Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́ Kí Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Máa Múnú Rẹ Dùn

Jẹ́ Kí Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Máa Múnú Rẹ Dùn

“Mo ti gba àwọn ìránnilétí rẹ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—SM. 119:111.

1. (a) Kí làwa èèyàn máa ń ṣe tí wọ́n bá rán wa létí ohun tá a ti mọ̀? Kí nìdí tá a fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀? (b) Báwo ni ìgbéraga ṣe lè nípa lórí ojú téèyàn fi ń wo ìmọ̀ràn?

OHUN tí àwa èèyàn máa ń ṣe tá a bá gba ìtọ́ni yàtọ̀ síra. Tí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ bá rán wa létí ohun kan, ó ṣeé ṣe ká fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gbà á, àmọ́ tó bá jẹ́ ojúgbà wa tàbí ẹni tí kò tó wa ló fún wa nímọ̀ràn, ó lè jẹ́ pé ṣe la máa kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà nù kó tiẹ̀ tó sọ ọ́ tán. Bó ṣe máa ń rí lára wa nígbà tí wọ́n bá bá wa wí tàbí tí wọ́n bá fún wa nímọ̀ràn máa ń yàtọ̀ síra gan-an. A lè banú jẹ́, a lè ní ẹ̀dùn ọkàn tàbí kí ohun tí wọ́n sọ kó ìtìjú bá wa. Ọ̀rọ̀ náà sì lè mú ká yẹ ara wa wò, ká gbà pé ọ̀rọ̀ náà kàn wá, ó sì lè mú ká ṣàtúnṣe tó yẹ. Kí ló máa ń mú kí ojú téèyàn fi ń wo ìmọ̀ràn yàtọ̀? Ọ̀kan lára ohun tó máa ń fà á ni ìgbéraga. Ká sòótọ́, ìgbéraga lè mú kéèyàn fojú tí kò tọ́ wo ìmọ̀ràn, ní ti pé ó lè mú kéèyàn pa ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un tì, kí ìyẹn sì mú kó pàdánù àǹfààní tó wà nínú irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀.—Òwe 16:18.

2. Kí nìdí táwa Kristẹni tòótọ́ fi mọrírì ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

2 Àmọ́, àwa Kristẹni tòótọ́ mọrírì àwọn ìmọ̀ràn àtàtà, pàápàá tí wọ́n bá gbé irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ìránnilétí Jèhófà ń mú ká ní ìjìnlẹ̀ òye, ó ń kọ́ wa, ó sì ń mú ká yẹra fún àwọn ìdẹkùn bí ìfẹ́ ọrọ̀, ìṣekúṣe, ìjoògùnyó tàbí ọtí àmujù. (Òwe 20:1; 2 Kọ́r. 7:1; 1 Tẹs. 4:3-5; 1 Tím. 6:6-11) Láfikún sí i, inú wa ń dùn pé a ní “ipò rere ọkàn-àyà” torí pé à ń fi àwọn ìránnilétí Ọlọ́run sílò.—Aísá. 65:14.

3. Ẹ̀mí rere tí onísáàmù ní wo ló yẹ káwa náà ní?

3 Tá ò bá fẹ́ kí àjọṣe tó ṣeyebíye tá a ní pẹ̀lú Baba wa ọ̀run bà jẹ́, a gbọ́dọ̀ máa fi ìtọ́ni Jèhófà sílò ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Ẹ wo bó ṣe máa dára tó tá a bá lè ní irú ẹ̀mí tí onísáàmù ní, ó sọ pé: “Mo ti gba àwọn ìránnilétí rẹ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní fún àkókò  tí ó lọ kánrin, nítorí pé àwọn ni ayọ̀ ńláǹlà ọkàn-àyà mi”! (Sm. 119:111) Ǹjẹ́ inú tiwa náà máa ń dùn sí àwọn òfin Jèhófà, àbí ńṣe la máa ń kà wọ́n sí ìnira nígbà míì? Tá a bá tiẹ̀ ń bínú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan torí pé wọ́n fún wa láwọn ìmọ̀ràn kan, kò yẹ ka torí ẹ̀ sorí kọ́. Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nítorí pé ọgbọ́n rẹ̀ kò láfiwé. Ní báyìí, a máa jíròrò ohun mẹ́ta tó lè mú ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

