Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  March 2013

‘Kò Sí Ohun Ìkọ̀sẹ̀’ fún Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà

‘Kò Sí Ohun Ìkọ̀sẹ̀’ fún Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà

“Ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ, kò sì sí ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.”—SM. 119:165.

1. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí sárésáré kan? Kí ló fi hàn pé kò rẹ̀wẹ̀sì?

OBÌNRIN kan wà tó ń jẹ́ Mary Decker. Kò tíì pé ọmọ ogún ọdún tó ti di sárésáré tó lókìkí kárí ayé. Nígbà tó fi máa di ọdún 1984, ó ti mọ eré sá débi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ti rò pé òun ló máa gba àmì ẹ̀yẹ góòlù nínú ìdíje Òlíńpíìkì tó wáyé lọ́dún náà. Àmọ́, ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ sí i. Bí wọ́n ṣe ń sáré lọ, ó fẹsẹ̀ kọ́ ẹni tí wọ́n jọ ń sáré, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì fara pa. Ńṣe ló bú sẹ́kún gbẹrẹgẹdẹ, wọ́n sì gbé e kúrò lórí pápá ìṣeré. Bí kò ṣe lè parí eré ìje náà nìyẹn o! Àmọ́, Mary kò jẹ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun. Kò tó ọdún kan lẹ́yìn náà tó tún kópa nínú ìdíje eré ibùsọ̀ àsáyípo kan. Ó sì fakọyọ ní ti pé kò sí obìnrin tó tíì yára sá eré àsáyípo bíi tiẹ̀ rí.

2. Irú eré wo ni àwa Kristẹni ń sá? Báwo ló ṣe yẹ ká máa sá eré náà?

2 Ńṣe ni ọ̀rọ̀ àwa Kristẹni náà dà bíi ti àwọn sárésáré. Àmọ́, ńṣe là ń sá eré tiwa ká bàa lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ láti máa sá eré náà nìṣó. Eré tá à ń sá ò dà bíi ti àwọn sárésáré tó máa ń sá eré àsápajúdé láàárín àkókò kúkúrú kí wọ́n bàa lè borí. Bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe sísáré kúṣẹ́kúṣẹ́, èyí tó lè gba pé kéèyàn dúró nígbà míì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló dà bí eré ìje ẹlẹ́mìí ẹṣin. Irú eré ìje yìí gba pé kéèyàn ní ìfaradà kó bàa lè sá eré náà dé òpin. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé gbogbo àwọn sárésáré nínú eré ìje ní ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnì kan ṣoṣo ní ń gba ẹ̀bùn náà? Ẹ sáré ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀ kí ọwọ́ yín lè tẹ̀ ẹ́.”—1 Kọ́r. 9:24.

3. Àwọn wo ló lè rí ẹ̀bùn eré ìje ìyè àìnípẹ̀kun gbà?

3 Bíbélì sọ fún wa pé kí àwa náà kópa nínú eré ìje yìí. (Ka 1 Kọ́ríńtì 9:25-27.) Tá a bá kópa nínú eré ìje yìí, a ó gba ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. Eré ìje yìí yàtọ̀  pátápátá sí àwọn eré ìje mìíràn. Ìdí tó sì fi yàtọ̀ ni pé gbogbo àwọn tó bá sá eré náà dópin ló máa gba ẹ̀bùn, ìyẹn tí wọ́n bá fara dà á títí dé òpin. (Mát. 24:13) Àmọ́ téèyàn ò bá tẹ̀ lé ìlànà tó wà fún àwọn sárésáré tàbí tó dúró kí eré ìje náà tó parí, kò ní rí ẹ̀bùn gbà. Eré ìje yìí nìkan ló sì lè mú kéèyàn jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.

4. Kí nìdí tí kò fi rọrùn láti sa eré ìje ìyè àìnípẹ̀kun?

4 Kò rọrùn láti sa eré ìje ìyè dópin. Ó gba pé ká ṣọ́ra gan-an ká sì mọ ohun tá à ń ṣe. Ẹnì kan ṣoṣo ló tíì sá eré ìje náà parí láìkọsẹ̀ rárá. Jésù Kristi sì ni ẹni náà. Àmọ́, Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi “máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Ják. 3:2) Òótọ́ pọ́ńbélé nìyẹn! Ìdí sì ni pé aláìpé ni àwa àti gbogbo àwọn tá a jọ ń sá eré ìje náà. Látàrí èyí, àìpé wa tàbí àìpé àwọn míì lè mú ká kọsẹ̀, lẹ́yìn náà a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ségesège, tàbí ká tiẹ̀ ṣubú pàápàá. Àmọ́ tá a bá ṣubú, a ṣì lè dìde pa dà, ká sì máa bá eré ìje náà nìṣó. Bí èyí bá ṣẹlẹ̀ sí wa, ó lè gba pé kí ẹnì kan ràn wá lọ́wọ́ ká tó lè máa sá eré ìje náà nìṣó. Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kó yà wá lẹ́nu pé a lè kọsẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tàbí léraléra.—1 Ọba 8:46.

