Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  May 2013

Ẹ̀yin Òbí Àtẹ̀yin Ọmọ, Ẹ Máa Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀

Ẹ̀yin Òbí Àtẹ̀yin Ọmọ, Ẹ Máa Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀

“Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.”—JÁK. 1:19.

1, 2. Báwo lọ̀rọ̀ ọmọ ṣe máa ń rí lára òbí? Ojú wo làwọn ọmọ fi máa ń wo àwọn òbí wọn? Àmọ́ kí ló máa ń ṣòro fún àwọn ọmọ àtàwọn òbí nígbà míì?

ÌWÉ kan tí wọ́n pè ní For Parents Only ròyìn àbájáde ìwádìí tí àwọn kan ṣe nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn ọmọ kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n bi àwọn ọmọ náà pé: “Tó o bá gbọ́ pé àwọn òbí rẹ máa kú lọ́lá, kí ni wàá fẹ́ sọ fún wọn?” Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ náà sọ pé àwọn ò ní sọ̀rọ̀ nípa èdèkòyédè táwọn ti ní, kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn máa sọ fún wọn pé kí wọ́n má bínú fún ìwà burúkú táwọn ti hù àti pé àwọn ò ní gbàgbé wọn láé.

2 Òótọ́ kan ni pé, àwọn ọmọ nífẹ̀ẹ́ òbí wọn, àwọn òbí náà sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn gan-an, pàápàá jù lọ àwa tá a jẹ́ Kristẹni. Síbẹ̀, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, èdèkòyédè máa ń wáyé láàárín òbí àti ọmọ. Kí nìdí tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀? Kí ni àwọn òbí àtàwọn ọmọ lè ṣe tí wọ́n á fi túbọ̀ máa ráyè bá ara wọn sọ̀rọ̀?

Ǹjẹ́ o lè wáyè láti wà pẹ̀lú àwọn yòókù nínú ìdílé rẹ, dípò tí wàá fi máa dá ṣe nǹkan?

Ẹ MÁA WÁ ÀYÈ LÁTI JÙMỌ̀ SỌ̀RỌ̀

3. (a) Kí ló mú kó ṣòro fún àwọn ìdílé kan láti máa jùmọ̀ sọ̀rọ̀? (b) Kí ló mú kó rọrùn fáwọn ìdílé tó wà ní Ísírẹ́lì àtijọ́ láti jọ máa wà pa pọ̀?

3 Ọ̀pọ̀ ìdílé ni kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè láti jọ máa sọ̀rọ̀ dáadáa. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ fàwọn ìdílé tó wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́. Nígbà tí Mósè ń sọ báwọn òbí ṣe lè máa kọ́ àwọn ọmọ wọn ní òfin Ọlọ́run, ó sọ pé: “kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diu. 6:6, 7) Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn ọmọ lè wà pẹ̀lú ìyá wọn nílé tàbí kí wọ́n wà pẹ̀lú bàbá wọn lóko tàbí níbi iṣẹ́ rẹ̀. Bí wọ́n ṣe wà pa pọ̀ yẹn máa ń jẹ́ kí wọ́n ráyè bá ara wọn sọ̀rọ̀ dáadáa. Nípa bẹ́ẹ̀, ó rọrùn fún òbí láti mọ ohun tí ọmọ rẹ̀  nílò, ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ àti irú ìwà tó ní. Bákan náà, ó máa ń jẹ́ káwọn ọmọ túbọ̀ mọ àwọn òbí wọn.

4. Kí ló ń mú kó ṣòro fàwọn ìdílé lónìí láti jọ máa sọ̀rọ̀?

4 Nǹkan ti yàtọ̀ pátápátá sí ti àtijọ́! Láwọn orílẹ̀-èdè kan, gbàrà tí wọ́n bá ti já ọmọ lẹ́nu ọmú ni wọ́n ti máa fi ọmọ náà sílé ìwé. Ọ̀pọ̀ òbí ló ń ṣiṣẹ́ níbi tó jìnnà sílé. Nígbà tí gbogbo wọn bá tiẹ̀ tún jàjà wà nílé, á tún di kóńkó jabele yálà nídìí tẹlifíṣọ̀n, fóònù tàbí kọ̀ǹpútà tàbí ẹ̀rọ ìgbàlódé míì. Nínú ọ̀pọ̀ ìdílé, àwọn òbí àtàwọn ọmọ ò fi bẹ́ẹ̀ ráyè máa bá ara wọn sọ̀rọ̀, ká má ṣẹ̀sẹ̀ wá sọ pé kí wọ́n mọwọ́ ara wọn.

5, 6. Kí làwọn òbí kan ti ṣe kí wọ́n lè máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn?

