Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  June 2013

Túbọ̀ Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Àwọn Ànímọ́ Jèhófà

Túbọ̀ Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Àwọn Ànímọ́ Jèhófà

“Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.”—ÉFÉ. 5:1.

1. (a) Èwo lára àwọn ànímọ́ Jèhófà lo rántí? (b) Àǹfààní wo la máa rí tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run?

ÈWO lára àwọn ànímọ́ Jèhófà lo sábà máa ń rántí? Àwọn tá a sábà máa ń rántí ni ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti agbára. Àmọ́, Jèhófà ní àwọn ànímọ́ àgbàyanu míì. Kódà, tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní, wọ́n lé ní ogójì. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn la sì ti jíròrò nínú àwọn ìwé wa. Ẹ wo bí ohun àgbàyanu tá a máa kọ́ nípa Jèhófà á ṣe pọ̀ tó tí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ yìí tàbí tá a jíròrò wọn nígbà ìjọsìn ìdílé! Àǹfààní wo la máa rí tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ yìí? Á mú ká túbọ̀ mọyì Baba wa ọ̀run. Bá a bá sì ṣe mọyì Jèhófà tó bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe máa wù wá láti sún mọ́ ọn tí a ó sì máa fara wé e.—Jóṣ. 23:8; Sm. 73:28.

2. (a) Ṣàkàwé béèyàn ṣe lè túbọ̀ mọyì àwọn ànímọ́ Jèhófà. (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtàwọn méjì tó tẹ̀ lé e?

2 Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn mọyì nǹkan? Ó túmọ̀ sí pé èèyàn mọ bí nǹkan ọ̀hún ṣe dára tó tàbí bó ṣe ṣe pàtàkì tó. Díẹ̀díẹ̀ lèèyàn máa ń mọyì nǹkan. Wo àpẹẹrẹ yìí ná: Kí ló sábà máa ń jẹ́ kéèyàn mọyì oúnjẹ kan? Ó lè jẹ́ pé òórùn oúnjẹ náà ló kọ́kọ́ máa fà ọ́ mọ́ra. Tó o bá wá tọ́ ọ wò, wàá rí i pé oúnjẹ náà ládùn gan-an. Tó bá yá, ìwọ náà á bẹ̀rẹ̀ sí í se oúnjẹ yìí. Lọ́nà kan náà, tá a bá fẹ́ túbọ̀ mọyì àwọn ànímọ́ Jèhófà, àá kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ànímọ́ náà, àá ronú jinlẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe lò ó. Lẹ́yìn náà, àá máa fi ànímọ́ náà sílò. (Éfé. 5:1) Nínú àpilẹ̀kọ yìí àtàwọn méjì tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò àwọn ànímọ́ Jèhófà tí a kì í sábà mẹ́nu kàn. Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ànímọ́ náà, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: Kí ni ànímọ́ náà túmọ̀ sí? Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń fi hàn? Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà?

 JÈHÓFÀ ṢEÉ SÚN MỌ́

3, 4. (a) Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan ṣeé sún mọ́? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi dá wa lójú pé òun ṣeé sún mọ́?

3 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan ṣeé sún mọ́. Ẹni tó ṣeé sún mọ́ jẹ́ onínúure, ẹni téèyàn máa ń rí bá sọ̀rọ̀ àti ẹni tó rọrùn láti bá sọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ àti ìṣesí rẹ̀ lè mú ká mọ̀ bóyá ó ṣeé sún mọ́ tàbí kò ṣeé sún mọ́.