Tó o bá ṣubú, gba ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n bá fún ẹ kó o sì dìde!

BÓ O BÁ TIẸ̀ KỌSẸ̀, MÁA SÁ ERÉ ÌJE NÁÀ NÌṢÓ

5, 6. (a) Kí ló túmọ̀ sí pé kò sí “ohun ìkọ̀sẹ̀” kankan fún àwa Kristẹni? Kí ló máa mú kí Kristẹni kan lè “dìde” tó bá kọsẹ̀? (b) Kí nìdí tí àwọn kàn kì í fi í “dìde” tí wọ́n bá ṣubú?

5 Nígbà tí ẹnì kan bá fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, àwọn kan lè sọ pé ńṣe ni onítọ̀hún “kọsẹ̀” tàbí pé ó “ṣubú.” Òótọ́ ni pé àwọn ọ̀rọ̀ yẹn lè túmọ̀ sí ohun kan náà, ṣùgbọ́n kì í rí bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Bí àpẹẹrẹ, gbọ́ ohun tí Òwe 24:16 sọ. Ó ní: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú; ṣùgbọ́n àwọn ẹni burúkú ni a óò mú kọsẹ̀ nípasẹ̀ ìyọnu àjálù.”

6 Ká tiẹ̀ sọ pé a kọsẹ̀ tàbí a ṣubú, a ṣì dìde. Bí a ò bá ṣáà ti dẹ́kun láti máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, òun náà ò ní dá wa dá àwọn ìṣòro wa, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ṣe àṣìṣe. Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè “dìde,” torí ó mọ̀ pé a fẹ́ràn òun. Ọ̀rọ̀ ìtùnú  lèyí jẹ́ fún gbogbo àwa tá a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkàn wá. Àmọ́, àwọn ẹni burúkú kì í fẹ́ láti “dìde.” Ìdí sì ni pé wọn kì í gba ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run àti ìrànlọ́wọ́ àwọn èèyàn rẹ̀. Àmọ́, Bíbélì sọ pé “kò sí ohun ìkọ̀sẹ̀” kankan fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òfin Jèhófà. Èyí tó túmọ̀ sí pé kò sí ohun ìkọ̀sẹ̀ èyíkéyìí tó lè mú kí àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ òfin Jèhófà dẹ́kun sísá eré ìje ìyè náà dópin.—Ka Sáàmù 119:165.

7, 8. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè “ṣubú,” síbẹ̀ kó ṣì rí ojú rere Ọlọ́run?

7 Nígbà míì, àìpé ẹ̀dá lè mú kí ẹnì kan máa dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké kan léraléra. Síbẹ̀, Jèhófà ṣì máa ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí olódodo tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà tó ń ṣubú ló ń dìde. Tàbí lédè mìíràn, tó bá jẹ́ pé ó ń ronú pìwà dà látọkàn wá tó sì ń ṣiṣẹ́ kára láti ṣe ohun tó tọ́. Gbogbo ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣẹ̀ tí wọ́n sì ronú pìwà dà ni Ọlọ́run máa ń pa dà kà wọ́n sí olódodo. (Aísá. 41:9, 10) Ìwé Òwe 24:16 tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ní ìpínrọ̀ karùn-ún kò tẹnu mọ́ àwọn àṣìṣe wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi hàn pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè “dìde.” (Ka Aísáyà 55:7.) Ó dá Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi lójú pé a máa sa gbogbo ipá wa láti ṣe ohun tó tọ́, ìyẹn ni wọ́n ṣe ń gbà wá níyànjú pé tá a bá ṣubú, ká “dìde.”—Sm. 86:5; Jòh. 5:19.

8 Bí sárésáré kan bá tiẹ̀ kọsẹ̀ tàbí tó ṣubú, ó ṣì lè yára dìde kó sì sá eré ìje náà dópin. Ṣùgbọ́n, a kò mọ “ọjọ́ àti wákàtí” tí eré ìje ìyè àìnípẹ̀kun tá à ń sá máa dópin. (Mát. 24:36) Ṣùgbọ́n tá a bá ń sá fún ohunkóhun tó lè mú ká kọsẹ̀, ó máa túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa sá eré ìje náà nìṣó, a ó sì sá a dópin. Kí la lè ṣe tá ò fi ní kọsẹ̀?

