Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  February 2013

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọkàn Rẹ Tàn Ẹ́ Jẹ

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọkàn Rẹ Tàn Ẹ́ Jẹ

Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jer. 17:9) Tí ohun kan bá wù wá gan-an láti ṣe, ǹjẹ́ kì í ṣe gbogbo ọ̀nà la ó fi wá bá a ṣe máa ṣe é?

Bíbélì jẹ́ ká rí ìdí tí kò fi yẹ kó jẹ́ pé ohunkóhun tó bá ṣáà ti wá sí wa lọ́kàn la ó máa ṣe. Ìwé Mátíù 15:19 sọ pé: “Láti inú ọkàn-àyà ni àwọn èrò burúkú ti ń wá, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, àwọn èké gbólóhùn ẹ̀rí, àwọn ọ̀rọ̀ òdì.” Ọkàn wa lè tàn wá jẹ, kó sì mú ká máa wí àwíjàre nígbà tá a bá fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́. Lẹ́yìn tá a bá ṣe nǹkan ọ̀hún tán la máa wá rí i pé a ti ṣe àṣìṣe ńlá. Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá ohun tó tọ́ ló wà lọ́kàn wa, kó má lọ di pé ọkàn wa á ṣì wá lọ́nà?

BÁWO LO ṢE LÈ MỌ OHUN TÓ WÀ LỌ́KÀN RẸ?

Tá a bá ń ka Bíbélì déédéé, báwo ló ṣe lè jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn wa?

Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tó o bá kà.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Héb. 4:12) Nígbà tá a bá ń ka Bíbélì, ó yẹ ká máa ṣàyẹ̀wò èrò àti ìwà wa. Èyí jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Torí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ ká sì máa ṣàṣàrò. Àṣàrò gba pé kéèyàn ronú jinlẹ̀ dáadáa lórí ohun tó bá kà, ìyẹn ló sì máa mú kí ìrònú wa bá ti Jèhófà mu.

Tá a bá ń fi àwọn ìmọ̀ràn àti ìlànà Bíbélì sílò, ẹ̀rí ọkàn wa á máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Ńṣe ni ẹ̀rí ọkàn wa dà bí ohùn kan tó ń bá wa sọ̀rọ̀ láti inú wa. Ó lè sọ fún wa pé ohun tá a fẹ́ ṣe kò dára, kò sì ní jẹ́ ká máa  wí àwíjàre nígbà tá a bá fẹ́ ṣe ohun tí kò dára. (Róòmù 9:1) Ní àfikún sí ìyẹn, ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì tó jẹ́ “ìkìlọ̀” fún wa. (1 Kọ́r. 10:11) Tá a bá fi àwọn àpẹẹrẹ yìí ṣe àríkọ́gbọ́n, a ò ní máa ṣe àwọn ìpinnu tí kò tọ́. Kí ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe?

Àdúrà máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn wa

Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ohun tó tọ́ ló wà lọ́kàn rẹ.

Jèhófà jẹ́ “olùṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà.” (1 Kíró. 29:17) Ó “tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Jòh. 3:20) Kò sí ohun tó pa mọ́ lójú Ọlọ́run. Tá a bá fi tọkàntọkàn sọ àníyàn ọkàn wa fún Jèhófà, tá a sì jẹ́ kó mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa, ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè mọ̀ bóyá ohun tó tọ́ ló wà lọ́kàn wa. A tiẹ̀ lè bẹ Ọlọ́run pé kó ‘dá ọkàn mímọ́ sínú wa.’ (Sm. 51:10) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà tá a bá fẹ́ mọ̀ bóyá èrò tó tọ́ ló wà lọ́kàn wa.

Àwọn nǹkan tí à ń gbọ́ nípàdé máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn wa

Máa tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nígbà tó o bá wà ní ìpàdé.

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nígbà tá a bá wà nípàdé? Ìdí ni pé ó máa jẹ́ ká lè máa fi òótọ́ inú ṣàyẹ̀wò ohun tó wà lọ́kàn wa. Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo ìgbà la máa ń rí nǹkan tuntun kọ́ nípàdé. Àmọ́ tá a bá ń lọ sípàdé déédéé, a óò túbọ̀ máa lóye àwọn ìlànà Bíbélì. Ibẹ̀ la ti máa gba àwọn ìránnilétí tó máa jẹ́ ká lè mọ̀ bóyá ohun tó tọ́ ló wà lọ́kàn wa, a ó sì lè ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ. Ìdáhùn àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tún lè ràn wá lọ́wọ́. (Òwe 27:17) Àmọ́, tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìpàdé jẹ, tara wa nìkan la ó máa gbọ́, ìyẹn sì lè mú ká ṣe àwọn ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu. (Òwe 18:1) Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mo máa ń lọ sípàdé déédéé? Bí mo bá lọ sípàdé, ǹjẹ́ mo máa ń fetí sílẹ̀ kí n lè rí ẹ̀kọ́ kọ́?’—Héb. 10:24, 25.

