Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà Máa Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà

Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà Máa Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà

“Ó dára láti máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run wa.”—SM. 147:1.

1, 2. (a) Tá a bá ń ronú, tá a sì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tá a nífẹ̀ẹ́, ipa wo nìyẹn lè ní lórí àjọṣe tó wà láàárín wa? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?

TÁ A bá ń ronú nípa ẹnì kan tá a nífẹ̀ẹ́, tá a sì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fáwọn ẹlòmíì, ó máa jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú ẹni náà túbọ̀ lágbára sí i. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí tó bá kan àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Olùṣọ́ àgùntàn ni Dáfídì, ọ̀pọ̀ ọjọ́ ló máa ń wo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run lálẹ́, tó sì máa ń ṣàṣàrò nípa Ẹlẹ́dàá tí kò láfiwé tó dá wọn. Ó tiẹ̀ sọ pé: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn, àti ọmọ ará ayé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?” (Sm. 8:3, 4) Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ronú lórí bí ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún Ísírẹ́lì tẹ̀mí ṣe ní ìmúṣẹ lọ́nà àgbàyanu, ó sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o!”—Róòmù 11:17-26, 33.

2 Nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, ńṣe là ń ronú, tá a sì ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Èyí sì máa ń ní ipa rere lórí wa gan-an. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ló ti rí i pé, lára ìbùkún táwọn ń rí ni pé ìfẹ́ táwọn ní fún Ọlọ́run túbọ̀ ń lágbára báwọn ṣe túbọ̀ ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Yálà ò ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún báyìí, àbí ńṣe ló ṣì ń ronú láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ronú nípa ìbéèrè yìí: Báwo ni iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe lè jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Tó bá jẹ́ pé aṣáájú-ọ̀nà ni ẹ́, bi ara rẹ pé, ‘Kí ló máa mú kí n máa bá a lọ lẹnu iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣeni láǹfààní yìí?’ Tó ò bá sì tíì di aṣáájú-ọ̀nà, o lè bi ara rẹ pé: ‘Àwọn ìyípadà wo ni mo lè ṣe tí èmi náà á fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí?’ Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò nípa àwọn ọ̀nà tí iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ń gbà mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.

 BÍ IṢẸ́ ÌSÌN ALÁKÒÓKÒ KÍKÚN ṢE Ń MÚ KÁ TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ

3. Ipa wo ló máa ń ní lórí wa nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, tá à ń sọ nípa ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá lọ́jọ́ iwájú?

3 Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá fáwọn èèyàn ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Nígbà tó o bá ń wàásù láti ilé dé ilé, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo lo fẹ́ràn láti máa lò? Ṣé Sáàmù 37:10, 11 ni, tàbí Dáníẹ́lì 2:44; tàbí Jòhánù 5:28, 29, tàbí Ìṣípayá 21:3, 4? Gbogbo ìgbà tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlérí Ọlọ́run, ńṣe ló máa ń mú wa rántí pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run wa tó jẹ́ ọ̀làwọ́ jẹ́ olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” Èyí sì ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn.—Ják. 1:17.

4. Kí nìdí tá a fi túbọ̀ ń mọyì oore Ọlọ́run tá a bá rí bí ebi tẹ̀mí ṣe ń han àwọn èèyàn léèmọ̀?

4 Bá a ṣe ń rí bí ebi tẹ̀mí ṣe ń han àwọn tá à ń bá pàdé lóde ẹ̀rí léèmọ̀, ńṣe la túbọ̀ ń mọyì òtítọ́ tá a ní. Àwọn èèyàn ayé ò ní ìtọ́sọ́nà tó ṣeé fọkàn tán tó lè mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí tó sì lè fún wọn láyọ̀. Ọ̀pọ̀ ló máa ń kọminú nípa ọjọ́ iwájú wọn, wọn ò sì nírètí. Wọn ò mọ ìdí tá a fi wà láyé. Àwọn tó tiẹ̀ lẹ́mìí ìsìn pàápàá ò fi bẹ́ẹ̀ mọ Ìwé Mímọ́. Ṣe lọ̀rọ̀ wọn dà bí tàwọn ara Nínéfè ìgbàanì. (Ka Jónà 4:11.) Bá a ṣe túbọ̀ ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, bẹ́ẹ̀ la túbọ̀ ń rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ipò tẹ̀mí àwọn tá à ń wàásù fún àti tàwa èèyàn Jèhófà. (Aísá. 65:13) Èyí ń mú ká máa rántí oore Jèhófà. Kì í ṣe pé ó ń pèsè ohun tá a nílò nípa tẹ̀mí nìkan ni, ó tún ń pe gbogbo èèyàn pé kí wọ́n wá gbà ìtura nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì ní ìrètí tó dájú.—Ìṣí. 22:17.

