A sọ fún ọ̀rẹ́ wa kan tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún pé: “Ó rọrùn fún ẹ láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àwọn òbí rẹ wà nínú òtítọ́, wọ́n á sì máa tì ẹ́ lẹ́yìn.” Àmọ́, ó sọ fún wa pé: “Bàbá kan náà ni gbogbo wa ní.” Ohun tó sọ yìí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan pé, Baba wa ọ̀run ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ó sì ń fún wọn lókun. Ohun tí Jèhófà ti gbé ṣe nínú ìgbésí ayé wa ti jẹ́ ká rí i pé bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn.

 ỌMỌ mẹ́wàá làwọn òbí wa bí. A sì ń gbé ní oko wa tó wà ní Àríwá Ostrobothnia, lórílẹ̀-èdè Finland. A ṣì kéré nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tá à ń gbé jìnnà sí àwọn apá ibi tí ogun ti le gan-an, a mọ̀ pé ìyà ń jẹ àwọn èèyàn gan-an. Lálẹ́ ọjọ́ kan, wọ́n ju bọ́ǹbù sí abúlé Oulu àti Kalajoki, ìbúgbàù náà sì mú kí ojú ọ̀run pupa fòò. Àwọn òbí wa ti sọ fún wa pé ká máa sá pa mọ́ tá a bá ti rí ọkọ̀ òfuurufú àwọn ológun lójú sánmà. Torí náà, nígbà tí Tauno, ẹ̀gbọ́n wa ọkùnrin, sọ fún wa nípa párádísè ilẹ̀ ayé níbi tí ẹnikẹ́ni ò ti ní máa jìyà, a fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀.

Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni Tauno nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ohun tó sì mú kó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ ni pé ó máa ń ka àwọn ìwé tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ̀ jáde. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, kò gbà láti wọṣẹ́ ológun torí ohun tó ti kọ́ nínú Bíbélì. Torí náà, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n, wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́. Àmọ́, ńṣe ni ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí wá fún un lókun, ó sì túbọ̀ fẹ́ láti sin Jèhófà. Torí náà, lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó túbọ̀ fi kún akitiyan rẹ̀ lóde ẹ̀rí. Àpẹẹrẹ rere tí ẹ̀gbọ́n wa yìí fi lélẹ̀ nígbà àdánwò wọ̀ wá lọ́kàn gan-an, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní abúlé kan tó wà nítòsí wa. A tún máa ń ṣiṣẹ́ kára ká lè rí owó tá a máa fi wọ mọ́tò lọ sí àwọn àpéjọ. A máa ń bá àwọn aládùúgbò wa ránṣọ, a máa ń gbin àlùbọ́sà, a sì tún máa ń ṣa èso. Torí pé a ní iṣẹ́ tó pọ̀ láti ṣe nínú oko, gbogbo wa kì í lè lọ sí àpéjọ nígbà kan náà.

Láti apá òsì: Matti (bàbá), Tauno, Saimi, Maria Emilia (màmá), Väinö (ọmọ), Aili àti Annikki lọ́dún 1935

Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó ti pinnu láti ṣe, èyí mú ká túbọ̀ fẹ́ràn rẹ̀, àwa méjèèjì sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1947. Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni Annikki nígbà yẹn, Aili sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún. Ọdún yẹn náà ni Saimi, ẹ̀gbọ́n wa obìnrin ṣèrìbọmi. A sì tún bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Linnea, ẹ̀gbọ́n wa obìnrin tó ti ṣègbéyàwó. Òun àti ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn tá a ti ṣèrìbọmi, a pinnu pé a ó máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ látìgbàdégbà.

A BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ÌSÌN ALÁKÒÓKÒ KÍKÚN

Láti apá òsì: Eeva Kallio, Saimi Mattila-Syrjälä, Aili, Annikki àti Saara Noponen lọ́dún 1949

Lọ́dún 1955, a kó lọ sí ìlú kan tó ń jẹ́ Kemi, èyí tó wà ní àríwá orílẹ̀-èdè náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa méjèèjì ń ṣiṣẹ́ nígbà yẹn, síbẹ̀ a fẹ́ láti di aṣáájú-ọ̀nà. Ṣùgbọ́n, ẹ̀rù ń bà wá pé tá a bá dín iṣẹ́ tá à ń ṣe kù, a ò ní lówó tó pọ̀ tó láti máa gbọ́ bùkátà ara wa. Torí náà, a ronú pé ó yẹ ká kọ́kọ́ tọ́jú owó pa mọ́ ká tó bẹ̀rẹ̀. Ìgbà yẹn ni arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká rí i pé a lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. A wá rí i pé dípò tí a ó fi gbẹ́kẹ̀ lé ara wa tàbí ìdílé wa, ńṣe ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Baba wa ọ̀run pé ó máa fún wa ní ohun tá a bá nílò.

