Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

A Ṣe Tán Láti Sin Jèhófà Níbikíbi Tó Bá Fẹ́

A Ṣe Tán Láti Sin Jèhófà Níbikíbi Tó Bá Fẹ́

Mi ò dá nìkan wàásù báyìí rí. Nígbàkigbà tí mo bá jáde òde ẹ̀rí, ẹ̀rù máa ń bà mi gán-an débi pé ńṣe lẹsẹ̀ mi méjèèjì á máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀. Èyí tó wá burú jù ni pé àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yẹn kì í tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ìwàásù rárá. Ṣe ni inú máa ń bí àwọn kan ṣùù débi pé wọ́n á fẹ́ lù mí. Kò lè yà yín lẹ́nu pé, ìwé pẹlẹbẹ kan ṣoṣo péré ni mo fi síta ní oṣù àkọ́kọ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà,”—Látẹnu Arákùnrin Markus.

ỌDÚN 1949, ìyẹn ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn ni ohun tí mo sọ lókè yìí ṣẹlẹ̀. Àmọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tó wáyé láwọn ọdún díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn. Orúkọ bàbá mi ni Hendrik. Wọ́n máa ń ṣe bàtà, wọ́n sì tún máa ń tún ọ̀gbà ṣe ní abúlé kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Donderen tó wà ní àríwá ìlú Drenthe, ní orílẹ̀-èdè Netherlands. Ibẹ̀ ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1927. Èmi ni ìkẹrin nínú ọmọ méje tí wọ́n bí, ẹ̀gbẹ́ títí eléruku sì ni ilé tá à ń gbé wà. Ìṣẹ́ àgbẹ̀ ni èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn tá a jọ ń gbé ládùúgbò ń ṣe, èmi náà sì máa ń gbádùn iṣẹ́ oko gan-an. Ọdún 1947 ni mo kọ́kọ́ mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sì ni mi nígbà yẹn. Ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan tó ń gbé ládùúgbò wa, ẹni tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Theunis Been, ni mo ti kọ́kọ́ mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí mo kọ́kọ́ mọ Theunis, mi ò fẹ́ràn rẹ̀ rárá tórí pé ara rẹ̀ kò yá mọ́ọ̀yàn. Àmọ́ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìwà rẹ̀ sì yí pa dà tó fi wá dẹni tára ẹ̀ ń yá mọ́ọ̀yàn. Èyí wú mi lórí gan-an débi pé nígbàkigbà tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ayé máa di Párádísè, mo máa ń fetí sílẹ̀, mo sì gba àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ wọ̀nyẹn gbọ́, ọ̀rẹ́ èmi àti ẹ̀ sì túbọ̀ wọ̀. *

Oṣù May ọdún 1948 ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í jáde òde ẹ̀rí, nígbà tó sì di oṣù tó tẹ̀ lé e ní June 20 mo ṣèrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè tá a ṣe ní ìlú Utrecht. Nígbà tó di January 1, 1949, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n sì ní kí n lọ máa sìn ní ìjọ kékeré kan ní àgbègbè Borculo tó wà ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Netherlands. Ìbi tí mò ń gbé síbẹ̀ jìnnà tó nǹkan bí àádóje [130] kìlómítà, mo bá  kúkú pinnu pé màá gbé kẹ̀kẹ́ mi lọ. Nǹkan bíi wákàtí mẹ́fà ni mo rò pé màá lò dé ibẹ̀, àmọ́ òjò tó rọ̀ ní ọjọ́ yẹn lágbára díẹ̀, ó sì fẹ́ atẹ́gùn gan-an. Nígbà tí màá fi rin ogójì [40] kìlómítà, ọjọ́ ti lọ. Mó yáa bọ́ọ́lẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́, mo lọ wọ ọkọ̀ ojú irin láti rin ìrìn-àjò àádọ́rùn [90] kìlómítà tó kù. Ìrìn wákàtí mẹ́fà wá di méjìlá [12]! Alẹ́ pátápátá ni mo tó dé ilé àwọn ará tí wọ́n ti ṣètò pé kí n dé sí. Ibẹ̀ ni mo sì gbé ní gbogbo àkókò tí mo fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní àgbègbè náà.

Àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan torí pé ogun ṣẹ̀ṣẹ̀ jà tán níbẹ̀ ni. Èmi náà ò sì ní ju kóòtù kan ṣoṣo, ó tiẹ̀ tún tóbi jù mi lọ, mo sì tún ní ṣòkòtò tí kò balẹ̀ méjì. Ká sòótọ́, ní oṣù tí mo kọ́kọ́ dé àgbègbè Borculo yẹn nǹkan ò rọgbọ fún mi rárá, àmọ́ Jèhófà bù kún mi, ní ti pé mò ń darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn tí mo lo oṣù mẹ́sàn-án níbẹ̀, wọ́n gbé mi lọ sílùú Amsterdam, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Netherlands.

ÁTI ABÚLÉ SÍ ÌLÚ ŃLÁ

Èmi tó jẹ́ pé abúlé ni mo dàgbà sí, mo wá bá ara mi ní Amsterdam, ìlú tó tóbi jù ní orílẹ̀-èdè Netherlands. Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ gan-an níbẹ̀. Ní oṣù àkọ́kọ́, iye ìwé tí mo fi síta ju iye tí mo fi síta ní gbogbo oṣù mẹ́sàn-án tí mo lò ní àgbègbè Borculo lọ. Ó kéré tán mò ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́jọ lóṣù. Lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ìjọ, (tá à ń pè ní olùṣekòkárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà báyìí), wọ́n yàn mí pé kí n sọ àsọyé. Ìgbà àkọ́kọ́ tí mo máa sọ àsọyé nìyẹn! Ẹ̀rù bà mi, àmọ́ kó tó dọjọ́ tí mo máa sọ àsọyé yẹn, wọ́n gbé mi lọ sí ìjọ míì. Ńṣe ni mo mí kanlẹ̀ tára sì tù mí. Àṣé mò ń tan ara mi ni, mi ò mọ̀ pé máa ṣì sọ àsọyé tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000]!

Markus rèé (lápá ọ̀tún lọ́hùn) tó ń jẹ́rìí ní òpópónà ní àdúgbò kan nítòsí ìlú Amsterdam lọ́dún 1950

Ní oṣù May ọdún 1950, wọ́n tún gbé mi lọ sí ìlú Haarlem. Ni wọ́n bá fún mi ní lẹ́tà pé kí n máa sìn gẹ́gẹ́ bí i alábòójútó àyíká. Mi ò lè sùn dáadáa fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko. Mo sọ fún arákùnrin Robert Winkler tó ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa pé mi ò tóótun fún iṣẹ́ náà. Àmọ́, ó sọ fún mi pé: “Ṣáà kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù náà, kíkọ́ ni mímọ̀.” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, wọ́n dá mi lẹ́kọ̀ọ́ fún oṣù kan, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. Nígbà tí mò ń bẹ ìjọ kan wò, mo rí arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tí ara rẹ̀ yá mọ́ọ̀yàn, tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó sì ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ, orúkọ rẹ̀ ni Janny Taatgen. Nígbà tó di ọdún 1955, mo gbé e níyàwó. Kí n tó tún máa bá ọ̀rọ̀ mi lọ́, ẹ jẹ́ kí ìyàwó mi sọ bó ṣe di aṣáájú-ọ̀nà àti bá a ṣe jọ sìn lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó.