5. Bá a ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, báwo nìyẹn ṣe ń jẹ́ ká máa fojú tó tọ́ wo àwọn ìṣòro wa?

5 Bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí kì í jẹ́ kí àwọn ìṣòro tá a ní mu wá lómi. Arábìnrin Trisha tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí nígbà táwọn òbí rẹ̀ kọ ara wọn sílẹ̀. Ó sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn lohun tó bà mí nínú jẹ́ jù lọ nígbèésí ayé mi.” Lọ́jọ́ kan, inú rẹ̀ ò dùn rárá, ó sì ń ṣe é bíi pé kó kàn dúró sílé. Síbẹ̀, ó lọ sóde ẹ̀rí láti lọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ mẹ́ta kan tí ilé wọn ò tòrò. Bàbá wọn ti pa wọ́n tì, ẹ̀gbọ́n wọn àgbà tó jẹ́ ọkùnrin sì hùwà ìkà sí wọn. Trisha wá sọ pé: “Lóòótọ́ ni ìṣòrò ń bá mi fínra mo sì máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn, àmọ́ kékeré ni tèmi lẹ́gbẹ̀ẹ́ táwọn ọmọ yìí. Bí mo ṣe ń bá wọn kẹ́kọ̀ọ́, mo rí i lójú wọn pé wọ́n láyọ̀ inú wọn sì dùn gan-an. Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ọmọ yẹn jẹ́ fún mi, pàápàá lọ́jọ́ yẹn.”

6, 7. (a) Bá a ṣe ń fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn, báwo ló ṣe ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun? (b) Bá a ṣe ń rí i tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa ń fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò, báwo ló ṣe ń mú ká túbọ̀ mọrírì ọgbọ́n Ọlọ́run?

6 Bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn Júù kan nígbà ayé rẹ̀ tó jẹ́ pé wọn kì í ṣe ohun tí wọ́n ń wàásù, ó sọ nípa wọn pé: “Ǹjẹ́ ìwọ, . . . ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ?” (Róòmù 2:21) A láyọ̀ pé àwọn aṣáájú-ọ̀nà wa ò dà bí àwọn Júù wọ̀nyẹn. Ọ̀pọ̀ àǹfààní ni wọ́n ní láti ṣàlàyé òtítọ́ Bíbélì fún àwọn èèyàn kí wọ́n sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. Kí wọ́n lè máa kọ́ni lọ́nà tó múná dóko, wọ́n máa ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀, wọ́n sì tún lè ṣe ìwádìí kí wọ́n lè dáhùn ìbéèrè tí wọ́n bá bá pàdé lóde ẹ̀rí. Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Janeen sọ pé: “Gbogbo ìgbà tí mo bá láǹfààní láti kọ́ àwọn mìíràn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo máa ń nímọ̀lára pé òtítọ́ yẹn túbọ̀ wọ èmi fúnra mi lọ́kàn ṣinṣin. Nípa bẹ́ẹ̀, mi ò dà bí omi adágún nípa tẹ̀mí, ṣe ni ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ ń lágbára.”

7 Bá a ṣe ń rí i tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò ń mú ká túbọ̀ mọrírì ọgbọ́n Ọlọ́run. (Aísá. 48:17, 18) Èyí ń tipa bẹ́ẹ̀ mú ká túbọ̀ máa sapá láti máa fi àwọn ohun táwa náà ń kọ́ sílò. Aṣáájú-ọ̀nà míì tó ń jẹ́ Adrianna sọ pé: “Ṣe ni ìgbésí ayé àwọn tó bá gbára lé ọgbọ́n tara wọn  máa ń dojú rú. Àmọ́, gbàrà tí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbára lé ọgbọ́n Ọlọ́run ni wọ́n ti máa rí àǹfààní tó wà nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀.” Phil náà sọ pé: “Wẹ́rẹ́ báyìí ni Jèhófà máa ń yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà, tó sì jẹ́ pé nígbà tí àwọn alára sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀ fúnra wọn pàbó ló já sí.”