Nígbà tí à ń lọ sí àpéjọ àgbègbè ní ìlú Kuopio lọ́dún 1952. Láti apá òsì: Annikki, Aili, Eeva Kallio

Nígbà yẹn, a ti ní owó tá a lè fi gbọ́ bùkátà ara wa fún oṣù méjì. Torí náà, ní oṣù May, ọdún 1957, a yọ̀ǹda ara wa láti ṣíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún oṣù méjì ní àdúgbò kan tó wà ní ẹkùn ilẹ̀ Lapland, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ń bà wá. Lẹ́yìn tí oṣù méjì náà pé, kọ́bọ̀ ò tíì dín nínú owó tá a fi pa mọ́, torí náà, a tún yọ̀ǹda  ara wa fún oṣù méjì sí i. Lẹ́yìn tí oṣù méjì yẹn pé, owó tá a fi pa mọ́ ṣì wà lọ́wọ́ wa. Ìgbà yẹn ló wá ṣe kedere sí wa pé Jèhófà máa bójú tó wa lóòótọ́. Lẹ́yìn àádọ́ta ọdún tá a ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, iye owó tá a fi pa mọ́ ṣì wà lọ́wọ́ wa! Ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà fà wá lọ́wọ́, tó sì ń sọ fún wa pé: “Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.”—Aísá. 41:13.

Lẹ́yìn àádọ́ta ọdún tá a ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, iye owó tá a fi pa mọ́ ṣì wà lọ́wọ́ wa!

Kaisu Reikko àti Aili rèé lóde ẹ̀rí

Lọ́dún 1958, alábòójútó àyíká béèrè lọ́wọ́ wa bóyá a fẹ́ láti lọ máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ìlú Sodankylä, ní ẹkùn ilẹ̀ Lapland. A sì gbà láti lọ síbẹ̀. Nígbà yẹn, arábìnrin kan ṣoṣo ló wà níbẹ̀. Ọ̀nà tó gbà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ fani mọ́ra gan-an ni. Ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọléèwé rẹ̀ lọ ṣèbẹ̀wò sí ìlú Helsinki tó jẹ́ olú ìlú Finland. Nígbà tí wọ́n ń kọjá lọ láàárín ìlú náà, arábìnrin àgbàlagbà kan fún ọmọdékùnrin náà ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, ó sì sọ fún un pé kó fún màmá rẹ̀. Nígbà tí màmá rẹ̀ kà á, ó mọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì ló wà nínú ìwé náà.

Nígbà tá a débẹ̀, a rẹ́ǹtì yàrá kan tó wà lókè ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti máa ń la pákó. Inú yàrá yẹn la ti ń ṣe ìpàdé. Ní ìbẹ̀rẹ̀, àwa mẹ́rin péré la máa ń ṣèpàdé, ìyẹn àwa méjèèjì, arábìnrin tá a bá níbẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀. Báwo la ṣe máa ń ṣèpàdé? A jọ máa ń ka àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìpàdé tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nígbà tó ṣe, ọkùnrin kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń la pákó náà. Òun àti ìdílé rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bá wa ṣèpàdé. Nígbà tó yá, òun àti ìyàwó rẹ̀ ṣèrìbọmi. Bó ṣe di pé a ní arákùnrin tó ń dárí àwọn ìpàdé wa nìyẹn o. Nígbà tó yá, àwọn ọkùnrin míì tún bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé wa láti ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń la pákó yẹn, àwọn náà sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, àwùjọ kékeré yẹn wá di ìjọ kan.