LẸ́YÌN TÁ A ṢÈGBÉYÀWÓ

Janny: Ọdún 1945, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá ni màmá mi rí òtítọ́. Màmá mi mọ bó tí ṣe pàtàkì tó láti kọ́ àwa ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ẹ̀kọ́ Bíbélì, torí náà kò fọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wa ṣeré rárá. Àmọ́, bàbá mi ò nífẹ̀ẹ́ sì ọ̀rọ̀ Bíbélì rárá. Tórí bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń ṣọ́ ìgbà tí bàbá mi ò ní sí nílé kí wọ́n lè kọ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ìpàdé tí mo kọ́kọ́ bá wọn lọ ni àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ṣe ní ìlú The Hague lọ́dún 1950. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, mo bá wọn lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ìpínlẹ̀ Assen ní ìlú Drenthe. Ìgbà àkọ́kọ́ sì nìyẹn tí mo máa ṣèpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Lọ́jọ́ tí mo bá wọn lọ sí ìpàdé yẹn, inú bí bàbá mi débi pé ṣe ni wọ́n lé mi jáde nílé. Ni màmá mi bá sọ fún mi pé, “O ṣáà mọ ibi tó o  lè máa gbé.” Ohun tí wọ́n sọ yé mi, ìyẹn ni pé mo lè lọ gbé ọ̀dọ̀ àwọn ará. Mo kọ́kọ́ lọ gbé lọ́dọ̀ ìdílé kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí ilé wọn ò jìnnà sọ́dọ̀ wa. Àmọ́, bàbá mi ò fi mí lọ́rùn sílẹ̀. Ni mo bá kó kúrò níbẹ̀ lọ sí ìjọ́ kan tó wà ní ìlú Deventer ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Overijssel tó jẹ́ nǹkan bí kìlómítà márùndínlọ́gọ́rùn-ún [95] sí ilé. Ohun tí bàbá mi ṣe wẹ́rẹ́ yẹn mà kó wọn sí wàhálà! Gẹ́gẹ́ bi òfin ìlú wa ti wí, mo ṣì kéré ju ẹni tí wọ́n lè lé kúrò nílé. Torí bẹ́ẹ̀, bàbá mi ní kí n máa bọ̀ nílé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá mi ò di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fi kú, síbẹ̀ wọn ò dí mi lọ́wọ́ ìpàdé àti òde ẹ̀rí mọ́.

Janny rèé (lápá ọ̀tún lọ́hùn) nígbà tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ́dún 1952

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo pa dà sílé, màmá mi ṣàìsàn gan-an débi pé wọn ò lè ṣe nǹkan kan, èmi ni mò ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ilé. Àmọ́, mi ò jẹ́ kí ìyẹn dí mi lọ́wọ́ láti má lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, mo sì ń tẹ̀ síwájú. Nígbà tó sì di ọdún 1951 mo ṣèrìbọmi. Mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] nígbà yẹn. Lọ́dún 1952, lẹ́yìn tí màmá mi gbádùn, mo gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, mo sì dara pọ̀ mọ́ àwọn arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà mẹ́ta kan. Àgbègbè méjì kan nílùú Drenthe la ti lọ wàásù, inú ọkọ̀ ojú omi kan tó ní ilé ni a gbé fún oṣù méjì gbáko tí a fi jọ ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Nígbà tó sì di ọdún 1953, mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ọdún kan lẹ́yìn ti mo di aṣáájú-ọ̀nà ni ọ̀dọ́ alábòójútó àyíká kan bẹ ìjọ wa wò. Markus ni alábòójútó àyíká náà. Nígbà tá a rí i pé tá a bá fẹ́ra a máa lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, a ṣègbéyàwó ní oṣù May, ọdún 1955. Ó ṣe tán, ẹni méjì ṣáà sàn ju ẹnì kan lọ.—Oníwàásù 4:9-12.

Ọdún 1955, lọ́jọ́ tá a ṣègbéyàwó

Markus: Lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, wọ́n ní ká lọ máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní ìpínlẹ̀ Veendam nílùú Groningen. Inú yàrá kótópó kan là ń gbe. Àmọ́, ìyàwó mi to yàrá náà dáadáa, ó sì bójú mu. Yàrá náà kéré débi pé, ojoojúmọ́ tá a bá fẹ́ sùn lálẹ́ la máa ní láti kó àga méjì àti tábìlì kan tá a ní sójú kan, ká lé ráyè tẹ́ bẹ́ẹ̀dì tá a máa fi sùn.

Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, wọ́n sọ mi di alábòójútó àyíká, wọ́n sì ní ká lọ máa sìn lórílẹ̀-èdè Belgium. Lọ́dún 1955, àwọ́n akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Belgium ò ju nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] lọ. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún [24,000]! Èdè tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Netherlands náà ni wọ́n ń sọ ní àgbègbè Flanders tó wà ní àríwá orílẹ̀-èdè Belgium. Àmọ́, bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́ lórílẹ̀-èdè Belgium yàtọ̀ díẹ̀. Torí bẹ́ẹ̀, ó kọ́kọ́ ṣòro fún wa láti gbọ́ wọn dáadáa. Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í lóye wọn.

