Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jèhófà Jẹ́ Ọ̀làwọ́ Ó Sì Ń Fòye Báni Lò

Jèhófà Jẹ́ Ọ̀làwọ́ Ó Sì Ń Fòye Báni Lò

“Jèhófà ń ṣe rere fún gbogbo gbòò, àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.”—SM. 145:9.

1, 2. Àǹfààní wo làwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà ní?

ARÁBÌNRIN kan wà tó ń jẹ́ Monika. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún márùndínlógójì [35] tó ti ṣègbéyàwó. Nígbà tó ń sọ bí àárín òun àtọkọ rẹ̀ ṣe rí, ó sọ pé: “Èmi àtọkọ mi mọwọ́ ara wa gan-an ni. Àmọ́, ó lè yà yín lẹ́nu pé, pẹ̀lú gbogbo ọdún tá a ti jọ wà yìí, àwọn nǹkan míì wà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọ̀ báyìí nípa ara wa!” Ọ̀pọ̀ nínú wa náà ló jẹ́ pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọ àwọn nǹkan kan nípa ọkọ tàbí aya wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ tá a ti ṣègbéyàwó. Kódà, àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ti jọ wà tipẹ́ pàápàá máa ń mọ nǹkan tuntun nípa ara wọn bọ́dún ṣe ń gorí ọdún.

2 Tá a bá fẹ́ràn ẹnì kan, ó máa wù wá ká túbọ̀ mọ ẹni náà dáadáa. Àmọ́, kò sí ọ̀rẹ́ tá a lè ní tó lè dà bí Jèhófà. A ò sì lè mọ ohun gbogbo nípa rẹ̀. (Róòmù 11:33) Títí ayé la ó máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀, a ó sì túbọ̀ máa mọyì wọn.—Oníw. 3:11.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ mú ká túbọ̀ mọyì bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, tí kì í sì í ṣe ojúsàájú. Ẹ jẹ́ ká tún jíròrò méjì míì lára àwọn ànímọ́ àgbàyanu Jèhófà. Àkọ́kọ́, ó jẹ́ ọ̀làwọ́, èkejì, ó máa ń fòye báni lò. Nínú ìjíròrò yìí, àá túbọ̀ rí i pé lóòótọ́ ni “Jèhófà ń ṣe rere fún gbogbo gbòò, àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.”—Sm. 145:9.

JÈHÓFÀ JẸ́ Ọ̀LÀWỌ́

4. Tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ ọ̀làwọ́, kí ló túmọ̀ sí?

4 Tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ ọ̀làwọ́, kí ló túmọ̀ sí? A lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Ìṣe 20:35, èyí tó sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká mọ  ohun tí ojúlówó ìwà ọ̀làwọ́ jẹ́. Tayọ̀tayọ̀ ni ọ̀làwọ́ èèyàn máa ń lo àkókò rẹ̀, tó sì máa ń náwó nára nítorí àwọn ẹlòmíì. Kì í ṣe bí ohun tí ẹnì kan fúnni ṣe pọ̀ tó ló ń fi hàn pé ó jẹ́ ọ̀làwọ́, bí kò ṣe pé kó jẹ́ látọkàn wá. (Ka 2 Kọ́ríńtì 9:7.) Kò sẹ́ni tó lawọ́ tó Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀.”—1 Tím. 1:11.

5. Àwọn nǹkan wo ló fi hàn pé Jèhófà jẹ́ ọ̀làwọ́?

5 Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ọ̀làwọ́? Jèhófà máa ń pèsè àwọn ohun táwa èèyàn nílò, kódà ó ń pèsè fáwọn tí kò tíì máa jọ́sìn rẹ̀. Bíbélì sọ pé, “Jèhófà ń ṣe rere fún gbogbo gbòò.” Lọ́nà wo? ‘Ó ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere. Ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.’ (Mát. 5:45) Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ fáwọn kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ pé Jèhófà “ṣe rere, ó ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Ìṣe 14:17) Ó ṣe kedere nígbà náà pé gbogbo èèyàn pátá ló ń jàǹfààní látinú bí Jèhófà ṣe jẹ́ ọ̀làwọ́.—Lúùkù 6:35.

