Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ǹjẹ́ Ó Wù Ẹ́ Láti Mọ Jèhófà?

Ǹjẹ́ Ó Wù Ẹ́ Láti Mọ Jèhófà?

“Èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn-àyà láti mọ̀ mí, pé èmi ni Jèhófà; wọn yóò sì di ènìyàn mi.”—JER. 24:7.

1, 2. Kí nìdí tí àwọn kan fi fẹ́ràn èso ọ̀pọ̀tọ́?

ṢÉ O ti jẹ́ èso ọ̀pọ̀tọ́ rí? Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó gbé láyé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì máa ń jẹ èso ọ̀pọ̀tọ́ dáadáa. (Náh. 3:12; Lúùkù 13:6-9) Lóde òní, ọ̀pọ̀ ibi kárí ayé ni wọ́n ti ń gbin èso náà. Ó jẹ́ èso kan tó ní ọ̀pọ̀ èròjà tó máa ń ṣara lóore. Àwọn kan sọ pé ó máa ń jẹ́ kí ọkàn wa ṣiṣẹ́ dáadáa.

2 Nígbà kan tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó wà nínú ọkàn àwọn èèyàn, ó fi ọkàn wọn wé èso ọ̀pọ̀tọ́. Ohun tó sọ sì lè ran àwa àtàwọn èèyàn wa lọ́wọ́. Kì í ṣe pé Jèhófà ń sọ fún àwọn èèyàn nípa bí èso ọ̀pọ̀tọ́ ṣe lè ṣe ara wọn lóore. Ńṣe ló kàn fi àkàwé náà kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Bí a ó ṣe máa jíròrò ohun tó sọ, ronú nípa ẹ̀kọ́ tí àwa Kristẹni lè rí kọ́ níbẹ̀.

3. Kí ni èso ọ̀pọ̀tọ́ inú Jeremáyà orí 24 dúró fún?

3 Ní ọdún 617 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù tó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà ń ṣe ohun tí Jèhófà kò fẹ́. Torí náà, Ọlọ́run fi ìran kan han Jeremáyà nípa ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí wọn. Nínú ìran náà, Jeremáyà rí apẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀tọ́ méjì, èyí tó dúró fún àwùjọ àwọn èèyàn méjì. Àwọn ọ̀pọ̀tọ́ tó wà nínú apẹ̀rẹ̀ kìíní “dára gan-an,” àmọ́ àwọn ọ̀pọ̀tọ́ tó wà nínú apẹ̀rẹ̀ kejì “burú gan-an.” (Ka Jeremáyà 24:1-3.) Àwọn ọ̀pọ̀tọ́ tó burú yẹn dúró fún Sedekáyà Ọba àti àwọn míì bíi tiẹ̀ tí Nebukadinésárì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ máa tó wá gbéjà kò. Àmọ́, àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n dà bí àwọn ọ̀pọ̀tọ́ tó dára. Lára wọn ni Ìsíkíẹ́lì, Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n ti wà ní Bábílónì nígbà yẹn, àtàwọn Júù tí wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn nígbà tó yá. Lára àwọn Júù tí wọ́n kó lọ sígbèkùn yìí sì máa tó pa dà wá sí Jerúsálẹ́mù láti wá tún tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ kọ́.—Jer. 24:8-10; 25:11, 12; 29:10.

4. Kí nìdí tí ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn èèyàn rere tó wà ní Júdà fi mú wa lọ́kàn le?

4 Kí ni Jèhófà sọ nípa àwọn èèyàn rere tó wà ní Júdà? Ó sọ pé: “Èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn-àyà  láti mọ̀ mí, pé èmi ni Jèhófà; wọn yóò sì di ènìyàn mi.” (Jer. 24:7) Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ yìí mú wa lọ́kàn le torí ó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run fẹ́ ká ní ‘ọkàn-àyà láti mọ’ òun, ìyẹn ni pé ká jẹ́ ẹni tó ń fẹ́ láti mọ Ọlọ́run, kó sì wù wá láti wà lára àwọn èèyàn rẹ̀. Báwo la ṣe lè jẹ́ irú èèyàn bẹ́ẹ̀? Àwọn ohun tá a máa ṣe rèé ká tó lè jẹ́ irú èèyàn bẹ́ẹ̀. Ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká ronú pìwà dà, ká yí pa dà, ká ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ká sì ṣe ìrìbọmi ní orúkọ Baba, Ọmọ àti ẹ̀mí mímọ́. (Mát. 28:19, 20; Ìṣe 3:19) Ṣé o ti ṣe àwọn ohun tá a kà sílẹ̀ yìí? Tó bá sì jẹ́ pé o ti ń lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà déédéé, ǹjẹ́ ò ń fojú sọ́nà láti ṣe èyí tó kù tó ò tíì ṣe lára àwọn ohun tá a kà sílẹ̀ yẹn?

5. Àwọn wo ni Jeremáyà dìídì kọ̀wé sí?

5 Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé a ti ṣe gbogbo ohun tá a sọ ní ìpínrọ̀ kẹrin yẹn, a ṣì gbọ́dọ̀ máa kíyè sí ìṣesí wa àti ìwà wa. Kí nìdí? A máa rí ìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ka ohun tí Jeremáyà sọ nípa ọkàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ lára àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ sọ nípa àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Júdà ká. Àwọn olùgbé ilẹ̀ Júdà ló dìídì kọ̀wé sí, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dá lórí ìgbà tí márùn-ún lára àwọn ọba rẹ̀ ń ṣàkóso. (Jer. 1:15, 16) Èyí fi hàn pé àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà ni Jeremáyà ń bá sọ̀rọ̀. Nígbà ayé Mósè, àwọn èèyàn náà gbà pé ti Jèhófà làwọn á máa ṣe. (Ẹ́kís. 19:3-8) Nígbà ayé Jeremáyà pẹ̀lú, àwọn èèyàn náà sọ pé: “A ti wá sọ́dọ̀ rẹ, nítorí ìwọ, Jèhófà, ni Ọlọ́run wa.” (Jer. 3:22) Àmọ́, ṣé wọ́n ní ọkàn tó dára?

Ó YẸ KÍ WỌ́N ṢÀYẸ̀WÒ OHUN TÓ WÀ LỌ́KÀN WỌN

6. Kí nìdí tó fi yẹ kó wù wá láti mọ ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ọkàn ìṣàpẹẹrẹ?

6 Àwọn dókítà òde òní lè fi ẹ̀rọ ṣàyẹ̀wò ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara ẹnì kan kí wọ́n sì mọ̀ bóyá ọkàn rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Àmọ́, Jèhófà lè rí ju ìyẹn lọ. Ó lè rí ohun tó wà nínú ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa. Ó sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n? Èmi, Jèhófà, ń wá inú ọkàn-àyà, . . . láti fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú èso ìbálò rẹ̀.” (Jer. 17:9, 10) Ọlọ́run mọ ohun tá a fẹ́, bá a ṣe ń ronú, bí ọ̀rọ̀ ṣe ń rí lára wa, ìwà wa àti ohun tá a fẹ́ fi ìgbésí ayé wa ṣe. Ọlọ́run máa ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú ọkàn rẹ. Ìwọ pẹ̀lú sì lè ṣe bẹ́ẹ̀, dé ìwọ̀n àyè kan.

7. Kí ni Jeremáyà sọ nípa ọkàn èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Júù ìgbà ayé rẹ̀?

7 A gbọ́dọ̀ máa ṣàyẹ̀wò ohun tó wà lọ́kàn wa. Báwo ni ọkàn ìṣàpẹẹrẹ èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà ṣe rí? Gbọ́ ohun tí Jeremáyà sọ. Ó ní: “Gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì jẹ́ aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà.” Èyí kì í ṣe ìdádọ̀dọ́ tí Òfin sọ pé kí àwọn Júù tó jẹ́ ọkùnrin máa ṣe. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù yìí dádọ̀dọ́, Jèhófà sọ pé wọ́n ṣì “wà ní ipò àìdádọ̀dọ́ síbẹ̀,” ìyẹn ni pé, wọ́n jẹ́ “aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà.” (Jer. 9:25, 26) Kí wá ni ìyẹn túmọ̀ sí?

8, 9. Nígbà ayé Jeremáyà, kí ló wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn Júù? Kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe?

8 Ọlọ́run sọ ohun tí àwọn Júù yẹn gbọ́dọ̀ ṣe fún wọn. Ohun tó sọ fún wọn yẹn sì wá jẹ́ ká lóye ìdí tó fi pè wọ́n ní “aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà.” Jèhófà sọ fún wọn pé kí wọ́n mú ìwà búburú kúrò nínú ọkàn wọn. Lẹ́yìn náà, ó ṣàlàyé ìdí tó fi fẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Kí ìhónú mi má bàa jáde lọ . . . ní tìtorí búburú ìbálò yín.” Èyí jẹ́ ká rí i pé ohun tó mú kí wọ́n máa ṣàìgbọràn sí Jèhófà ni pé ohun búburú ló wà lọ́kàn wọn. (Ka Máàkù 7:20-23.) Wọ́n ya ọlọ̀tẹ̀, wọ́n sì kọ̀ láti yí pa dà. Èrò ọkàn  wọn àti ìwà wọn burú lójú Jèhófà. (Ka Jeremáyà 5:23, 24; 7:24-26.) Ọlọ́run sọ bí wọ́n ṣe lè yí pa dà fún wọn, ó ní: “Ẹ dá ara yín ládọ̀dọ́ fún Jèhófà, kí ẹ sì gé adọ̀dọ́ ọkàn-àyà yín kúrò.”—Jer. 4:4; 18:11, 12.