MÁA GBÀDÚRÀ

4. Kí lohun kan tí kò yí pa dà nígbèésí ayé Dáfídì?

4 Nǹkan ò fara rọ fún Dáfídì Ọba nígbá ayé rẹ̀, àmọ́ ohun kan wà tí kò yí pa dà, ìyẹn ni bó ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, Ẹlẹ́dàá rẹ̀ pátápátá. Dáfídì sọ pé: “Jèhófà, ọ̀dọ̀ rẹ ni mo gbé ọkàn mi gan-an sókè sí. Ìwọ Ọlọ́run mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.” (Sm. 25:1, 2) Kí ló mú kí Dáfídì ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ nínú Baba rẹ̀ ọ̀run?

5, 6. Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa nípa àjọṣe tó wà láàárín Dáfídì àti Jèhófà?

5 Ìgbà tí àwọn èèyàn kan bá wà nínú ìṣòro nìkan ni wọ́n máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó bá jẹ́ pé ìgbà tí ọ̀rẹ́ tàbí ìbátan rẹ kan bá nílò owó tàbí ojúure rẹ nìkan ló máa ń pè ọ́? Tó bá yá, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ohun tó máa rí gbà ló ń wá, kì í ṣe pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ ní ti gidi. Àmọ́ Dáfídì kì í ṣe irú èèyàn bẹ́ẹ̀. Ó hàn nínú àjọṣe tí Dáfídì ní pẹ̀lú Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ pé ó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ó sì tún nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, lọ́jọ́ dídùn àti lọ́jọ́ kíkan.—Sm. 40:8.

6 Kíyè sí ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nígbà tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó sì ń yìn ín lógo, ó sọ pé: “Ìwọ Jèhófà Olúwa wa, orúkọ rẹ mà kún fún ọlá ńlá ní gbogbo ilẹ̀ ayé o, ìwọ tí a ń ròyìn iyì rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ lókè ọ̀run!” (Sm. 8:1) Ǹjẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn kò fi hàn pé Dáfídì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Baba rẹ̀ ọ̀run? Dáfídì mọyì bí Ọlọ́run ṣe tóbi lọ́lá àti bí ògo rẹ̀ ṣe pọ̀ tó, ìyẹn ló mú kó máa yin Jèhófà “láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”—Sm. 35:28.

7. Àǹfààní wo là ń rí bá a ṣe ń sún mọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà?

7 Bíi ti Dáfídì, ó yẹ káwa náà máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo ká lè túbọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Ják. 4:8) Bá a ṣe ń sún mọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà tún jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tá a fi ń rí ẹ̀mí mímọ́ gbà.—Ka 1 Jòhánù 3:22.

8. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa sọ àsọtúnsọ tá a bá ń gbàdúrà?

8 Tó o bá ń gbàdúrà, ṣé o máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan ní àsọtúnsọ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kó o tó gbàdúrà máa lo ìṣẹ́jú mélòó kan láti ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó o fẹ́ sọ. Wò ó báyìí ná: Ká sọ pé àwọn ọ̀rọ̀ kan náà lo máa ń sọ ní àsọtúnsọ ní gbogbo ìgbà tó o bá ń bá ọ̀rẹ́ tàbí ìbátan rẹ kan sọ̀rọ̀, báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára rẹ̀? Ó lè má kọbi ara sí ọ̀rọ̀ rẹ mọ́. Òótọ́ ni pé Jèhófà máa tẹ́tí sí àdúrà àtọkànwá táwa ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ bá ń gbà. Àmọ́, kò ní dára ká máa sọ ohun kan náà ní gbogbo ìgbà tá a bá ń gbàdúrà sí i.

9, 10. (a) Àwọn nǹkan wo la lè sọ tá a bá ń gbàdúrà? (b) Kí ló lè mú ká máa gbàdúrà látọkànwá?

9 Ó ṣe kedere pé tá a bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run, àdúrà wa kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ orí ahọ́n. Bí a bá ṣe ń gbàdúrà sí Jèhófà látọkànwá tó, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe túbọ̀ sún mọ́ ọn, bẹ́ẹ̀ náà la ṣe máa túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e. Àmọ́, àwọn nǹkan wo la lè sọ nínú àdúrà wa? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” (Fílí. 4:6) Kókó náà ni pé, bí ohunkóhun bá wà tó lè nípa lórí àjọṣe wà pẹ̀lú Ọlọ́run tàbí lórí ìgbésí ayé wa, ó yẹ ká mẹ́nu kàn án nínú àdúrà wa.