6, 7. (a) Àwọn wo ni Jèhófà máa ń fẹ́ láti pèsè fún jù lọ? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan to fi hàn pé Jèhófà máa ń pèsè fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

6 Ó máa ń wu Jèhófà gan-an láti pèsè fáwọn tó ń fòótọ́ sìn ín. Dáfídì Ọba sọ pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.” (Sm. 37:25) Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó ń fòótọ́ sin Jèhófà lè jẹ́rìí sí i pé, bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.

7 Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Nancy ní ìṣòro kan. Ó nílò iye tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] náírà láti sanwó ilé tó ń gbé, ọjọ́ kejì ni wọ́n sì fún un dà. Àmọ́ kò lówó lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà nípa ọ̀rọ̀ náà, mo sì gba ilé oúnjẹ tí mo ti ń báwọn ta oúnjẹ lọ. Mi ò retí pé ẹnikẹ́ni máa fún mi lówó lọ́jọ́ yẹn torí pé ó bọ́ sí ọjọ́ táwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ wá jẹun. Àmọ́, ó yà mí lẹ́nu pé, ńṣe làwọn tó wá jẹun kàn ń fún mi lówó lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Nígbà tí mo sì máa ṣírò owó tí wọ́n fún mi, iye owó ilé tí mo fẹ́ san gẹ́lẹ́ ni.” Ó dá Nancy lójú pé Jèhófà fún un ní ohun tó nílò gan-an.—Mát. 6:33.

8. Ẹ̀bùn tó ṣe pàtàkì jù lọ wo ni Jèhófà fún wa?

8 Gbogbo èèyàn pátá ni Jèhófà nawọ́ ẹ̀bùn tó ṣe pàtàkì jù lọ sí. Kí ni ẹ̀bùn náà? Ẹbọ ìràpadà Jésù ni. Jésù sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) Gbogbo èèyàn pátá ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ayé. Torí náà, gbogbo èèyàn tó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ló lè rí ẹ̀bùn yìí gbà. Àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 10:10) Kò sí ẹ̀rí míì tó tún ju èyí lọ pé Jèhófà jẹ́ ọ̀làwọ́!

 BÁ A ṢE LÈ JẸ́ Ọ̀LÀWỌ́ BÍI TÍ JÈHÓFÀ

Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ọ̀làwọ́ bíi tòun (Wo ìpínrọ̀ 9)

9. Báwo la ṣe lè jẹ́ ọ̀làwọ́ bíi ti Jèhófà?

 9 Báwo la ṣe lè jẹ́ ọ̀làwọ́ bíi ti Jèhófà? A mọ̀ pé Jèhófà “ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa”; torí náà, ó yẹ kó máa wù wá láti ṣàjọpín pẹ̀lú àwọn míì, kí ayọ̀ wọn lè kún. (1 Tím. 6:17-19) Tayọ̀tayọ̀ là ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan látinú ohun ìní wa tá a sì ń ṣèrànwọ́ fáwọn aláìní. (Ka Diutarónómì 15:7.) Kí ló lè mú ká máa lawọ́ sáwọn èèyàn? Ńṣe làwọn Kristẹni kan pinnu pé nígbàkigbà tẹ́nì kan bá fún wọn lẹ́bùn, àwọn náà á rí i pé àwọn fún ẹlòmíì lẹ́bùn. Àìmọye àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó bá dọ̀rọ̀ pé kéèyàn lawọ́.

10. Kí ni ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ ọ̀làwọ́?

10 Ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ ọ̀làwọ́ ni pé ká máa lo àkókò wa àti okun wa láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ká sì máa fún wọ́n ní ìṣírí. (Gál. 6:10) Láti mọ̀ bóyá lóòótọ́ là ń ṣe bẹ́ẹ̀, a lè bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ àwọn èèyàn mọ̀ mí sí ẹni tó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tó sì máa ń tẹ́tí sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn? Nígbà tẹ́nì kan bá ní kí n bá òun ṣe nǹkan tàbí kí n ran òun lọ́wọ́ fún nǹkan kan, ṣé ó máa ń yá mi lára láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ìgbà wo ni mo gbóríyìn fún ọkọ tàbí aya mi àtàwọn ọmọ mi kẹ́yìn? Ìgbà wo ni mo gbóríyìn fún àwọn ará ìjọ mi kẹ́yìn?’ Tá a bá “sọ fífúnni dàṣà,” ó dájú pé àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àárín àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa á sì túbọ̀ gún.—Lúùkù 6:38; Òwe 19:17.

11. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà lawọ́ sí Jèhófà?

 11 A lè fi hàn pé a lawọ́ sí Jèhófà náà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Fi àwọn ohun ìní rẹ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.” (Òwe 3:9) Lára àwọn ohun tó níye lórí tá a lè lò tinútinú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa ni àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa. Àwọn  ọmọdé náà lè lawọ́ sí Jèhófà. Bàbá kan tó ń jẹ́ Jason sọ pé: “Tá a bá ti fẹ́ fi owó sínú àpótí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ńṣe ni èmi àtìyàwó mi máa ń fún àwọn ọmọ wa ní owó náà, kí wọ́n lè fi sínú àpótí ọrẹ fúnra wọn. Inú wọn sì máa ń dùn gan-an, torí pé ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ń fún Jèhófà ní nǹkan.” Àwọn ọmọ tó ti mọ béèyàn ṣe ń fún Jèhófà ní nǹkan láti kékeré máa ń láyọ̀. Bó sì ṣe máa mọ́ wọn lára dàgbà nìyẹn.—Òwe 22:6.

JÈHÓFÀ MÁA Ń FÒYE BÁNI LÒ

12. Kí ló túmọ̀ sí láti fòye báni lò?

12 Ànímọ́ àgbàyanu míì tí Jèhófà ní ni ìfòyebánilò. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a sábà máa ń tú sí ìfòyebánilò túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ ẹni tí kì í rin kinkin mọ́ nǹkan. (Títù 3:1, 2) Ẹni tó ń fòye báni lò kì í rin kinkin mọ́ òfin, kì í fúngun mọ́ni, kì í sì í le koko mọ́ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń ṣe àwọn èèyàn jẹ́jẹ́, ó máa ń wo ibi tágbára wọn mọ àti ipò tí wọ́n wà. Ó máa ń fẹ́ láti tẹ́tí sí àwọn èèyàn. Nígbà tó bá sì yẹ bẹ́ẹ̀, ó máa ń gbà kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́ lọ́nà tí wọ́n bá rí i pé ó dára jù láti ṣe é.

13, 14. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń fòye báni lò? (b) Kí la rí kọ́ látinú bí Jèhófà ṣe fòye bá Lọ́ọ̀tì lò?

13 Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń fòye báni lò? Ó máa ń gba tàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rò, ó sì sábà máa ń gbà wọ́n láyè láti ṣe nǹkan lọ́nà tí wọ́n bá fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ọ̀nà tó gbà fòye bá Lọ́ọ̀tì ọkùnrin olódodo náà lò. Nígbà tí Jèhófà pinnu pé òun máa pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run, ó sọ fún Lọ́ọ̀tì pé kó sá lọ sórí àwọn òkè ńlá. Torí àwọn ìdí kan, Lọ́ọ̀tì bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun sá lọ síbòmíì. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí? Ńṣe ni Lọ́ọ̀tì ń sọ pé kí Jèhófà yí ìtọ́ni rẹ̀ pa dà torí tòun!—Ka Jẹ́nẹ́sísì 19:17-20.

14 Àwọn kan lè sọ pé ìgbàgbọ́ Lọ́ọ̀tì kò lágbára tàbí pé aláìgbọràn ni. Ó ṣe tán, kò sí àní-àní pé ibi yòówù kí Lọ́ọ̀tì sá lọ, Jèhófà máa dáàbò bò ó, torí bẹ́ẹ̀ kò sídìí fún un láti bẹ̀rù. Àmọ́, ẹ̀rù ṣáà ń bà á, Jèhófà náà ò sì bá a jiyàn. Ó gbà kí Lọ́ọ̀tì sá lọ síbi tó ní òun fẹ́ sá lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti pinnu pé òun máa pa ìlú tó fẹ́ sá lọ náà run tẹ́lẹ̀, àmọ́ nítorí tiẹ̀ ni kò ṣe pa á run mọ́. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 19:21, 22.) Ó ṣe kedere pé Jèhófà kì í rin kinkin. Ó fòye bá Lọ́ọ̀tì lò, ó sì yọ̀ǹda fún un láti ṣe ohun tó fẹ́ ṣe.