8. Tá a bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará wa lóde ẹ̀rí, ipa wo ló máa ń ní lórí wa?

8 Tá a bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará wa lóde ẹ̀rí, ó máa ń gbé wa ró nípa tẹ̀mí. (Òwe 13:20) Ọ̀pọ̀ aṣáájú-ọ̀nà ló máa ń bá àwọn ajíhìnrere bíi tiwọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tí wọ́n sì jọ máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ náà. Èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fún ara wọn níṣìírí. (Róòmù 1:12; ka Òwe 27:17.) Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Lisa sọ pé: “Níbi iṣẹ́, ẹ̀mí ìbánidíje, owú, òfófó àti ọ̀rọ̀ rírùn wọ́pọ̀ gan-an ni. Kò sóhun tí wọn ò lè ṣe torí kí wọ́n lè dépò iwájú. Wọ́n tiẹ̀ lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà míì tàbí kí wọ́n máa pẹ̀gàn wa nítorí pé ìwà wá yàtọ̀ sí tiwọn. Àmọ́ nígbà tá a bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará wa lóde ẹ̀rí, ó máa ń gbé wa ró gan-an. Kò sí bó ṣe lè rẹ̀ mí tó, nígbà tí mo bá dé ilé, ńṣe ni inú mi máa ń dùn.”

9. Bí tọkọtaya bá ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà, báwo ló ṣe máa ń mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?

9 Bí tọkọtaya bá jọ ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. (Oníw. 4:12) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Madeline tóun àti ọkọ rẹ̀ jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sọ pé: “Èmi àti ọkọ mi jọ máa ń sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe gbádùn òde ẹ̀rí lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, tàbí ká jíròrò bá a ṣe lè lo ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì kíkà wa lóde ẹ̀rí. Bá a ṣe ń pẹ́ sí i lẹ́nu iṣẹ́ yìí bẹ́ẹ̀ la túbọ̀ ń sún mọ́ra sí i.” Trisha náà sọ pé: “Èmi àtọkọ mi máa ń ṣọ́ra gan-an ka má bàa jẹ gbèsè, a ò sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ owó dá ìjà sílẹ̀ láàárín wa. Ètò kan náà làwa méjèèjì jọ ṣe fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Nípa bẹ́ẹ̀, a mọ àwọn  ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ara wa dáadáa. Èyí wá mú ká túbọ̀ lóye ara wa dáadáa, tí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà sì túbọ̀ lágbára.”

Tí ọwọ́ èèyàn bá dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, èèyàn máa ní ìfọkànbalẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 9)

10. Tá a bá ń fi àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́, tá a sì ń rí bí Ọlọ́run ṣe ń tì wá lẹ́yìn, báwo nìyẹn ṣe ń mú ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

10 Bá a ṣe ń fi ohun tó jẹ́ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, tá a sì ń rí bí Jèhófà ṣe ń tì wá lẹ́yìn àti bó ṣe ń dáhùn àdúrà wa, ńṣe la túbọ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé e. Dé ìwọ̀n àyè kan, bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn fún gbogbo Kristẹni tó jẹ́ olóòótọ́. Àmọ́, àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ti rí i pé báwọn ṣe ń gbára lé Jèhófà ló ń mú kí àwọn lè máa bá iṣẹ́ náà nìṣó. (Ka Mátíù 6:30-34.) Wọ́n sọ fún arákùnrin kan tó ń jẹ́ Curt tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àti adelé alábòójútó àyíká láti lọ bẹ ìjọ kan wò. Ó sì gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìrìn-àjò yìí máa gba kó wakọ̀ fún odindi wákàtí méjì ààbọ̀ kí òun àti ìyàwó rẹ̀ tóun náà jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tó débẹ̀. Ṣùgbọ́n epo tó wà nínú ọkọ̀ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan, ó lè gbé wọn lọ àmọ́ kò lè gbé wọn pa dà. Kò tún wá lówó lọ́wọ́ torí pé ó ṣì ku ọ̀sẹ̀ kan kó tó gba owó oṣù rẹ̀. Arákùnrin Curt wá sọ pé: “Ṣe ni mò ń bi ara mi bóyá ó tọ́ bí mo ṣe gbà láti lọ bẹ ìjọ tó jìnnà yẹn wò.” Ni wọ́n bá gbàdúrà sí Jèhófà, wọ́n sì gbà pé ó máa bójú tó wọn. Lẹ́yìn náà wọ́n pinnu láti lọ. Bó ṣe kù díẹ̀ kí wọ́n lọ ni arábìnrin kan pè wọ́n, ó sì sọ pé òun ní ẹ̀bùn kan tí òun fẹ́ fún wọn. Kò yà yín lẹ́nu pé iye owó tí wọ́n nílò gẹ́lẹ́ ni arábìnrin yẹn fún wọn. Arákùnrin Curt wá sọ pé: “Téèyàn bá ń ní irú ìrírí yìí látìgbàdégbà, ó máa ń jẹ́ kéèyàn rí i pé lóòótọ́ ni ọwọ́ Jèhófà wà lára òun.”