BÁWO NI ỌKÀN WA ṢE MÁA Ń TÀN WÁ JẸ?

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni ọkàn wa lè gbà tàn wá jẹ. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò mẹ́rin lára wọn: ìlépa àwọn nǹkan tara, ọtí líle, àwọn tá a yàn lọ́rẹ̀ẹ́ àti eré ìdárayá.

Ìlépa àwọn nǹkan tara.

Gbogbo wa la nílò oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé. Kò sí ohun tó burú nínú pé kéèyàn ní wọn. Àmọ́, Jésù kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe máa ka àwọn nǹkan tara sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé wa. Jésù sọ ìtàn ọkùnrin kan tó fi oríṣiríṣi oúnjẹ kún inú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ rẹ̀. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé kò sáyè mọ́ tó máa kó àwọn irè oko sí nígbà ìkórè tó ń bọ̀. Ọkùnrin náà wá pinnu pé ńṣe lòun máa wó ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí yẹn, tí òun á sì kọ́ òmíràn tí ó tóbi dáadáa ju ìyẹn lọ. Ó wá sọ pé: “Ibẹ̀ ni èmi yóò sì kó gbogbo ọkà mi jọ sí àti gbogbo àwọn ohun rere mi; ṣe ni èmi yóò sọ fún ọkàn mi pé: ‘Ọkàn, ìwọ ní ọ̀pọ̀ ohun rere tí a tò jọ pa mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn.’” Àmọ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yìí kò rántí pé ẹ̀mí òun lè bọ́ ní òru ọjọ́ yẹn. Gbogbo èrò rẹ̀ á sì wá dòfo.—Lúùkù 12:16-20.

Bí a ṣe ń dàgbà sí i, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe wàhálà púpọ̀ láti kó owó àtàwọn nǹkan tara púpọ̀ jọ, èyí tá a ronú pé ó máa jẹ́ àbọ̀wábá nígbà tí ọjọ́ ogbó bá dé. Èyí lè bá wa débi tí a ó fi máa pa àwọn ìpàdé jẹ nítorí iṣẹ́ àṣejù, tí a kò sì ní máa lọ sí òde ẹ̀rí déédéé. Ó sì lè mú ká pa àwọn ojúṣe wa tì lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni ẹ́ ńkọ́, tó o sì gbà pé iṣẹ́  aṣáájú-ọ̀nà jẹ́ ohun tó dára gan-an téèyàn lè fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe? Ṣé o kì í ronú pé ó dìgbà tó o bá kọ́kọ́ kó owó jọ dáadáa ná kó o tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà? Ǹjẹ́ kò yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe nísinsìnyí ká bàa lè ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Àbí, ta ló lè sọ nínú wa bóyá ilẹ̀ ọ̀la máa mọ́ bá òun?

Ọtí líle.

Ìwé Òwe 23:20 sọ pé: ‘Má ṣe wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri.’ Tó o bá fẹ́ràn láti máa mu ọtí líle, o lè máa ṣe àwáwí nípa ìdí tó o fi ń mu ọtí nígbà gbogbo. Bí àpẹẹrẹ, o lè máa sọ pé: ‘Mi ò kí ń mu ún ní àmupara. Mo kàn fi ń gbádùn ẹ̀mí mi ni.’ Tó bá jẹ́ pé ọtí lo fi ń pàrònú rẹ́ tàbí tó o fi ń gbádùn ẹ̀mí rẹ, a jẹ́ pé ó yẹ kó o fòótọ́ inú ṣàyẹ̀wò ohun tó wà lọ́kàn rẹ.

Àwọn tá a yàn lọ́rẹ̀ẹ́.

Ojoojúmọ́ là ń bá àwọn tí kì í ṣe olùjọ́sìn Jèhófà pàdé. Ó lè jẹ́ ní iléèwé, níbi iṣẹ́ tàbí lóde ẹ̀rí. Àmọ́, kò dára ká máa bá wọn ṣe wọléwọ̀de tàbí ká sọ wọ́n di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. A lè máa sọ pé wọ́n dáa léèyàn, wọ́n sì ṣe ọmọlúwàbí. Àmọ́, ká má bàa di ẹni tá a ṣì lọ́nà, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́r. 15:33) Bí ìdọ̀tí kékeré ṣe lè sọ omi tó mọ́ di ẹlẹ́gbin, bẹ́ẹ̀ náà ni àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ṣe lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. A wá lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bíi tiwọn, ká máa múra bíi tiwọn, ká máa sọ̀rọ̀ bíi tiwọn, ká sì máa hùwà bíi tiwọn.