9 Ńṣe lọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà ayé Jeremáyà dà bí ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́, tí wọ́n sì ní láti ṣiṣẹ́ abẹ fún. Irú ìṣòro táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní nígbà ayé Mósè náà nìyẹn. (Diu. 10:16; 30:6) Báwo làwọn Júù ṣe lè “gé adọ̀dọ́ ọkàn-àyà” wọn “kúrò”? Ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí wọ́n mú èrò tàbí ìfẹ́ ọkàn èyíkéyìí tó ń mú kí wọn ṣá òfin Jèhófà tì kúrò nínú ọkàn wọn.—Ìṣe 7:51.

BÁ A ṢE LÈ MỌ JÈHÓFÀ LÓNÌÍ

10. Báwo ni Dáfídì ṣe ṣàyẹ̀wò ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀? Báwo la ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì?

10 Ó yẹ ká máa dúpẹ́ pé Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe fún wa láti mọ ohun tí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ túmọ̀ sí. Ṣùgbọ́n àwọn kan lè máa ṣe kàyéfì nípa bí ohun tá à ń kọ́ nípa ọkàn ìṣàpẹẹrẹ yìí ṣe kan àwa ìránṣẹ́ Jèhófà. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, tí wọ́n sì ń hùwà tó dára. Kò sí ohun tó fi hàn pé wọ́n ti ń di “ọ̀pọ̀tọ́” tí kò dára. Ṣùgbọ́n ká má ṣe gbàgbé pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni Dáfídì, síbẹ̀ ó bẹ Jèhófà pé: “Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn-àyà mi. Wádìí mi wò, kí o sì mọ àwọn ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè, kí o sì rí i bóyá ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára wà nínú mi.”—Sm. 17:3; 139:23, 24.

11, 12. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣàyẹ̀wò ohun tó wà lọ́kàn wa? (b) Kí la ò gbọ́dọ̀ retí pé kí Jèhófà ṣe?

11 Jèhófà fẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa mọ òun. Lédè mìíràn, ó fẹ́ ká jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ òun, kò sì fẹ́ kí ohunkóhun fà wá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Jeremáyà sọ pé Jèhófà máa ń wádìí àwọn olódodo wò àti pé ó ń rí “kíndìnrín àti ọkàn-àyà.” (Jer. 20:12) Bí Jèhófà bá ń ṣàyẹ̀wò ọkàn àwọn tó jẹ́ olódodo, ǹjẹ́ kò ní dára kí gbogbo wa ṣàyẹ̀wò ọkàn wa ká lè mọ ohun tó wà níbẹ̀ gan-an? (Ka Sáàmù 11:5.) Tá a bá fi òótọ́ inú ṣàyẹ̀wò ohun tó wà lọ́kàn wa, ó ṣeé ṣe ká rí i pé àwọn èrò tí kò tọ́ ti fara pa mọ́ síbẹ̀. A lè rí i pé a ti ń ní àwọn àfojúsùn kan tí kò dára àti pé ìwà wa àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa ń fẹ́ àbójútó. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe la máa ń lọ́ra láti ṣègbọràn sí Jèhófà. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ńṣe lọ̀rọ̀ wa dà bíi tẹni tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ abẹ fún kí ọkàn rẹ̀ lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Iṣẹ́ abẹ ìṣàpẹẹrẹ yìí ló máa jẹ́ ká mú àwọn ohun búburú yẹn kúrò lọ́kàn wa. Kí wá ni díẹ̀ lára àwọn ìwà tàbí ìmọ̀lára tí kò tọ́ tó ṣeé ṣe kó wà nínú ọkàn wa? Kí la lè ṣe nípa irú àwọn ìwà tàbí ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀?—Jer. 4:4.