10 A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àdúrà táwọn  ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ gbà, èyí tó wà nínú Bíbélì. (1 Sám. 1:10, 11; Ìṣe 4:24-31) Àwọn orin àti àdúrà àtọkànwá sí Jèhófà ló kún inú ìwé Sáàmù. Onírúurú ìmọ̀lára táwa èèyàn máa ń ní bóyá nígbà tí inú èèyàn bá ń dùn ni ò tàbí nígbà tínú èèyàn bá bà jẹ́ ló wà nínú àdúrà àti orin wọ̀nyẹn. Tá a bá ń fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ táwọn olóòótọ́ yẹn sọ, àdúrà tá à ń gbà sí Jèhófà máa túbọ̀ nítumọ̀.

MÁA ṢÀṢÀRÒ LÓRÍ ÀWỌN ÌRÁNNILÉTÍ ỌLỌ́RUN

11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣàṣàrò lórí ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

11 Dáfídì sọ pé: “Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n.” (Sm. 19:7) Àní tá ò bá tiẹ̀ ní ìrírí, àá di ọlọ́gbọ́n tá a bá ń pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́. Àmọ́ ṣá o, àwọn ìmọ̀ràn kan wà nínú Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ pé tá a bá máa jàǹfààní nínú wọn, a gbọ́dọ̀ ṣàṣàrò lé wọn lórí. Èyí jóòótọ́ tó bá kan àwọn ọ̀ràn to gba pé ká jẹ́ adúróṣinṣin. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn lè máa rọ̀ wá pé ká ṣe ohun tí kò tọ́, bóyá níléèwé tàbí lẹ́nu iṣẹ́ wa. A lè dojú kọ ipò tó ń béèrè pé ká tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ tàbí pé ká má ṣe lọ́wọ́ sí ìṣèlú tàbí ogun. Ó sì lè jẹ́ ọ̀rọ̀ tó kan fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nípa aṣọ wíwọ̀ àti ìmúra. Tá a bá ti mọ èrò Ọlọ́run lórí àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká lè múra ọkàn wa sílẹ̀, àá sì lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe tí a bá bá ara wa nírú ipò bẹ́ẹ̀. Tá a bá ti ṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ṣáájú tá a sì ti múra sílẹ̀, a ò ní kábàámọ̀.—Òwe 15:28.

12. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká máa ronú lé táá jẹ́ ká máa fi ìránnilétí Ọlọ́run sọ́kàn?

12 Bá a ṣe ń retí ìgbà tí Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ǹjẹ́ bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa fi hàn pé a ṣì wà lójúfò? Bí àpẹẹrẹ, ṣé òótọ́ la gbà pé ìparun máa tó dé bá Bábílónì Ńlá? Ǹjẹ́ àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú, bíi gbígbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé ṣì wà lọ́kàn wa digbí bó ṣe rí nígbà tá a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ wọn? Ṣé ìtara wa fún iṣẹ́ ìwàásù kò ti máa jó rẹ̀yìn torí pé à ń bójú tó ọ̀ràn ara ẹni? Ṣé ọ̀rọ̀ nípa ìrètí àjíǹde, sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ àti bó ṣe máa dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run láre ṣì ṣe pàtàkì sí wa? Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí irú àwọn ìbéèrè yìí, àá lè máa ṣe ohun tí onísáàmù náà sọ, àá máa pa ‘àwọn ìránnilétí Ọlọ́run mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní fún àkókò tí ó lọ kánrin’.—Sm. 119:111.

13. Kí nìdí táwọn nǹkan kan kò fi yé àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní? Sọ àpẹẹrẹ kan.

13 Ní báyìí, a lè má fi bẹ́ẹ̀ lóye àwọn nǹkan kan nínú Bíbélì torí pé kò tíì tó àkókò tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe kedere. Léraléra ni Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ó pọn dandan pé kí òun jìyà kí òun sì kú. (Ka Mátíù 12:40; 16:21.) Àmọ́, àwọn àpọ́sítélì kò lóye ọ̀rọ̀ náà. Ẹ̀yìn ìgbà tí Jésù kú, tó jíǹde, tó sì fara han àwọn kan lára wọn ni wọ́n tó lóye ọ̀rọ̀ náà. Lákòókò yẹn, ó “ṣí èrò inú wọn payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ láti mòye ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.” (Lúùkù 24:44-46; Ìṣe 1:3) Bákan náà, ìgbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ló tó yé wọ́n pé ọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run máa wà.—Ìṣe 1:6-8.

14. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, ohun tó dára tá a lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀ wo làwọn ará wa kan ṣe nígbà tí wọn kò lóye àlàyé nípa ọjọ́ ìkẹyìn?

14 Ohun tó jọ èyí ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ní èrò tí kò tọ́ nípa “ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tím. 3:1) Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1914, àwọn kan rò pé àkókò ti tó tí àwọn máa lọ sọ́run. Nígbà tí wọ́n rí i pé ibi táwọn fojú sí ọ̀nà kò gba ibẹ̀, wọ́n tún Ìwé Mímọ́ yẹ̀ wò, wọ́n wá rí i pé àwọn ní púpọ̀ láti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Máàkù 13:10) Nípa bẹ́ẹ̀, lọ́dún 1922, Arákùnrin J. F. Rutherford, tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù rọ àwọn tó péjọ sí àpéjọ àgbáyé tí wọ́n ṣe ní Cedar Point,  ní ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pé: “Ẹ wò ó, Ọba náà ti ń ṣàkóso! Ẹ̀yin ni aṣojú tí ń polongo rẹ̀. Torí náà, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.” Látìgbà yẹn, àwọn èèyàn ti mọ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní mọ iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere ìjọba náà.”—Mát. 4:23; 24:14.

15. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ṣàṣàrò lórí bí Ọlọ́run ṣe darí àwọn èèyàn rẹ̀?

15 Bá a ṣe ń ṣàṣàrò lórí ọ̀nà àgbàyanu tí Jèhófà gbà darí àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà yẹn lọ́hùn-ún àti bó ṣe ń darí wa lákòókò yìí ń mú ká túbọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé lọ́jọ́ iwájú, á mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, á sì ṣe ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé. Bákan náà, àwọn ìránnilétí Ọlọ́run máa ń mú wa ronú nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí kò tíì nímùúṣẹ, ó sì máa ń sọ wọ́n dọ̀tun lọ́kàn wa. Ẹ jẹ́ kí ó dá wa lójú pé tá a bá ń ṣàṣàrò lórí wọn àá túbọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.

MÁA LỌ́WỌ́ NÍNÚ ÌGBÒKÈGBODÒ TẸ̀MÍ

16. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù?

16 Ọlọ́run alágbára ni Jèhófà, kì í fi nǹkan falẹ̀ rárá. Onísáàmù náà béèrè pé: “Ta ni ó ní okun inú bí ìwọ, Jáà?” Ó wá fi kún un pé: “Ọwọ́ rẹ le, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni a gbé ga.” (Sm. 89:8, 13) Ohun tí onísáàmù yìí sọ bá a mu gan-an, torí pé Jèhófà mọyì bá a ṣe ń lọ́wọ́ nínú àwọn ohun tó jẹ mọ́ ire Ìjọba Ọlọ́run, ó sì máa ń bù kún wa. Ó ń rí bí àwa ìránṣẹ́ rẹ̀, lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà ṣe ń tiraka. A ò jókòó tẹtẹrẹ, ká wá máa jẹ “oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.” (Òwe 31:27) À ń fara wé Ẹlẹ́dàá wa ní ti pé à ń jẹ́ kí ọwọ́ wa dí gan-an lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Àwa fúnra wa máa ń rí àǹfààní bá a ṣe ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, inú Jèhófà náà sì ń dùn láti bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.—Ka Sáàmù 62:12.

17, 18. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìwà ìṣòtítọ́ máa ń múni fọkàn tán ìtọ́ni Jèhófà? Sọ àpẹẹrẹ kan.

 17 Báwo ni ìwà ìṣòtítọ́ ṣe ń mú ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà? Ronú nípa ohun tí Bíbélì sọ pé ó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Jèhófà ti sọ fáwọn àlùfáà tó gbé àpótí májẹ̀mú pé kí wọ́n wọnú Odò Jọ́dánì. Àmọ́, bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sún mọ́ odò Jọ́dánì, wọ́n rí i pé odò náà ti kún àkúnya torí pé àsìkò òjò ni. Kí làwọn èèyàn náà máa ṣe o? Ṣé wọ́n á pàgọ́ sétí odò ni, kí wọ́n dúró fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan títí odò náà fi máa fà? Rárá o, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, wọ́n sì tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Bíbélì sọ pé: ‘Bi awọn alufa ti o ru apoti naa [ṣe] tẹ ẹsẹ wọn bọ etí omi naa, omi ti nti oke ṣan wa duro. Awọn alufa ti o ru apoti majẹmu OLUWA duro ṣinṣin lori ilẹ gbigbẹ laarin Jordani, titi gbogbo awọn eniyan naa fi goke Jordani tan.’ (Jóṣ. 3:12-17, Bíbélì Ajuwe) Ẹ wo bí inú àwọn èèyàn náà ti máa dùn tó nígbà tí wọ́n rí i tí omi tó ń ru gùdù náà dúró digbí! Kò sí àní-àní pé ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì túbọ̀ lágbára torí pé wọ́n fọkàn tán ìtọ́ni Jèhófà.

Ṣé ìwọ náà máa fi hàn pé o ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé táwọn èèyàn Jèhófà ní lọ́jọ́ Jóṣúà? (Wo ìpínrọ̀ 17 àti 18)

18 Lóòótọ́, Jèhófà kì í ṣe irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ mọ́ fún àwa èèyàn rẹ̀ lóde òní. Àmọ́, bí a ti ń ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú rẹ̀, ó ń bù kún wa. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ń fún wa lókun láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wa, ìyẹn láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Kristi Jésù tó jẹ́ òléwájú Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé òun á máa tì wọ́n lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ pàtàkì yìí, ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn . . . Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:19, 20) Àwọn tí wọ́n ń tijú tàbí tí wọ́n ń bẹ̀rù tẹ́lẹ̀ lára wa lè jẹ́rìí sí i pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló ran àwọn lọ́wọ́ láti máa fìgboyà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí.—Ka Sáàmù 119:46; 2 Kọ́ríńtì 4:7.

19. Tá ò bá tiẹ̀ lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run, kí lohun tó dá wa lójú?

19 Àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó kò jẹ́ kí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kan lè ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́. Síbẹ̀ ohun tó dájú ni pé, “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” mọ ìṣòro tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní. (2 Kọ́r. 1:3) Ó mọrírì gbogbo ohun tá à ń ṣe láti mú kí ire Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú. Bá a ti ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láìka ìṣòro tá a lè ní sí, ǹjẹ́ kí gbogbo wa fi sọ́kàn pé ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ẹbọ ìràpadà Kristi lohun náà gan-an tó ń pa ọkàn wa mọ́ láàyè.—Héb. 10:39.

20, 21. Sọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a gbà ń fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

20 À ń lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa nínú ìjọsìn Jèhófà débi tí agbára wa bá gbé e dé. Ká sòótọ́, gbogbo ọkàn wa la fẹ́ máa fi “ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere.” (2 Tím. 4:5) Ó sì dájú pé inú wa máa ń dùn láti ṣe iṣẹ́ náà, torí pé à ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti “wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Ó ṣe kedere pé bá a ṣe ń bọlá fún Jèhófà tá a sì ń yìn ín lógo, ó ń mú ká lọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí. (Òwe 10:22) Ó sì ń mú ká túbọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ẹlẹ́dàá wa.—Róòmù 8:35-39.

21 Bá a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ò lè dẹni tó ń fọkàn tán àwọn ìtọ́ni Jèhófà ní ọ̀sán kan òru kan, a gbọ́dọ̀ sapá gidigidi ká tó lè nírú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, máa gbára lé Jèhófà nígbà gbogbo nípasẹ̀ àdúrà. Máa ṣàṣàrò nípa bí Jèhófà ṣe mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ nígbà àtijọ́ àti bó ṣe máa mú un ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. Máa lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tẹ̀mí, wàá sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára. Ó dájú pé àwọn ìránnilétí Jèhófà máa wà títí ayé. Ó sì dájú pé ìwọ alára náà lè wà títí lọ gbére!