Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  August 2013

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn òbí máa jókòó ti ọmọ wọn tá a yọ lẹ́gbẹ́ láwọn ìpàdé ìjọ?

Kò sídìí láti máa fa ọ̀rọ̀ lórí ibì tó yẹ kí ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́ máa jókòó nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwé ìròyìn yìí ti fún àwọn òbí níṣìírí pé kí wọ́n ṣèrànwọ́ fún nípa tẹ̀mí àwọn ọmọ wọn tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ àmọ́ tí wọ́n ṣì ń gbé lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Àlàyé tá a ṣe nínú ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́ Naa November 15, 1988, ojú ìwé 19 àti 20, fi hàn pé òbí kan tiẹ̀ lè ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ tí kò tíì tójúúbọ́ tá a yọ lẹ́gbẹ́ àmọ́ tó ṣì ń gbé pẹ̀lú wọn. A retí pé èyí á fún ọmọ náà níṣìírí láti ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ.

Ó máa bọ́gbọ́n mu pé kí ọmọ kan tí kò tíì tójúúbọ́ tá a yọ lẹ́gbẹ́ jókòó jẹ́ẹ́ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Torí pé kò sí òfin tó sọ pé ẹ̀yìn ni kí ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́ máa jókòó nípàdé, a jẹ́ pé kò burú bí ọmọ tá a yọ lẹ́gbẹ́ bá jókòó ti àwọn òbí rẹ̀ níbikíbi tí wọ́n bá jókòó. Torí pé ire ọmọ náà nípa tẹ̀mí jẹ àwọn òbí rẹ̀ lógún, wọ́n máa rí i pé ọmọ náà ń jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ láwọn ìpàdé. Tí wọ́n bá jẹ́ kí ọmọ náà jókòó tì wọ́n, dípò kó dá jókòó níbòmíì, á ṣeé ṣe fún ọmọ náà láti pọkàn pọ̀.

Ká wá sọ pé ọmọ tá a yọ lẹ́gbẹ́ náà ò gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ mọ́ ńkọ́? Ṣé òun náà lè máa jókòó ti àwọn òbí rẹ̀? Nínú àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn yìí tó ti kọjá, a ti ṣàlàyé ohun tó yẹ kí Kristẹni kan ṣe tó bá kan ọ̀rọ̀ kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí kan tá a yọ lẹ́gbẹ́ àmọ́ tí wọn ò jọ gbé pọ̀. * Àmọ́ o, ohun kan ni pé kí ẹni tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ pé kó jókòó jẹ́ẹ́ pẹ̀lú àwọn ìbátan rẹ̀ nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́, nǹkan ọ̀tọ̀ pátápátá sì ni pé kí wọ́n máa wá ọ̀nà láti kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láìsí ìdí kan tó ṣe gún mọ́. Bí àwọn ará ilé ẹní tá a yọ lẹ́gbẹ́ náà bá mọ ààlà tó yẹ kó wà láàárín àwọn àti ẹni tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú Ìwé Mímọ́ pé ká má ṣe kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ̀, kò ní sí wàhálà kankan lórí ọ̀rọ̀ yìí.—1 Kọ́r. 5:11, 13; 2 Jòh. 11.

Torí náà, kò sídìí láti máa fa ọ̀rọ̀ lórí bóyá ẹnì kan tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ jókòó ti àwọn ìbátan rẹ̀ tàbí àwọn ará míì nínú ìjọ, tí onítọ̀hún bá ṣáà ti jókòó jẹ́ẹ́. Onírúurú ìṣòro ló lè wáyé tá a bá fòté lé e pé ìbi kan ló yẹ káwọn kan jókòó nípàdé, bó tilẹ̀ jẹ́ ipò nǹkan lè gba pé káwọn kan jókòó sí apá ibì kan pàtó. Tórí náà, tí gbogbo wa àti ìdílé ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́ bá ń sapá láti tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ lórí ìyọlẹ́gbẹ́, kò sídìí tó fi yẹ ká máa fa ọ̀rọ̀ lórí ìbi tó yẹ káwọn tó wá sí ìpàdé jókòó sí, tá ò bá ṣáà ti ṣe ohunkóhun tó lè mú àwọn mìíràn kọsẹ̀. *

^ ìpínrọ̀ 5 Wo Ile-Iṣọ Naa January 15, 1982, ojú ìwé 29 àti 30.

^ ìpínrọ̀ 6 Èyí jẹ́ àtúnṣe sí ohun tá a ti sọ nínú Ilé Ìṣọ́ April 1, 1953, (Gẹ̀ẹ́sì) ojú ìwé 223.