11. Sọ ìbùkún táwọn aṣáájú-ọ̀nà máa ń rí.

11 Àwọn aṣáájú-ọ̀nà ń rí i pé bí àwọn ṣe ń tara bọ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, táwọn sì túbọ̀ ń sún mọ́ ọn làwọn ń rí ìbùkún rẹ̀ gbà lọ́pọ̀ yanturu. (Diu. 28:2) Síbẹ̀, iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà náà ní àwọn ìpèníjà tirẹ̀. Kò sí ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro tí ìwà ọ̀tẹ̀ Ádámù dá sílẹ̀. Lóòótọ́, àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan ti fi iṣẹ́ ìsìn náà sílẹ̀ fúngbà díẹ̀ nítorí àwọn ìṣòro kan, àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ jẹ́ èyí tí wọ́n lè bójú tó tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ kó sí i rárá. Kí ló lè ran àwọn aṣáájú-ọ̀nà lọ́wọ́ tí wọ́n á fi máa gbádùn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wọn?

MÁ ṢE FI IṢẸ́ ÌSÌN AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ SÍLẸ̀

12, 13. (a) Kí ló yẹ kí aṣáájú-ọ̀nà kan ṣe tó bá ń ṣòro fún un láti ní iye wákàtí tá à ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí aṣáájú-ọ̀nà kan ṣètò àkókò rẹ̀ kó lè máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó máa dá kẹ́kọ̀ọ́, kó sì máa ṣàṣàrò?

12 Ọwọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà máa ń dí gan-an ni. Kò sì rọrùn láti ṣe gbogbo àwọn nǹkan tó yẹ ní ṣíṣe. Torí náà, ó yẹ kí wọ́n ṣètò àkókò wọn dáádáá. (1 Kọ́r. 14:33, 40) Tó bá ṣòro fún aṣáájú-ọ̀nà kan láti ní iye wákàtí tá à ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó lè gba pé kó tún yẹ bó ṣe ń lo àkókò rẹ̀ wò. (Éfé. 5:15, 16) Ó lè bi ara rẹ̀ pé: ‘Báwo ni àkókò tí mò ń lò nídìí eré ìdárayá tàbí eré ọwọ́dilẹ̀ ṣe pọ̀ tó? Ǹjẹ́ kò yẹ kí n túbọ̀ kó ara mi níjàánu? Ṣé mo lè dín àkókò tí mò ń lò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mi kù?’ Gbogbo wa la gbà pé ó rọrùn fáwọn nǹkan téèyàn ò wéwèé tẹ́lẹ̀ láti gba àkókò ẹni, nípa bẹ́ẹ̀, àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ní láti máa yẹ ìgbòkègbodò wọn wò lóòrèkóòrè kí wọ́n sì ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ.

13 Ó yẹ kí aṣáájú-ọ̀nà kan fi Bíbélì kíkà lójoojúmọ́, ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣe àṣàrò kún ìṣètò rẹ̀. Torí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí aṣáájú-ọ̀nà kan kó ara rẹ̀ ní ìjánu, kí àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì má bàa gbà á lákòókò, débi tí kò fi ní ráyè fún àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì. (Fílí. 1:10) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé aṣáájú-ọ̀nà kan ti lọ sóde ẹ̀rí látàárọ̀, ó sì ní in lọ́kàn pé tóun bá dé òun máa múra ìpàdé sílẹ̀. Àmọ́ nígbà tó dé, lẹ́tà tó dé fún un ló kọ́kọ́ kà. Lẹ́yìn náà, ó tan kọ̀ǹpútà rẹ̀ láti ka àwọn lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà kí ó sì fèsì wọn. Bákan náà, ó tún yẹ ìkànnì kan wò láti rí i bóyá iye owó ọjà  kan tó fẹ́ rà ti wálẹ̀. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, nǹkan bíi wákàtí méjì ti kọjá kò sì tíì bẹ̀rẹ̀ sí í múra ìpàdé tó ní lọ́kàn. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ yìí fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Ògbóǹkangí eléré ìdárayá kan gbọ́dọ̀ tọ́jú ara rẹ̀ dáádáá tó bá fẹ́ pẹ́ nídìí eré ìdárayá tó ń ṣe. Bákan náà, ó yẹ kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà ní ètò tó ṣe gúnmọ́ láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n bá fẹ́ máa bá a lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn.—1 Tím. 4:16.

14, 15. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wọn lọ́rùn? (b) Bí aṣáájú-ọ̀nà kan bá ní ìṣòro, kí ló yẹ kó ṣe?

