànà òdodo rẹ̀. (2 Kọ́r. 4:4; Títù 3:3) Torí náà, tó bá jẹ́ pé orí ohun tá a rò pé ó tọ́ tó sì bọ́gbọ́n mu lójú wa nìkan là ń gbé àwọn ìpinnu wa kà, bó ti wù ká ronú jinlẹ̀ lórí ìpinnu náà tó, ńṣe là ń tan ara wa jẹ.—Òwe 14:12.

6. Kí ló lè mú ká ní àròjinlẹ̀?

6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí bá a ṣe lè ṣeé ká má ṣàṣìṣe lérò, lọ́rọ̀ àti níṣe, àmọ́ ẹni pípé ni Jèhófà, Baba wa ọ̀run ní tiẹ̀, kì í ṣe àṣìṣe rárá. (Diu. 32:4) Inú wa dùn pé ó ti mú kó ṣeé ṣe fún wà láti yí èrò wa pa dà ká lè ní ìyèkooro èrò inú tàbí lédè míì, ká lè ní àròjinlẹ̀. (Ka 2 Tímótì 1:7.) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a fẹ́ máa ronú lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání ká sì máa hùwà tó bọ́gbọ́n mu. A gbọ́dọ̀ kápá èrò wa àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa, ká sì máa fara wé Jèhófà ní ti bó ṣe ń ronú, bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀ àti bó ṣe ń ṣe nǹkan.

7, 8. Sọ ìrírí kan tó fi hàn pé èèyàn lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání láìka ìnira tàbí ìṣòro sí.

7 Wo àpẹẹrẹ yìí ná. Àṣà kan tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn kan tó ń ṣí kúrò láti ìlú kan sí òmíràn ni pé kí wọ́n fi ọmọ tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ránṣẹ́ sí àwọn ìbátan wọn, kí wọ́n lè máa bá wọn tọ́jú rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n á lè gbájú mọ́ iṣẹ́ wọn, wọ́n á sì lè rí owó púpọ̀ tù jọ. * Obìnrin kan wà tó ń gbé nílẹ̀ àjèjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ọmọkùnrin làǹtìlanti kan. Àkókò tó bí ọmọ yìí náà ló bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ń tẹ̀ síwájú gan-an. Tẹbí tọ̀rẹ́ ló ń rọ̀ ọ́ pé kí òun àti ọkọ rẹ̀ fi ọmọ tuntun náà ránṣẹ́ sáwọn òbí wọn àgbà nílé. Àmọ́, ẹ̀kọ́ Bíbélì tí obìnrin náà ń kọ́ mú kó yé e pé gẹ́gẹ́ bí òbí, òun ni Ọlọ́run gbéṣẹ́ fún láti tọ́ ọmọ náà dàgbà. (Sm. 127:3; Éfé. 6:4) Báwọn èèyàn bá tiẹ̀ rò pé kò sóhun tó burú nínú irú àṣà bẹ́ẹ̀, ṣó yẹ kó lọ́wọ́ nínú rẹ̀? Àbí ńṣe ló yẹ kó fi ohun tó ń kọ́ nínú Bíbélì sílò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn lè fa ọ̀dá owó, ó sì lè mú káwọn èèyàn máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́? Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni obìnrin yìí, kí ni wàá ṣe?

8 Ìdààmú bá obìnrin yìí lóòótọ́, nǹkan sì tojú sú u. Kí ló wá ṣe? Ńṣe ló yíjú sí Jèhófà, tó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó tọ́ òun sọ́nà. Ó fi ọ̀rọ̀ náà tó ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn míì nínú ìjọ létí. Àwọn ìgbésẹ̀ yìí ló mú kó mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe. Ó tún ronú nípa ẹ̀dùn ọkàn táwọn ọmọ tí wọ́n mú kúrò lọ́dọ̀ òbí wọn láti kékeré máa ń ní. Lẹ́yìn tó ti yiiri ọ̀rọ̀ yìí wo pẹ̀lú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ó pinnu pé òun kò ní fi ọmọ òun ránṣẹ́ sílé. Nígbà tí ọkọ rẹ̀ kíyè sí báwọn ará ṣe gbárùkù tì í àti bí ọmọ  náà ṣe ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún bó ṣe ń dàgbà, òun náà gbà pé kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé ìyàwó rẹ̀ wá sípàdé.

