‘Kí ni yóò jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?’—MÁT. 24:3.

1. Kí ló ń wù wá láti mọ̀, bíi ti àwọn àpọ́sítélì?

NÍGBÀ tó ku díẹ̀ kí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fẹ́ mọ bí nǹkan ṣe máa rí fún wọn lọ́jọ́ ọ̀la. Torí náà, ní ọjọ́ mélòó kan kí Jésù tó kú, mẹ́rin lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mát. 24:3; Máàkù 13:3) Nígbà tí Jésù máa dáhùn, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oríṣiríṣi nǹkan tó gbàfiyèsí tó máa ṣẹlẹ̀, èyí tó wà nínú Mátíù orí 24 àti 25. Àwọn ohun tó sọ yìí ṣe pàtàkì sí wa gan-an torí pé àwa náà fẹ́ láti mọ bí nǹkan ṣe máa rí fún wa lọ́jọ́ ọ̀la.

2. (a) Kí ló ti ń wù wá pé ká túbọ̀ lóye látọjọ́ tó ti pẹ́? (b) Ìbéèrè mẹ́ta wo la máa jíròrò?

2 Ọjọ́ pẹ́ táwa ìránṣẹ́ Jèhófà ti máa ń gbàdúrà pé ká túbọ̀ lóye àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa ọjọ́ ìkẹyìn. Ó máa ń wù wá pé ká túbọ̀ lóye àkókò náà gan-an tí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù máa ṣẹ. Ní báyìí, a máa gbé ìbéèrè mẹ́ta kan yẹ̀ wò tó máa jẹ́ ká rí i pé òye wa ti túbọ̀ ṣe kedere. Àwọn ìbéèrè náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú “ìgbà wo?” Èkíní, ìgbà wo ni “ìpọ́njú ńlá” máa bẹ̀rẹ̀? Èkejì, ìgbà wo ni Jésù máa ṣèdájọ́ àwọn “àgùntàn” àti “ewúrẹ́”? Ẹ̀kẹta, ìgbà wo ni Jésù “ń bọ̀” tàbí ìgbà wo ló máa dé?—Mát. 24:21; 25:31-33.

ÌGBÀ WO NI ÌPỌ́NJÚ ŃLÁ MÁA BẸ̀RẸ̀?

3. Òye wo la ní tẹ́lẹ̀ nípa ìpọ́njú ńlá?

3 Láwọn àkókò kan, a gbà pé ìpọ́njú ńlá bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 1914. Èrò wa tún ni pé Jèhófà “ké ọjọ́ wọnnì kúrú” lọ́dún 1918 nígbà tí ogun yẹn parí, kí àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró lè wàásù ìhìn rere dé gbogbo orílẹ̀-èdè. (Mát. 24:21, 22) A gbà pé tí iṣẹ́ ìwàásù náà bá ti parí, Ọlọ́run máa pa ìṣàkóso Sátánì run. Èyí wá mú ká ronú pé ìpele mẹ́ta  ni ìpọ́njú ńlá pín sí: Ó ní ìbẹ̀rẹ̀ (1914 sí 1918), Ọlọ́run ké ìpọ́njú náà kúrú (látọdún 1918 síwájú), ó sì máa parí pẹ̀lú ogun Amágẹ́dọ́nì.

4. Òye wo la ní tó mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa ọjọ́ ìkẹyìn túbọ̀ ṣe kedere?

4 Àmọ́ nígbà tá a túbọ̀ gbé àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa ọjọ́ ìkẹyìn yẹ̀ wò, a wá lóye pé ẹ̀ẹ̀mejì ni apá kan lára àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ní ìmúṣẹ. (Mát. 24:4-22) Ìmúṣẹ àkọ́kọ́ ti wáyé nílẹ̀ Jùdíà ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, nígbà tí ìmúṣẹ ẹ̀ẹ̀kejì jẹ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí, ó sì máa kárí ayé. Òye tuntun tá a ní yìí mú ká tún àwọn àlàyé kan ṣe. *

5. (a) Ìgbà tó nira wo ló bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914? (b) Ìgbà wo ni irú ìroragógó wàhálà yìí wáyé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni?

