Bàbá mi sọ pé: “Àpẹẹrẹ àtàtà mà ni Nóà fi lélẹ̀ fún wa o! Ó sapá láti ṣègbọràn sí Jèhófà ó sì tún nífẹ̀ẹ́ ìdílé rẹ̀. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo wọn láti wọnú ọkọ̀ áàkì, wọ́n sì la Ìkún-omi já.”

LÁTI kékeré ni mo ti mọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn, torí bàbá mi ò lè ṣe kí wọ́n má sọ ọ́. Akíkanjú èèyàn ni bàbá mi, wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ kí nǹkan máa lọ bó ṣe yẹ, wọ́n sì kórìíra ìrẹ́jẹ. Torí bẹ́ẹ̀, kò ṣòro fún wọn láti mọ̀ pé òtítọ́ ni àlàyé Bíbélì tí wọ́n gbọ́ ní ọdún 1953. Látìgbà yẹn, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti fi ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì kọ́ àwa ọmọ wọn. Màmá mi ò kọ́kọ́ fẹ́ pa àwọn àṣà ìsìn Kátólíìkì tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ tì. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò.

Kò rọrùn fún àwọn òbí mi láti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìdí ni pé màmá mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà, bàbá mi sì rèé, wọ́n máa ń pẹ́ kí wọ́n tó dé láti oko. Tí wọ́n bá máa fi dé, á ti rẹ̀ wọ́n débi pé nígbà míì tí wọ́n bá tiẹ̀ ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ṣe ni wọ́n á máa tòògbé. Àmọ́, wàhálà wọn lórí wa kò já sásán. Àwa mẹ́rin ni wọ́n bí, ọkùnrin méjì àti obìnrin méjì, èmi sì làgbà gbogbo wọn. Èmi náà ni mo kọ́ àwọn yòókù lẹ́kọ̀ọ́. Lára ohun tí mo máa ń kọ́ wọn ni ohun tí bàbá mi sábà máa ń mẹ́nu kàn pé, Nóà ṣègbọràn sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀, ó sì tún nífẹ̀ẹ́ ìdílé rẹ̀. Mo fẹ́ràn ìtàn yẹn gan-an! Kò pẹ́ tá a fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní àgbègbè Roseto degli Abruzzi tó wà ní etíkun Adriatic ní orílẹ̀-èdè Ítálì.

Ọdún 1955 ni ìgbà àkọ́kọ́ tí èmi àti màmá mi lọ sí àpéjọ àgbègbè. Ọmọ ọdún mọ́kànlá péré ni mi nígbà yẹn, ìlú Róòmù ni wọ́n ti ṣe àpéjọ náà, ó sì gba pé ká rin ìrìn àjò tó jìnnà gan-an. Apá ìwọ̀ oòrùn ni ìlú Róòmù wà sílùú wa, àìmọye òkè ńlá la sì ní láti gba kọjá. Síbẹ̀, látìgbà yẹn ni mo ti fẹ́ràn láti máa lọ sáwọn àpéjọ.

Mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1956, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], mo di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ìlú Latina ní gúúsù Róòmù ni wọ́n gbé mi lọ. Nǹkan bí ọ̀gọ́rùn-ún mẹ́ta [300] kìlómítà nìlú yìí sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí mi. Àwọn èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń tẹ̀dó síbẹ̀ ni, nípa bẹ́ẹ̀ kò sí ìbẹ̀rù pé bóyá àwọn kan máa tako ẹni tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú èmi àti èkejì mi máa ń dùn gan-an bá a ṣe ń fi ọ̀pọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde. Àmọ́, torí pé mo ṣì kéré nígbà yẹn, ṣe ni àárò ilé máa ń sọ mi. Síbẹ̀, mo tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí mo ti gbà.

Ọjọ́ tá a ṣègbéyàwó

Lọ́dún 1963, ètò Ọlọ́run rán mi lọ sílùú Milan pé kí n lọ  dara pọ̀ mọ́ àwọn tó fẹ́ ṣètò ibi tá a máa lò fún Àpéjọ Àgbáyé ti “Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun” tá a máa ṣe lọ́dún yẹn. Mo tún yọ̀ǹda ara mi lákòókò àpéjọ náà, mo ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí mo bá ṣiṣẹ́ ni Paolo Piccioli tó wá láti ìlú Florence. Ní ọjọ́ kejì àpéjọ náà, arákùnrin yìí sọ àsọyé tó ń tani jí kan nípa àwọn àǹfààní téèyàn máa rí tó bá yàn láti wà láìṣègbéyàwó. Mo rántí pé mo sọ nínú ọkàn mi lọ́jọ́ yẹn pé bóyá ni arákùnrin yìí máa gbéyàwó. Àmọ́, kò pẹ́ tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà síra. A wá rí i pé ọ̀rọ̀ àwa méjèèjì bára mu, àfojúsùn wa jọra, a jọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì jọ máa ń wù wá láti ṣègbọràn sí Jèhófà. Nígbà tó di ọdún 1965, a ṣègbéyàwó.