12 Ohun kan tó dájú ni pé Jèhófà ò ní mú ká yí pa dà tipátipá. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ nípa “àwọn ọ̀pọ̀tọ́ tí ó dára náà” pé òun máa ‘fún wọn ní ọkàn-àyà láti mọ’ òun. Kò sọ pé òun máa fi tipátipá yí wọn lọ́kàn pa dà. Èyí tó fi hàn pé wọ́n gbọ́dọ̀ pinnu lọ́kàn ara wọn pé àwọn fẹ́ láti mọ  Ọlọ́run, ohun tó sì yẹ kí àwa náà ṣe nìyẹn.

Ṣàyẹ̀wò ọkàn rẹ, mú èròkerò tó bá wà níbẹ̀ kúrò, kó o lè rí ìbùkún Ọlọ́run

13, 14. Báwo ni ohun tó wà nínú ọkàn Kristẹni kan ṣe lè jẹ́ ewu fún un?

13 Jésù sọ pé: “Láti inú ọkàn-àyà ni àwọn èrò burúkú ti ń wá, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, àwọn èké gbólóhùn ẹ̀rí, àwọn ọ̀rọ̀ òdì.” (Mát. 15:19) Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá ń ro èròkerò, ó lè ṣe panṣágà tàbí àgbèrè. Bí kò bá ronú pìwà dà, kò ní rí ojúure Ọlọ́run mọ́ títí láé. Àmọ́, bí kò bá tiẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, èròkerò ṣì lè máa gbilẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀. (Ka Mátíù 5:27, 28.) Torí náà, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé a kò fàyè gba èròkerò nínú ọkàn wa. Ṣé o kì í ronú ṣáá nípa ẹnì kan tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ lọ́nà tí Ọlọ́run kò fẹ́? Ṣé èrò kan wà tó yẹ kó o mú kúrò lọ́kàn rẹ?

14 Bákan náà, bí Kristẹni kan kò bá ṣọ́ra, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí bínú sí arákùnrin tàbí arábìnrin kan títí tó fi máa kórìíra rẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀. (Léf. 19:17) Ó yẹ kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ sapá gidigidi láti mú irú èrò bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn.—Mát. 5:21, 22.

15, 16. (a) Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè di “aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà”? (b) Kí lo rò pé ó fà á tí Jèhófà ò fi fẹ́ ká jẹ́ “aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà”?

15 Ọ̀pọ̀ Kristẹni kì í fàyè gba irú èrò yìí nínú ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n, Jésù tún sọ̀rọ̀ nípa “àwọn èrò burúkú.” Bí àpẹẹrẹ, a lè máa ronú pé àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn ìbátan wa ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn lọ. Òótọ́ ni pé Bíbélì gba àwa Kristẹni níyànjú pé ká fẹ́ràn àwọn ìbátan wa, ká má sì dà bí àwọn tó wà nínú ayé lónìí, tí wọn kò ní “ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tím. 3:1, 3) Àmọ́, àṣejù lè wọ ìfẹ́ tá a ní sí àwọn ìbátan wa. Lọ́nà wo? Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé “okùn ọmọ ìyá yi.” Torí náà, bí ẹnì kan bá ṣẹ èèyàn wọn kan, ńṣe ni wọ́n máa gbà á kanrí. Ọ̀rọ̀ wọn wá dà bíi ti àwọn ẹ̀gbọ́n Dínà tí wọ́n fárígá torí pé Ṣékémù fipá bá àbúrò wọn lò pọ̀. Látàrí ìyẹn, wọ́n pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin. (Jẹ́n. 34:13, 25-30) Bákan náà, èrò búburú tó wà lọ́kàn Ábúsálómù mú kó pa Ámínónì. (2 Sám. 13:1-30) Gbogbo èyí mú kó ṣe kedere pé “èrò burúkú” léwu gan-an ni.

16 Àwọn kan máa ń bínú gan-an téèyàn bá ṣẹ èèyàn wọn kan tàbí tí wọ́n bá ronú pé ẹnì kan ṣẹ èèyàn wọn. Kí ni wọ́n sábà máa ń ṣe fún irú ẹni bẹ́ẹ̀? Wọn ò ní fẹ́ láti bá onítọ̀hún da nǹkan pọ̀ mọ́. (Héb. 13:1, 2) Ọ̀ràn kékeré kọ́ ni kéèyàn máa gbé ìbínú sọ́kàn tàbí kó má ṣe bá ẹlòmíì dá nǹkan pọ̀ mọ́, torí irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò fi ìfẹ́ hàn. Bí Jèhófà tó  ń ṣàyẹ̀wò ọkàn bá rí èrò tí kò tọ́ yìí nínú ọkàn wa, ohun tó máa sọ ni pé “aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà” ni wá. (Jer. 9:25, 26) Ẹ má sì jẹ́ ká gbàgbé ohun tí Jèhófà sọ fún àwọn Júù yẹn. Ó ní kí wọ́n ‘gé adọ̀dọ́ ọkàn-àyà wọn kúrò.’—Jer. 4:4.