15, 16. Báwo ni Òfin Mósè ṣe fi hàn pé Jèhófà máa ń fòye báni lò? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

15 Òfin Mósè tún jẹ́ àpẹẹrẹ míì tó fi hàn pé Jèhófà máa ń fòye báni lò. Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá tálákà débi tí kò lè fi ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí ewúrẹ́ rúbọ, ó lè lo oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan ò tiẹ̀ wá lágbára láti ra ẹyẹlé méjì ńkọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, Jèhófà gbà kí irú ẹnì bẹ́ẹ̀ fi ìyẹ̀fun díẹ̀ rúbọ. Àmọ́ o, kì í kàn ṣe ìyẹ̀fun kan ṣá. Òfin Ọlọ́run sọ pé kí ẹni náà mú “ìyẹ̀fun kíkúnná” wá, irú èyí tí wọ́n fi máa ń ṣe àwọn èèyàn pàtàkì lálejò. (Jẹ́n. 18:6) Báwo nìyẹn ṣe fi hàn pé Jèhófà ń fòye báni lò?—Ka Léfítíkù 5:7, 11.

16 Jẹ́ ká wò ó báyìí ná, ká sọ pé ọmọ Ísírẹ́lì ni ẹ́, tálákà sì ni ẹ́. Bó o ṣe dé àgọ́ ìjọsìn pẹ̀lú ìyẹ̀fun díẹ̀ lọ́wọ́ lo bá rí àwọn ọmọ ìlú rẹ tó rí jájẹ dáadáa tí wọ́n fa ẹran wá láti fi rúbọ. Ojú wá ń tì ẹ́ pé ìyẹ̀fun lásán-làsàn ni ìwọ́ wá fi rúbọ. Àmọ́, o wá rántí pé ìyẹ̀fun tó o mú wá ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. Kí nìdí? Ohun kan ni pé, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ní kó o mú ìyẹ̀fun kíkúnná wá. Lédè míì, ohun tí Jèhófà ń sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ tálákà ni pé: ‘Mo mọ̀ pé agbára yín ò ká àgùntàn, ewúrẹ́ tàbí ẹyẹ, àmọ́ mo mọ̀ pé ohun  tágbára yín ká lẹ́ fi rúbọ.’ Ó ṣe kedere pé bí Jèhófà ṣe gba tàwọn èèyàn náà rò fi hàn pé ó máa ń fòye bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò.—Sm. 103:14.

17. Irú ìjọsìn wo ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí?

 17 Ó máa ń tù wá nínú nígbà tá a bá rántí pé Jèhófà máa ń fòye báni lò àti pé inú rẹ̀ dùn sí ìjọsìn tá a fi tọkàntọkàn ṣe. (Kól. 3:23) Arábìnrin àgbàlagbà kan lórílẹ̀-èdè Ítálì, tó ń jẹ́ Constance sọ pé: “Ohun tí mo fẹ́ràn ju lọ ni pé kí n máa sọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn. Ìdí nìyẹn tí mi ò fi jáwọ́ láti máa wàásù, tí mo sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, inú mi máa ń bà jẹ́ torí pé àìlera mi ò jẹ́ kí n lè ṣe tó bí mo ṣe fẹ́. Àmọ́, mo mọ̀ pé Jèhófà mọ ibi tágbára mi mọ, ó nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì mọyì ìwọ̀nba tí agbára mi gbé.”