KẸ́KẸ́ PA MỌ́ ÀWỌN ÀLÙFÁÀ ṢỌ́Ọ̀ṢÌ LẸ́NU

Ọdún mẹ́wàá ni mo fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé nílùú Florence. Inú wa máa ń dùn gan-an bá a ṣe ń rí i táwọn ìjọ ń pọ̀ sí i. Bá a tún ṣe ń rí báwọn ọ̀dọ́ ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí ń wú wa lórí gan-an. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi àti ọkọ mi máa ń báwọn jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí, a sì tún máa ń ṣeré ìdárayá pẹ̀lú wọn, kódà ọkọ mi máa ń gbá bọ́ọ̀lù pẹ̀lú wọn. Ká sóòótọ́, ó máa ń wù mí gan-an pé kí ọkọ mi máa wà pẹ̀lú mi, àmọ́ mo tún mọ̀ pé àwọn ìdílé àtàwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ náà nílò ẹni tó máa fara balẹ̀ gbọ́ wọn táá sì ràn wọ́n lọ́wọ́, ó sì dájú pé wọ́n mọrírì bí ọkọ mi ṣe máa ń yọ̀ọ̀da ara rẹ̀ gan-an.

Tí mo bá ń rántí àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn, ńṣe ni inú mi máa ń dùn. Ọ̀kan nínú wọn ni Adriana. Bá a ṣe ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ni òun náà ń kọ́ àwọn ìdílé méjì míì ní ohun tó ń kọ́. Làwọn ìdílé yìí bá ṣètò pé kí àlùfáà kan wá jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì bíi Mẹ́talọ́kan àti àìleèkú ọkàn pẹ̀lú wọn, wọ́n sì ní káwa náà wà níbẹ̀. Ká má fọ̀rọ̀ gùn, àwọn olórí ẹ̀sìn mẹ́ta ló pésẹ̀ lọ́jọ́ náà. Ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́ ojú àwọn ọ̀rọ̀ náà pọ̀, ọ̀tọ̀ lohun tó wà nínú Bíbélì, ọ̀tọ̀ lohun tí wọ́n ń sọ. Ó wá hàn kedere sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa pé àwọn ẹ̀kọ́ wọn kò bá Bíbélì mu rárá. Ohun tí wọ́n rí nígbà ìjíròrò ọjọ́ yẹn nípa lórí ọ̀pọ̀ nínú wọn débi pé àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lára àwọn ìdílé méjì yẹn ló di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Lónìí, a kì í lo irú ọ̀nà yẹn mọ́ láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ nígbà yẹn lọ́hùn, ọkọ mi ò kẹ̀rẹ̀ tó bá di pé ká jíròrò ẹ̀kọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn àlùfáà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì ti jíròrò pẹ̀lú wọn lọ́nà yẹn. Mo rántí ọjọ́ kan tó jẹ́ pé ńṣe lèrò pé jọ bìbà tí wọ́n ń gbọ́ wa. A ò mọ̀ pé àwọn àlùfáà wọ̀nyẹn ti ṣètò ṣáájú pé kí àwọn kan nínú àwùjọ náà bi ọkọ mi láwọn ìbéèrè kan tí wọ́n ronú pé kò ní lè dáhùn tójú á sì tì í. Àmọ́, ibi tí wọ́n fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀. Ṣàdédé ni ẹnì kan nínú àwùjọ náà sọ pé ó pẹ́ tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti máa ń lọ́wọ́ sí ìṣèlú, torí náà òun fẹ́ mọ̀ bóyá ó yẹ kí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì máa lọ́wọ́ sí ìṣèlú tàbí kò yẹ. Ni kẹ́kẹ́ bá pa mọ́ àwọn àlùfáà yẹn lẹ́nu, wọn ò mọ ohun tí wọ́n máa sọ. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ni iná bá kú mọ́ wa lójú, àwọn èèyàn náà  sì tú ká. Lẹ́yìn ọdún mélòó kan la tó wá gbọ́ pé àwọn àlùfáà yẹn ló ṣètò pé kí wọ́n paná bí ọ̀rọ̀ bá fẹ́ bẹ́yìn yọ.