BÁ A ṢE LÈ MÁA BÁ A NÌṢÓ LÁTI MỌ ỌLỌ́RUN

17. Báwo ni ìbẹ̀rù Jèhófà ṣe máa mú kó rọrùn fún wa láti yí ohun tó wà lọ́kàn wa pa dà?

17 Tó o bá ṣàyẹ̀wò ohun tó wà lọ́kàn rẹ, o ṣeé ṣe kó o rí i pé o kì í tètè pa àwọn ìtọ́ni Jèhófà mọ́. Ó lè jẹ́ pé o ti di “aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà” láwọn ọ̀nà kan. O lè rí i pé ẹ̀rù máa ń bà ẹ́ torí ohun táwọn míì á máa rò nípa rẹ. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o di olókìkí tàbí olówó rẹpẹtẹ. O lè rí i pé o lágídí tàbí kó wù ẹ́ láti máa ṣe tinú ẹ. Bí ọ̀rọ̀ àwọn míì náà ṣe rí nìyẹn. (Jer. 7:24; 11:8) Jeremáyà sọ pé àwọn Júù aláìṣòótọ́ ìgbà ayé rẹ̀ “ní ọkàn-àyà agídí àti ọ̀tẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn, tó sì ń fún wọn ní gbogbo nǹkan tí wọ́n ṣaláìní, síbẹ̀ wọn kò “bẹ̀rù Jèhófà.” (Jer. 5:23, 24) Tá a bá ní ìbẹ̀rù Jèhófà, ìyẹn ni pé, tá a bá ń bọ̀wọ̀ fún un, a máa mú àwọn nǹkan búburú kúrò ní ọkàn wa. Ìbẹ̀rù Jèhófà á tún mú kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti yí ohun tó wà lọ́kàn wa pa dà ká sì ṣe ohunkóhun tí Jèhófà bá sọ pé ká ṣe.

18. Kí ni Jèhófà sọ pé òun máa ṣe fún àwọn tó bá dá májẹ̀mú tuntun?

18 Bí a ṣe ń sa gbogbo ipá wa, Jèhófà máa fún wa ní “ọkàn-àyà láti mọ̀” ọ́n. Ohun tó sọ pé òun máa ṣe fún àwọn ẹni àmì òróró tó bá dá májẹ̀mú tuntun nìyẹn. Ó sọ pé: “Èmi yóò fi òfin mi sínú wọn, inú ọkàn-àyà wọn sì ni èmi yóò kọ ọ́ sí. Èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn, àwọn fúnra wọn yóò sì di ènìyàn mi.” Ó tún sọ síwájú sí i pé: “Olúkúlùkù wọn kì yóò sì tún máa kọ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, àti olúkúlùkù wọn arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Jèhófà!’ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí, láti orí ẹni tí ó kéré jù lọ nínú wọn àní dé orí ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú wọn . . . Nítorí èmi yóò dárí ìṣìnà wọn jì, ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́.”—Jer. 31:31-34. *

19. Ohun àgbàyanu wo làwa Kristẹni ń fojú sọ́nà fún?

19 À ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí máa ní ìmúṣẹ. Ó yẹ kó máa wu gbogbo wa láti mọ Jèhófà ká sì wà lára àwọn èèyàn rẹ̀. Ó máa ṣeé ṣe fún wa láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà títí ayérayé nígbà tí Ọlọ́run bá dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi. Níwọ̀n bí Jèhófà ti ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ máa dárí ji àwọn ẹlòmíì, bó bá tiẹ̀ dà bíi pé ó ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀. A gbọ́dọ̀ sapá gidigidi láti mú ìbínú àti ìkórìíra kúrò lọ́kàn wa. Èyí á mú ká fi hàn pé a fẹ́ láti sin Jèhófà, a sì fẹ́ láti túbọ̀ mọ̀ ọ́n. A máa dà bí àwọn tí Jèhófà sọ fún pé: “Ẹ óò wá mi, ẹ ó sì rí mi, nítorí ẹ ó fi gbogbo ọkàn-àyà yín wá mi. Dájúdájú, èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ rí mi.”—Jer. 29:13, 14.

^ ìpínrọ̀ 18 Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa májẹ̀mú tuntun náà wà ní orí 14 nínú ìwé náà, Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà.