“Ẹ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú, ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere.”—RÓÒMÙ 12:9.

1, 2. (a) Kí ló mú ọ pinnu láti sin Ọlọ́run? (b) Àwọn ìbéèrè wo nípa ogún tẹ̀mí wa la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

Ọ̀KẸ́ àìmọye àwa èèyàn Jèhófà la ti pinnu pé Jèhófà Ọlọ́run la ó máa sìn, a ó sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi. Ìpinnu tá a ṣe yìí mọ́gbọ́n dání gan-an, ọwọ́ pàtàkì la sì fi mú un. (Mát. 16:24; 1 Pét. 2:21) Kó tiẹ̀ tó di pé a pinnu pé Jèhófà la máa sìn, ńṣe la fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, a ò kàn kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ mélòó kan lóréfèé. Nínú Bíbélì, a kẹ́kọ̀ọ́ nípa ogún tí Jèhófà ṣèlérí fún wa, ẹ̀kọ́ yìí sì mú ká túbọ̀ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Tá ò bá sì dáwọ́ ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ nípa Ọlọ́run àti Jésù Kristi dúró, ọwọ́ wa máa tẹ ogún tí Ọlọ́run ṣèlérí náà.—Jòh 17:3; Róòmù 12:2.

2 Tá a bá fẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ dán mọ́rán, a gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan táá múnú rẹ̀ dùn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí: Kí ni ogún tẹ̀mí wa? Báwo ló ṣe yẹ kó ṣe pàtàkì sí wa tó? Kí la lè ṣe tá a máa fi rí ogún yìí gbà? Kí ló lè mú ká máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání?

KÍ NI OGÚN TẸ̀MÍ WA?

3. (a) Kí làwọn ẹni àmì òróró máa jogún (b) Kí làwọn “àgùntàn mìíràn” máa jogún?

3 Ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwa Kristẹni máa jogún ìyè àìleèkú ní ọ̀run. Àǹfààní ara ọ̀tọ̀ ni wọ́n máa ní torí pé wọ́n á bá Jésù ṣàkóso nínú ìjọba rẹ̀. (1 Pét. 1:3, 4) Àwọn tó máa bá Kristi jọba yìí gbọ́dọ̀ di àtúnbí. (Jòh 3:1-3) Ogún wo ló wà fáwọn “àgùntàn mìíràn,” tí wọ́n ti ń bá àwọn ẹni àmì òróró  ṣiṣẹ́ pọ̀ láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run? (Jòh 10:16) Ogún tí Ádámù àti Éfà pàdánù làwọn máa jogún, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Níbẹ̀, kò ní sí ìyà, ikú tàbí ọ̀fọ̀ mọ́. (Ìṣí. 21:1-4) Abájọ tí Jésù fi ṣèlérí fún ọkùnrin kan tí wọ́n kàn mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—Lúùkù 23:43.

4. Àwọn ìbùkún wo là ń gbádùn báyìí?

4 Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn ìbùkún kan wà tá à ń gbádùn lára ogún tẹ̀mí wa. Nítorí pé a nígbàgbọ́ nínú “ìràpadà tí Kristi Jésù san,” ọkàn wa balẹ̀ a sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. (Róòmù 3:23-25) A lóye ohun tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ṣe lọ́jọ́ iwájú dáadáa. Inú wa sì máa ń dùn gan-an bá a ṣe ń kíyè sí ìfẹ́ alọ́májàá tó so àwa ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kárí ayé pọ̀. Láfikún, Jèhófà tún fún wa ní àǹfààní pé ká jẹ́ Ẹlẹ́rìí òun. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká mọyì ogún tẹ̀mí tá a ní yìí!

5. Kí ni Sátánì ń gbìyànjú láti ṣe fún wa? Kí la lè ṣe tá ò fi ní kó sínú pańpẹ́ rẹ̀?

5 Tá ò bá fẹ́ kí ogún wa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gan-an ká má báa kó sínú pańpẹ́ Sátánì. Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń wá bó ṣe máa mú ká ṣe ohun tí kò tọ́ ká lè pàdánù ogún tẹ̀mí wa. (Núm. 25:1-3, 9) Torí ó mọ̀ pé Jèhófà máa tó pa òun run, ó túbọ̀ ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ṣì wá lọ́nà. (Ka Ìṣípayá 12:12, 17.) Nípa bẹ́ẹ̀, tá a bá fẹ́ “dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù,” ó bọ́gbọ́n mu pé ká túbọ̀ mọyì ogún tẹ̀mí wa. (Éfé. 6:11) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Ísọ̀ tó jẹ́ àkọ́bí Ísákì yẹ̀ wò. Irú ọwọ́ wo ló fi mú ogún rẹ̀? Ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́?