Eré ìdárayá.

Lóde òní, ṣàṣà ni eré ọwọ́dilẹ̀ téèyàn ò lè ṣe lórí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nínú àwọn eré náà ni kò yẹ kí àwa Kristẹni máa ṣe. Kódà, Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo láàárín yín.’ (Éfé. 5:3) Àmọ́ tó bá ń wù wá ká máa gbọ́ ọ̀rọ̀ rírùn tàbí ká máa wo àwọn ohun àìmọ́ ńkọ́? A lè ronú pé gbogbo èèyàn ló nílò eré ìdárayá àti fàájì níwọ̀nba, ó sì wà lọ́wọ́ kálukú láti yan irú èyí tó máa ṣe àti bó ṣe máa ṣe é. Àmọ́, ó dára ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ní gbogbo ìgbà. Ká má ṣe jẹ́ kí ojú wa máa wo ohun àìmọ́ kankan, ká má sì ṣe máa tẹ́tí gbọ́ wọn.

KÒ TÍÌ PẸ́ JÙ LÁTI ṢE ÀTÚNṢE

Ká sọ pé ọkàn wa ti ṣì wá lọ́nà, tá a sì máa ń wí àwíjàre tá a bá ṣe àwọn nǹkan búburú, kò tíì pẹ́ jù láti ṣe àtúnṣe o! (Éfé. 4:22-24) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì.

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Miguel * tún èrò rẹ̀ pa nípa àwọn nǹkan tara. Ó sọ pé: “Ní orílẹ̀-èdè tí èmi, ìyàwó mi àti ọmọ wa ọkùnrin ń gbé, àwọn èèyàn sábà máa ń fẹ́ láti ra àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, ọ̀pọ̀ ló sì ń gbé ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ra gbogbo nǹkan ìgbàlódé tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, mo sì máa ń ronú pé ìyẹn ò ní kí n má ṣe déédéé nípa tẹ̀mí. Àmọ́, kò pẹ́ rárá tí mo fi rí i pé ohun tí mò ń ṣe yẹn ò bójú mu. Torí náà, mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè yí èrò mi pa dà. Mo sọ fún un pé ó wu èmi àti ìdílé mi láti máa sìn ín tọkàntọkàn. A wá pinnu láti jẹ́ kí nǹkan tara díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, a sì lọ sí ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Nígbà tó ṣe, a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. A ti wá rí i báyìí pé kò pọn dandan ká kó àwọn nǹkan tara jọ ká tó lè gbádùn ayé wa.”

Ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Lee. Ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ ló ń kó ní tiẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa fara balẹ̀ ronú lórí ohun tó wù wá àti ohun tá à ń ṣe. Ìgbà gbogbo ni Lee àtàwọn tí wọ́n jọ dòwò pọ̀ máa ń ṣèpàdé, wọ́n sì máa ń mutí yó kẹ́ri lẹ́yìn ìpàdé náà. Síbẹ̀ kò lè ṣe kó má lọ síbi tí wọ́n ti ń pàdé. Ó sábà máa ń mutí yó, á wá máa dùn ún nígbà tí ojú rẹ̀ bá wálẹ̀. Ó wá rí i pé ó pọn dandan pé kí òun ṣàyẹ̀wò ohun tó wà lọ́kàn òun. Ó sọ pé: “Ìmọ̀ràn Bíbélì àti àwọn àbá táwọn alàgbà fún mi jẹ́ kí n rí i pé ohun tó kó mi sí wàhálà ni pé àwọn tí kò fẹ́ràn Jèhófà ni mò ń bá rìn.” Dípò tí arákùnrin yìí ì bá fi máa ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tó ń bá dòwò pọ̀, bó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀, orí fóònù ló ti ń bá ọ̀pọ̀ nínú wọn dúnàádúrà báyìí.

Kò yẹ ká máa tan ara wa jẹ rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká fi òótọ́ inú yẹ ara wa wò ká lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Báwo la ṣe lè yẹ ara wa wò? Ọ̀nà kan ni pé ká gbàdúrà sí Jèhófà torí pé òun ló “mọ àwọn àṣírí ọkàn-àyà.” (Sm. 44:21) Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún lè ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá ń kà á, ńṣe ló máa dà bíi pé à ń wo ara wa nínú dígí, èyí sì máa jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. (Ják. 1:22-25) Jèhófà tún máa ń fún wa ní àwọn ìtọ́ni tó ṣeyebíye nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa àti láwọn ìpàdé wa. Àwọn ọ̀nà yìí ni Jèhófà gbà ń ràn wá lọ́wọ́ láti dáàbò bo ọkàn wa ká lè máa ṣe ohun tó tọ́.

^ ìpínrọ̀ 18 A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.