ÀWỌN NǸKAN TÓ LÈ MÚ KÁ KỌSẸ̀

9. Àwọn nǹkan márùn-ún wo la máa jíròrò?

9 A máa jíròrò àwọn nǹkan márùn-ún tó lè mú ká kọsẹ̀. Àwọn nǹkan márùn-ún náà ni kùdìẹ̀-kudiẹ wa, kí ọkàn ẹni máa fà sí ohun tí kò dára, ká máa rò pé nǹkan ò lọ bó ṣe yẹ nínú ìjọ, ìpọ́njú tàbí inúnibíni àti àìpé àwọn ẹlòmíì. Àmọ́, tá a bá kọsẹ̀, ẹ jẹ́ ká rántí pé Jèhófà máa ń ní sùúrù gan-an, kò sì ní yára kà wá sí aláìṣòótọ́ tàbí kó pa wá tì.

10, 11. Kí ni kùdìẹ̀-kudiẹ Dáfídì mú kó ṣe?

10 A lè fi kùdìẹ̀-kudiẹ wa wé àwọn òkúta wẹẹrẹ tó lè wà lójú ọ̀nà tí àwọn sárésáré ti ń sáré ìje. Kí ọ̀rọ̀ yìí lè yé wa dáadáa, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì Ọba àti àpọ́sítélì Pétérù nígbà kan. Tá a bá fara balẹ̀ wo ìtàn ìgbésí ayé àwọn méjèèjì yìí, a máa rí méjì lára irú àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ yìí, ìyẹn àìní ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìbẹ̀rù èèyàn.

11 Nítorí pé Dáfídì Ọba ò kó ara rẹ̀ níjàánu, ó ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Nábálì kàn án lábùkù, díẹ̀ ló kù kó gbéjà kò ó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì máa ń ṣe ohun tí kò tọ́ nígbà míì, kò dẹ́kun láti máa ṣe ohun tó wu Jèhófà. Torí ìrànlọ́wọ́ tó ń rí gbà lọ́dọ̀ àwọn míì, ó máa ń “dìde” ní gbogbo ìgbà tó bá ṣe àṣìṣe.—1 Sám. 25:5-13, 32, 33; 2 Sám. 12:1-13.

12. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ṣe àṣìṣe, kí ló mú kó máa sá eré ìje náà nìṣó?

12 Ìbẹ̀rù èèyàn máa ń mú kí Pétérù ṣe àṣìṣe nígbà míì. Síbẹ̀, kò kọ Jésù sílẹ̀, ó ń bá a nìṣó láti máa sin Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà mẹ́ta ni Pétérù sọ pé òun kò mọ Jésù. (Lúùkù 22:54-62) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó mú kí àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni rí ara wọn bíi pé wọ́n sàn ju àwọn Kèfèrí tó di Kristẹni lọ. Ohun tí Pétérù ṣe yẹn kò dára, ó sì lè mú káwọn míì bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ nínú ìjọ. Torí náà, Pọ́ọ̀lù bá a wí gidigidi. (Gál. 2:11-14) Ṣé ìyẹn wá mú kí ìgbéraga ru bo Pétérù lójú débi tí kò fi sá eré ìje náà mọ́? Rárá o. Ńṣe ló ronú  jinlẹ̀ lórí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, ó fara mọ́ ìbáwí náà, ó sì ń sá eré ìje náà nìṣó.

13. Báwo ni àìsàn ṣe lè mú ká kọsẹ̀?

13 Àìsàn máa ń mú kí ayé nira fúnni. Èyí sì ti mú kí àwọn kan dẹ́kun láti máa sá eré ìje náà. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínlógún tí arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Japan ti ṣèrìbọmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn, àìsàn náà sì bá a fínra gidigidi. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àníyàn tó ń ṣe nípa àìsàn náà mú kó di aláìṣedéédéé. Nígbà tó sì yá, ó di aláìṣiṣẹ́mọ́. Àwọn alàgbà méjì wá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá a sọ gbé e ró débi pé ó tún bẹ̀rẹ̀ sí wá sípàdé. Ó ní nígbà tí àwọn ará rí òun, wọ́n fọ̀yàyà kí òun, ìyẹn sì wú u lórí débi pé ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Arábìnrin wa yìí ti ń sá eré ìje náà nìṣó báyìí.