MÁ ṢE DÀ BÍ ÍSỌ̀

6, 7. Ta ni Ísọ̀? Kí ni Ísọ̀ ì bá jogún?

6 Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́rin [4,000] sẹ́yìn, Rèbékà tó jẹ́ aya Ísákì bí ìbejì, ó pè wọ́n ní Ísọ̀ àti Jékọ́bù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ìyá kan náà làwọn ìbejì yìí, ìwà wọn ò jọra. Bíbélì sọ pé, “Ísọ̀ sì di ọkùnrin tí ó mọ bí a ti ṣé ń ṣọdẹ, ọkùnrin inú pápá,” nígbà tí “Jékọ́bù [jẹ́] ọkùnrin aláìlẹ́gàn, tí ń gbé inú àwọn àgọ́.” (Jẹ́n. 25:27) Bíbélì pe Jékọ́bù ní aláìlẹ́gàn torí pé ó jẹ́ olóòótọ́ àti ẹnì tó bẹ̀rù Ọlọ́run.

7 Ìgbà táwọn ọmọ yìí wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ni Ábúráhámù, bàbá wọn àgbà kú. Àmọ́, Jèhófà ò gbàgbé ìlérí tó ti ṣe fún Ábúráhámù. Nígbà tó yá, Ọlọ́run tún ìlérí náà ṣe fún Ísákì. Ọlọ́run sọ fún un pé nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ̀ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 26:3-5.) Èyí fi hàn pé ọ̀kan lára ọmọ-ọmọ Ábúráhámù ló máa di Mèsáyà, ìyẹn irú ọmọ tó máa jẹ́ olóòótọ́, èyí tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ nípa rẹ̀. Torí pé Ísọ̀ ni àkọ́bí Ísákì, òun ló lẹ́tọ̀ọ́ sí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún baba ńlá wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ìlà ìdílé rẹ̀ ló yẹ kí Mèsáyà ti jáde. Ẹ ò rí i pé ogún tí Ísọ̀ ní yìí kò láfiwé! Àmọ́, ìbéèrè náà ni pé, ṣé Ísọ̀ mọyì ogún yìí?

Má ṣe jẹ́ kí ogún tẹ̀mí rẹ bọ́ mọ́ ẹ́ lọ́wọ́

8, 9. (a) Ǹjẹ́ Ísọ̀ mọyì ogun rẹ̀? Ṣàlàyé (b) Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, èrò wo ni Ísọ̀ wá ní nípa ìpinnu tó ṣe? Kí ló wa ṣe lẹ́yìn náà?

8 Lọ́jọ́ kan tí Ísọ̀ ti oko dé, ó bá Jékọ́bù tó ń se ọbẹ̀. Ó wá sọ fún Jékọ́bù pé: “Jọ̀wọ́, tètè fún mi ní ìwọ̀n tí ó ṣe é gbé mì lẹ́ẹ̀kan lára pupa-pupa yẹn, nítorí àárẹ̀ ti mú mi!” Ni Jékọ́bù bá sọ pé: “Ta ẹ̀tọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí fún mi lákọ̀ọ́kọ́ ná!” Kí ni Ísọ̀ wá ṣe? Ó ní, ‘àǹfààní wo ni ogún ìbí jẹ́ fún  mi?’ Bí Ísọ̀ ṣe ta ogún ìbí rẹ̀ nìyẹn o. Torí kí ni? Torí abọ́ ọbẹ̀ kan péré! Kí ọ̀rọ̀ náà lè dá Jékọ́bù lójú pé lóòótọ́ ni Ísọ̀ fẹ́ ta ogún ìbí rẹ̀ fún un, ó sọ pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi ná!” Ísọ̀ ò tiẹ̀ rò ó pé ẹ̀ẹ̀mejì, ló bá ta ogún ìbí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, “Jékọ́bù sì fún Ísọ̀ ní búrẹ́dì àti ọbẹ̀ ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, ó sì jẹ, ó sì mu. Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.” Ẹ ò rí nǹkan, Ísọ̀ ò rí ogún ìbí rẹ̀ bí ohun tó já mọ́ nǹkan kan.—Jẹ́n. 25:29-34.