ÀWỌN ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌSÌN MÍÌ TẸ̀ WÁ LỌ́WỌ́

Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tá a ṣègbéyàwó, ètò Ọlọ́run sọ pé kí ọkọ mi máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. Kò rọrùn fún ọkọ mi láti fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, torí pé iṣẹ́ náà ń mówó wọlé gan-an. Àmọ́ lẹ́yìn tá a fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, a gbà láti ṣe iṣẹ́ ìsìn náà. A máa ń gbádùn àwọn ará tá a bá dé sílé wọn gan-an. Lọ́wọ́ alẹ́, a sábà máa ń kóra jọ ká lè kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀. Tá a bá ṣe tán, ọkọ mi tún máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n bá fún wọn nílé ìwé, pàápàá tó bá jẹ́ ìṣirò. Ọkọ mi tún fẹ́ràn kó máa kàwé gan-an, ó sì máa ń sọ ohun tó gbádùn nínú àwọn ìwé tó kà. Láwọn ọjọ́ Monday, èmi àti ọkọ mi sábà máa ń lọ sí ìgboro níbi táwọn ará ò sí láti wàásù, a sì máa ń pè wọ́n sípàdé tó máa wáyé nírọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.

A máa ń gbádùn àwọn àkókò tà ń lò pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́. Ọkọ mi tiẹ̀ máa ń bá wọn gbá bọ́ọ̀lù

Lẹ́yìn ọdún méjì tá a ti ń bẹ ìjọ wò, ètò Ọlọ́run ní ká máa bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú Róòmù. Ọ̀rọ̀ òfin ni wọ́n ní kí ọkọ mi máa bójú tó, èmi sì ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń bójú tó àwọn ìwé ìròyìn. Ìyàtọ̀ ńlá gbáà ló wà láàárín iṣẹ́ alábòójútó àyíká àti iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì, àmọ́ a pinnu pé ohun tí wọ́n bá ní ká ṣe la máa ṣe. Inú wa dùn gan-an bí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ṣe ń gbòòrò sí i látìgbàdégbà àti báwọn ará ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè Ítálì. Láàárín àkókò yìí náà ni ìjọba fọwọ́ sí iṣẹ́ wa lábẹ́ òfin. A gbádùn iṣẹ́ ìsìn wa ní Bẹ́tẹ́lì gan-an ni.

Ọkọ mi gbádùn iṣẹ́ tó ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì

Àkókò yìí kan náà làwọn èèyàn ń bá àwọn ará wa ṣe ẹjọ́ torí pé wọn ò gbẹ̀jẹ̀ sára. Ẹjọ́ kan tiẹ̀ wáyé láàárín ọdún 1981 sí 1985 tí ìròyìn nípa rẹ̀ sì tàn káàkiri. Wọ́n fẹ̀sùn kan tọkọtaya kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí pé àwọn ni wọ́n pa ọmọbìnrin wọn. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, àrùn kan tó gbòde lákòókò yẹn ní àgbègbè Mẹditaréníà ló ba ẹ̀jẹ̀ ara ọmọ náà jẹ́. Àrùn yìí ló sì pa ọmọ náà. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ṣèrànwọ́ fún àwọn agbẹjọ́rò tó ń gbẹnu sọ fáwọn òbí ọmọ náà. Wọ́n lo ìwé àṣàrò kúkúrú kan àti ìtẹ̀jáde Jí! kan tí wọ́n tẹ̀ lákànṣe láti fi ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀jẹ̀ àti òtítọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà. Àlàyé náà sì ṣe kedere. Ní gbogbo àkókò yẹn, bí ọkọ mi bá ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láàárọ̀ báyìí, ó di òru kó tó ṣíwọ́. Èmi náà sì ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́

OHUN ÀÌRÒTẸ́LẸ̀ KAN ṢẸLẸ̀

Ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ogún [20] ọdún tá a ṣègbéyàwó. Mo lóyún! Nígbà tá à ń wí yìí, ẹni ọdún mọ́kànlélógójì [41] ni mi, ọkọ mi sì jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta [49]. Ni mo bá sọ fún ọkọ mi. Nínú ìwé àkọsílẹ̀ rẹ̀ tó máa ń kọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojúmọ́ sí, ó kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i: “Àdúrà: Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni ìyàwó mi ti lóyún, jọ̀wọ́ jẹ́ ká lè máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wa nìṣó. Máa ṣe jẹ́ kí ìtara wa nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ dín kù. Jẹ́ ká lè jẹ́ òbí tó dára tó sì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún ọmọ wa. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, jẹ́ kí n lè fi ohun tí mo ti ń kọ́ àwọn ará nínú àsọyé mi láti ọgbọ̀n [30]  ọdún yìí wá sílò, bó tiẹ̀ jẹ́ díẹ̀ nínú rẹ̀.” Ká sòótọ́, Jèhófà dáhùn àdúrà wa.