5 A tún wá mọ̀ pé ọdún 1914 kọ́ ni ìpọ́njú ńlá bẹ̀rẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé nígbà tí Bíbélì ń sọ bí ìpọ́njú ńlá ṣe máa bẹ̀rẹ̀, gbígbéjà ko ìsìn èké ló sọ pé ó máa fi bẹ̀rẹ̀, kì í ṣe ogun láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Nípa bẹ́ẹ̀, ogun tó bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 1914 kì í ṣe ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà.” (Mát. 24:8) Irú “ìroragógó wàhálà” yìí ló ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà láàárín ọdún 33 sí 66 Sànmánì Kristẹni.

6. Báwo la ṣe máa mọ̀ tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀?

6 Báwo la ṣe máa mọ̀ tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀? Jésù sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nípasẹ̀ Dáníẹ́lì wòlíì, (kí òǹkàwé lo ìfòyemọ̀,) nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” (Mát. 24:15, 16) Ìmúṣẹ àkọ́kọ́ wáyé lọ́dún 66 Sànmánì Kristẹni. Lọ́dún yẹn, àwọn ọmọ ogun Róòmù (tó dúró fún “ohun ìríra”) gbéjà ko Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì (tí àwọn Júù kà sí ibi mímọ́). Ìmúṣẹ ẹ̀ẹ̀kejì máa wáyé nígbà tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (tó ṣàpẹẹrẹ “ohun ìríra”  ti òde òní) bá “dúró” tàbí tó bá gbéjà ko ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì (tí àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ gbà pé ó jẹ́ mímọ́) tó sì tún gbéjà ko gbogbo apá tó ṣẹ́ kù lára Bábílónì Ńlá. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà yìí ni Ìṣípayá 17:16-18 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Torí náà, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló máa bẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá.

7. (a) Báwo ni a ṣe gba “ẹran ara” là ní ọ̀rúndún kìíní? (b) Kí la lè retí pé yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

7 Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A óò ké ọjọ́ wọnnì kúrú.” Ọdún 66 Sànmánì Kristẹni ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí kọ́kọ́ ṣẹ. Nígbà yẹn, àwọn ọmọ ogun Róòmù ké àkókó tí wọ́n fi gbéjà ko Jerúsálẹ́mù kúrú. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà sá kúrò nílùú kí a lè gba “ẹran ara,” [tàbí ẹ̀mí] wọn là. (Ka Mátíù 24:22; Mál. 3:17) Torí náà, kí la lè retí pé yòó ṣẹlẹ̀ lákòókò ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀? Jèhófà máa ké àkókò tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè fi máa gbéjà ko ìsìn èké kúrú, ní ti pé kò ní jẹ́ kí ó pa ìsìn tòótọ́ run pa pọ̀ mọ́ ìsìn èké. Èyí á mú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run rí ìgbàlà.

8. (a) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló máa wáyé lẹ́yìn tí apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà bá ti kọjá? (b) Ìgbà wo ló jọ pé ẹni tó bá gbẹ̀yìn sáyé lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa lọ sí ọ̀run? (Wo àfikún àlàyé.)

 8 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà bá ti kọjá? Jésù fi hàn pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣì máa wáyé kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀. Kí làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà? Inú àkọsílẹ̀ tó wà nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì 38:14-16 àti Mátíù 24:29-31, la ti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. (Kà á.) * Ẹ̀yìn ìyẹn ni ogun Amágẹ́dọ́nì máa jà. Ogun Amágẹ́dọ́nì yìí ló máa kẹ́yìn ìpọ́njú ńlá, bí ìgbà tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run ní ọdún 70 Sànmánì Kristẹni. (Mál. 4:1) Bó ṣe jẹ́ pé ogun Amágẹ́dọ́nì ló máa kẹ́yìn, ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ yìí máa ṣàrà ọ̀tọ̀ ní ti pé, ó máa jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ “tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí.” (Mát. 24:21) Ẹ̀yìn  ìgbà yẹn ni Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi máa wá bẹ̀rẹ̀.

9. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa ìpọ́njú ńlá ṣe rí lára àwa èèyàn Jèhófà?

9 Ẹ ò rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìpọ́njú ńlá yìí fúnni lókun gan-an. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó jẹ́ kó dá wa lójú pé ìnira yòówù tí ì báà dojú kọ wá, àwa èèyàn Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, máa là á já. (Ìṣí. 7:9, 14) Paríparí rẹ̀, inú wa dùn pé Jèhófà máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, àwọn èèyàn á sì gbà pé òun ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run.—Sm. 83:18; Ìsík. 38:23.