MÁA FÒYE BÁNI LÒ BÍI TI JÈHÓFÀ

18. Báwo làwọn òbí ṣe lè fara wé Jèhófà?

18 Báwo la ṣe lè máa fòye báni lò bíi ti Jèhófà? Ẹ jẹ́ ká rántí bí Jèhófà ṣe fòye bá Lọ́ọ̀tì lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ ohun tí Lọ́ọ̀tì máa ṣe, síbẹ̀ ó tẹ́tí sí i nígbà tó ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀, ó sì gba tiẹ̀ rò. Ẹ̀yin òbí, ṣé ẹ lè fara wé Jèhófà? Ṣé ẹ lè tẹ́tí sáwọn ọmọ yín nígbà tí wọ́n bá ń sọ ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí? Tó bá ṣeé ṣe, ṣé ẹ lè gbà kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan kan lọ́nà tí wọ́n fẹ́? Ìmọ̀ràn nípa bí ẹ̀yìn àtàwọn ọmọ yín ṣe lè jọ jíròrò nígbà tẹ́ ẹ bá fẹ́ gbé òfin táwọn ọmọ yín á máa tẹ̀ lé nínú ilé kalẹ̀ wà nínú Ilé Ìṣọ́ September 1, 2007. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀yin òbí lẹ láṣẹ láti pinnu pé iye aago báyìí lẹ fẹ́ káwọn ọmọ yín máa wọlé. Síbẹ̀, á dára tẹ́ ẹ bá jẹ́ káwọn ọmọ yín sọ èrò wọn nípa aago tẹ́ ẹ yàn náà. Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọ yín dábàá aago míì, ẹ lè gba tiwọn rò kẹ́ ẹ sì dábàá aago míì, níwọ̀n bí kò bá ti ta ko ìlànà kankan nínú Bíbélì. Ẹ lè wá rí i pé á túbọ̀ rọrùn fáwọn ọmọ yín láti lóye àwọn òfin tẹ́ ẹ fún wọn, wọ́n á sì máa tẹ̀ lé e. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹ ti gbọ́ tẹnu wọn, ẹ sì ti gba tiwọn rò kẹ́ ẹ tó ṣe òfin náà.

19. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè máa fòye báni lò bíi ti Jèhófà?

19 Àwọn alàgbà máa ń sapá kí wọ́n lè máa fòye báni lò bíi ti Jèhófà. Ọ̀nà tí wọ́n sì máa ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, wọn kì í retí pé káwọn ará máa ṣe ohun tí agbára wọn kò gbé. Ẹ rántí pé Jèhófà ò fojú kéré ẹbọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ tálákà, ó mọyì rẹ̀ gan-an. Lọ́nà kan náà, ìwọ̀nba làwọn ará kan lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, bóyá torí àìlera wọn tàbí ọjọ́ ogbó. Kí lẹ̀yin alàgbà lè ṣe tínú àwọn ará bẹ́ẹ̀ ò bá dùn torí pé wọn ò lè ṣe tó bó ṣe wù wọ́n? Ẹ sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn, kẹ́ ẹ jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jèhófà mọyì wọn gan-an, ó mọ̀ pé gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe ni wọ́n ń ṣe.—Máàkù 12:41-44.

20. Ṣé ìfòyebánilò túmọ̀ sí pé kéèyàn máa ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run? Ṣàlàyé.

20 Àmọ́ o, pé èèyàn ń fòye bá ara rẹ̀ lò kì í ṣe ohun kan náà pẹ̀lú kéèyàn máa ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run, torí kéèyàn lè ṣàánú ara rẹ̀. (Mát. 16:22) A ò ní fẹ́ máa ṣe ìmẹ́lẹ́ ká wá máa ṣàwáwí pé ṣe là ń fòye bá ara wa lò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa “tiraka tokuntokun” láti ti ire Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn. (Lúùkù 13:24) Ìlànà méjì là ń fi sílò, ọ̀kan ò sì gbọ́dọ̀ pa èkejì lára. Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ lo ara wa tokuntokun, ká má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ká máa fi sọ́kàn pé Jèhófà ò ní ká ṣe ju agbára wa lọ. Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà mọyì wa gan-an tá a bá ti ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe. Ǹjẹ́ inú wa ò dún pé Baba wa ọ̀run mọrírì ohun tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ó sì ń fòye bá wa lò? Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò méjì míì lára àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Jèhófà ní.—Sm. 73:28.

“Fi àwọn ohun ìní rẹ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.”—Òwe 3:9 (Wo ìpínrọ̀ 11)

“Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é.”—Kól. 3:23 (Wo ìpínrọ̀ 17)