9, 10. Kí ló túmọ̀ sí tá a bá ní ká máa ro àròjinlẹ̀, ọ̀nà wo la sì lè gba ṣe bẹ́ẹ̀?

9 Àpẹẹrẹ kan péré nìyẹn wulẹ̀ jẹ́, àmọ́ ó jẹ́ ká rí i pé ẹni tó ní àròjinlẹ̀ kì í ṣe nǹkan torí pé òun tàbí àwọn míì rò pé ó dáa kí òun ṣe nǹkan náà, tàbí torí pé àǹfààní wà níbẹ̀. A lè fi ọkàn wa tó jẹ́ aláìpé yìí wé aago tó máa ń sáré jù tàbí tó máa ń fà sẹ́yìn jù. Ẹni bá ń fi irú aago bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ máa ní ìjákulẹ̀ gidigidi. (Jer. 17:9) Èyí fi hàn pé a ní láti máa fi ìlànà Ọlọ́run tó ṣeé gbára lé darí ìrònú àti ìfẹ́ ọkàn wa.—Ka Aísáyà 55:8, 9.

10 Abájọ tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Kíyè sí gbólóhùn náà, ‘má ṣe gbára lé òye tìrẹ.’ Ẹ̀yìn náà ló wá sọ pé “ṣàkíyèsí [Jèhófà].” Òun nìkan ni ìrònú rẹ̀ pé, tí kì í ṣàṣìṣe. Torí náà, nígbàkigbà tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu, ẹ jẹ́ ká máa yẹ Bíbélì wò ká lè mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ohun tá a fẹ́ ṣe. Lẹ́yìn náà, ká jẹ́ kí èrò Ọlọ́run darí ìpinnu wa. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni tó ń mú èrò tirẹ̀ bá èrò Ọlọ́run mu la lè sọ pé ó ń ro àròjinlẹ̀ tàbí pé ó yè kooro ní èrò inú.

MÁA KỌ́ AGBÁRA ÌWÒYE RẸ

11. Kí lohun kan tó lè mú ká mọ bá a ṣe lè máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání?

11 Kò rọrùn rárá láti ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání kéèyàn sì tún ṣe ohun tó pinnu. Èyí máa ń ṣòro gan-an fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi tàbí àwọn tó ń sapá láti tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe fún àwọn wọ̀nyí tí Bíbélì pè ní ìkókó nípa tẹ̀mí láti tẹ̀ síwájú dáadáa. Wo bí ọmọdé kan tó ń kọ́ ìrìn ṣe lè máa rìn láì ṣubú. Ohun kan tó lè ṣe tí kò fi ní ṣubú ni pé kó máa gbé ẹsẹ̀ níkọ̀ọ̀kan. Bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn fáwọn ìkókó nípa tẹ̀mí tó bá di pé kí wọ́n ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Ẹ rántí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn tó dàgbà nípa tẹ̀mí pé, “wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” Ọ̀rọ̀ náà “tipasẹ̀ lílò” àti “kọ́” fi hàn pé èèyàn gbọ́dọ̀  máa sapá láìdáwọ́ dúró. Ohun táwọn ẹni tuntun náà gbọ́dọ̀ ṣe nìyẹn.—Ka Hébérù 5:13, 14.

Tá a bá ń ṣe ìpinnu tó tọ́ nínú àwọn ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́, ńṣe là ń kọ́ agbára ìwòye wa (Wo ìpínrọ̀ 11)

12. Kí ló máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání?

12 Bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ojoojúmọ́ la máa ń ṣe ìpinnu, yálà àwọn ìpinnu pàtàkì tàbí àwọn ìpinnu kéékèèké. Ìwádìí kan fi hàn pé nínú nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ìpinnu tá a máa ń ṣe, èyí tó lé ní ogójì ló ti mọ́ wa lára láti máa ṣe, láìsí pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń jókòó ronú lórí bá a ṣe máa ṣe wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, láràárọ̀ o ní láti pinnu aṣọ tó o máa wọ̀. O lè gbà pé ìyẹn kò tó nǹkan, torí bẹ́ẹ̀, o ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ronú kó o tó yan èyí tó o máa wọ̀, pàápàá tó o bá ń kánjú. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì kó o ronú nípa bóyá aṣọ tó o fẹ́ wọ̀ máa buyì kún ẹ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà. (2 Kọ́r. 6:3, 4) Nígbà tó o bá lọ ra aṣọ, ó ṣeé ṣe kó o ti ronú nípa ọ̀nà tí wọ́n gbà rán aṣọ náà àti bóyá ó jẹ́ irú èyí táwọn èèyàn ń gba tiẹ̀. Àmọ́, ó tún yẹ kó o ronú bóyá ó bójú mu? Iye tó máa ná ẹ ńkọ́? Béèyàn bá ń ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nínú ọ̀ràn yìí, ńṣe ni onítọ̀hún ń kọ́ agbára ìwòye rẹ̀, á sì mú kó lè ṣe ìpinnu tó tọ́ nínú ọ̀ràn tó túbọ̀ lágbára.—Lúùkù 16:10; 1 Kọ́r. 10:31.