ÌGBÀ WO NI JÉSÙ MÁA ṢÈDÁJỌ́ ÀWỌN ÀGÙNTÀN ÀTI EWÚRẸ́?

10. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, òye wo la ní nípa ìyàsọ́tọ̀ àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́?

10 Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò ìgbà tí apá mìíràn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù máa ṣẹ, ìyẹn àkàwé tó sọ nípa ìdájọ́ àwọn tó fi wé àgùntàn àti ewúrẹ́. (Mát. 25:31-46) Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, a rò pé látìgbà tí Jésù ti di ọba lọ́dún 1914 ló ti ń ṣèdájọ́ àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tàbí ewúrẹ́ àti pé ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ ìkẹyìn. Nígbà yẹn, a gbà pé àwọn tó kọ etí ikún sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n sì kú kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀ jẹ́ ewúrẹ́, torí náà wọn kò ní jíǹde.

11. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe ọdún 1914 ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwọn èèyàn sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tàbí ewúrẹ́?

11 Lọ́dún 1995, ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà tún ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ inú Mátíù 25:31, tó sọ pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀.” Ìwé ìròyìn náà ṣàlàyé pé lóòótọ́ ni Jésù di ọba Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1914, àmọ́ kò tíì “jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀” láti ṣèdájọ́ “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 25:32; fi wé Dáníẹ́lì 7:13.) Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé àkàwé nípa bí Jésù ṣe máa ya àwọn àgùntàn kúrò lára ewúrẹ́ dìídì fi Jésù hàn gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́. (Ka Mátíù 25:31-34, 41, 46.) Torí pé Jésù kò tíì di Onídàájọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè lọ́dún 1914, ó dájú nígbà náà pé kì í ṣe ọdún yẹn ló bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwọn èèyàn sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tàbí ewúrẹ́. * Ìgbà wo gan-an ni Jésù máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèdájọ́?

12. (a) Ìgbà wo ni Jésù máa jókòó fún ìgbà àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ láti dá àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́jọ́? (b) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni Mátíù 24:30, 31 àti Mátíù 25:31-33, 46 sọ nípa rẹ̀?

 12 Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa ọjọ́ ìkẹyìn fi hàn pé lẹ́yìn ìparun ìsìn èké ni Jésù máa jókòó fún ìgbà àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ láti dá àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́jọ́. Bó ṣe wà ní  ìpínrọ̀ 8, díẹ̀ lára àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bá jókòó gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ wà nínú Mátíù 24:30, 31. Tá a bá kíyè sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, àá rí i pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nínú ẹsẹ yìí jọ èyí tó sọ nínú àkàwé nípa àgùntàn àti ewúrẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ènìyàn máa dé nínú ògo rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì; gbogbo ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè máa kóra jọ síwájú rẹ̀; àwọn tó kà sí àgùntàn máa “gbé orí [wọn] sókè” torí pé wọ́n máa jogún “ìyè àìnípẹ̀kun.” * Àmọ́, àwọn tó kà sí ewúrẹ́ máa “lu ara wọn nínú ìdárò,” torí pé Ọmọ ènìyàn máa ké wọn kúrò títí láé.—Mát. 25:31-33, 46.

13. (a) Ìgbà wo ni Jésù máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tàbí ewúrẹ́? (b) Ipa wo ló yẹ kí òye yìí ní lórí ọwọ́ tá a fi ń mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

13 Ibo la wá lè parí èrò sí? Ibi tá a lè parí èrò sí ni pé ìgbà tí Jésù bá dé nígbà ìpọ́njú ńlá ló máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tàbí ewúrẹ́. Tó bá wá di Amágẹ́dọ́nì, ìyẹn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa kẹ́yìn ìpọ́njú ńlá, ó máa ké àwọn èèyàn tó dà bí ewúrẹ́ kúrò títí láé. Ipa wo ló yẹ kí òye yìí ní lórí ọwọ́ tá a fi ń mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Ó jẹ́ ká rí bí iṣẹ́ ìwàásù wa ti ṣe pàtàkì tó, ó sì yẹ ká  fọwọ́ gidi mú un. Ní báyìí, àyè ṣì wà fún àwọn èèyàn láti yí pa dà kí wọ́n sì máa rin ojú ọ̀nà híhá tó “lọ sínú ìyè,” àmọ́ tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ̀rẹ̀, kò ní sí àyè mọ́. (Mát. 7:13, 14) Lóòótọ́, ìwà táwọn èèyàn ń hù báyìí lè jọ ti àgùntàn tàbí ewúrẹ́. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ìgbà ìpọ́njú ńlá ni Jésù máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn yálà gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tàbí ewúrẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa, kí ọ̀pọ̀ lè gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kí wọ́n sì lè wá sin Jèhófà.

