Bí Bíbélì ṣe ròyìn rẹ̀ nínú Jòhánù 11:35, kí ló fà á tí Jésù fi da omijé lójú kó tó jí Lásárù dìde?

Nígbà tí ẹnì kan tá a fẹ́ràn bá kú, a máa ń sunkún torí pé àárò rẹ̀ á máa sọ wá. Òótọ́ ni pé Jésù nífẹ̀ẹ́ Lásárù gan-an, àmọ́ kì í ṣe nítorí pé Lásárù kú ni Jésù ṣe ń da omijé lójú. Àwọn ọ̀rọ̀ míì tí Jòhánù kọ sílẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé àánú àwọn ìbátan Lásárù ló ṣe Jésù, ìyẹn ló sì fà á tó fi da omijé lójú.—Jòh. 11:36.

Nígbà tí Jésù kọ́kọ́ gbọ́ pé Lásárù ń ṣàìsàn, kò kánjú lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kó lè wò ó sàn. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí [Jésù] gbọ́ pé [Lásárù] ń ṣàìsàn, nígbà náà, ó dúró ní ti gidi fún ọjọ́ méjì ní ibi tí ó wà.” (Jòh. 11:6) Kí ló dé tí Jésù kò fi tètè lọ? Ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ láti ṣe ni kò jẹ́ kó tètè lọ. Ó sọ pé: “Ikú kọ́ ni ìgbẹ̀yìn àìsàn yìí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ fún ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.” (Jòh. 11:4) Ikú kọ́ ni “ìgbẹ̀yìn” tàbí òpin àìsàn tó ń ṣe Lásárù. Jésù fẹ́ kí ikú Lásárù “jẹ́ fún ògo Ọlọ́run.” Lọ́nà wo? Jésù máa tó ṣe iṣẹ́ ìyanu kan tó máa gbàfiyèsí, ìyẹn ni pé ó máa tó jí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ yìí dìde.

Nígbà tí Jésù ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó fi ikú wé oorun. Ìdí nìyẹn tó fi sọ fún wọn pé òun “ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí [Lásárù] kúrò lójú oorun.” (Jòh. 11:11) Lójú Jésù, ohun tó fẹ́ ṣe yẹn dà bí ìgbà tí òbí kan bá ń jí ọmọ rẹ̀ tó ti sùn. Torí náà kò sídìí tó fi máa bara jẹ́ torí pé Lásárù kú.

Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá ló fà á tí Jésù fi da omijé lójú? Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ tí Bíbélì ń sọ bọ̀ ló jẹ́ ká rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. Nígbá tí Jésù rí Màríà tó jẹ́ arábìnrin Lásárù àtàwọn míì tí wọ́n ń sunkún, “ó kérora nínú ẹ̀mí, ó sì dààmú.” Ẹ̀dùn ọkàn táwọn èèyàn náà ní ló mú kí Jésù kẹ́dùn débi pé “ó kérora nínú ẹ̀mí.” Ìdí nìyẹn tí ‘Jésù fi bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.’ Ó ba Jésù nínú jẹ́ gan-an bó ṣe rí i tí ìbànújẹ́ dorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n kodò.—Jòh. 11:33, 35.

Ìtàn yìí fi hàn pé Jésù ní agbára, ó sì lè jí àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde, kí ó sì mú kí wọ́n ní ìlera tó jí pépé nínú ayé tuntun. Ó tún jẹ́ ká rí i pé Jésù mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwọn tí ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù mú èèyàn wọn lọ. Ẹ̀kọ́ míì tá a tún rí kọ́ nínú ìtàn yìí ni pé ó yẹ ká máa káàánú àwọn tí ẹ̀dùn ọkàn bá torí pé wọ́n pàdánù èèyàn wọn.

Jésù mọ̀ pé òun máa jí Lásárù dìde. Síbẹ̀, nítorí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ àti àánú tó ní sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí, ó da omijé lójú. Bákan náà, tá a bá ń fi ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ro ara wa wò, ó lè mú ká “sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Téèyàn bá ń sunkún nígbà téèyàn ẹni kan bá kú kò túmọ̀ sí pé èèyàn ò nígbàgbọ́ nínú àjíǹde. Àpẹẹrẹ àtàtà mà ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa yìí o, ní ti pé ó káàánú àwọn tí ẹ̀dùn ọkàn bá torí pé wọ́n pàdánù ẹnì kan nínú ikú, ó tún da omijé lójú bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì máa jí Lásárù dìde.