4 Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun ṣeé sún mọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run tí agbára rẹ̀ kò sì ní ààlà, síbẹ̀ ó ṣe tán láti gbọ́ àdúrà wa. (Ka Sáàmù 145:18; Aísáyà 30:18, 19.) Kò síbi tá a wà tá ò ti lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀, a sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbàkigbà. Kódà, kò sí pé à ń kánjú torí pé a lè bá a sọ̀rọ̀ títí dìgbà tá a bá fẹ́. Kò sì ní sọ fún wa láé pé à ń yọ oun lẹ́nu. (Sm. 65:2; Ják. 1:5) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó fi hàn pé Jèhófà fẹ́ ká máa bá òun sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì sọ pé, “ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀” wa àti pé ‘ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ dì wá mú ṣinṣin.’ (Sm. 34:15; 63:8) Wòlíì Aísáyà fi Jèhófà wé olùṣọ́ àgùntàn, ó sọ pé: “Apá rẹ̀ ni yóò fi kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọpọ̀; oókan àyà rẹ̀ sì ni yóò gbé wọn sí.” (Aísá. 40:11) Rò ó wò ná! Jèhófà fẹ́ ká sún mọ́ òun bí ọ̀dọ́ àgùntàn tí olùṣọ́ àgùntàn kan gbé mọ́ra. A mà dúpẹ́ o pé Baba wa ọ̀run ṣeé sún mọ́! Báwo làwa náà ṣe lè jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́ bíi ti Jèhófà?

ÀNÍMỌ́ PÀTÀKÌ TÓ YẸ KÁWỌN ALÀGBÀ NÍ

5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn alàgbà ṣeé sún mọ́?

5 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí mélòó kan tí wọ́n ń ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí pé, “Ànímọ́ wo ló wù ọ́ jù pé kí alàgbà kan ní?” Láìka ti pé orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wà sí, ohun tí ọ̀pọ̀ sọ ni pé àwọn máa ń fẹ́ràn àwọn alàgbà tó ṣeé sún mọ́. Ká sòótọ́ gbogbo àwa Kristẹni ló yẹ kó ní ànímọ́ yìí, àmọ́, ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn alàgbà ṣeé  sún mọ́. (Aísá. 32:1, 2) Arábìnrin kan sọ ìdí tó fi gbà pé ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn alàgbà ṣeé sún mọ́, ó ní: “Tí alàgbà kan bá ṣeé sún mọ́ léèyàn tó lè jàǹfààní látinú àwọn ànímọ́ rere míì tó ní.” Ǹjẹ́ o gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí arábìnrin yìí sọ? Àmọ́, kí ló lè mú kéèyàn jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́?

6. Kí la lè ṣe ka bàa lè jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́?

6 Ohun kan tá a lè ṣe ni pé ká jẹ́ káwọn ará mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn dénúdénú. Tí alàgbà kan bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará dénú, tó sì máa ń ṣe ohun tó fi hàn pé ó wù ú láti ràn wọ́n lọ́wọ́, àwọn ará máa mọ̀, títí kan àwọn ọmọdé. (Máàkù 10:13-16) Ọmọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Carlos sọ pé: “Inú mi máa ń dùn gan-an bí mo ṣe máa ń rí i tí àwọn alàgbà máa ń bá àwọn ará sọ̀rọ̀ nípàdé, tí wọ́n máa ń rẹ́rìn-ín sí wọn, tí wọ́n sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́.” Òótọ́ ni pé alàgbà kan lè sọ pé òun ṣeé sún mọ́ àti pé òun wà lárọ̀ọ́wọ́tó, àmọ́, ó yẹ kí ìwà rẹ̀ náà fi hàn bẹ́ẹ̀. (1 Jòh. 3:18) Báwo ló ṣe lè jẹ́ kó hàn nínú ìwà rẹ̀?

7. Kí nìdí tó fi máa ń rọrùn fáwọn èèyàn láti bá wa sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí báàjì àpéjọ láyà wa? Ẹ̀kọ́ wo lèyí sì kọ́ wa?

7 Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí ná. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, arákùnrin kan lọ sípàdé àgbègbè “Kí Ìjọba Ọlọ́run Dé” lórílẹ̀-èdè míì, ó sì fi báàjì rẹ̀ sáyà. Bí olùtọ́jú èrò inú ọkọ̀ òfuurufú tí arákùnrin náà wà ṣe rí báàjì yìí, ó sọ pé: “Kó yáa dé ni o! Àmọ́, ẹ jọ̀ọ́, mo ṣì máa bi yín láwọn ìbéèrè kan lórí ọ̀rọ̀ yìí.” Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nìyẹn o, olùtọ́jú èrò náà sì gba àwọn ìwé ìròyìn wa. Ọ̀pọ̀ nínú wa náà ló ti ní irú ìrírí yìí. Kí nìdí táwọn èèyàn fi máa ń fẹ́ láti bá wa sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí báàjì àpéjọ wa? Ìdí ni pé báàjì náà ń jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ mọ ibi tá à ń lọ, àwa náà sì ti ṣe tán láti jẹ́rìí fún wọn. Lọ́nà kan náà, àwọn alàgbà lè ṣe àwọn nǹkan tó máa fi hàn pé ìgbàkigbà làwọn ará lè rí àwọn bá sọ̀rọ̀. Àwọn nǹkan wo ni wọ́n lè ṣe?