Janny: Iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò gba kéèyàn ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan kan. Kẹ̀kẹ́ wa la máa ń gbé lọ sáwọn ìjọ káàkiri. Ilé àwọn ará la sì máa ń dé sí, tórí pé a ò nílé tara wa. Látìgbà tá a bá ti dé sí ilé àwọn ará, ó di àárọ̀ Tuesday ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé é ká tó gbéra kúrò níbẹ̀ lọ sí ìjọ míì. Síbẹ̀, a ka àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní yìí sí ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà.

Markus: Nígbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, a ò mọ èyíkéyìí nínú àwọn ará tó wà láwọn ìjọ tá à ń bẹ̀ wò, síbẹ̀ wọ́n máa ń gbà wà tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n máa ń ṣaájò wa, wọ́n sì máa ń fún wa ní nǹkan. (Héb. 13:2) Ọ̀pọ̀ ọdún la lò lórílẹ̀-èdè Belgium tá a fí ń bẹ àwọn ìjọ tó ń sọ èdè Dutch wò. Ọ̀pọ̀ ìbùkún lá sì ti rí lẹ́nu iṣẹ́ náà. Bí  àpẹẹrẹ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn ará tó wà ní àgbègbè tí wọ́n tí ń sọ èdè Dutch la ti wá mọ̀ báyìí, wọ́n sì ti dẹni ọ̀wọ́n fún wa. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ la mọ̀ tó jẹ́ pé, bí wọ́n ṣe ń dàgbà sí i ni wọ́n túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń ya ara wọn sí mímọ́ fún un. Àwọn ohun tó jẹ mọ́ ire Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n sì ń jẹ́ kó gbawájú nínú ìgbésí ayé wọn. Èyí tó pọ̀ nínú wọn ló ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún kan tàbí òmíràn. Èyí sì ń múnú wa dùn gan-an. (3 Jòh. 4) Ó hàn pé Jèhófà ń lò wá láti máa fún wọn níṣìírí kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ìtẹ̀síwájú wọn nípa tẹ̀mí náà sì jẹ́ orísun ìṣírí fún wa. “Pàṣípààrọ̀ ìṣírí” yìí mú ká lè máa fi tọkàntọkàn bá iṣẹ́ ìsìn wa nìṣó.—Róòmù 1:12.

ÌṢÒRO DÉ ÀMỌ́ JÈHÓFÀ BÙ KÚN WA

Markus: Látìgbà tá a ti ṣègbéyàwó ló ti wà lọ́kàn wa láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ká lè túbọ̀ kúnjú ìwọ̀n, ojoojúmọ́ la máa ń kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì, fún wákàtí kan ó kéré tán. Àmọ́, kò rọrùn fún wa láti kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì látinú ìwé. A wá pinnu pé á dára kí a lọ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lákòókò ìsinmi wa. A mọ̀ pé tá a bá wà níbẹ̀, tá a sì ń jáde òde ẹ̀rí, a máa gbọ́ èdè náà dáadáa. Nígbà tó di ọdún 1963, wọ́n fi àpò ìwé kan tí lẹ́tà méjì wà nínú rẹ̀ ránṣẹ́ sí wa láti orílé-iṣẹ́ ní Brooklyn. Ọ̀kan fún ìyàwó mi, ọkàn fún mi. Wọ́n fi lẹ́tà yẹn pè mi sí àkànṣe Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì olóṣù mẹ́wàá gbáko! Wọ́n ṣètò ilé ẹ̀kọ́ yìí láti dá àwa arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n á sì tún fún wa láwọn ìtọ́ni kan nípa ètò Ọlọ́run. Nínú ọgọ́rùn-ún akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n pè sí ilé ẹ̀kọ́ náà, méjìlélọ́gọ́rin [82] jẹ́ ọkùnrin, àwọn tó kù sì jẹ́ obìnrin.

Janny: Nínú lẹ́tà tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi, wọ́n ní kí n ronú lé e lórí tàdúrà-tàdúrà, bóyá màá lè dúró ní orílẹ̀-èdè Belgium tí ọkọ mi á fi dé láti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ká sòótọ́, inú mi ò dùn rárá. Ṣe ló dà bíi pé Jèhófà ò bù kún gbogbo ìsapá mi láti ṣe púpọ̀ sí i. Àmọ́, mo pe orí ara mi wálé. Mo ronú lórí ìdí tí wọ́n fi dá ilé ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀, ìyẹn láti fún àwọn tó bá láǹfààní ẹ̀ ní ìtọ́ni tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè wàásù ìhìn rere náà dé gbogbo ayé. Lẹ́yìn náà, mo gbà láti dúró, wọ́n sì ní kí n máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ìlú Ghent lórílẹ̀-èdè Belgium pẹ̀lú Arábìnrin Anna àti Maria Colpaert.

Markus: Torí kí n lè túbọ̀ lóye èdè Gẹ̀ẹ́sì dáadáa, wọ́n ní kí n kọ́kọ́ wá lo oṣù márùn-un ní Brooklyn, kí ilé ìwé náà tó bẹ̀rẹ̀. Níbẹ̀, mo ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìkówèéránṣẹ́ àti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn. Bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ ní orílé-iṣẹ́ wa, pàápàá bó ti jẹ́ pé àwọn tó ń ṣètò bá a ṣe máa fi ìwé ránṣẹ́ sí àwọn ìlú bí Éṣíà, Yúróòpù àti Amẹ́ríkà ti Gúúsù ni mò ń bá ṣiṣẹ́, ó ti mú kí ń mọ púpọ̀ nípa ẹgbẹ́ ará tó wà kárí ayé. Mi ò lè gbàgbé Arákùnrin A. H. Macmillan tó ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò látìgbà tí Arákùnrin Russell wà láyé. Láìka pé ó ti dàgbà tí kò sí tún fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ràn mọ́, kì í pa ìpàdé jẹ́ rárá. Èyí wú mi lórí gan-an, ó mú kí n túbọ̀ rí i pé a ò gbọ́dọ̀ ní èrò náà pé ìpàdé kì í tán àti pé kì í ṣe ìgbà tó bá rọrùn fún wa nìkan ló yẹ ká máa lọ sípàdé.—Héb. 10:24, 25.

Janny: Mi ò lè ka iye ìgbà témi àtọkọ mi máa ń kàn síra wa láàárín ọ̀sẹ̀. A máa ń ṣàárò ara wa gan-an ni! Láìka ìyẹn sí, ọkọ mi gbádùn ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, èmi náà sì gbádùn iṣẹ́ ìsìn mi. Nígbà tí ọkọ mi fi máa pa dà dé láti ilé ẹ̀kọ́ náà, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́tàdínlógún [17] ni mò ń darí! Kò rọrùn fún wa ní gbogbo oṣù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] tá ò fi wà pa pọ̀ yẹn, a ní láti fi àwọn nǹkan kan du ara wa, àmọ́, Jèhófà bù kún wa. Lọ́jọ́ tí ọkọ mi máa dé, ọkọ̀ òfuurufú tó gbé e wálé kò tún tètè dé, àní fún ọ̀pọ̀ wákàtí! Àmọ́, nígbà tó jàjà dé, ṣe la dì mọ́ra wa, tí omijé ayọ̀ sì ń bọ́ lójú wa. Látìgbà yẹn, a tí wá di bí ìgbín fà, ìkarawun á tẹ̀ lé e.

 A DÚPẸ́ PÉ JÈHÓFÀ LÒ WÁ LÓNÍRÚURÚ Ọ̀NÀ

Markus: Lẹ́yìn tí mo dé láti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní oṣù December, ọdún 1964, wọ́n ní ká lọ máa sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ọkàn wa ti balẹ̀, a ti rò pé ibi tá a ti máa ṣíṣẹ́ ìsìn wa nìyẹn. Àfi bó ṣe dẹ̀yìn oṣù mẹ́ta tí wọ́n ní kí n lọ máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àgbègbè nílùú Flanders. Nígbà tó yá, wọ́n rán Arákùnrin Aalzen àti ìyàwó rẹ̀, Els Wiegersma gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì sí orílẹ̀-èdè Belgium. Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n ní kí wọ́n máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àgbègbè, wọ́n sì dá àwa pa dà sí Bẹ́tẹ́lì, wọ́n ní kí n máa ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn. Láti ọdún 1968 sí ọdún 1980, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n yí iṣẹ́ wa pa dà, a lè wà ní Bẹ́tẹ́lì lákòókò kan, wọ́n sì tún lè ní ká lọ máa bẹ àwọn ìjọ wò, gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Àmọ́, nígbà tó yá, lọ́dún 1980 sí 2005, wọ́n ní kí n máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àgbègbè.

Lóòótọ́, iṣẹ́ ìsìn wa ń yí pa dà lọ̀pọ̀ ìgbà, àmọ́ a ò gbàgbé pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a sì ti pinnu láti sìn ín tọkàntọkàn. Gbogbo apá ibi tí wọ́n bá ti ní ká lọ sìn la ti máa ń gbádùn àwọn iṣẹ́ tá a ń ṣe, torí a gbà pé ìyípadà yòówù kó wáyé jẹ́ fún ire Ìjọba Ọlọ́run.

Janny: Èyí tó tiẹ̀ múnú mi dùn jù lọ ni bí mo ṣe láǹfààní láti tẹ̀ lé ọkọ mi lọ́ sí orílé-iṣẹ́ wa ní Brooklyn lọ́dún 1977 àti Patterson lọ́dún 1997, ìyẹn nígbà tó lọ gba àfikún ẹ̀kọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka.

JÈHÓFÀ MỌ OHUN TÁ A NÍLÒ

Markus: Lọ́dún 1982, wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún ìyàwó mi, mo sì dúpẹ́ pé ó kọ́fẹ pa dà. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ìjọ tó wà nílùú Louvain fún wa ní yàrá kan tí wọ́n kọ́ sókè Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ láti nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún tá a ti ń sìn, tá a ní yàrá tó jẹ́ tiwa! Iṣẹ́ ńlá ni mo máa ń ṣe láwọn ọjọ́ Tuesday tá a bá fẹ́ lọ sí ìjọ míì. Mo máa ń kó ẹrù wa sọ̀ kalẹ̀, máa sì tún gòkè lọ́pọ̀ ìgbà. Ìyẹn lórí àtẹ̀gùn mẹ́rìnléláàádọ́ta [54]! Nígbà tó di ọdún 2002, wọ́n ṣètò yàrá kan fún wa ní ìsàlẹ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, ṣe la dúpẹ́ pé a ò ní máa gòkè bọ́ọ́lẹ̀ mọ́. Nígbà tí mo di ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin [78], wọ́n ní ká lọ máa sìn ní ìlú Lokeren gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Inú wa sì dùn pé a ṣì lè máa jáde òde ẹ̀rí déédéé.

“A gbà pé, ibi tá a tí ń sìn tàbí ipò tá a wà kọ́ ló ṣe pàtàkì, ẹni tá à ń sìn ló ṣe”

Janny: Lápapọ̀ èmi àti ọkọ mi ti lo ohun tó lé ní ọgọ́fà [120] ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Nínú ọ̀rọ̀ tiwa, a ti rí bí Jèhófà ṣe mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé ‘òun kì yóò fi wá sílẹ̀ lọ́nàkọnà’ àti pé tá a bá fòótọ́ inú sìn ín, a ‘kò ní ṣaláìní ohun kan.’—Héb. 13:5; Diu. 2:7.

Markus: Nígbà tá a wà lọ́dọ̀ọ́, a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà. A ò wá àwọn nǹkan ńláńlá fún ara wa. A ṣe tán láti sìn níbi yòówù tí wọ́n bá rán wa lọ. Torí a gbà pé, ibi tá a tí ń sìn tàbí ipò tá a wà kọ́ ló ṣe pàtàkì, ẹni tá à ń sìn ló ṣe kókó.

^ ìpínrọ̀ 5 Lẹ́yìn ìgbà yẹn bàbá mi, ìyà mi, àǹtí mi àgbà àtàwọn àbúrò mi ọkùnrin méjì náà di Ẹlẹ́rìí.