ÀWỌN ÌṢÒRO TÁ A BÁ PÀDÉ

Àwọn ibi tá a ti máa ń lọ wàásù jìnnà gan-an. Ká tó lè dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, a máa ń rìn, a máa ń gun kẹ̀kẹ́, a sì tún máa ń wọ ọkọ̀ ojú omi. Kẹ̀kẹ́ tá a ní ló tún mú kí nǹkan rọrùn gan-an fún wa. Kẹ̀kẹ́ la máa ń gùn lọ sí àwọn àpéjọ, a sì tún máa ń gùn ún lọ sí ilé àwọn òbí wa tó fi ọ̀pọ̀ kìlómítà jìnnà sí ibi tá à ń gbé. Nígbà òtútù, a máa ń jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, a máa ń wọ bọ́ọ̀sì lọ sí ọ̀kan lára àwọn abúlé tó wà ní àgbègbè náà, a ó sì máa wàásù láti ilé dé ilé. Tá a bá ti kárí gbogbo ilé tó wà ní abúlé kan, a ó kọjá lọ sí abúlé míì. Ìgbà míì wà tí ìrì dídì tó wà lójú ọ̀nà máa ń pọ̀ gan-an. Ká ní ẹnì kan ti gba ojú ọ̀nà náà kọjá ká tó débẹ̀,  ì bá rọrùn láti tọ ipasẹ̀ onítọ̀hún. Àmọ́ bí ìrí dídì bá ti sẹ̀ lẹ́yìn tó kọjá, ojú ipasẹ̀ rẹ̀ á ti dí. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé, ìrì dídì náà kì í le gbagidi, ńṣe ló máa ń rọ̀, torí náà, ẹsẹ̀ la máa ń fi wọ́ ọ, èyí kò sì rọrùn rárá.

A wà lóde ẹ̀rí nígbà òtútù

A sábà máa ń wọ àwọn aṣọ òtútù táá jẹ́ kí ara wa móoru nígbà òtútù àti nígbà tí ìrí dídì bá ń sẹ̀. Ìbọ̀sẹ̀ tá a máa ń wọ̀ máa ń tó méjì sí mẹ́ta, èyí tó máa ń bo ẹsẹ̀ wa dé orúnkún. A sì tún máa ń wọ bàtá tó gùn dé orúnkún. Síbẹ̀, ńṣe ni yìnyín máa ń kún inú bàtà náà. Tá a bá fẹ́ gun ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, á máa bọ́ bàtà wa, a ó sì gbọn ìrí dídì tó wà nínú wọn dà nù. Bákan náà, apá ìsàlẹ̀ aṣọ agbòtútù wa máa ń tutù rinrin torí pé ó máa ń kan ìrí dídì tá a bá ń rìn, á sì le gbagidi. Lẹ́yìn tá a rin ìrìn kìlómítà mọ́kànlá dé ilé kan, ìyàwó ilé náà sọ fún wa pé: “Ìgbàgbọ́ yín mà lágbára o, tẹ́ ẹ fi lè jáde wá bá wa nínú òtútù yìí.”

Torí ọ̀nà tó jìn síra, a sábà máa ń sùn mọ́jú lọ́dọ̀ àwọn ará abúlé tá a bá ti lọ wàásù. Tó bá ti di ìrọ̀lẹ́, a ó bẹ̀rẹ̀ sí í bí àwọn èèyàn bóyá wọ́n lè jẹ́ ká sun ilé wọn mọ́jú. Àwọn ilé náà kì í ṣe ilé aláruru o, àmọ́ ara àwọn èèyàn náà yá mọ́ni, onínúure sì ni wọ́n. Wọ́n máa ń fún wa ní ibi tá a máa sùn, wọ́n sì tún máa ń fún wa lóúnjẹ. Lọ́pọ̀ ìgbà, orí awọ ẹran la máa ń sùn. Àmọ́, àwọn kan ní yàrá àlejò tí wọ́n máa ń fi wá wọ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó ń gbé nínú ilé ńlá kan mú wa lọ sí òkè ilé rẹ̀. Ó fi yàrá kan hàn wá, bẹ́ẹ̀dì tó dára tí wọ́n tẹ́ aṣọ funfun nigínnigín sí ló sì wà níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń jíròrò Bíbélì pẹ̀lú ìdílé yìí títí di ààjìn òru. Nígbà tá a dé ilé kan, tọkọtaya tó ń gbé níbẹ̀ sùn sí apá kan nínú yàrá náà, àwa sì sùn sí apá kejì. Ńṣe ni ọkùnrin náà àti ìyàwó rẹ̀ ń da ìbéèrè bò wá, a sì jíròrò Bíbélì pẹ̀lú wọn títí di òru.

IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ WA Ń SÈSO RERE

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣálẹ̀ ni ilẹ̀ Lapland, ìlú tó rẹwà gan-an ni. Oríṣiríṣi ẹwà ló sì máa ń gbé yọ jálẹ̀ ọdún. Àmọ́, àwọn tó fetí sí ìhìnrere náà tí wọ́n sì fẹ́ láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ ló rẹwà jù lójú tiwa. Lára àwọn tó lọ́kàn rere tá a wàásù fún ni àwọn agégẹdú tí wọ́n wá gé igi nínú oko ní ilẹ̀ Lapland. Nígbà míì, táwa méjèèjì bá wọnú ilé kékeré kan, ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tó tóbi fàkìàfakia la máa bá níbẹ̀. Inú wọn máa ń dùn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì, wọ́n sì tún máa ń ka àwọn ìwé wa.

A ní ọ̀pọ̀ ìrírí tó lárinrin. Lọ́jọ́ kan, aago tó wà ní pápákọ̀ òfuurufú fi ìṣẹ́jú márùn-ún yára, torí náà ọkọ̀ já wa sílẹ̀. A wá pinnu láti wọ ọkọ̀ míì ká sì gba abúlé míì lọ. A kò tíì wàásù dé abúlé yẹn rí, àmọ́ nígbà tá a dé ilé àkọ́kọ́, a rí ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó sọ pé, “Ẹ ti dé, mo ti ń retí yín.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, a ti ń kọ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ti sọ fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé kó sọ fún wa pé ká wá sọ́dọ̀ òun lọ́jọ́ yẹn. Àmọ́, kò sẹ́ni tó jíṣẹ́ rẹ̀ fún wa. A wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ òun àti àwọn ìbátan rẹ̀ tí wọ́n ń gbé nítòsí ibẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ tá a fi pa ìkẹ́kọ̀ọ́ náà  pọ̀, àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ wá jẹ́ méjìlá. Láti ìgbà yẹn wá, ọ̀pọ̀ èèyàn látinú ìdílé náà ló ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Lọ́dún 1965, wọ́n ní ká lọ sí apá gúúsù ìlú náà, ká lè lọ sìn ní ìjọ tó wà ní Kuusamo. Nígbà yẹn, àwọn akéde díẹ̀ ló wà ní ìjọ náà. Ó kọ́kọ́ ṣòro láti ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ náà. Ọwọ́ pàtàkì ni wọ́n fi mú ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe, wọn kò sì fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù wa. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn wà níbẹ̀ tí wọ́n ní ọ̀wọ̀ fún Bíbélì. Torí náà, à ń sún mọ́ àwọn èèyàn náà díẹ̀díẹ̀ ká lè mọ̀ wọ́n dáadáa. Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún méjì, ó túbọ̀ rọrùn fún wa láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

A ṢÌ Ń FÌTARA ṢE IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ NÁÀ

Ara àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rèé

Ní báyìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ la ṣì ń lọ sóde ẹ̀rí, àmọ́ a ò lè ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Ìpínlẹ̀ ìwàásù wa fẹ̀ gan-an ni, ó sì ti wá rọrùn fún wa láti máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀ báyìí torí pé Aili ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń wakọ̀. Ọmọ ẹ̀gbọ́n wa ọkùnrin ló ní kó lọ kọ́ bí wọ́n ṣe ń wakọ̀, ó sì gba ìwé àṣẹ ọkọ̀ wíwà lọ́dún 1987, nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56]. Ní báyìí, inú ilé kan tí wọ́n kọ́ mọ́ ara Gbọ̀ngàn Ìjọba wa là ń gbé, èyí sì túbọ̀ mú kí nǹkan rọrùn fún wa.

Inú wa dùn pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àríwá orílẹ̀-èdè Finland báyìí. Nígbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà níbí, àwọn akéde díẹ̀ la bá. Àmọ́, ní báyìí, àwọn ìjọ tó wà níbí ti pọ̀ débi pé wọ́n ti di àyíká kan. Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá lọ sí àpéjọ àkànṣe, àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àgbègbè, a sábà máa ń rí ẹni táá sọ fún wa pé àwa là ń kọ́ ìdílé òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tóun ṣì wà lọ́mọdé. Ó dájú pé Ọlọ́run ti fìbùkún sí iṣẹ́ wa.—1 Kọ́r. 3:6.

A máa ń gbádùn òde ẹ̀rí kódà lọ́jọ́ tí òjò bá ń rọ̀

Lọ́dún 2008, ó pé àádọ́ta ọdún géérégé tá a ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó mú káwa méjèèjì lè máa fún ara wa níṣìírí ká sì máa sìn ín nìṣó. A ò ní àwọn nǹkan ńláńlá o, àmọ́ kò sígbà tí Jèhófà kò fún wa ní òun tá a nílò. (Sm. 23:1) Ó ti wá ṣe kedere sí wa báyìí pé kò yẹ ká bẹ̀rù rárá nígbà tá a fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Jálẹ̀ gbogbo ọdún tá a fi ṣe iṣẹ́ náà, Jèhófà ti fún wa lókun, gẹ́gẹ́ bó ti ṣèlérí pé: “Èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.”—Aísá. 41:10.