8. Kí làwọn alàgbà lè ṣe láti fi hàn pé àwọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará? Ipa wo lèyí sì máa ní lórí àwọn ará?

8 Lóòótọ́, bá a ṣe ń ṣe nílẹ̀ yìí, èèwọ̀ ibòmíì ni. Àmọ́, tá a bá ń rẹ́rìn-ín músẹ́ sáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tá à ń kí wọn tẹ̀rín tọ̀yàyà, tá a sì ń béèrè àlàáfíà wọn, wọ́n á gbà pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn dénú. Ta ló yẹ kó kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jésù ná. Bíbélì sọ pé nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wà pa pọ̀, Jésù “sún mọ́ tòsí, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀.” (Mát. 28:18) Bákàn náà lọ̀rọ̀ rí lóde òní, àwọn alàgbà ló máa ń kọ́kọ́ sún mọ́ àwọn ará kí wọ́n lè bá wọn sọ̀rọ̀. Ipa wo lèyí máa ń ní lórí àwọn ará? Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rùn-ún [88] sọ pé: “Báwọn alàgbà ṣe máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́ sí mi tí wọ́n sì máa ń gbóríyìn fún mi nígbà tí mo bá dé Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń mú kí n nífẹ̀ẹ́ wọn.” Arábìnrin míì tóun náà ń ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí sọ pé: “Ó lè dà bí ohun tí kò tó nǹkan, àmọ́ inú mi máa ń dùn gan-an táwọn alàgbà bá kí mi tẹ̀rín tọ̀yàyà nígbà ti mo bá dé ìpàdé.”

Ẹ MÁA WÁ ÀYÈ LÁTI BÁ ÀWỌN ARÁ SỌ̀RỌ̀

9, 10. (a) Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni Jèhófà fún wa? (b) Kí làwọn alàgbà lè ṣe káwọn ará lè máa rí wọn bá sọ̀rọ̀?

 9 Ohun kan ni pé tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn máa sún mọ́ wa, a gbọ́dọ̀ máa wáyè fún wọn. Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jèhófà fi lélẹ̀ fún wa nípa èyí. Bíbélì sọ pé Jèhófà “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Ọ̀nà kan táwọn alàgbà lè gbà fara wé Jèhófà ni pé kí wọ́n máa wáyè  láti bá àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà sọ̀rọ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé. Arákùnrin aṣáájú-ọ̀nà kan sọ pé: “Mo máa ń mọyì rẹ̀ gan-an bí alàgbà kan bá béèrè àlàáfíà mi, tó sì dúró láti gbọ́ ohun tí mo ní láti sọ.” Arábìnrin kan tó ti ń sin Jèhófà láti nǹkan bí àádọ́ta [50] ọdún sọ pé: “Tí àwọn alàgbà bá wáyè láti bá mi sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé, ó máa ń mú kí n nímọ̀lára pé èmi náà wúlò.”

10 Lóòótọ́, iṣẹ́ àwọn alàgbà pọ̀ gan-an. Àmọ́, tí wọ́n bá wà nípàdé, ó yẹ kí wọ́n máa wáyè láti bá àwọn ará sọ̀rọ̀.

JÈHÓFÀ KÌ Í ṢE OJÚSÀÁJÚ

11, 12. (a) Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan kì í ṣe ojúsàájú? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú?

