Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  June 2013

Ẹ̀yin Alàgbà, Ẹ Máa Tu “Ọkàn Tí Àárẹ̀ Mú” Lára

Ẹ̀yin Alàgbà, Ẹ Máa Tu “Ọkàn Tí Àárẹ̀ Mú” Lára

Arábìnrin kan wà tó ń jẹ́ Angela, * ó ti lé ní ọgbọ̀n [30] ọdún, kò sì tíì lọ́kọ. Ọ̀kan rẹ̀ ò ba lẹ̀ bó ṣe ń retí àwọn alàgbà tó ń bọ̀ wá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó ń ronú pé: ‘Kí ni àwọn alàgbà yẹn máa sọ?’ Òótọ́ ni pé ó ti ṣe díẹ̀ tó ti wá sípàdé, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé tó bá fi máa délé lálẹ́ láti ibi tó ti ń tọ́jú àwọn àgbàlagbà, ó ti máa ń rẹ̀ ẹ́ gan-an. Kò tán síbẹ̀, ara ìyà rẹ̀ ò tún yá, èyí sì tún ń kó ìrònú bá a.

Ká sọ pé ìwọ ni alàgbà tó fẹ́ lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Angela, báwo lo ṣe máa gbé e ró? (Jer. 31:25) Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀ tó o bá fẹ́ ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ “ọkàn tí àárẹ̀ mú,” bíi ti Angela.

RONÚ NÍPA OHUN TÓ Ń BÁ WỌN FÍNRA

Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń rẹ àwa fúnra wa bóyá nítorí wàhálà iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, tàbí nígbà míì àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí pàápàá lè mú kó rẹ̀ wá. Bí àpẹẹrẹ, ‘okun tán’ nínú wòlíì Dáníẹ́lì nígbà tó rí ìran kan tí òye rẹ̀ ò sì yé e. (Dán. 8:27) Báwo ló ṣe wá rí ìrànlọ́wọ́ gbà? Ọlọ́run rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sí i kó lè ṣàlàyé ìran náà fún un, kó sì tún fi dá a lójú pé Jèhófà ti gbọ́ àdúrà rẹ̀. Àti pé, ó ṣì jẹ́ ‘ẹni tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi’ lójú Jèhófà. (Dán. 9:21-23) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, áńgẹ́lì míì tún lo irú àwọn ọ̀rọ̀ tó fún un níṣìírí yẹn láti tún fún un lókun.—Dán. 10:19.

Kó o tó lọ bẹ ẹnì kan wò, kọ́kọ́ ronú nípa ẹni náà àti àwọn ìṣòro tó ní

Tí ọ̀kan nínú àwọn ará wa bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí nǹkan tojú sú u, ìwọ náà lè fún un níṣìírí. Kó o tó lọ bẹ ẹni yẹn wò, kọ́kọ́ ronú nípa ẹni náà àti àwọn ipò tó wà. Àwọn ìṣòro wo ló ní? Kí ló mú kí ìṣòro náà kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a? Àwọn ànímọ́ rere wo lo ti kíyè sí pé ó ní? Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Richard tó ti ń sìn  gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún ohun tó lé ní ogún [20] ọdún sọ pé: “Ohun tí mo kọ́kọ́ máa ń ronú nípa rẹ̀ ni àwọn ànímọ́ tó dára tí ẹni náà ní. Lẹ́yìn náà máa wá fara balẹ̀ ronú nípa ìṣòro rẹ̀. Èyí máa ń mú kó rọrùn fún mi láti sọ ọ̀rọ̀ tó máa tù wọ́n lára tó sì máa fún wọn níṣìírí.” Tó bá jẹ́ pé ìwọ́ àti alàgbà kan lẹ jọ fẹ́ lọ bẹ ẹnì kan wò, ohun tó dára ni pé kẹ́ ẹ jọ ronú nípa ẹni náà àti ìṣòro rẹ̀ kẹ́ ẹ tó lọ.

Ẹ JẸ́ KÍ ARA TÙ WỌ́N

Kì í sábà yá àwọn èèyàn lára láti sọ ìṣòro wọn àti bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wọn. Àmọ́, báwo lo ṣe lè mú kí ara tu ẹni tó o lọ ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀? O lè kọ́kọ́ rẹ́rìn-ín músẹ́, kó o sì sọ̀rọ̀ rere tó lè fún un níṣìírí. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Michael tó ti ń sìn gẹ́gẹ́ bi alàgbà fún ohun tó lé ní ogójì ọdún sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí: “Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé àwọn alàgbà lè máa bẹ́ àwọn ará wò nínú ilé wọn, torí pé ó máa ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn dáadáa. Ọjọ́ pẹ́ tí mo ti ń fojú sọ́nà fún ìbẹ̀wò tá a ṣe sọ́dọ̀ rẹ yìí.”

Kò sì burú tẹ́ ẹ bá kọ́kọ́ gbàdúrà pẹ̀lú ẹni náà kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀. Nínú àdúrà kan tí Pọ́ọ̀lù gbà, ó mẹ́nu kan àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ànímọ́ tó dára tí wọ́n ní. Irú bí ìfẹ́, ìgbàgbọ́ àti ìfaradà. (1 Tẹs. 1:2, 3) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó máa dára tí ìwọ náà bá mẹ́nu kan àwọn ànímọ́ tó dára tí ẹni náà ní nígbà tẹ́ ẹ bá ń gbàdúrà. Irú àdúrà bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kí ìjíròrò yín lè gbéni ró, ara á sì tu onítọ̀hún náà. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Ray sọ pé: “Nígbà míì, a kì í mọyì ara wa, a sì lè má rí àwọn ohun tó dáa tá à ń gbé ṣe, àmọ́ tí ẹnì kan bá sọ ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó mọyì àwọn ohun tá à ń ṣe, èyí máa ń fún wa níṣìírí gan-an.”