Ní báyìí, àyè ṣì wà fún àwọn èèyàn láti yí pa dà kí wọ́n sì máa rin ojú ọ̀nà híhá tó “lọ sínú ìyè,” àmọ́ tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ̀rẹ̀, kò ní sí àyè mọ́ (Wo ìpínrọ̀ 13)

ÌGBÀ WO NI JÉSÙ Ń BỌ̀ TÀBÍ TÓ MÁA DÉ?

14, 15. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mẹ́rin wo ló sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí Jésù máa dé gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́?

14 Tá a bá tún fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ Jésù, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí òye wa yí pa dà nípa ìgbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì míì máa wáyé? Inú àsọtẹ́lẹ̀ náà gan-an la ti máa rí ìdáhùn. Ẹ jẹ́ ká wò ó ná.

15 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 24:29–25:46, àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí àtèyí tó máa wáyé nígbà ìpọ́njú ńlá ni Jésù dìídì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nínú àwọn ẹsẹ yìí, ẹ̀ẹ̀mẹjọ ni Jésù mẹ́nu kàn án pé òun “ń bọ̀” tàbí pé òun máa dé. * Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìpọ́njú ńlá, ó sọ pé: ‘wọn yóò rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run.’ “Ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.” “Ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” Nínú àkàwé nípa àgùntàn àti ewúrẹ́, Jésù sọ pé: ‘Ọmọ ènìyàn nínú ògo rẹ̀.’ (Mát. 24:30, 42, 44; 25:31) Ọjọ́ iwájú nígbà tí Jésù máa dé gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ ni ibi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tá a tọ́ka sí yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn ibi mẹ́rin míì wo la tún lè tọ́ka sí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yẹn?

16. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mẹ́rin míì wo ló tún sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí Jésù máa dé?

16 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹrú olóòótọ́ àti olóye, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹrú náà bí ọ̀gá rẹ̀ nígbà tí ó bá dé, bá rí i tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀.” Nínú àkàwé nípa àwọn wúńdíá, Jésù sọ pé: “Bí wọ́n tí ń lọ láti rà á, ọkọ ìyàwó dé.” Nínú àkàwé nípa tálẹ́ńtì, Jésù sọ pé: “Lẹ́yìn àkókò gígùn, ọ̀gá ẹrú wọnnì dé.” Nínú àkàwé yìí kan náà, ọ̀gá náà sọ pé: “Nígbà tí mo bá sì dé, èmi ì bá wá gba ohun tí ó jẹ́ tèmi.” (Mát. 24:46;  25:10, 19, 27) Ìgbà wo ni àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ń tọ́ka sí?

17. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìgbà wo la sọ pé Jésù dé, bó ṣe wà nínú Mátíù 24:46?

17 Tẹ́lẹ̀ rí, a ti sọ nínú àwọn ìwé wa pé ìgbà tí Jésù wá tàbí tí ó dé ní ọdún 1918 ni àwọn ibi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ń sọ nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ kíyè sí ohun tí Jésù sọ nípa “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Ka Mátíù 24:45-47.) Báwo la ṣe lóye ìgbà tí Jésù dé, bó ṣe wà ní ẹsẹ 46? A gbà tẹ́lẹ̀ pé ọdún 1918 ni Jésù “dé” láti wá wo bí ipò tẹ̀mí àwọn ẹni àmì òróró ṣe rí àti pé ọdún 1919 ló yan ẹrú náà sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní Ọ̀gá rẹ̀. (Mál. 3:1) Àmọ́, nígbà tá a tún gbé àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yìí yẹ̀ wò, a wá rí i pé ìgbà tá a rò pé ó ṣẹ kọ́ ló ṣẹ. Ó pọn dandan nígbà náà pé ká tún ojú ìwòye wa ṣe. Kí nìdí?

18. Ibo la máa parí èrò sí tá a bá ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ Jésù látòkèdélẹ̀ nípa ìgbà tó máa dé?

18 Nínú àwọn ẹsẹ tó ṣáájú Mátíù 24:46, gbogbo ìgbà tí Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “dé” ló fi ń tọ́ka sí ìgbà tóun máa wá ṣèdájọ́ àwọn èèyàn, tó sì máa fìyà tó tọ́ jẹ wọ́n nígbà ìpọ́njú ńlá. (Mát. 24:30, 42, 44) Bákan náà, bá a ṣe ṣàlàyé ní  ìpínrọ̀ 12, ìgbà ìpọ́njú ńlá yìí kan náà ni Jésù ń tọ́ka sí nígbà tó sọ pé òun máa “dé” nínú Mátíù 25:31, ìyẹn ìgbà tó máa wá ṣèdájọ́ àwọn èèyàn. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti parí èrò sí pé ọjọ́ iwájú tí Jésù máa dé, ìyẹn nígbà ìpọ́njú ńlá náà ló máa yan ẹrú olóòótọ́ sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀, bó ṣe wà nínú Mátíù 24:46, 47. * Kò sí àní-àní pé bá a ṣe ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ Jésù látòkèdélẹ̀ mú kó ṣe kedere pé ọjọ́ iwájú tí Jésù máa wá ṣèdájọ́ àwọn èèyàn ni àwọn ibi mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ìyẹn nígbà ìpọ́njú ńlá.

19. Àwọn àyípadà wo la ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò tán? Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

19 Lákòótán, kí la rí kọ́? Níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, a sọ pé á máa jíròrò àwọn ìbéèrè mẹ́ta tó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú “ìgbà wo?” Lákọ̀ọ́kọ́, a kẹ́kọ̀ọ́ pé kì í ṣe ọdún 1914 ni ìpọ́njú ńlá bẹ̀rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè bá gbéjà ko Bábílónì Ńlá. Lẹ́yìn náà, a jíròrò ìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe ọdún 1914 ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèdájọ́ àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ó di ìgbà ìpọ́njú ńlá. Paríparí rẹ̀, a wá ṣàyẹ̀wò ìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe ọdún 1919 ni Jésù dé láti yan ẹrú olóòótọ́ sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ó di ìgbà ìpọ́njú ńlá. Ó fi hàn nígbà náà pé, ìgbà ìpọ́njú ńlá ni ìgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a ṣèwádìí rẹ̀ yìí ń tọ́ka sí. Báwo ni àwọn àyípadà tó bá òye wa yìí ṣe mú ká túbọ̀ lóye àkàwé tí Jésù ṣe nípa ẹrú olóòótọ́? Bákan náà, báwo ló ṣe mú ká túbọ̀ lóye àwọn àpèjúwe tàbí àkàwé Jésù míì tó ń ṣẹ lọ́jọ́ ìkẹyìn yìí? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

 

^ ìpínrọ̀ 4 Ìpínrọ̀ 4: Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, ka Ilé-Ìṣọ́nà February 15, 1994, ojú ìwé 8 sí 21 àti Ilé Ìṣọ́ May 1, 1999, ojú ìwé 8 sí 20.

^ ìpínrọ̀ 8 Ìpínrọ̀ 8: Ọ̀kan lára ohun tí àwọn ẹsẹ yìí sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ni bí Jésù ṣe máa “kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀.” (Mát. 24:31) Nípa bẹ́ẹ̀, ọ jọ pé lẹ́yìn tí apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá bá ti kọjá la máa gbé gbogbo ẹni àmì òróró tó bá ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé máa gòkè re ọ̀run, ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni ogun Amágẹ́dọ́nì máa jà. Àlàyé yìí ni kẹ́ ẹ fi sọ́kàn báyìí dípò èyí tá a ṣe nínú “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà August 15, 1990, ojú ìwé 30.

^ ìpínrọ̀ 11 Ìpínrọ̀ 11: Wo Ilé-Ìṣọ́nà, October 15, 1995, ojú ìwé 18 sí 28.

^ ìpínrọ̀ 12 Ìpínrọ̀ 12: Wo àkọsílẹ̀ tó jọ ọ́ ní Lúùkù 21:28.

^ ìpínrọ̀ 15 Ìpínrọ̀ 15: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n ń pè ní er′kho·mai la túmọ̀ sí “dé”, ohun kan náà la sì túmọ̀ sí “ń bọ̀.”

^ ìpínrọ̀ 18 Ìpínrọ̀ 18: Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “tí ó bá dé” nínú Mátíù 24:46 náà la túmọ̀ sí “ń bọ̀” nínú Mátíù 24:30, 42, 44.