11 Òmíràn lára àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Jèhófà ní ni pé kì í ṣe ojúsàájú. Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan kì í ṣe ojúsàájú? Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ẹ̀tanú, kì í gbè sẹ́yìn ẹnì kan, kì í sì fi igbá kan bọ̀kan nínú. Tá ò bá fẹ́ máa ṣe ojúsàájú, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbà pé ọ̀kan náà ni gbogbo wa. Ó ṣe tán, Yorùbá ṣáà sọ pé bá a ṣe bí ẹrú la bí ọmọ. Bí ẹnì kan kì í bá ṣojúsàájú, kò ní máa wojú kó tó ṣe nǹkan. Kò ní tìtorí pé ẹnì kan jẹ́ olówó kó wá fún un láwọn àǹfààní kan, kí ó sì wá fi àǹfààní náà du ẹlòmíì torí pé ó jẹ́ tálákà. (Ìṣe 10:34) Torí náà, gbogbo èèyàn lẹni tí kì í ṣojúsàájú máa ń pọ́n lé, láìka ìrísí wọn tàbí ipò wọn láwùjọ sí.

12 Tó bá dọ̀rọ̀ ká báni lò láìsí ojúsàájú Jèhófà kò láfiwé. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú” àti pé “kì í fi ojúsàájú bá ẹnikẹ́ni lò.” (Ka Ìṣe 10:34, 35; Diutarónómì 10:17.) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.

Àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì gbà pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú (Wo ìpínrọ̀ 13 àti 14)

13, 14. (a) Ìṣòro wo làwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì ní? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun kì í ṣe ojúsàájú?

 13 Nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì márùn-ún ní ìṣòro kan tí wọ́n fẹ́ kí Mósè bá wọn yanjú. Kí ni ìṣòro náà? Wọ́n mọ̀ pé ìdílé kọ̀ọ̀kan máa tó gba ìpín tirẹ̀ nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í pín ilẹ̀ fáwọn èèyàn. (Núm. 26:52-55) Àmọ́ lákòókò tá à ń sọ yìí, Sélóféhádì bàbá wọn ti kú, kò sì ní ọmọkùnrin kankan. Àwọn náà ò sì tíì lọ́kọ. Ó ṣe tán, ọmọkùnrin nìkan ni Òfin sọ pé ó lè jogún ilẹ̀ bàbá rẹ̀. (Núm. 26:33) Nígbà tí wọ́n bá máa pín ilẹ̀ fáwọn èèyàn, ta ló máa gba ogún ìdílé wọn? Ṣé àwọn ìbátan bàbá wọn ló máa gba ogún tó tọ́ sí ìdílé wọn ni àbí báwo? Kí làwọn ọmọbìnrin náà wá ṣe?

14 Àwọn ọmọbìnrin náà lọ bá Mósè, wọ́n ní kó gba ẹjọ́ àwọn rò, wọ́n sọ pé: “Èé ṣe tí a ó fi mú orúkọ baba wá kúrò ní àárín ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkùnrin?”  Wọ́n wá bẹ̀bẹ̀ pé: “Fún wa ní ohun ìní ní àárín àwọn arákùnrin baba wa.” Ṣé ohun tí Mósè wá sọ ni pé, ‘Kò sí ṣíṣe, kò sí àìṣe, ohun tí Òfin sọ la máa ṣe’? Rárá o, ńṣe ni Mósè fi ọ̀rọ̀ náà tó Jèhófà létí. (Núm. 27:2-5) Kí ni Jèhófà wá sọ? Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì ń sọ ohun tí ó tọ́. Lọ́nàkọnà, kí o fún wọn ní ohun ìní ti ogún ní àárín àwọn arákùnrin baba wọn, kí o sì mú kí ogún baba wọn kọjá sọ́dọ̀ wọn.” Kódà Jèhófà tún fọba lé e. Ó ní kí Mósè fi kún Òfin náà pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin èyíkéyìí kú láìní ọmọkùnrin kankan, nígbà náà, kí ẹ mú kí ogún rẹ̀ kọjá sọ́dọ̀ ọmọbìnrin rẹ̀.” (Núm. 27:6-8; Jóṣ. 17:1-6) Látìgbà yẹn lọ ló ti di pé àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì tó bá ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ máa ń rí ogún gbà.

15. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ṣe sáwọn èèyàn rẹ̀, ní pàtàkì àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́? (b) Ìtàn míì wo lo lè tọ́ka sí nínú Bíbélì tó fi hàn pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú?