9 Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, nígbà tó ku díẹ̀ kí Ísákì kú, Rèbékà ṣètò pé kí Jékọ́bù gba ẹ̀tọ́ tó yẹ kí Ísọ̀ gbà gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí. Ó ṣe tán, Ísọ̀ kúkú ti ta ẹ̀tọ́ yìí fún un. Nígbà tí Ísọ̀ wá rí i pé ìwà òmùgọ̀ gbáà lòun hù bí òun ṣe ta ogún ìbí òun, ó bẹ bàbá rẹ̀ pé: “Súre fún mi, àní fún èmi náà, baba mi! . . . Ṣé ìwọ kò ṣẹ́ ìbùkún kan kù fún mi ni?” Ni Ísákì bá sọ fún Ísọ̀ pé ọ̀rọ̀ náà ti kọjá àtúnṣe, pé òun ti súre fún Jékọ́bù, kò sì ṣeé gbà pa dà. Bí Ísọ̀ ṣe bú sẹ́kún nìyẹn o!—Jẹ́n. 27:30-38.

10. Kí ni Jèhófà sọ nípa Ísọ̀ àti Jékọ́bù? Kí sì nìdí?

10 Ẹ̀kọ́ wo ni ohun tí Ísọ̀ ṣe yìí kọ́ wa? Ohun tí Ísọ̀ ṣe fí hàn pé bó ṣe máa tẹ́ ìfẹ́ ọkàn ara rẹ̀ lọ́rùn lohun tó jẹ ẹ́ lógún, kì í ṣe bó ṣe máa rí ogún tí Jèhófà ti ṣèlérí gbà. Èyí wá fi hàn pé Ísọ̀ kò mọyì ogún ìbí rẹ̀, kò sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, tara rẹ̀ nìkan ló rò, kò ro tàwọn ọmọ tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. Àmọ́ Jékọ́bù ní tiẹ̀ mọyì ogún ìbí yẹn gan-an, kò sì jẹ́ kó bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìmọ̀ràn tí àwọn òbí rẹ̀ fún un ló tẹ̀ lé nígbà tó máa yan aya. (Jẹ́n. 27:46–28:3) Èyí gba pé kó ní sùúrù, kí ó sì fara da ìnira. Àmọ́, torí pé ó ṣègbọràn, Jèhófà bù kún un, ó sì di baba ńlá Mèsáyà. Kí ni Jèhófà wá sọ nípa Ísọ̀ àti Jékọ́bù? Jèhófà sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù, Ísọ̀ ni mo sì kórìíra.”—Mál. 1:2, 3.

11. (a) Kí nìdí tóhun tó ṣẹlẹ̀ sí Ísọ̀ fi jẹ́ ẹ̀kọ́ fún àwa Kristẹni? (b) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi mẹ́nu kan àgbèrè nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Ísọ̀?

11 A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ísọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kì wá nílọ̀ pé ká ṣọ́ra “kí ó má bàa sí àgbèrè kankan tàbí ẹnikẹ́ni tí kò mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀, bí Ísọ̀, ẹni tí ó fi àwọn ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí tọrẹ ní pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.” (Héb. 12:16) Ó yẹ ká fi ìkìlọ̀ yìí sọ́kàn. Ojoojúmọ́ la gbọ́dọ̀ máa fojú tó tọ́ wo àwọn nǹkan tẹ̀mí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní kó sínú ìdẹwò, a ò sì ní pàdánù ogún tẹ̀mí wa. Kí wá nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi mẹ́nu kan àgbèrè nígbà tó ń sọ ohun tí Ísọ̀ ṣe? Ìdí ni  pé tá a bá jẹ́ kí ẹran ara lò wá bó ṣe lo Ísọ̀, wẹ́rẹ́ la máa lọ́wọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ bí àgbèrè, a sì lè tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù ogún tẹ̀mí wa.