KỌ́ BÓ O ṢE LÈ MÁA ṢE OHUN TÓ TỌ́

13. Kí la nílò táá jẹ́ ká lè máa ṣe ohun tá a pinnu?

13 Gbogbo wa la mọ̀ pé ohun kan ni kéèyàn pinnu ohun tó tọ́, àmọ́ nǹkan ọ̀tọ̀ ni pé kéèyàn ṣe ohun tó pinnu náà. Bí àpẹẹrẹ, ohun tó fà á táwọn kan tó ń mu sìgá kò fi lè jáwọ́ ni pé ìpinnu wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára. Ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe ni pé kí wọ́n dúró lórí ìpinnu wọn. Àwọn kan gbà pé ṣe ni agbára tí kálukú wa ní láti ṣe ìpinnu ká sì dúró lórí ìpinnu náà dà bí iṣan ara wa. Bí a bá ṣe ń lò ó tó bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe máa lágbára. Àmọ́ tí a kì í bá fi bẹ́ẹ̀ lò ó déédéé, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í sún kì tàbí kó tiẹ̀ kú pátápátá. Torí náà, kí la lè ṣe táá jẹ́ ká lè máa dúró lórí ìpinnu wa, tá ò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ láti ṣe ohun tá a ti pinnu? Àfi ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́.—Ka Fílípì 2:13.

14. Kí ló fún Pọ́ọ̀lù lágbára láti ṣe ohun tó mọ̀ pé ó yẹ kí òun ṣe?

14 Pọ́ọ̀lù alára ti ní ìrírí ohun tá à ń sọ yìí. Ó kédàárò nígbà kan pé: “Agbára àti-fẹ́-ṣe wà pẹ̀lú mi, ṣùgbọ́n agbára àtiṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ kò sí.” Ó mọ ohun tó fẹ́ ṣe tàbí ohun tó yẹ kó ṣe, àmọ́ àwọn nǹkan kan máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà míì tí kì í jẹ́ kó lè ṣe é. Ó sọ pé: “Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.” Ṣé kò wá sí ọ̀nà àbáyọ mọ́ ni? Ọ̀nà àbáyọ wa. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:18, 22-25) Nígbà tó ń kọ̀wé sáwọn míì, ó sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílí. 4:13.

15. Tí ìpinnu tá a fẹ́ ṣe bá kàn àwọn kan, ipa wo ló lè ní lórí wọn tá a bá ṣe ohun tá a pinnu? Ipa wo ló máa ní tá ò bá ṣe ohun tá a pinnu?

15 Ó ṣe kedere pé tá a bá máa múnú Ọlọ́run dùn, a gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu tó tọ́ ká sì dúró lórí ìpinnu wa. Ẹ rántí ọ̀rọ̀ tí Èlíjà sọ lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì fáwọn tó ń jọ́sìn Báálì àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ apẹ̀yìndà. Ó sọ pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ ó fi máa tiro lórí èrò méjì tí ó yàtọ̀ síra? Bí Jèhófà bá ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; ṣùgbọ́n bí Báálì bá ni, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” (1 Ọba 18:21) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, àmọ́ ṣe ni wọ́n ń “tiro” láìṣe ìpinnu kan. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Jóṣúà ṣe ohun tó tọ́ ni tiẹ̀, ó fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nígbà tó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Bí ó bá burú ní ojú yín láti  máa sin Jèhófà, lónìí yìí, ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín . . . Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.” (Jóṣ. 24:15) Kí ni àbájáde ìpinnu tí Jóṣúà ṣe yìí? Jèhófà bù kún òun àtàwọn tí wọ́n jọ wà pa pọ̀, ó mú kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí, “ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.”—Jóṣ. 5:6.