14, 15. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe bí ọkàn wa bá ń fà sí ohun tí kò dára? Ṣàpèjúwe.

14 Ọ̀pọ̀ èèyàn ti kọsẹ̀ torí pé ọkàn wọn ń fà sí ohun tí kò dára. Bí ọkàn wa bá ń fà sí ohun tí kò dára, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa kí èrò wa àti ìwà wa lè máa wà ní mímọ́ àti ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run. Jésù sọ pé bí ojú wa tàbí ọwọ́ wa bá ń mú wa kọsẹ̀, ńṣe ni ká “sọ ọ́ nù.” Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé ká má ṣe fàyè gba èròkerò àti ìṣekúṣe, torí pé wọ́n lè mú ká dẹ́kun láti máa sá eré ìje náà.—Ka Mátíù 5:29, 30.

15 Arákùnrin kan tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú òtítọ́ sọ pé látìgbà tí òun ti gbọ́njú ló ti máa ń wu òun láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin bíi tòun. Ó sọ pé òun kì í rẹ́ni fi ojú jọ, ara òun kì í sì í balẹ̀ tóun bá wà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Nígbà tó fi máa pé ọmọ ogún ọdún, ó ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ó sì tún jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ. Nígbà tó ṣe, ó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, wọ́n sì bá a wí. Lẹ́yìn náà, àwọn alàgbà ràn án lọ́wọ́. Ó ń gbàdúrà, ó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ń sapá láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Gbogbo èyí mú kó lè máa sá eré ìje náà nìṣó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pẹ́ tí gbogbo nǹkan yìí ti ṣẹlẹ̀ sí i, ó sọ pé: “Èrò yẹn ṣì máa ń wá sí mi lọ́kàn, àmọ́ mi ò kì í jẹ́ kó mú mi rẹ̀wẹ̀sì. Mo mọ̀ pé Jèhófà ò ní jẹ́ ká rí àdánwò tó ju agbára wa lọ. Torí náà, mo gbà pé Ọlọ́run mọ̀ pé mo lè kẹ́sẹ járí.” Arákùnrin yìí kò fẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ lẹ́nu eré ìje náà. Ó mọ̀ pé ohun yòówù kí òun fara dà ní báyìí, tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, torí ó mọ̀ pé òun máa gba ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun. Ó sọ pé: “Títí dìgbà náà, màá máa bá a nìṣó láti ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe.”

16, 17. (a) Kí ló ran arákùnrin kan lọ́wọ́ nígbà tó ronú pé àwọn kan ti hùwà àìdáa sí òun? (b) Tá ò bá fẹ́ kọsẹ̀, kí ló yẹ ká máa rántí?

16 A lè fa ìkọ̀sẹ̀ fún ara wa tá a bá ń ronú pé àwọn nǹkan ò lọ bó ṣe yẹ nínú ìjọ. Ní orílẹ̀-èdè Faransé, arákùnrin kan tó ti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà rí ronú pé àwọn kan nínú ìjọ ṣe àìdáa sí òun. Nítorí èyí, ó bínú gan-an, kò wá sí ìpàdé mọ́, kò sì lọ sóde ẹ̀rí mọ́. Àwọn alàgbà méjì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n fara balẹ̀ gbọ́ àlàyé rẹ̀ nípa oun tó sọ pé ó fà á. Lẹ́yìn náà, wọ́n rọ̀ ọ́ pé kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Wọ́n tún rán an létí pé ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kó máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run. Ó gba ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un, ó pa dà sínú ìjọ, ó sì ń sá eré ìje náà nìṣó.

17 Gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa rántí pé Jésù Kristi ni Ọlọ́run yan ṣe Orí ìjọ. Torí náà, kò yẹ ká máa ṣàníyàn nípa ohun táwọn èèyàn aláìpé ń ṣe. Bíbélì sọ pé Jésù ní ojú tó dà “bí ọwọ́ iná ajófòfò.” Èyí fi hàn pé ó mọ gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ ju ẹnikẹ́ni nínú wa lọ. (Ìṣí. 1:13-16) Bí àpẹẹrẹ, a lè ronú pé àwọn nǹkan ò lọ bó ṣe yẹ nínú ìjọ. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé àwa la ṣi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóye tàbí kó jẹ́ pé àwa la ò mọ ohun tó fà á tí ọ̀ràn fi rí bó ṣe rí. Bí ìṣòro èyíkéyìí bá wà nínú ìjọ, Jésù máa  yanjú rẹ̀ lọ́nà tó tọ́ àti nígbà tó bá yẹ. Torí náà, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohun tí ẹlòmíì bá ṣe sí wa nínú ìjọ mú ká kọsẹ̀.