MÚRA ỌKÀN RẸ SÍLẸ̀ NÍSINSÌNYÍ

12. (a) Kí ni Sátánì ń ṣe láti dẹ wá wò? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá dojú kọ ìdẹwò láti ṣe ohun tí kò tọ́.

12 Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, a máa ń sa gbogbo ipá wa láti yẹra fún àwọn ipò tó lè mú ká ṣèṣekúṣe. Bí ẹnì kan bá sì fẹ́ dẹ wá wò, a máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká má ṣe kó sínú ìdẹwò. (Mát. 6:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń sapá gan-an láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ayé búburú yìí, lemọ́lemọ́ ni Sátánì ń wá bó ṣe máa ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. (Éfé. 6:12) Ó ṣe tán, òun ni Ọlọ́run ayé yìí, ó mọ bí òun ṣe lè dẹ wá wò tá a fi máa ṣe ohun búburú tí ọkàn ẹ̀dá èèyàn máa ń fà sí. (1 Kọ́r. 10:8, 13) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o bára rẹ nínú ipò tó lè mú kó o lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe. Kí ni wàá ṣe? Ṣe wàá dà bí Ísọ̀ tó fi ìwàǹwára sọ pé “tètè fún mi”? Àbí ṣe ni wàá yẹra fún ìdẹwò tí wàá sì sá, bí Jósẹ́fù ṣe sá kúrò lọ́dọ̀ aya Pọ́tífárì tó fẹ́ kó sùn ti òun?—Ka Jẹ́nẹ́sísì 39:10-12.

13. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀ Kristẹni lónìí ṣe ṣe bíi Jósẹ́fù, àmọ́ báwo làwọn kan ṣe hùwà bí Ísọ̀? (b) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá ò bá fẹ́ dà bí Ísọ̀?

13 Ọ̀pọ̀ àwọn ara wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ti dójú kọ àwọn ìdẹwò, èyí tó gba pé kí wọ́n ṣe ìpinnu bóyá àwọn máa ṣe bíi ti Ísọ̀ tàbí bíi ti Jósẹ́fù. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì ti ṣe ìpinnu tó dára tí wọ́n sì múnú Jèhófà dùn. (Òwe 27:11) Àmọ́, àwọn kan hùwà bí Ísọ̀ tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù ogún tẹ̀mí wọn. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tí wọ́n bá wí nínú ìjọ tàbí tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ló jẹ́ nítorí pé wọ́n ṣe ìṣekúṣe. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ìsinsìnyí ló ti yẹ ká múra ọkàn wa sílẹ̀ dáadáa ká bàa lè borí ìdẹwò! (Sm. 78:8) A máa jíròrò àwọn nǹkan méjì tá a lè ṣe táá jẹ́ ká lè múra ọkàn wa sílẹ̀ láti borí ìdẹwò, táá sì jẹ́ ká lè ṣèpinnu tó dára.

RONÚ JINLẸ̀ KÓ O SÌ GBÁRA DÌ

Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ńṣe là ń gbára dì ká má bàa kó sínú ìdẹwò

14. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká ronú lé tó máa jẹ́ ká kórìíra ohun búburú ká sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere?

14 Ohun àkọ́kọ́ ni pé, ká máa ronú nípa ohun tó máa jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ tá a bá dá. Bá a bá ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó la ṣe máa mọyì ogún tẹ̀mí wa. Ó ṣe tán, tá a bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan, a ò ní fẹ́ ṣe ohun tó máa dùn ún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó máa múnú rẹ̀ dùn la ó máa ṣe. Torí náà, ó yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ lorí ipa tó máa ní lórí àwa fúnra wa àtàwọn ẹlòmíì tá a bá ṣe ohun tí kò tọ́. Á dára ká bi ara wa pé: ‘Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà tí mó bá lọ́wọ́ nínú ìwà yìí? Ipa wo ló máa ní lórí ìdílé mi? Báwo ló ṣe máa rí lára àwọn ará nínú ìjọ? Ṣé ìwà mi kò ní mú àwọn míì kọsẹ̀?’ (Fílí. 1:10) A tún lè bi ara wa pé: ‘Ṣé ó bọ́gbọ́n mu kí n ṣe gbogbo àkóbá yìí torí ìgbádùn ojú ẹsẹ̀? Ṣó wù mí kí ọ̀rọ̀ mi dà bíi ti Ísọ̀ tó ki ìka àbámọ̀ bọnu lẹ́yìn tọ́rọ̀ bẹ́yìn yọ?’ (Héb. 12:17) Tá a bá ronú dáadáa lórí àwọn ìbéèrè yìí, àá lè kórìíra ohun búburú, àá sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere. (Róòmù 12:9) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́, a ó ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa pàdánù ogún tẹ̀mí wa.—Sm. 73:28.

15. Kí la lè ṣe tá ò fi ní kó sínú ìdẹwò, tí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ò sì ní bà jẹ́?

15 Ohun kejì ni pé, ká gbára dì ká bàa lè borí ìdẹwò. Jèhófà ti pèsè onírúurú nǹkan tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti  múra sílẹ̀ ká lè borí ìdẹwò èyíkéyìí, ká sì pa àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ mọ́. Lára wọn ni àwọn ìpàdé ìjọ, àdúrà, iṣẹ́ ìwàásù àti àǹfààní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (1 Kọ́r. 15:58) Tá a bá ń gbàdúrà tọkàntọkàn, tá a sì ń lo ara wa lóde ẹ̀rí, ńṣe là ń gbára dì láti borí ìdẹwò. (Ka 1 Tímótì 6:12, 19.) Torí náà, a gbọ́dọ̀ sapá gan-an láti máa ṣe àwọn nǹkan yìí tá ò bá fẹ́ kó sínú ìdẹwò. (Gál. 6:7) Ohun tí ìwé Òwe orí kejì sì rọ̀ wá pé ká ṣe gan-an nìyẹn.

MÁA “BÁ A NÌṢÓ NÍ WÍWÁ A”

16, 17. Kí ló lè mú ká ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu?

16 Ìwé Òwe orí kejì rọ̀ wá pé ká sapá gan-an ká lè ní ọgbọ́n àti agbára láti ronú. Torí pé wọ́n á mú ká mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. Wọ́n á tún jẹ́ ká lè kápá èrò burúkú tó máa ń wá sọ́kàn wa dípò tá a fi máa jẹ́ kó mú wa ṣe ohun tí kò tọ́. Àmọ́, kó tó di pé a ní ọgbọ́n àti agbára láti ronú, a gbọ́dọ̀ sapá gan-an. Bíbélì sọ pé: “Ọmọ mi, ìwọ yóò bá gba àwọn àsọjáde mi, tí ìwọ yóò sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ, láti lè dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n, kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀; jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí o bá ké pe òye, tí o sì fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀, bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a bí fàdákà, tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an. Nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.”—Òwe 2:1-6.

17 Tá a bá ń ṣe ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ, a ó lè ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. A ò ní kó sínú ìdẹwò tá a bá ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Jèhófà yí wa lọ́kàn pa dà, tá à ń bẹ̀ ẹ́ pé kó máa tọ́ wa sọ́nà, tá a sì ń walẹ̀ jìn nínú Bíbélì bí ẹni tó ń wá ìṣúra tó fara sin.

18. Kí lo pinnu láti máa ṣe? Kí nìdí?

18 Jèhófà máa fún wa ní ìmọ̀, òye, ìfòyemọ̀ àti ọgbọ́n tá a bá sapá gan-an láti ní wọn. Bá a ṣe ń sapá láti lò wọ́n, a óò túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà dáadáa. Àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú Jèhófà yìí kò ní jẹ́ ká kó sínú ìdẹwò. Tá a bá túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà, tá a sì ń bẹ̀rù rẹ̀, a máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀. (Sm. 25:14; Ják. 4:8) Ǹjẹ́ kí àjọṣe tó dára tá a ní pẹ̀lú Jèhófà àti ìfẹ́ láti máa fí ọgbọ́n Ọlọ́run hùwà mú ká máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Nípa bẹ́ẹ̀, a máa múnú Jèhófà dùn, a ò sì ní pàdánù ogún tẹ̀mí wa.