14 Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ máa ń sapá láti jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wọn lọ́rùn. Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níṣìírí pé kí wọ́n jẹ́ kí ojú wọn mú ọ̀nà kan. (Mát. 6:22) Jésù alára jẹ́ kí ojú òun mú ọ̀nà kan kó bàa lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láìsí ìpínyà ọkàn. Ìdí nìyẹn tó fi lè sọ pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀sí, ṣùgbọ́n Ọmọ ènìyàn kò ní ibi kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” (Mát. 8:20) Tí aṣáájú-ọ̀nà kan bá máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ó yẹ kó ní in lọ́kàn pé bí òun bá ṣe ń kó ohun ìní tara jọ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni òun ṣe máa nílò àkókò tó láti máa bójú tó wọn, ṣàtúnṣe wọn, tàbí pààrọ̀ wọn.

15 Àwọn aṣáájú-ọ̀nà mọ̀ pé inú-rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí látọ̀dọ̀ Jèhófà ni àǹfààní iṣẹ́ ìsìn táwọn ní yìí, kì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe wọn. Torí náà, kí wọ́n lè máa bá a lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn náà, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n gbára lé Jèhófà. (Fílí. 4:13) Ká sòótọ́, a ò lè sá fún ìṣòrò. (Sm. 34:19) Àmọ́, tí ìṣòro bá dé, ó yẹ káwọn aṣáájú-ọ̀nà gbára lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, kí wọ́n sì jẹ́ kó ran àwọn lọ́wọ́ dípò kí wọ́n yára fi àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ní sílẹ̀. (Ka Sáàmù 37:5.) Bí wọ́n ṣe ń rí i tí Ọlọ́run ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ṣe ni wọ́n á túbọ̀ máa sún mọ́ Baba wọn ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wọn tó sì ń bójú tó wọn.—Aísá. 41:10.

ǸJẸ́ O LÈ ṢE AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ?

16. Tó bá wù ẹ́ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà, kí ló yẹ kó o ṣe?

16 Tíwọ náà bá fẹ́ máa rí ìbùkún táwọn aṣáájú-ọ̀nà ń rí, gbàdúrà sí Jèhófà. (1 Jòh. 5:14, 15) Bá àwọn tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ní àwọn àfojúsùn kan tí wàá máa lé táá mú kó o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ohun tí Arákùnrin Keith àti ìyàwó rẹ̀ Erika ṣe gan-an nìyẹn. Tẹ́lẹ̀, bíi tàwọn ojúgbà wọn, àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni wọ́n fi máa ń ṣiṣẹ́, kò sì pẹ́ rárá lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó tí wọ́n ra ilé kan àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tuntun kan. Wọ́n sọ pé: “A ronú pé àwọn nǹkan yẹn máa mú ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá.” Nígbà tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ Keith, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ó wá sọ pé: “Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà mú kí n rántí ayọ̀ téèyàn máa ń ní téèyàn bá wà lóde ẹ̀rí.” Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá tọkọtaya kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ṣọ̀rẹ́. Tọkọtaya yìí mú kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n máa láyọ̀ gan-an tí wọ́n bá jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wọn lọ́rùn, tí wọ́n sì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Kí wá ni Keith àti Erika ṣe? Wọ́n sọ pé, “A ṣe àkọsílẹ̀ àwọn àfojúsùn tẹ̀mí tá a ní, a lẹ̀ ẹ́ mọ́ ara fìríìjì wa, a sì máa ń fàmì sí èyí tí ọwọ́ wa bá ti tẹ̀.” Nígbà tó yá, wọ́n di aṣáájú-ọ̀nà.

17. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kó o ṣe ìyípadà tó bá yẹ kó o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà?

17 Ǹjẹ́ o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà? Tí kò bá rọrùn fún ẹ láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà báyìí, máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Tó o bá gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò tàdúrà-tàdúrà, o lè wá rí i pé wàá lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà tó o bá ṣètò àkókò rẹ dáadáa, tó o sì yí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ pa dà. Tó o bá ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ìwọ náà á wá rí i pé ayọ̀ tó o máa rí á kọjá àwọn ohun tó o fi du ara rẹ. Wàá ní ìtẹ́lọ́rùn téèyàn máa ń ní téèyàn bá fi àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú. (Mát. 6:33) Wàá túbọ̀ ní ayọ̀ téèyàn máa ń ní téèyàn bá ń fún àwọn ẹlòmíì ní nǹkan. Lékè gbogbo rẹ̀, wàá túbọ̀ ní àǹfààní láti máa ronú nípa Jèhófà àti láti máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, wàá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wàá sì máa mú ọkàn rẹ̀ yọ̀.