5 Ǹjẹ́ o lè ṣe àwọn àtúnṣe kan kó o lè túbọ̀ máa wà pẹ̀lú ìdílé rẹ? (Ka Éfésù 5:15, 16.) Ńṣe làwọn ìdílé kan dín àkókò tí wọ́n máa ń lò nídìí tẹlifíṣọ̀n tàbí kọ̀ǹpútà kù. Àwọn míì ṣètò pé kí ìdílé wọn máa jẹun pa pọ̀, ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn òbí kan máa ń lo àkókò ìjọsìn ìdílé láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ lo àkókò yẹn láti jíròrò àwọn ìlànà Ọlọ́run pa pọ̀. Èyí sì ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọwọ́ ara wọn dáadáa. Àmọ́, kì í ṣe irú àwọn àkókó bẹ́ẹ̀ nìkan ló yẹ kí ìdílé máa wà pa pọ̀. Á dára kí ìdílé máa wáyè láti bá ara wọn sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́. Lójúmọ́ kọ̀ọ̀kan, kó tó di pé àwọn ọmọ máa lọ síléèwé, ẹ jọ jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́, ẹ sọ̀rọ̀ ìṣírí fún wọn tàbí kẹ́ ẹ gbàdúrà pa pọ̀. Ó dájú pé èyí máa ran àwọn ọmọ yẹn lọ́wọ́ gan-an jálẹ̀ ọjọ́ yẹn!

6 Àwọn òbí kan ti ṣe àyípadà nígbèésí ayé wọn kí wọ́n lè túbọ̀ máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ńṣe ni Laura, * fi iṣẹ́ bóojí-o-jími tó ń ṣe sílẹ̀ kó lè máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. Ó sọ pé: “Ńṣe ló máa ń di bóò-lọ-o-yàá-mi nígbà tí gbogbo wa bá ń kánjú àtilọ síléèwé tàbí ibiṣẹ́ láàárọ̀. Ọmọ ọ̀dọ̀ ni mo gbà tó  ń bá mi tọ́jú àwọn ọmọ mi, nígbà tí mo bá sì fi máa délé lálẹ́, àwọn ọmọ náà á ti sùn.” Lẹ́yìn tí Laura fi iṣẹ́ rẹ̀ yìí sílẹ̀, owó ò fi bẹ́ẹ̀ wọlé bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ fún un, àmọ́ inú rẹ̀ dùn pé àwọn ọmọ òun ń rí òun láti sọ ohun tójú wọn ń rí níléèwé. Ó wá sọ pé: “Mo máa ń tẹ́tí sí bí wọ́n ṣe ń gbàdúrà, mo máa ń tọ́ wọn sọ́nà, mo máa ń fún wọn níṣìírí, mo sì máa ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.”

Ẹ “YÁRA NÍPA Ọ̀RỌ̀ GBÍGBỌ́”

7. Kí ló sábà máa ń fa ìṣòro láàárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ?

7 Àwọn tó kọ̀wé For Parents Only tún fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn ọmọdé nípa ohun tí kì í jẹ́ kí wọ́n fẹ́ láti máa bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀. Ohun táwọn ọmọ náà sọ ni pé “wọ́n kì í tẹ́tí sí wa.” Ohun kan náà làwọn òbí sọ nígbà tí wọ́n bi wọ́n léèrè ọ̀rọ̀. Wọ́n ní àwọn ọmọ kì í tẹ́tí sáwọn. Torí náà, tẹ́ ẹ bá fẹ́ jọ máa sọ̀rọ̀ dáadáa, ẹ rí i pé ẹ̀ ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ara yín.—Ka Jákọ́bù 1:19.

8. Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè fi hàn pé lóòótọ́ lẹ̀ ń tẹ́tí sí àwọn ọmọ yín?

8 Ẹ̀yin òbí, ṣe lóòótọ́ lẹ máa ń tẹ́tí sáwọn ọmọ yín? Ká sòótọ́, kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn, pàápàá tó bá ti rẹ̀ yín tẹnutẹnu tàbí tó dà bíi pé ọ̀rọ̀ ọ̀hún ò níláárí. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ fojú kéré yìí lè ṣe pàtàkì lọ́kàn ọmọ yín. Òbí kan tó ń “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́” kò kàn ní máa gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ọmọ rẹ̀ ń sọ nìkan, àmọ́ ó tún máa kíyè sí bó ṣe ń sọ̀rọ̀ náà. Ó máa kíyè sí ohùn rẹ̀, ìṣesí rẹ̀ àti ìrísí ojú rẹ̀. Èyí á jẹ́ kó mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀. Ó tún ṣe pàtàkì pé kí òbí máa béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ ọmọ. Bíbélì sọ pé, “Ìmọ̀ràn ní ọkàn-àyà ènìyàn dà bí omi jíjìn, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ni yóò fà á jáde.” (Òwe 20:5) Ẹ̀yin òbí, ẹ nílò ìjìnlẹ̀ òye àti ìfòyemọ̀ nígbà tẹ́ ẹ bá ń bá àwọn ọmọ yín sọ̀rọ̀, pàápàá tó bá kan àwọn ọ̀rọ̀ tó gbẹgẹ́.