FÚN WỌN NÍ Ẹ̀BÙN Ẹ̀MÍ

Ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ṣoṣo lo kà nígbà tó o bá ń fún àwọn èèyàn ní ìṣírí, ńṣe lò ń fún wọn ní “ẹ̀bùn ẹ̀mí.” (Róòmù 1:11) Bí àpẹẹrẹ, ìrẹ̀wẹ̀sì lè mú kí arákùnrin kan máa wo ara rẹ̀ bí ẹni tí kò jámọ́ nǹkan kan, bíi ti onísáàmù kan tó fi ara rẹ̀ wé “ìgò awọ nínú èéfín.” Láìka bí ẹ̀dùn ọkàn ṣe bá  onísáàmù yìí tó, ó sọ pé: “Àwọn ìlànà rẹ ni èmi kò gbàgbé.” (Sm. 119:83, 176) Lẹ́yìn tó o bá ti ṣàlàyé ẹsẹ Bíbélì náà ní ṣókí, fi dá a lójú pé o mọ̀ pé òun náà “kò gbàgbé” àwọn òfin Jèhófà.

O tún lè lo àkàwé tí Jésù sọ nípa ẹyọ owó dírákímà kan tó sọ nù láti fi ran arábìnrin kan tó ti ṣáko lọ tàbí tí ìtara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ti dín kù lọ́wọ́. (Lúùkù 15:8-10) Ó ṣeé ṣe kí ẹyọ owó tó sọ nù náà jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ẹyọ owó fàdákà tí wọ́n máa ń tò pọ̀ láti fi ṣe ẹ̀gbà ọrùn iyebíye táwọn obìnrin máa ń fi ṣe ọ̀ṣọ́. Tó o bá jíròrò àkàwé yẹn pẹ̀lú obìnrin náà, á jẹ́ kó rí i pé òun pẹ̀lú ṣeyebíye nínú ìjọ Kristẹni. O lè jẹ́ kó tún yé e pé, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àgùntàn rẹ̀ kéékèèké.

Inú àwọn ará wa máa ń dùn láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n kà nínú Bíbélì. Torí náà, má ṣe máa dá nìkan sọ gbogbo ọ̀rọ̀. Lẹ́yìn tó o bá ti ka ẹsẹ Bíbélì kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ipò ẹni náà, tọ́ka sì gbólóhùn kan níbẹ̀ kó o wá sọ fún un pé kó sọ èrò rẹ̀ lórí ohun tí ẹsẹ yẹn sọ. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ìwé 2 Kọ́ríńtì 4:16 lẹ kà, o lè bi í pé: “Ǹjẹ́ o lè rántí àwọn ọnà kan tí Jèhófà ti gbà sọ ẹ́ dọ̀tun, tàbí tó ti fún ẹ lágbára?” Irú àwọn ìbéèrè yìí á mú kó sọ èrò ọkàn rẹ̀ jáde. Lópin ìjíròrò náà, ẹ̀yin méjèèjì lẹ máa rí ìṣírí gbà.—Róòmù 1:12.

Inú àwọn ará wa máa ń dùn láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n kà nínú Bíbélì

O tún lè fún ẹnìkan níṣìírí tó o bá jíròrò ìtàn ìgbésí ayé ẹnìkan láti inú Bíbélì tí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i fara jọ ti onítọ̀hún. Àpẹẹrẹ Ánà àti Ẹpafíródítù lè jẹ́ orísun ìtùnú fún ẹnì kan tí ẹ̀dùn ọkàn bá. Àwọn méjèèjì ni wọ́n ní ẹ̀dùn ọkàn láwọn ìgbà kan, àmọ́ wọ́n ṣì ṣeyebíye lójú Jèhófà. (1 Sám. 1:9-11, 20; Fílí. 2:25-30) Ọ̀pọ̀ àwọn àpẹẹrẹ míì ló ṣì wà nínú Bíbélì tó o lè fi ran àwọn tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́.

Ẹ TÚBỌ̀ MÁA FI ÌFẸ́ HÀN

O lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ ẹni náà jẹ ọ́ lógún tí o kò bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà mọ sí ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ tó o ṣe sọ́dọ̀ rẹ̀. (Ìṣe 15:36) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti parí ìjíròrò yín, o lè sọ fún un pé ó máa wù ẹ́ kẹ́ jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Alàgbà kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bernard, tó ti ń sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ó sọ pé tí òun bá pa dà rí arákùnrin tàbí arábìnrin kan tí òun ti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀, ńṣe ni òun máa ń fọgbọ́n béèrè bóyá ó ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ràn tí òun fún un. Ó ní òun á sọ pé: “Báwo wá ni? Ṣé nǹkan sì ti wá yàtọ̀ báyìí?” Tó o bá ń béèrè bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún wọn, ńṣe lò ń fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ ọ́ lógún, èyí á sì jẹ́ kó o mọ̀ bóyá wọ́n ṣì nílò ìrànlọ́wọ́.

Àkókò tá a wà yìí gan-an làwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin túbọ̀ nílò ẹni táá máa ṣìkẹ́ wọn, tó máa lóye wọn, táá sì máa fìfẹ́ hàn sí wọn. (1 Tẹs. 5:11) Torí náà, kó o tó ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan, kọ́kọ́ ronú nípa àwọn ìṣòrò tí onítọ̀hún ní. Fi ọ̀rọ̀ ẹni náà sádùúrà, kó o sì ronú lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o fẹ́ fi gbé e ró. Nípa bẹ́ẹ̀, wàá lè rí àwọn ọ̀rọ̀ tó máa tu “ọkàn tí àárẹ̀ mú” náà lára!

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí orúkọ náà pa dà.