15 Ẹ wo bí ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ọmọbìnrin yẹn ṣe fi hàn pé ó jẹ́ onínúure àti pé kì í ṣe ojúsàájú! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọbìnrin náà kò lẹ́ni tó lè gbèjà wọn, Jèhófà pọ́n wọn lé bó ṣe ṣe sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù. (Sm. 68:5) Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló ṣì wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—1 Sám. 16:1-13; Ìṣe 10:30-35, 44-48.

A LÈ FARA WÉ JÈHÓFÀ

16. Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà tí kì í ṣe ojúsàájú?

16 Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà tí kì í ṣe ojúsàájú? Ẹ rántí pé a ti sọ tẹ́lẹ̀ pé tá ò bá fẹ́ máa ṣe ojúsàájú, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbà pé ọ̀kan náà ni gbogbo wa. Ó ṣeé ṣe ká gbà pé àwa kì í ṣe ẹ̀tanú ní tiwa, àti pé a kì í ṣe ojúsàájú. Àmọ́ o, ká má gbàgbé pé ìpàkọ́ onípàkọ́ la máa ń rí, a kì í rí tara ẹni. Torí náà, báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá a máa ń ṣojúsàájú tàbí a kì í ṣojúsàájú? Jésù fi àpẹẹrẹ tó dára lé lẹ̀. Nígbà tó fẹ́ mọ ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa rẹ̀, ó bi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Ta ni àwọn ènìyàn ń sọ pé Ọmọ ènìyàn jẹ́?” (Mát. 16:13, 14) Ìwọ náà lè ṣe bíi ti Jésù. O lè pé ọ̀rẹ́ rẹ kan tó lè bá ẹ sọ òótọ́ ọ̀rọ̀. Béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá lóòótọ́ ni o kì í ṣe ojúsàájú. Ó ṣeé ṣe kó sọ fún ẹ pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹ̀yà kan ju àwọn yòókù lọ, tàbí pé o máa ń ka àwọn olówó àtàwọn tó kàwé dáadáa sí nígbà tó jẹ́ pé o kì í ka àwọn tí kò lẹ́nu láwùjọ sí pàtàkì. Kí lo lè ṣe tí ọ̀rẹ́ rẹ bá sọ bẹ́ẹ̀ fún ẹ? Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣàtúnṣe, kó o sì lè túbọ̀ máa fara wé e.—Mát. 7:7; Kól. 3:10, 11.

17. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé à kì í ṣe ojúsàájú?

 17 Nínú ìjọ, a lè fara wé Jèhófà tá a bá ń hùwà tó fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún àwọn ará tá a sì ń ṣe dáadáa sí olúkúlùkù wọn. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ kó àwọn ará lẹ́nu jọ, ó yẹ ká pe àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn opó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ síbi àpèjẹ náà. (Ka Gálátíà 2:10; Jákọ́bù 1:27.) Bákàn náà, ká rí i pé à ń wàásù fáwọn èèyàn láìka èdè, ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè yòówù kí wọ́n ti wá sí. Ó ṣe tán, èdè tá a fi ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa báyìí ti tó ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600]. Ẹ̀rí tó ṣe kedere lèyí mà jẹ́ o pé a kì í ṣe ojúsàájú!

18. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì bí Jèhófà ṣe jẹ ẹni tó ṣeé sún mọ́ tí kì í sì ṣe ojúsàájú?

18 Ó dájú pé, tá a bá fara balẹ̀ ronú nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, tí kì í sì í ṣe ojúsàájú, a máa túbọ̀ mọyì Jèhófà gan-an. Tá a bá sì mọyì Jèhófà, àá túbọ̀ fẹ́ láti máa fara wé e, èyí á sì hàn nínú bá a ṣe ń hùwà sáwọn ará wa àtàwọn tá à ń bá pàdé lóde ẹ̀rí.

“Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.”—Sm. 145:18 (Wo ìpínrọ̀ 9)

“Jèhófà Ọlọ́run yín . . . kì í fi ojúsàájú bá ẹnikẹ́ni lò.”—Diu. 10:17 (Wo ìpínrọ̀ 17))