9. Kí nìdí tó fi yẹ kí ẹ̀yin ọmọ máa tẹ́tí sáwọn òbí yín?

9 Ẹ̀yin ọmọ, ṣé ẹ máa ń tẹ́tí sáwọn òbí yín? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé, “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 1:8) Fi sọ́kàn pé àwọn òbí rẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, ire rẹ sì jẹ wọ́n lógún. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kó o máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. (Éfé. 6:1) Tíwọ àtàwọn òbí rẹ bá ń bá ara yín sọ̀rọ̀ dáadáa, tó o sì mọ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, á rọrùn fún ẹ láti máa ṣègbọràn sí wọn. Torí náà, jẹ́ káwọn òbí rẹ mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á túbọ̀ lóye rẹ. Àmọ́ o, máa rí i pé ìwọ náà ń sapá láti lóye wọn.

10. Kí la rí kọ́ lára Rèhóbóámù?

10 Ṣé kì í ṣe ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ lo máa ń tẹ̀ lé? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, yáa ṣọ́ra. Lóòótọ́, ìmọ̀ràn wọn lè dára lójú ẹ, àmọ́ ó lè má ṣe ẹ́ láǹfààní rárá. Ó tiẹ̀ lè kó ẹ́ sí ìṣòrò pàápàá. Máa rántí ọ̀rọ̀ Yorùbá tó sọ pé, bí ọmọdé bá láṣọ bí àgbà kó lè ní àkísà bí àgbà. Bákan náà, àwọn ọ̀dọ́ kì í sábà ronú nípa àkóbá tí ìpinnu tí wọ́n ń ṣe báyìí lè ṣe fún wọn lẹ́yìn ọ̀la. Máa rántí Rèhóbóámù, ọmọ Sólómọ́nì Ọba! Nígbà tó di ọba, kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn táwọn àgbàlagbà fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn tí kò mọ́gbọ́n dání táwọn tí wọ́n jọ ṣe ọmọdé fún un ló tẹ̀ lé. Ìyẹn ló fà á táwọn èèyàn fi dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀. (1 Ọba 12:1-17) Má ṣe fìwà jọ Rèhóbóámù o! Máa bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀, jẹ́ kí wọ́n mọ bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára rẹ. Máa fi ìmọ̀ràn wọn sílò. Kó o sì máa rántí pé wọ́n gbọ́n jù ẹ́ lọ dáadáa.—Òwe 13:20.

11. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ táwọn òbí kì í bá fara balẹ̀ tẹ́tí sí àwọn ọmọ?

11 Ẹ̀yin òbí, ṣé ẹ fẹ́ káwọn ọmọ yín máa gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ yín dípò àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn? Tẹ́ ẹ bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ yáa jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti máa bá yín sọ̀rọ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan  sọ pé ńṣe làwọn òbí òun máa ń gbaná jẹ nígbàkigbà tóun bá ti dẹ́nu lé ọ̀rọ̀ ọkùnrin. Ó ní bí wọ́n ṣe máa ń ṣe yìí máa ń bí òun nínú, torí náà ńṣe ni òun máa ń dákẹ́. Ọ̀dọ́bìnrin míì sọ pé, “Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa ń fẹ́ káwọn òbí wọn fún wọn nímọ̀ràn, àmọ́ tí wọn ò bá wá ka ọ̀rọ̀ wọn sí, ńṣe làwọn ọmọ máa lọ sọ́dọ̀ ẹlòmíì tí wọ́n gbà pé ó lè ran àwọn lọ́wọ́, títí kan àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí.” Torí náà ẹ̀yin òbí, ẹ jẹ́ kó mọ́ yín lára láti máa fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ sì mọ bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára wọn, tò bá tiẹ̀ dà bíi pé ọ̀rọ̀ náà kò tó nǹkan. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún wọn láti máa sọ tinú wọn, wọ́n á sì máa fi ìmọ̀ràn yín sílò.

Ẹ “LỌ́RA NÍPA Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ”

12. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé ńṣe lẹ̀yin òbí máa ń bínú nígbà táwọn ọmọ yín bá fọ̀rọ̀ lọ̀ yín?

12 Ohun tí ẹ̀yin òbí bá sọ tàbí tẹ́ ẹ bá ṣe nígbà táwọn ọmọ yín bá ń sọ tinú wọn lè mú kó ṣòro fún wọn láti máa bá yín sọ̀rọ̀. Ká sòótọ́, ohun tọ́mọ yín sọ lè múnú bí yín nígbà míì. Ọ̀pọ̀ ewu ló sì wà nínú ayé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ẹ ò sì fẹ́ káwọn ọmọ yín kó sínú ewu. (2 Tím. 3:1-5) Àmọ́, àwọn ọmọ yín lè má gbà pé ṣe lẹ̀ ń dáàbò bo àwọn, wọ́n lè máa ronú pé ńṣe lẹ ò fẹ́ káwọn ní òmìnira.

13. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí ẹ̀yin òbí máa yára fèsì ọ̀rọ̀ táwọn ọmọ yín bá sọ?

13 Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ̀yin òbí ṣọ́ra kẹ́ ẹ tó máa fèsì ọ̀rọ̀ táwọn ọmọ yín bá sọ. Ká sòótọ́, kì í rọrùn láti ní sùúrù táwọn ọmọ yín bá sọ ohun tó múnú bí yín. Àmọ́, á dára tẹ́ ẹ bá lè fara balẹ̀ dáadáa kẹ́ ẹ tó fèsì. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.” (Òwe 18:13) Tẹ́ ẹ bá fara balẹ̀, tẹ́ ò já lu ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n á lè sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wọn. Ó dìgbà tẹ́ ẹ bá rídìí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ dáadáa kẹ́ ẹ tó mọ ohun tẹ́ ẹ lè ṣe. Ó lè wá ṣe kedere sí yín pé ẹ̀dùn ọkàn tí àwọn ọmọ yín ní ló fà á tí ọ̀rọ̀ wọn fi dà bí “ọ̀rọ̀ ẹhànnà.” (Jóòbù 6:1-3) Ẹ jẹ́ káwọn ọmọ yín mọ̀ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ wọn, torí náà, ẹ máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, kẹ́ ẹ sì máa fọ̀rọ̀ ẹnú yín gbé wọn ró.

14. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí ẹ̀yin ọmọ máa yára fèsì?

14 Ẹ̀yin ọmọ, ó yẹ kí ẹ̀yin náà máa fara balẹ̀ kẹ́ ẹ tó sọ̀rọ̀. Ẹ má ṣe máa gbó àwọn òbí yín lẹ́nu, ẹ máa rántí pé àwọn òbí yín ni Ọlọ́run yàn pé kó tọ́ yín. (Òwe 22:6) Ẹ má gbàgbé pé àwọn náà ti ṣe ọmọdé rí. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n kábàámọ̀ àwọn àṣìṣe tí wọ́n ṣe nígbà yẹn, wọn ò sì fẹ́ kí ẹ̀yin náà jìn sírú ọ̀fìn bẹ́ẹ̀. Ẹ má ṣe mú àwọn òbí yín lọ́tàá, ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé ńṣe ni wọ́n fẹ́ kó dáa fún yín. (Ka Òwe 1:5.) Máa “bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ,” kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ nìwọ náà nífẹ̀ẹ́ wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ó máa rọrùn fún wọn láti máa tọ́ ẹ lọ́nà tí Jèhófà fẹ́.—Éfé. 6:2, 4.

Ẹ MÁ ṢE TÈTÈ MÁA BÍNÚ

15. Kí ló lè mú ká máa ní sùúrù fáwọn tá a nífẹ̀ẹ́, tá ò sì ní tètè máa bínú sí wọn?

15 A kì í fi bẹ́ẹ̀ mú sùúrù fún àwọn tá a bá fẹ́ràn, ó ṣe tán, ẹni téèyàn bá sùn tì ló máa ń jarunpá lù. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè, ó sọ pé, “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò. Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.” (Kól. 1:1, 2; 3:19, 21) Ó tún gba àwọn ará tó wà ní Éfésù nímọ̀ràn pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Éfé. 4:31) Ẹ jẹ́ ká sapá láti túbọ̀ máa fi àwọn ànímọ́ bí ìpamọ́ra, ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu, tó jẹ́ ara èso tẹ̀mí sílò. Tá a bá ń ṣe  bẹ́ẹ̀, a ò ní tètè máa bínú nígbà táwọn èèyàn bá ṣe ohun tó lè mú wa bínú.—Gál. 5:22, 23.

16. Báwo ni Jésù ṣe tọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́nà? Kí nìdí tí ohun tó ṣe yìí fi jọni lójú gan-an?

16 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jésù ná. Wo bí ẹ̀dùn ọkàn tí Jésù ní lálẹ́ ọjọ́ tó jẹun kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe pọ̀ tó. Ó mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ kú ikú oró. Ó mọ̀ pé òun ní láti jẹ́ olóòótọ́ kí òun bàa lè sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ àti pé kí aráyé lè rí ìgbàlà. Síbẹ̀, nídìí oúnjẹ tí wọ́n wà, ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé àwọn àpọ́sítélì yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe awuyewuye gbígbónájanjan lórí èwo nínú wọn ló tóbi jù lọ. Àmọ́, Jésù kò jágbe mọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò bínú sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi pẹ̀lẹ́tù tún ojú ìwòye wọn ṣe. Ó rán wọn létí pé àwọn ló ti wà pẹ̀lú òun lọ́jọ́ dídùn àti lọ́jọ́ kíkan. Ó wá sọ fún wọn pé òun mọ̀ pé wọ́n máa jẹ́ olóòótọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Èṣù máa pọ́n wọn lójú. Kódà, ó tún ṣèlérí fún wọn pé wọ́n máa bá òun jọba ní ọ̀run.—Lúùkù 22:24-32.

Ṣé o máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí àwọn ọmọ rẹ?

17. Kí ló lè mú kí ẹ̀yin ọmọ máa ṣe pẹ̀lẹ́?

17 Ó yẹ kí ẹ̀yin ọmọ náà máa ṣe pẹ̀lẹ́. Lóòótọ́, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé òfin àwọn òbí ẹ ti pọ̀ jù, pàápàá ní báyìí tó o ronú pé ìwọ náà kì í ṣe ọmọdé mọ́. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé wọn ò fọkàn tán ẹ. Àmọ́, máa rántí pé àwọn òbí rẹ fẹ́ràn ẹ gan-an, ìyẹn ló fà á tí wọ́n fi ń ṣe àníyàn nípa rẹ. Torí náà, tó o bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, tó o sì ń fi ìtọ́ni wọn sílò, wọ́n á máa fọ̀wọ̀ tiẹ̀ náà wọ̀ ẹ́, wọ́n á sì fọkàn tán ẹ. Wọ́n lè wá fún ẹ ní òmìnira láti ṣe àwọn ìpinnu kan. Bíbélì pe ẹni tó bá ń ṣe pẹ̀lẹ́ tàbí tó bá ń fara balẹ̀ ní ọlọ́gbọ́n. Ó sọ pé: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.”—Òwe 29:11.

18. Tí àwọn tó wà nínú ìdílé bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn, báwo ló ṣe lè mú kí wọ́n túbọ̀ máa bá ara wọn sọ̀rọ̀?

18 Torí náà, ẹ̀yin òbí àtẹ̀yin ọmọ wa ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe rẹ̀wẹ̀sì tó bá jẹ́ pé ẹ kì í fi bẹ́ẹ̀ jùmọ̀ sọ̀rọ̀ bẹ́ ẹ ṣe fẹ́ nínú ìdílé yín. Ẹ máa ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe, kẹ́ ẹ sì máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. (3 Jòh. 4) Nínú ayé tuntun, ẹni pípé ni gbogbo wa máa jẹ́, àá lè máa bá ara wa sọ̀rọ̀ fàlàlà, a ó sì máa lóye ara wa dáadáa. Àmọ́, ní báyìí ná, a ṣì máa ń ṣàṣìṣe. Torí náà, má ṣe jẹ́ kó ni ẹ́ lára láti máa tọrọ àforíjì. Bákàn náà, máa dárí ji ẹni tó bá ṣẹ̀ ẹ́. Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ so yín pọ̀, kẹ́ ẹ sì wà níṣọ̀kan. (Kól. 2:2) Ẹ má gbàgbé, ìfẹ́ lágbára gan-an. Ó máa ń jẹ́ kéèyàn ní sùúrù, kéèyàn sì jẹ́ onínúure. Ìfẹ́ máa ń mú kéèyàn ṣe pẹ̀lẹ́, kéèyàn sì máa dárí jini. Ìfẹ́ “máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo.” (1 Kọ́r. 13:4-7) Tẹ́ ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín, ẹ ó lè máa bá ara yín sọ̀rọ̀ fàlàlà nínú ìdílé, ẹ ó sì túbọ̀ máa gbọ́ ara yín yé. Á mú kí ilé yín tòrò, ẹ ó sì máa mú inú Jèhófà dùn.

^ ìpínrọ̀ 6 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.