MÁA ṢE ÌPINNU TÓ BỌ́GBỌ́N MU, JÈHÓFÀ YÒÓ SÌ BÙ KÚN Ọ

16, 17. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé àǹfààní wà níbẹ̀ téèyàn bá ṣe ìpinnu tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.

16 Wo àpẹẹrẹ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lóde òní. Arákùnrin kan wà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi, ó níyàwó, wọ́n sì ní ọmọ kékeré mẹ́ta. Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ sọ fún un pé kó jẹ́ káwọn lọ máa ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ míì tí owó oṣù rẹ̀ gbé pẹ́ẹ́lí ju ibi tí wọ́n wà lọ, tí wọ́n sì tún máa ń fún àwọn òṣìṣẹ́ wọn ní owó àjẹmọ́nú. Arákùnrin wa yìí ronú nípa ọ̀rọ̀ náà, ó sì gbàdúrà nípa rẹ̀. Lóòótọ́ owó tó ń gbà níbi tó wà yẹn kéré, àmọ́ ìdí tó fi yan iṣẹ́ náà ni pé wọ́n kì í ṣiṣẹ́ lópin ọ̀sẹ̀. Èyí sì jẹ́ kó lè máa lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí pẹ̀lú ìdílé rẹ̀. Ó ronú pé tóun bá lọ ṣíṣẹ́ yẹn, ó kéré tán láàárín oṣù mélòó kan tóun bá kọ́kọ́ débẹ̀, kò ní sí irú àyè tí òun ní yìí. Tó bá jẹ́ ìwọ ni, kí ni wàá ṣe?

17 Lẹ́yìn tí arákùnrin náà ro bí iṣẹ́ náà ṣe máa kó bá àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ńṣe ló kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ náà, bó tílẹ̀ jẹ́ pé owó ńlá ni wọ́n máa san fún un. Ǹjẹ́ o rò pé ó kábàámọ̀ ìpinnu tó ṣe yẹn? Rárá. Ó gbà pé àwọn ìbùkún tẹ̀mí tí òun àti ìdílé òun ń rí gbà ń ṣe àwọn láǹfààní ju owó oṣù èyíkéyìí tí wọ́n lè san fún òun. Inú òun àti ìyàwó rẹ̀ dùn gan-an nígbà tí àkọ́bí wọn tó jẹ́ ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́wàá sọ fún wọn pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn, òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ará àti pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Ó sọ pé òun fẹ́ ya ara òun sí mímọ́ fún Jèhófà, òun sì fẹ́ ṣèrìbọmi. Ẹ ò rí i pé ọmọ náà mọrírì bí bàbá rẹ̀ ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa fífi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ̀!

Máa ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu, wàá sì rí ayọ̀ láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará (Wo ìpínrọ̀ 18)

18. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání lójoojúmọ́?

18 Ọ̀pọ̀ ọdún ni Jésù tó jẹ́ Mósè Títóbi Jù ti ń darí àwa olùjọsìn Jèhófà tó sì ń ṣamọ̀nà wa nínú ayé Sátánì tó dà bí aginjù yìí. Òun náà tún ni Jóṣúà Títóbi Jù. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ti ṣe tán láti pa ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí run, kí ó sì kó àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wọnú ayé tuntun òdodo tí Ọlọ́run ṣèlérí. (2 Pét. 3:13) Torí náà, kì í ṣe àkókò yìí ló yẹ ká pa dà sáwọn ohun tí kò lérè tá à ń ṣe tẹ́lẹ̀, yálà ní ti bá a ṣe ń ronú, ìwà tá à ń hù, àwọn nǹkan tá a kà sí pàtàkì àtàwọn àfojúsùn wa. Dípò bẹ́ẹ̀, àkókò tó yẹ ká túbọ̀ máa fòye mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe nìyí. (Róòmù 12:2; 2 Kọ́r. 13:5) Torí náà, jẹ́ kí ìpinnu rẹ ojoojúmọ́ àtàwọn ohun tó o yàn láti ṣe mú kó o yẹ lẹ́ni tí Ọlọ́run máa bù kún títí láé.—Ka Hébérù 10:38, 39.

^ ìpínrọ̀ 7 Ìdí táwọn míì fi ń fọmọ ránṣẹ́ sáwọn òbí wọn àgbà ni pé kí wọ́n lè máa fi wọ́n yangàn lójú tẹbí tọ̀rẹ́ pé àwọn náà ti ní ọmọ-ọmọ.