18. Kí la lè ṣe tí a kò fi ní rẹ̀wẹ̀sì tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni bá dé?

18 Ohun méjì míì tó lè mú ká kọsẹ̀ ni ìpọ́njú tàbí inúnibíni àti àìpé àwọn míì nínú ìjọ. Nínú ìtàn tí Jésù sọ nípa ọkùnrin afúnrúgbìn kan, ó sọ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run kan máa kọsẹ̀ tí wọ́n bá dojú kọ “ìpọ́njú” tàbí tí wọ́n bá ṣe “inúnibíni” sí wọn. Àwọn ìbátan wa, àwọn aládùúgbò wa, tàbí ìjọba lè pọ́n wa lójú tàbí kí wọ́n ṣe inúnibíni sí wa torí pé à ń ṣe ohun tí Bíbélì fi kọ́ wa. Lábẹ́ irú ipò yẹn, ẹnì kan lè kọsẹ̀ bí kò bá “ní gbòǹgbò nínú ara rẹ̀.” Tàbí lédè mìíràn, bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò bá lágbára. (Mát. 13:21) Àmọ́, tá a bá pinnu láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù rẹ̀ máa mú kí ìgbàgbọ́ wa fìdí múlẹ̀ ṣinṣin. Torí náà, tá a bá wà nínú ìṣòro, ẹ jẹ́ ká máa ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun “tí ó yẹ fún ìyìn.” (Ka Fílípì 4:6-9.) Jèhófà máa ń fún wa lókun láti dojú kọ àdánwò, kí àwọn ipò tó lè koko má bàa mú ká kọsẹ̀.

Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ láti sá eré ìje náà dópin!

19. Kí ni kò ní jẹ́ ká kọsẹ̀ bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá?

19 Àwọn kan kò sin Jèhófà mọ́ torí àìpé àwọn ẹlòmíì. Ẹnì kan sì lè kọsẹ̀ torí pé àwọn míì ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn tirẹ̀ kò fàyè gbà. (1 Kọ́r. 8:12, 13) Bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá, ṣé inú máa bí wa débi pé a máa fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀? Bíbélì sọ fún wa pé ká má ṣe máa dáni lẹ́jọ́, àmọ́ ká máa dárí jini, kódà tá a bá tiẹ̀ rò pé ó yẹ ká bínú. (Lúùkù 6:37) Bí inú bá ń bí ẹ, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mi ò kì í sọ àwọn èèyàn di aláìmọ̀ọ́ṣe torí pé wọn kì í ṣe nǹkan lọ́nà tí mò ń gbà ṣe é? Ṣé mi ò ní fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀ nítorí àìpé àwọn tá a jọ jẹ́ ará?’ Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló máa jẹ́ ká tètè yanjú aáwọ̀ èyíkéyìí tí kò bá ní jẹ́ ká sá eré ìje ìyè náà dé òpin.

FI ÌFARADÀ SÁRÉ, MÁ ṢE KỌSẸ̀

20, 21. Kí lo pinnu pé wàá ṣe bó o ṣe ń sá eré ìje ìyè?

20 Ṣé ó wù ẹ́ láti sá “eré ìje náà dé ìparí”? (2 Tím. 4:7, 8) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde wa. Máa ṣe ìwádìí kó o sì máa ṣe àṣàrò kó o lè mọ àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó mú ẹ kọsẹ̀. Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sọ ẹ́ di alágbára. Rántí pé tó o bá ṣubú, o ṣì lè dìde, kó o sì máa sá eré ìje náà nìṣó, títí wàá fi sá a parí. Èyí fi hàn pé a lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àṣìṣe wa, ká sì túbọ̀ máa sapá bá a ṣe ń sá eré ìje ìyè náà.

21 Bíbélì fi hàn pé tá a bá fẹ́ gba èrè ìyè àìnípẹ̀kun, a gbọ́dọ̀ sá eré ìje náà títí dé ìparí. Bá a ṣe ń sá eré ìje náà, Jèhófà á máa fún wa ní “ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sm. 119:165) Yóò máa bá a nìṣó láti ràn wá lọ́wọ́ nísinsìnyí, yóò sì tún fún wa ní ìbùkún ayérayé tá a bá sá eré náà dópin.—Ják. 1:12.