Ilaria ni a sọ ọmọ tá a bí. Nǹkan ò rọrùn fún wa rárá nígbà tá a bí ọmọ wà. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì ṣẹlẹ̀ tó kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Gẹ́lẹ́ bí Òwe 24:10 ṣe sọ ọ́ lọ̀rọ̀ rí, pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” Ṣùgbọ́n ní gbogbo àkókò yẹn, a ò fi ara wa sílẹ̀, ṣe la fọwọ́ sowọ́ pọ̀.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ilaria máa ń sọ pé inú òun dùn pé àwọn òbí tó fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìsìn ló tọ́ òun dàgbà. A nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ òbí rere fun un. Kò sígbà tá a pa á tì. Mo máa ń ráyè fún dáadáa. Tí ọkọ mi bá tún dé lálẹ́, wọ́n máa ń bá a ṣeré, wọ́n sì tún máa ń kọ́ ọ níṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì wọ́n lè níṣẹ́ táwọn náà fẹ́ ṣe, wọ́n ṣì máa wáyé gbọ́ tiẹ̀ ná kó tó di pé wọ́n ṣe tiwọn. Nígbà míì, ó lè tó aago méjì tàbí mẹ́ta òru kí wọ́n tó sùn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọmọ wa máa ń sọ pé “Bàbá mi lọ́rẹ̀ẹ́ tí mo fẹ́ràn jù lọ”

Iṣẹ́ ọmọ títọ́ ò rọrùn rárá, pàápàá tó bá kan ti pé ká kọ́ ọmọ láti ṣe ohun tó tọ́. Àmọ́, a ò jẹ́ kó sú wa láti jẹ́ kọ́mọ wa mọ ìlànà Jèhófà, a ò sì gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún un. Èyí sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa hùwà tó dáa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Mo rántí ìgbà kan tó ṣe ohun tí kò dára nígbà tóun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan jọ ń ṣeré. A lo Bíbélì láti jẹ́ kó mọ̀ pé ìwà tó hù náà kò dára. A sì rí i pé ó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ yẹn.

Ilaria máa ń sọ pé òun mọrírì bí àwa òbí rẹ̀ ṣe ń lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó ti wà nílé ọkọ báyìí, òun náà sì rí i pé àǹfààní wà níbẹ̀ téèyàn bá ń ṣègbọràn, tó sì ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà.

A JẸ́ ONÍGBỌRÀN LÁKÒÓKÒ WÀHÁLÀ

Lọ́dún 2008, dókítà sọ fún ọkọ mi pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ. Ó kọ́kọ́ dà bíi pé ọkọ mi máa bọ́ lọ́wọ́ àìsàn náà. Ní gbogbo àkókò yẹn, ó máa ń fún mi níṣìírí, kò jẹ́ kí n kárí sọ rárá. Àwọn dókítà tó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ dáadáa ló ń tọ́jú ọkọ mi. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ wákàtí ni èmi àti Ilaria fi máa ń bẹ Jèhófà pé kó má fi wá sílẹ̀, kó jẹ́ ká lè fara dà á. Nígbà tó yá, àìsàn ọkọ mi wá burú débi pe abarapá ọkùnrin wá dẹni tó rọ kalẹ̀, tí kò lè ṣe nǹkan kan mọ́. Nígbà tó di ọdún 2010, ọkọ mi kú. Àdánù ńlá gbáà ló jẹ́ fún mi. Àmọ́, tí mo bá ń rántí bí Jèhófà ṣe lò wá ní gbogbo ọdún márùnlélógójì [45] tá a fi jọ wà, ará máa ń tù mí. A ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Mo sì mọ̀ dájú pé kò ní gbàgbé iṣẹ́ wa. Mò ń fójú sọ́nà sí ìgbà tí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jòhánù 5:28, 29 máa ṣẹ, tí màá tún pa dà rí ọkọ mi.

“Mo ṣì máa ń rántí ìgbà tí mo wà ní kékeré tí mo fẹ́ràn ìtàn Nóà gan-an. Ìpinnu mi ò sì tíì yí pa dà pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá ní kí n ṣe ni máa ṣe”

Mo ṣì máa ń rántí ìgbà tí mo wà ní kékeré tí mo fẹ́ràn ìtàn Nóà gan-an. Ìpinnu mi ò sì tíì yí pa dà pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá ní kí n ṣe ni máa ṣe. Mo mọ̀ pé ìṣòro yòówù kí n ní, ohun yòówù kí n yááfì tàbí ohun yòówù kí n pàdánù, wọn ò tó nǹkan tí mo bá fi wé bí Ọlọ́run ti ṣe bù kún mi lọ́nà àgbàyanu. Ká sòótọ́, kò sóhun tó dáa tó pé ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà!