Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) July 2013

Ẹ̀dà yìí jẹ́ ká mọ nípa àwọn òye tuntun tá a ní nípa ìgbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ máa nímùúṣẹ àti ẹni tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye jẹ́ gan-an.

“Sọ fún Wa, Ìgbà Wo Ni Nǹkan Wọ̀nyí Yóò Ṣẹlẹ̀?”

Òye wo la ṣẹ̀sẹ̀ ní nípa ìgbà tí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nínú Mátíù orí 24 àti 25 máa nímùúṣẹ?

“Wò ó! Mo Wà Pẹ̀lú yín ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́”

Àkàwé àlìkámà àti èpò sọ nípa àkókò tí wọ́n fúnrúgbìn, àkókò tó dàgbà àti ìgbà ìkórè. Òye tuntun wo la ní báyìí nípa ìgbà ìkórè?

Jésù Ń Tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn

Báwo ni Jésù ṣe pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní? Ǹjẹ́ ọ̀nà kan náà ló ń gbà pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa lónìí?

“Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?”

Kà nípa òye tuntun tá a ní nípa ẹrú olóòótọ́ àti olóye. Wo bí ẹrú yìí ṣe ń mú ká máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí àti bó ṣe ń mú ká ní àjọṣe rere pẹ̀lú Jèhófà.

Ẹnì Kan Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Arákùnrin Mark Sanderson di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ ní September 1, 2012.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

A Ṣe Tán Láti Sin Jèhófà Níbikíbi Tó Bá Fẹ́

Kà nípa bí tọkọtaya kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Netherlands ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, láìka ìṣòro tí wọ́n dojú kọ àti bí ipò wọn ṣe ń yí pa dà sí.

“Àwòrán Yìí Mà Dára Gan-an O!”

Àwọn àwòrán ń mú ká túbọ̀ ronú jinlẹ̀, kí ohun tá à ń kọ́ sì wọ̀ wá lọ́kàn. Báwo làwọn àwòrán mèremère yìí ṣe lè ṣe ẹ́ láǹfààní?